Ìbẹ̀rù Àwọn Òkú Tànkálẹ̀
Ó ti pẹ́ tí oòrùn ti wọ̀. Ó pẹ́ ọ díẹ̀ ju bí o ti fẹ́ lọ kí ó tó máa darí lọ sílé. Bí o ti ń rìn gba ibi itẹ́ àdúgbò kọjá, ọkàn-àyà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí lùkìkì. Ìpa késekése ọwọ́ àṣálẹ́ náà mú kí ó ṣeéṣe fún ọ láti gbọ́ ìró tí ó kéré jùlọ. Lójijì ohùn híhan gooro kan, tí ń múni tagìrì dún jáde láti ọ̀nà jíjìn wá. O yára tẹsẹ̀mọ́rìn—bẹ́ẹ̀ ni o ń mí gúlegúle—bí o ti forílé ibi ààbò ní ilé rẹ̀.
ÌWỌ ha ti ní ìrírí ìpayà rí nígbà tí o lọ sí ibi itẹ́ kan tàbí tí o wà nítòsí rẹ̀ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èrò ìsìn kan tí ó wọ́pọ̀ káàkiri àgbáyé—pé ẹ̀mí àwọn òkú lè ran àwọn alààyè lọ́wọ́ tàbí kí ó pa wọ́n lára ti lè nípa lórí rẹ.
Ọ̀pọ̀ àwọn àṣà ìgbàgbọ́-nínú-ohun-asán ti gbèrú nítorí èrò ìgbàgbọ́ náà pé àwọn òkú nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn alààyè tàbí pé wọ́n lè pa àwọn alààyè lára bí a kò bá tù wọ́n lójú. Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Latin-America ó jẹ́ àṣà ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti máa kọ́ ibùgbé kékeré kan tí ó ní àgbélébùú níbi tí ìjàm̀bá bá ti ṣekú pa ẹnìkan. Àwọn ènìyàn máa ń tan àbẹ́là wọ́n a sì fi òdòdó síbẹ̀ nínú ìsapá wọn láti fìfẹ́hàn tàbí láti ṣèrànlọ́wọ́ fún ọkàn tàbí ẹ̀mí ẹni tí ó kú náà. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ìròyìn ti tànkálẹ̀ nípa àwọn ìdáhùn “àgbàyanu” sí àwọn àdúrà, kí àwọn ènìyàn baà lè máa lọ lemọ́lemọ́ síbi animita, ibùgbé kékeré tí a kọ́ fún ọkàn tàbí ẹ̀mí òkú náà. Níbẹ̀ ni wọ́n ti ń ṣe mandas, tàbí àwọn ìdàníyàn, pé bí ẹni tí ó kú náà bá lè ràn àwọn lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí tàbí mú kí ọwọ́ àwọn tẹ ohun kan—bóyá ìwòsàn àgbàyanu kan—àwọn yóò fi ìmoore àwọn hàn ní ọ̀nà àkànṣe kan. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, wọ́n lè mú ẹ̀sùn wá pé ọkàn ènìyàn kan ń farahàn nínú òkùnkùn àṣálẹ́, ó sì ń kó ìpayà bá àwọn wọnnì tí ó bá rí. Wọ́n sábà máa ń sọ pé irú àwọn ọkàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwọn penando, tí ń mú àwọn alààyè bínú nítorí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.
Ìsapá tí kò kéré ni àwọn ènìyàn ń ṣe ní ọ̀pọ̀ àwọn ilẹ̀ láti tú “àwọn ẹ̀mí” òkú lójú. Wọ́n máa ń ṣe àwọn àsè híhẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀, wọ́n máa ń rú àwọn ẹbọ, wọ́n sì máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìpọ́nni—nítorí àtilè taari ìyà láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí àwọn tí ó ti kú síwájú. Wọ́n ronú pé títu ẹ̀mí àwọn òkú lójú yóò yọrísí èrè àti ìbùkún fún àwọn aláṣẹ̀yìndè òkú náà.
Ìròyìn kan láti Africa sọ pé, “Ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé ẹ̀ṣẹ́ kìí ṣẹ́ ‘lásán tàbí lọ́nà àdánidá.’ Ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí—ìbáà jẹ́ àìsàn, ìjábá, ìyàgàn, ìṣòro ìṣúnná-owó, àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò tàbí oòrùn àrànṣúlẹ̀, ìjàm̀bá, àìsí ìṣọ̀kan nínú ìdílé, ikú—wọ́n ní èrò pé àwọn ẹ̀mí àìrí tí ó ní agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ ni ń bẹ nídìí gbogbo wọn.” Ìròyìn mìíràn sọ pé: “Àwọn ènìyàn gbàgbọ́ pé ẹ̀mí àwọn babańlá wọn ní ibùgbé lọ́run tí ojú wọn kò sì kúrò lára àwọn aláṣẹ̀yìndè wọn lórí ilẹ̀-ayé. Wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn babańlá ní agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ, tí wọ́n lè lò láti bùkún àti láti dáàbòbo àwọn ìbátan wọn lórí ilẹ̀-ayé tàbí kí wọ́n fi jẹ wọ́n níyà, èyí sinmi lórí bí àwọn ìbátan náà bá ṣe bọlá fún tàbí ṣe àìka àwọn òkú náà sí.”
Ṣùgbọ́n irúfẹ́ èyí ha wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bí? Kí ni èrò rẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
“Animita” kan ní Chile