ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 9/15 ojú ìwé 30-31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Nípa Gbèsè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìṣòro Owó Tàbí Tí Mo Bá Jẹ Gbèsè?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Yíyá Àwọn Ọ̀rẹ́ Lówó àti Yíyáwó Lọ́wọ́ Wọn
    Jí!—1999
  • Yíyá Awọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ wa Lówó
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 9/15 ojú ìwé 30-31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ní awọn àkókó tí ọrọ̀-ajé lekoko yii, ọ̀pọ̀ awọn ènìyàn ati ilé-iṣẹ́ ń yíjú sí ìwọkogbèsè. Ó ha yẹ fún Kristian kan lati pẹjọ́ fún ìwọkogbèsè lójú ìwòye Ìwé Mímọ́ bí?

Ìdáhùn sí ìbéèrè yii pèsè àkàwé dídára kan nipa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe lè fún wa ní ìtọ́sọ́nà tí ó ṣeémúlò lórí awọn ọ̀ràn tí ó ṣe kedere pé wọn jẹ́ ti òde-òní. Ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ní awọn òfin tí ń dárí ọ̀ràn nipa ìwọkogbèsè. Awọn òfin naa yàtọ̀síra lati orílẹ̀-èdè kan sí orílẹ̀-èdè kejì, kìí sìí ṣe ojúṣe Kristian lati fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó jẹmọ́ ọ̀ràn òfin lórí ọ̀ràn yii. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí a wo àkópọ̀ ohun tí òfin fàyègbà lórí ìwọkogbèsè.

Ìdí kan tí ìjọba fi gba ẹnìkọ̀ọ̀kan ati awọn ile-iṣẹ́ okòwò láyè lati jẹ́wọ́ ìwọkogbèsè ni pé ó fún awọn wọnnì tí ń yánilówó tabi awọn atajà àwìn (awọn ayánilówó) ní ààbò díẹ̀ kúrò lọ́wọ́ awọn ènìyàn tabi ilé-iṣẹ́ okòwò tí ó yáwó tabi tí ó jẹ gbèsè (awọn ajigbèsè) ṣugbọn tí wọn kò san gbèsè tí wọn jẹ. Fún awọn ayánilówó ó lè dàbí ẹni pé ojútùú kanṣoṣo ní lati rọ kóòtù pé kí ó jẹ́wọ́ onígbèsè naa pé ó ti wọkogbèsè kí a baà lè pín dúkìá-ìní onígbèsè naa lati fi san apákan gbèsè naa.

Ọ̀nà mìíràn tí ìwọkogbèsè ń gbà ṣiṣẹ́ ni gẹ́gẹ́ bí ìdáàbòbò fún awọn ajigbèsè tí wọn kò lè tẹ́ ayánilówó wọn lọ́rùn. A lè fàyègba ajigbèsè naa lati pẹjọ́ fún ìwọkogbèsè, kí ayánilówó rẹ̀ baà lè gbà lára awọn dúkìá-ìní rẹ̀. Síbẹ̀, òfin lè yọ̀ọ̀da fún un lati fọwọ́ mú ilé rẹ̀ tabi awọn dúkìá-ìní kan tí ó mọ níwọ̀n kí ó sì máa bá ìgbésí-ayé rẹ̀ lọ láìsí ìfòyà pípàdánù tabi kí ayánilówó rẹ̀ tẹ́lẹ̀rí fagbára gbà á.

Nígbà naa, ó ṣe kedere, pé awọn òfin wọnyi ni a pète lati fún ìhà méjèèjì ní ààbò díẹ̀ lórí ọ̀ràn ìṣúnná-owó tabi ìdókòwò. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a kíyèsí àmọ̀ràn rírannilọ́wọ́ tí Bibeli fúnni.

Yoo ṣòro fún ẹnìkan lati ka Bibeli lati páálí dé páálí kí ó má sì mọ̀ pé kò fún jíjẹ gbèsè ní ìṣírí. A rí irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ ní Owe 22:7: “Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún [awínni, NW].”

Pẹ̀lúpẹ̀lù, rántí pé, àkàwé Jesu ní Matteu 18:23-⁠34 tí ó níí ṣe pẹlu ẹrú kan tí ó jẹ gbèsè ńlá. “Oluwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a tà á, ati obìnrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní,” ṣugbọn ọ̀gá naa, tí ó jẹ́ ọba, dẹwọ́ ó sì fi àánú hàn. Nígbà tí ẹrú naa fihàn níkẹyìn pé oun jẹ́ aláìláàánú, ọba naa pàṣẹ pé kí a “fi í fún awọn onítúbú, títí yoo fi san gbogbo gbèsè èyí tí ó jẹ ẹ́.” Lọ́nà tí ó ṣe kedere, ipa ọ̀nà tí ó dára jùlọ, ipa ọ̀nà tí a dámọ̀ràn rẹ̀, ni lati yẹra fún yíyá owó.

Awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní Israeli ìgbàanì ń bá araawọn ṣòwò, nígbà mìíràn yíyáwó ati yíyánilówó máa ń wáyé. Kí ni Jehofa fún wọn ní ìtọ́ni lati ṣe? Ó bófinmu ó sì bójúmu fún Heberu kan lati gba èlé, bí ẹnikan bá fẹ́ yáwó lati ṣòwò tabi kí ó fi fẹ òwò naa lójú. Bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọrun rọ awọn ènìyàn rẹ̀, lati jẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan nígbà tí wọn bá ń yá aláìní ọmọ Israeli kan lówó; wọn kò níláti jèrè lati inú ipò tí kò báradé nipa gbígba èlé. (Eksodu 22:25) Deuteronomi 15:​7, 8 sọ pé: “Bí tálákà kan bá ń bẹ ninu yin, . . . kí iwọ kí ó la ọwọ́ rẹ fún un, kí iwọ kí ó sì wín in ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ tó fún àìní rẹ̀, ní ohun tí ń fẹ́.”

Irú inúrere tabi ìgbatẹnirò bẹ́ẹ̀ ni a fihàn ninu awọn ìlànà tí ó fàṣẹ lélẹ̀ pé awọn ayánilówó kò lè fipá gba awọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí-ayé lọ́wọ́ ajigbèsè kan, irú bí ọlọ ìdílé tabi ẹ̀wù tí a nílò lati mú ara ẹni naa móoru lóru.​—⁠Deuteronomi 24:​6, 10-⁠13; Esekieli 18:​5-⁠9.

Àmọ́ ṣáá o, kìí ṣe gbogbo awọn Ju ní wọn tẹ́wọ́gbà tí wọn sì ṣàmúlò ẹ̀mí tí ó wà ninu awọn òfin onífẹ̀ẹ́ wọnyi lati ọwọ́ Onídàájọ́ ńlá ati Olùfúnni-Ní-Ìlànà-Òfin wọn. (Isaiah 33:22) Awọn Ju oníwọra kan fi ọwọ́ lílekoko mú awọn arákùnrin wọn. Lónìí, pẹlu, awọn ayánilówó kan lè lekoko kí wọn má sì fòyebánilò ninu awọn ohun ti wọn béèrè fún, àní wọn tilẹ̀ lè lekoko mọ́ Kristian olùfọkànsìn kan tí kò lè sanwó lójú-ẹsẹ̀ nitori tí ó nírìírí awọn ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ kan. (Oniwasu 9:11) Nípasẹ̀ ìfagbáramúni, ati àìgbojúbọ̀rọ̀ wọn awọn ẹni ayé tí wọn jẹ́ ayánilówó lè fipá ti ajigbèsè kan wọ inú ipò kan tí oun ti lè ronú pé oun níláti dáàbòbo ara oun. Lọ́nà wo? Ninu awọn ọ̀ràn kan kìkì ohun tí ayánilówó naa mọ̀ ni ìgbésẹ̀ tí ó jẹmọ́ ọ̀ràn òfin nipa ìwọkogbèsè. Nitori naa Kristian kan, tí kìí ṣe oníwọra tabi aláìbìkítà nipa gbèsè rẹ̀, lè yíjú sí pípẹjọ́ fún ìwọkogbèsè.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a níláti wà lójúfò sí òdìkejì ọ̀ràn naa. Gbèsè lè wọ Kristian kan lọ́rùn kìkì nitori pé oun kò lo ìkóra-ẹni-níjàánu ninu iye tí ó ná tabi bí ó ṣe ná an tabi nitori pé kò lo ìríran tẹ́lẹ̀ tí ó fòyehàn ninu ṣíṣe ìpinnu lórí iṣẹ́ okòwò rẹ̀. Oun ha níláti jẹ́ oníwà àgunlá nipa gbèsè naa kí ó sì tètè wá ìtura nipa ìwọkogbèsè, ní títipa bẹ́ẹ̀ pa awọn ẹlòmíràn lára nitori ìpinnu rẹ̀ tí kò mọ́yánlórí bí? Bibeli kò fọwọ́sí irú àìka nǹkan kún bẹ́ẹ̀ níti ọ̀ràn ìnáwó. Ó rọ ìránṣẹ́ Ọlọrun lati jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ni oun jẹ́ bẹ́ẹ̀ni. (Matteu 5:37) Pẹ̀lúpẹ̀lù, rántí, àlàyé Jesu nipa ṣíṣe ìṣirò iye tí yoo náni ṣáájú bíbẹ̀rẹ̀ síí kọ́ ilé-ìṣọ́. (Luku 14:​28-⁠30) Ní ìbámu pẹlu ìyẹn, Kristian kan níláti gbé awọn àbájáde tí kò wuni tí ó ṣeéṣe kí ó wáyé yẹ̀wò ṣáájú kí ó tó kówọnú gbèsè ìṣúnná owó. Gbàrà tí ó bá sì ti jẹ gbèsè, ó níláti rí ẹrù-iṣẹ́ rẹ̀ lati san owó padà fún ẹni naa tabi ilé-iṣẹ́ naa tí ó jẹ lówó. Bí ọ̀pọ̀ awọn mìíràn bá rí Kristian kan gẹ́gẹ́ bí aláìka nǹkan kún tabi aláìṣeé gbẹ́kẹ̀lé, oun ti lè ba orúkọ rere rẹ̀ tí ó tí làkàkà fún jẹ́ nipa bẹ́ẹ̀ kì yoo ní ẹ̀rí rere mọ́ lọ́dọ̀ awọn ara ìta.​—⁠1 Timoteu 3:​2, 7.

Rántí ohun tí Orin Dafidi 15:4 sọ fún wa nipa irú awọn ẹni tí Jehofa ń tẹ́wọ́gbà. A kà pé: “Ó [ẹni tí Ọlọrun tẹ́wọ́gbà] búra sí ibi araarẹ̀, tí kò sì yípadà.” Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọrun retí pé kí awọn Kristian hùwà sí awọn ayánilówó wọn gẹ́gẹ́ bí awọn naa yoo ti fẹ́ kí a hùwà sí wọn.​—⁠Matteu 7:12.

Ní àkópọ̀, nígbà naa, Bibeli kò fagilé e pé nínu ipò lílégbákan ó ṣeéṣe, kí Kristian kan jọlá ààbò tí òfin Kesari pèsè lórí ìwọkogbèsè. Bí ó ti wù kí ó rí, awọn Kristian gbọ́dọ̀ tayọ níti àìlábòsí ati ìṣeégbáralé. Nipa bẹ́ẹ̀, wọn níláti jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ninu ìfẹ́-ọkàn àtọkànwá wọn lati mú awọn ojúṣe wọn níti ọ̀ràn owó ṣẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́