ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 8/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídá Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́ mọ̀ ní Àkókò Òpin
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Àwọn Ọjọ́ Alásọtẹ́lẹ̀ Danieli àti Ìgbàgbọ́ Wa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Jèhófà Ṣèlérí Èrè Àgbàyanu fún Dáníẹ́lì
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Ìwé Dáníẹ́lì àti Ìwọ
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 8/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

A gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Danieli bí a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú “Ilé-Ìṣọ́nà.” Bí ó ti wù kí ó rí, èéṣe tí àwọn déètì fún ìgbà mẹ́ta àti ààbọ̀ ti Ìfihàn 11:3 fi yàtọ̀ sí ti ìwé “Revelation Climax”?

Bẹ́ẹ̀ni, Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1993, lóòótọ́ ṣe àtúnṣe ráńpẹ́ nípa àwọn ọjọ́ ìmúṣẹ òde-òní ti Ìfihàn 11:3. Èéṣe?

Lákọ̀ọ́kọ́ jẹ́ kí a wo Ìfihàn 11:2 (NW), èyí tí ó mẹ́nukan “oṣù méjìlélógójì” ní ìparí. A tẹ̀síwájú ní ẹsẹ̀ 3 pé: “Èmi óò sì yọ̀ọ̀da fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèjì, wọn óò sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó lé ọgọ́ta nínú aṣọ ọ̀fọ̀.” Nígbà wo ni ìyẹn ní ìmúṣẹ?

Lóòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ sórí àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró lẹ́yìn òpin “àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” (Àkókò àwọn Keferi) ní 1914. (Luku 21:24, NW; 2 Korinti 1:​21, 22) Ní ṣíṣàlàyé lórí èyí, ìwé Revelation​—⁠Its Grand Climax At Hand!a (1988) sọ ní ojú-ewé 164 pé: “Sáà ọlọ́dún mẹ́ta àti ààbọ̀ kan wà tí a sàmìsí nígbà tí àwọn ìrírí lílekoko àwọn ènìyàn Ọlọrun báradọ́gba pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọtẹ́lẹ̀ níhìn-⁠ín​—⁠bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìbẹ́sílẹ̀ ogun àgbáyé kìn-ín-⁠ní ní apá ìparí 1914 tí ó sì tẹ̀síwájú títí di apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1918.”

Ṣàkíyèsí pé àwọn ọjọ́ tí a filélẹ̀ jẹ́ “ìgbà ìbẹ́sílẹ̀ ogun àgbáyé kìn-ín-⁠ní ní apá ìparí 1914 (títí) di apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1918.” Èyí ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú àwọn ọjọ́ tí a sábà máa ń fihàn, gẹ́gẹ́ bíi nínú ìwé “Then Is Finished the Mystery of God,” ojú-ewé 261 sí 264, (1969).*

Bí ó ti wù kí ó rí, Ilé-Ìṣọ́nà pa àfiyèsí pọ̀ sórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Danieli, ìwé tí ó mẹ́nukan sáà àkókò tí ó ṣe é fiwéra pẹ̀lú èyí tí a mẹ́nukàn lẹ́yìn náà nínú Ìfihàn lẹ́ẹ̀mejì​—⁠ọdún 3 1/2, tàbí oṣù 42. Láti ṣe ṣàkó, Danieli 7:25 (NW) sọ pé àwọn ẹni-mímọ́ Ọlọrun ni a óò gbéjàkò “títí fi di ìgbà àkókò kan, àti àwọn àkókò, àti ìdajì àkókò,” tàbí ìgbà 3 1/2. Lẹ́yìn náà, Danieli 12:7 sọtẹ́lẹ̀ nípa “àkókò kan, àwọn àkókò, àti ààbọ̀ àkókò,” tàbí ìgbà 3 1/2, tí yóò dé ògógóró rẹ̀ pẹ̀lú “àṣepé ìfúnká àwọn ènìyàn mímọ́.”

Nítorí náà a ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó níí ṣe pẹ̀lú sáà àkókò tí ó ṣe é fiwéra nínú Danieli 7:25, Danieli 12:7, àti Ìfihàn 11​:2, 3, àti ní Ìfihàn 13:5 pẹ̀lú. Àwọn ìtẹ̀jáde wa ti fihàn pé gbogbo àwọn wọ̀nyí ní ìmúṣẹ wọn ní sáà àkókò 1914 sí 1918. Ṣùgbọ́n ní jíjíròrò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn ọjọ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n sì parí yàtọ̀ díẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1993, béèrè pé: “Báwo ni gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bíbáradọ́gba wọ̀nyí ṣe ní ìmúṣẹ?” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ti ìgbà 3 1/2 tí a mẹ́nukàn nínú Danieli 7:25, Danieli 12:7 àti Ìfihàn 11:3 ni a mọ̀ sí “àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bíbáradọ́gba.” Nítorí náà, wọn yóò ṣe déédéé níti ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí wọn.

Níti ìparí, ìwé ìròyìn náà fihàn bí ìgbéjàkò àwọn ẹni-àmì-òróró Ọlọrun (Danieli 7:25) ṣe dé ògógóró ní June 1918 nígbà tí a dá J. F. Rutherford àti àwọn olùdarí Watch Tower Bible and Tract Society mìíràn “lẹ́jọ́ ìjìyà ọlọ́jọ́ gbọọrọ nínú ẹ̀wọ̀n lórí àwọn ẹ̀sùn èké.” Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn dájúdájú jẹ́ “àṣepé ìfúnká àwọn ènìyàn mímọ́,” gẹ́gẹ́ bí Danieli 12:7 ti sọ ọ́.

Kíkà á padà láti June 1918 gbé wa dé December 1914 gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà 3 1/2 náà. Ní ìparí oṣù yẹn ní 1914, àwọn ẹni-àmì-òróró Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé wá mọ kókó ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ fún ọdún tí ń bọ́: “‘Ẹ̀yin lè mu nínú aago tí èmi óò mu?’​—⁠Matteu 20:​20-⁠23.” Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó kéde rẹ̀ kìlọ̀ pé: “Ṣùgbọ́n ta ni ó mọ̀ bóyá àwọn àdánwò àrà-ọ̀tọ̀ kan lè wà, aago ìjìyà tàbí ìdójútì, fún àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Ọ̀dọ́-Àgùtàn láàárín ọdún 1915!” Gẹ́gẹ́ bí Danieli 7:25 ti sọtẹ́lẹ̀ nípa sáà ìgbà 3 1/2 yìí, ‘ìgbéjàko àwọn ẹni-mímọ́ Ọ̀gá-Ògo fúnraawọn bẹ̀rẹ̀ ó sì tẹ̀síwájú.’ Àwọn orílẹ̀-èdè ni a fàwọ inú Ogun Àgbáyé I, tí ó mú un rọrùn fún wọn láti máa bá ìgbéjàkò tí kò tọ́ náà nìṣó. Òpin rẹ̀ ni pé: Gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó báradọ́gba​—⁠Danieli 7:25, 12:​7, àti Ìfihàn 11:⁠3​—​ní ìmúṣẹ ní ọdún 3 1/2, tàbí oṣù 42 náà, láti December 1914 sí June 1918.

Èyí ṣàlàyé ìmúsunwọ̀n ráńpẹ́ nínú àwọn ọjọ́ ìmúṣẹ Ìfihàn 11:3. Àtúnṣe yìí jẹ́ ohun tí a lè fi sọ́kàn bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ tí a sì ń lo ìwé náà Revelation Climax ní ọjọ́ iwájú.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́