ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 7/15 ojú ìwé 28-30
  • Báwo Ni Kàlẹ́ńdà Àwọn Ju Ti Péye Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Kàlẹ́ńdà Àwọn Ju Ti Péye Tó?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Ìbẹ̀rẹ̀ Rẹ̀ Lélẹ̀
  • “Sànmánnì Ìṣẹ̀dá”
  • Ibi tí A Gbé Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ọjọ́ Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ náà Kà
  • Àwọn Ìtàn Àtọwọ́dọ́wọ́ àti Àwọn Ìtumọ̀
  • Ohun Ìrántí ti Ìsìn
  • Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ọrọ-Afikun si Ori 14
    “Kí Ijọba Rẹ Dé”
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 7/15 ojú ìwé 28-30

Báwo Ni Kàlẹ́ńdà Àwọn Ju Ti Péye Tó?

NÍ ÌBÁMU pẹ̀lú kàlẹ́ńdà àwọn Ju, Thursday, September 16, 1993, ní ọjọ́ àjọ̀dún Rosh Hashanah. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, shofar, tàbí kàkàkí tí a fi ìwo àgbò ṣe, ni a óò fun láti polongo ọdún titun náà tí ó wọlé dé. Ọdún náà jẹ́ 5754 (kàlẹ́ńdà àwọn Ju), ó sì bẹ̀rẹ̀ láti September 16, 1993, sí September 5, 1994.

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a kíyèsí pé ìyàtọ̀ 3,760 ọdún wà láàárín ọ̀nà tí àwọn Ju gbà ń ka àkókò àti ti àwọn ará Ìwọ̀-Oòrùn, tàbí ti Gregory, kàlẹ́ńdà tí ìlò rẹ̀ wọ́pọ̀ nísinsìnyí. Èéṣe tí ìyàtọ̀ yìí fi wà? Àti pé báwo ni kàlẹ́ńdà àwọn Ju ti péye tó?

Fífi Ìbẹ̀rẹ̀ Rẹ̀ Lélẹ̀

Ọ̀nà ìgbà ka àkókò èyíkéyìí gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pàtó tàbí ọ̀gangan ìtọ́kasí. Fún àpẹẹrẹ, Kristẹndọm ń ka àkókò láti ọdún tí wọ́n lérò pé a bí Jesu Kristi. Àwọn déètì láti ìgbà náà ni a sọ pé ó jẹ́ tí sànmánnì Kristian. Àwọn ni a sábà máa ń fi ìkékúrú náà A.D. sàmì sí, láti inú ọ̀rọ̀ Latin náà anno Domini, tí ó túmọ̀sí “ní ọdún Oluwa.” Àwọn déètì ṣáájú ìgbà yẹn ni a sàmì B.C., “Ṣáájú Kristi” sí.a Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn ará China bákan náà ń ka àkókò láti 2698 B.C.E., ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso ìtàn àròsọ Huang-Ti, Olú-Ọba Ìyeyè. Nípa báyìí, February 10, 1994, sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ 4692 ọdún òṣùpá ti àwọn ará China. Bí ó ti wù kí ó rí, níti kàlẹ́ńdà àwọn Ju ńkọ́?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Jewish Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀nà tí àwọn Ju máa ń sábà lò báyìí ní kíkọ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ni láti sọ iye ọdún tí ó ti kọjá láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé.” Ọ̀nà yìí, tí a mọ̀ láàárín àwọn Ju sí Sànmánnì Ìṣẹ̀dá wá di lílò lọ́nà wíwọ́pọ̀ ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹsàn-⁠án C.E. Nípa báyìí, àmì A.M. máa ń sábà ṣíwájú àwọn déètì nínú kàlẹ́ńdà àwọn Ju. Ó dúró fún anno mundi, tíí ṣe ìkékúrú ab creatione mundi, tí ó túmọ̀sí “láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé.” Níwọ̀n bí ọdún yìí ti jẹ́ A.M. 5754, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà yìí fún kíka àkókò, “ìṣẹ̀dá ayé” ni a gbà pé ó ti wáyé ní 5,753 ọdún sẹ́yìn. Jẹ́ kí á wo bí a ti dórí ìpinnu yìí.

“Sànmánnì Ìṣẹ̀dá”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica (1971) pèsè àlàyé yìí: “Nínú onírúurú ìṣirò àwọn rabbi ‘Sànmánnì Ìṣẹ̀dá’ bẹ̀rẹ̀ nígbà ìrúwé ọ̀kan nínú àwọn ọdún tí ó wà láàárín 3762 àti 3758 B.C.E. Bí ó ti wù kí ó rí, láti ọ̀rúndún kejìlá C.E., ó di ìtẹ́wọ́gbà pé ‘Sànmánnì Ìṣẹ̀dá’ bẹ̀rẹ̀ ní 3761 B.C.E. (ní pàtó, ní Oct. 7 ọdún yẹn). Ìṣirò náà ni a gbéka ìṣekòńgẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìdí tí Bibeli mẹ́nukàn àti àwọn ìṣirò tí a rí nínú ìwé ìjímìjí àwọn Ju tí a kọ lẹ́yìn kíkọ Bibeli.”

Ọ̀nà kíka ọjọ́ láti ìgbà “ìṣẹ̀dá ayé” ní pàtàkì ni a gbékarí bí àwọn rabbi ṣe túmọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ Bibeli. Nítorí ìgbàgbọ́ wọn pé ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀ ni a dá ní ọjọ́ mẹ́fà oníwákàtí-⁠24 péré, àwọn rabbi ọ̀mọ̀wé, àti ti àwọn Kristẹndọm, lérò pé ìṣẹ̀dá ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Adamu, wáyé ní ọdún kan náà tí ìṣẹ̀dá ayé wáyé. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò péye.

Àkòrí àkọ́kọ́ nínú Genesisi bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ pé: “Ní àtètèkọ́ṣe Ọlọrun dá ọ̀run òun ayé.” Lẹ́yìn náà ó tẹ̀síwájú láti júwe ohun tí Ọlọrun ṣe ní “àwọn ọjọ́” mẹ́fà tí ó tẹ̀lé e láti yí ayé padà láti ipò ‘júujùu tí ó sì ṣófo’ sí ibùgbé tí ó bójúmu fún àwọn ènìyàn. (Genesisi 1:​1, 2) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọdún ti lè wà láàárín àwọn ìgbésẹ̀ méjèèjì yìí. Síwájú síi, àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá kìí ṣe àkókò oníwákàtí-⁠24, bí ẹni pé àwọn ìgbòkègbodò Ẹlẹ́dàá ni a fi ìdíwọ̀n bẹ́ẹ̀ pààlà sí. Pé “ọjọ́” kan nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí lè gùn ju wákàtí 24 ni Genesisi 2:4 fihàn, tí ó sọ̀rọ̀ nípa gbogbo àwọn àkókò ìṣẹ̀dá bí “ọjọ́” kan. Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún ni ó kọjá lọ láàárín ọjọ́ ìṣẹ̀dá kìn-⁠ín-ní àti ìkẹfà, nígbà tí a dá Adamu. Fífi ọjọ́ ìṣẹ̀dá Adamu sí ìgbà kan náà pẹ̀lú ti àwọn ọ̀run tí ó ṣeé fojúrí àti ayé kò bá Ìwé Mímọ́ mu bẹ́ẹ̀ sì ni kò bá ìmọ̀⁠-⁠ìjìnlẹ̀ mu. Síbẹ̀, báwo ni wọ́n ṣe dórí ìpinnu pé “Sànmánnì Ìṣẹ̀dá” bẹ̀rẹ̀ ní 3761 B.C.E.?

Ibi tí A Gbé Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ọjọ́ Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ náà Kà

Lọ́nà tí ó baninínújẹ́, ọ̀pọ̀ nínú ìwé àwọn Ju èyí tí a gbé ìṣirò tí a ń jíròrò lọ́wọ́ yìí kà kò sí mọ́. Ohun tí ó ṣẹ́kù ni iṣẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ń pè ní Seder ʽOlam (Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ayé) ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. A kà á sí ti ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Talmud ti ọ̀rúndún kejì C.E. Yose ben Halafta. Iṣẹ́ yìí (tí a ń pè ní Seder ʽOlam Rabbah lẹ́yìn náà láti yà á sọ́tọ̀ kúrò lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ Sànmánnì Agbedeméjì tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Seder ʽOlam Zuṭa) fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àwọn ìtàn hàn bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Adamu sí ọ̀rúndún kejì C.E. ìdìtẹ̀ àwọn Ju lòdìsí Romu lábẹ́ èké Messia náà Bar Kokhba. Báwo ni òǹkọ̀wé náà ṣe rí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀?

Nígbà tí Yose ben Halafta gbìyànjú láti tẹ̀lé àkọsílẹ̀ Bibeli, ó fi àwọn ìtumọ̀ tirẹ̀ kún un níbi tí ẹsẹ náà kò bá ṣe kedere nípa àwọn ọjọ́ tí ó ní nínú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Jewish Encyclopedia sọ pé: “Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, . . . ó sọ àwọn ọjọ́ náà ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́, yàtọ̀ sí èyí ó ń ṣàfikún àwọn ọ̀rọ̀ àti halakot [àwọn ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́] ti àwọn rabbi tí ó ṣíwájú àti ti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.” Àwọn mìíràn kò fi bẹ́ẹ̀ láàánú nípa ìdíwọ̀n wọn. The Book of Jewish Knowledge mú un ṣe kedere pé: “Ó bẹ̀rẹ̀ kíkà láti Sànmánnì Ìṣẹ̀dá àti, nípa bẹ́ẹ̀, ó fi àwọn ọjọ́ tí kò fẹsẹ̀múlẹ̀ fún onírúurú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ Ju tí a lérò pé ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà Adamu, ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, sí ìgbà Alexander Ńlá.” Ṣùgbọ́n, báwo ni irú àwọn ìtumọ̀ àti àwọn àfikún yìí ṣe nípa lórí ìpéye àti ìjótìítọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn Ju? Jẹ́ kí a wò ó.

Àwọn Ìtàn Àtọwọ́dọ́wọ́ àti Àwọn Ìtumọ̀

Ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rabbi, Yose ben Halafta ṣírò pé tẹ́ḿpìlì kejì ní Jerusalemu wà pẹ́ tó 420 ọdún. Èyí ni a gbéka orí ìtumọ̀ tí àwọn rabbi fún àsọtẹ́lẹ̀ Danieli “aláàádọ́rin ọ̀sẹ̀,” tàbí 490 ọdún. (Danieli 9:24) Sáà àkókò yìí ni a lò fún àlàfo tí ó wà láàárín ìparun tẹ́ḿpìlì àkọ́kọ́ àti ìsọdahoro ti èkejì. Ní fífi àyè 70 ọdún ìgbèkùn ní Babiloni sílẹ̀, Yose ben Halafta dórí ìpinnu náà pé tẹ́ḿpìlì kejì wà pẹ́ tó 420 ọdún.

Bí ó ti wù kí ó rí, ìtumọ̀ yìí kó wọnú ìṣòro ńláǹlà. Àwọn ọdún ìbìṣubú Babiloni (539 B.C.E.) àti ti ìparun tẹ́ḿpìlì ẹlẹ́ẹ̀kejì (70 C.E.) jẹ́ àwọn ọjọ́ ìtàn tí a mọ̀. Nígbà náà, àkókò tí tẹ́ḿpìlì kejì fi wà níláti jẹ́ 605 dípò 420 ọdún. Nípa fífún àkókò yìí ní 420 ọdún péré, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àwọn Ju ti fi 185 ọdún dínkù.

Àsọtẹ́lẹ̀ Danieli kìí ṣe nípa bí tẹ́ḿpìlì Jerusalemu náà yóò ti pẹ́ tó lórí ìdúró. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó sọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí Messia náà yóò farahàn. Àsọtẹ́lẹ̀ náà fihàn ní kedere pé “láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti tún Jerusalemu ṣe àti láti tún un kọ́, títí dé ìgbà ọmọ-aládé ẹni-òróró náà, yóò jẹ́ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta.” (Danieli 9:​25, 26) Nígbà tí a fi ìpìlẹ̀ tẹ́ḿpìlì náà lélẹ̀ ní ọdún kejì ìpadàbọ̀ àwọn Ju láti ìgbèkùn (536 B.C.E.), “ọ̀rọ̀ náà” láti tún ìlú Jerusalemu kọ́ kò jáde lọ títí di “ogún ọdún Artasasta ọba.” (Nehemiah 2:​1-⁠8) Àkọsílẹ̀ ìtàn tí ó péye fi 455 B.C.E. lélẹ̀ bí ọdún yẹn. Kíka “ọ̀sẹ̀” 69, tàbí 483 ọdún síwájú, yóò mú wa dé 29 C.E. Ìgbà yẹn ni ìfarahàn Messia náà, ní ìgbà ìrìbọmi Jesu.b

Kókó mìíràn nípa ìtumọ̀ àwọn rabbi tí ó yọrísí àìṣedéédéé kíkàmàmà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn Ju níí ṣe pẹ̀lú àkókò ìbí Abrahamu. Àwọn rabbi ṣe àròpọ̀ àwọn ọdún àwọn ìran tí ó tẹ̀lé araawọn tí a kọsílẹ̀ ní Genesisi 11:​10-⁠26 wọ́n sì bu 292 ọdún fún àkókò tí ó wà láti ìgbà Ìkún-Omi sí ìgbà ìbí Abrahamu (Abramu). Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣòro náà wà nínú ìtumọ̀ tí àwọn rabbi ṣe fún ẹsẹ 26, tí ó sọ pé: “Tera sì wà ní àádọ́rin ọdún, ó sì bí Abramu, Nahori, àti Harani.” Láti inú èyí, ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Ju lérò pé Tera jẹ́ ẹni 70 ọdún nígbà tí ó bí Abrahamu. Síbẹ̀, ẹsẹ náà kò sọ ní pàtó pé Tera bí Abrahamu ní ẹni 70 ọdún. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó kàn wulẹ̀ sọ pé ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta lẹ́yìn tí ó di ẹni 70 ọdún.

Láti rí ọjọ́ orí Tera gan-⁠an nígbà tí ó bí Abrahamu, a kàn níláti kà síwájú síi nínú ìtàn Bibeli náà ni. Láti Genesisi 11:32–12:4, a kẹ́kọ̀ọ́ pé lẹ́yìn ikú Tera ní ọjọ́ orí 205, Abrahamu àti ìdílé rẹ̀ fi Harani sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Jehofa. Nígbà yẹn Abrahamu jẹ́ ẹni 75 ọdún. Nígbà náà Abrahamu ni a ti níláti bí nígbà tí Tera jẹ́ ẹni 130 ọdún, dípò 70. Nípa bẹ́ẹ̀, àkókò tí ó wà láti ìgbà Ìkún-Omi sí ìgbà ìbí Abrahamu jẹ́ 352 ọdún, dípò 292 ọdún. Níbi yìí ìtòlẹ́sẹẹṣẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn Ju ti ní àṣìṣe 60 ọdún.

Ohun Ìrántí ti Ìsìn

Irú àwọn àṣìṣe àti àìṣedéédéé nínú Seder ʽOlam Rabbah àti àwọn iṣẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọjọ́ ti Talmud mìíràn ti kó ìtìjú bá àwọn ọ̀mọ̀wé Ju ó sì ti fa àwọn ìjíròrò tí ó jọjú láàárín wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsapá púpọ̀ ni wọ́n ti ṣe láti mú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí báramu pẹ̀lú àwọn òtítọ́ ìtàn tí ó ṣe kedere, wọn kò tíì ṣe àṣeyọrí délẹ̀délẹ̀. Èéṣe? “Ìfẹ́-ọkàn wọn fún ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kò tó ti ìsìn,” ni gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica ṣàkíyèsí. “Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ni a gbọ́dọ̀ gbéga ohun yòówù kí ó dé, pàápàá lójú ìyapa ìsìn.” Dípò ṣíṣàmúkúrò ìdàrúdàpọ̀ tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn dá sílẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé Ju mélòókan ń gbìyànjú láti bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn àkọsílẹ̀ inú Bibeli. Àwọn mìíràn sapá láti wá ìtìlẹ́yìn nínú ìtàn àròsọ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Babiloni, Egipti, àti Hindu.

Nítorí ìdí èyí, àwọn òpìtàn kò ka “Sànmánnì Ìṣẹ̀dá” sí iṣẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ọ̀mọ̀wé Ju díẹ̀ ni yóò sapá láti gbèjà rẹ̀, àti pàápàá irú àwọn iṣẹ́ ìtọ́kasí tí ó ṣeé gbáralé bí àwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Jewish Encyclopedia àti Encyclopaedia Judaica lọ́pọ̀ ìgbà kò fi ojúrere wò ó. Nígbà náà, àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Ju ti kíka àkókò láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé ni a kò lè kà sí ohun tí ó péye bí a bá fi ojú-ìwòye ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bibeli wò ó, tíí ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò àsọtẹ́lẹ̀ Jehofa Ọlọrun tí a ṣípayá.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a  Ẹ̀rí Bibeli àti ti ìtàn tọ́kasí ọdún 2 B.C. bí ọjọ́ ìbí Jesu Kristi. Nígbà náà, nítorí ìṣedéédéé, ọ̀pọ̀ yàn láti lo àmì náà C.E. (Sànmánnì Tiwa) àti B.C.E. (Ṣáájú Sànmánnì Tiwa), èyí sì ni ọ̀nà tí a gbà ń tọ́kasí àwọn ọjọ́ nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society.

b Fún àlàyé lẹ́kùn-⁠ún-rẹ́rẹ́, wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 2, ojú-ìwé 614 sí 616, 900 sí 902, tí a tẹ̀ láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́