ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 11/1 ojú ìwé 9-15
  • Jehofa—Bàbá Wa Oníyọ̀ọ́nú Lọ́nà Jẹ̀lẹ́ńkẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa—Bàbá Wa Oníyọ̀ọ́nú Lọ́nà Jẹ̀lẹ́ńkẹ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ààlà Ìyọ́nú Àtọ̀runwá
  • Ìyọ́nú fún Orúkọ Rẹ̀
  • Ọ̀nà Gíga Jùlọ Tí A Gbà Fi Ìyọ́nú Hàn
  • Nígbà tí Àánú Ń Ṣe Jesu
  • Àwọn Àkàwé Tí Wọ́n Tẹnumọ́ Ìyọ́nú
  • Jèhófà Ń Fi Ìyọ́nú Ṣàkóso
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ẹ Ní Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • “Àánú Ṣe É”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 11/1 ojú ìwé 9-15

Jehofa​—⁠Bàbá Wa Oníyọ̀ọ́nú Lọ́nà Jẹ̀lẹ́ńkẹ́

“Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ oníyọ̀ọ́nú.” ​—⁠JAKỌBU 5:11, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé, NW.

1. Èéṣe tí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ fi ń fà mọ́ Jehofa Ọlọrun?

ÀGBÁYÉ tóbi tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé kò ṣeéṣe fún àwọn onímọ̀ nípa ojúde òfúúrufú láti ka gbogbo iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tiwa, tí ń jẹ́ Milky Way, tóbi gbàràmù-gbaramu débi pé kò ṣeéṣe fún ènìyàn láti ka gbogbo ìràwọ̀ inú rẹ̀. Àwọn ìràwọ̀ kan, bí Antares, tóbi wọ́n sì mọ́lẹ̀ ju oòrùn wa lọ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà. Ẹ wo bí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá gbogbo àwọn ìràwọ̀ tí ń bẹ lágbàáyé ti gbọ́dọ̀ jẹ́ alágbára tó! Nítòótọ́, òun ni ẹni “tí ń mú ogun wọn jáde wá ní iye: ó ń pe gbogbo wọn ní orúkọ.” (Isaiah 40:26) Síbẹ̀, Ọlọrun amúnikúnfún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ kan náà yìí tún jẹ́ “oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ oníyọ̀ọ́nú.” (NW) Ẹ sì wo bí ìmọ̀ yẹn ṣe ń tu àwọn ìránṣẹ́ Jehofa tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn lára tó, ní pàtàkì àwọn wọnnì tí wọ́n ń jìyà inúnibíni, àìsàn, ìsoríkọ́, tàbí àwọn ìnira mìíràn!

2. Ojú wo ni àwọn ènìyàn ayé yìí fi ń wo èrò ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà?

2 Àwọn kan ń ka èrò ìmọ̀lára onínútítẹ́ bíi, ti “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ati awọn ìyọ́nú” Kristi, sí àìlera. (Filippi 2:1, NW) Níwọ̀n bí ọgbọ́n èrò-orí ti ẹfolúṣọ̀n ti nípa lé wọn lórí, wọ́n ń fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti fi araawọn sí ipò àkọ́kọ́ kódà bí ó bá túmọ̀sí pípa ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn lára. Àwọn kan lára àwọn ẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú eré ìnàjú àti eré ìdárayá jẹ́ ọ̀dájú tí wọn kìí sọkún tàbí fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn. Àwọn alákòóso òṣèlú kan ń hùwà lọ́nà kan náà. Ọlọ́gbọ́n èrò-orí Stoiki náà Seneca, ẹni tí ó fún òṣìkà olú-ọba Nero ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, tẹnumọ́ ọn pé “àánú jẹ́ àìlera.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ti M’Clintock àti Strong Cyclopædia sọ pé: “Àwọn agbára ìdarí ìgbàgbọ́ nínú ọgbọ́n èrò-orí Stoiki . . . ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́ nínú ọkàn àwọn ènìyàn ní àwọn àkókò ìwòyí pàápàá.”

3. Báwo ni Jehofa ṣe ṣàpèjúwe ara rẹ̀ fún Mose?

3 Yàtọ̀ sí èyí, àkópọ̀ ìwà Ẹlẹ́dàá aráyé ń mú ọkàn yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀. Ó fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣàpèjúwe araarẹ̀ fún Mose pé: “OLUWA, OLUWA, Ọlọrun aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, onípamọ́ra, àti ẹni tí ó pọ̀ ní oore àti òtítọ́; . . . tí ó ń dárí àìṣedéédéé, àti ìrékọjá, àti ẹ̀ṣẹ̀ jì, àti nítòótọ́ tí kìí jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà.” (Eksodu 34:​6, 7) Lótìítọ́, Jehofa parí ìṣàpèjúwe ara rẹ̀ yìí nípa títẹnumọ́ ìdájọ́-òdodo rẹ̀. Òun kì yóò dá àwọn olùmọ̀ọ́mọ̀dẹ́ṣẹ̀ sí láìfi ìyà tí ó tọ́ sí wọn jẹ wọ́n. Síbẹ̀, ó kọ́kọ́ ṣàpèjúwe araarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun tí ó jẹ́ aláàánú, ní olówuuru tí ó “kún fún àánú.”

4. Kí ni ìtumọ̀ tí ń mú ọkàn yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ọ̀rọ̀ Heberu náà tí a sábà ń túmọ̀ sí “àánú” ní?

4 Nígbà mìíràn ọ̀rọ̀ náà “àánú” ni a ronú pé kí ó jẹyọ kìkì nínú ọ̀ràn ìdájọ́ ṣíṣe ṣàkó, tí a ti ń fawọ́ ìjìyà sẹ́yìn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìfiwéra àwọn ìtumọ̀ Bibeli ṣe ìmújáde ìtumọ̀ dídọ́ṣọ̀ ti ọ̀rọ̀-àpèjúwe Heberu tí a fàyọ láti inú ọ̀rọ̀-ìṣe náà ra·chamʹ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti sọ, ìtumọ̀ ìpìlẹ̀ rẹ̀ ni “láti jẹ́ onínútítẹ́.” Ìwé Synonyms of the Old Testament ṣàlàyé pé, “Racham ń sọ nípa ìmọ̀lára ìyọ́nú jíjinlẹ̀ àti oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, irú èyí tí ń rusókè nígbà tí a bá rí i tí àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa tàbí àwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ wa bá ní àìlera tàbí tí wọ́n ń jìyà.” Àwọn ìtumọ̀ mìíràn tí ń mú ọkàn yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ nípa ànímọ́ fífanilọ́kànmọ́ra yìí ni a lè rí nínú Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 2, ojú-ìwé 375 sí 379.

5. Báwo ni àánú ti ṣe kedere tó nínú Òfin Mose?

5 Ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọrun farahàn lọ́nà ṣíṣe kedere nínú Òfin tí ó fifún orílẹ̀-èdè Israeli. Àwọn tí ó kù-díẹ̀-kí-à-tó-fún, bí àwọn opó, ọmọ òrukàn, àti òtòṣì, ni a gbọ́dọ̀ fi ìyọ́nú bálò. (Eksodu 22:​22-⁠27; Lefitiku 19:​9, 10; Deuteronomi 15:​7-⁠11) Olúkúlùkù, títíkan àwọn ẹrú àti ẹranko, ni wọ́n gbọ́dọ̀ jàǹfààní láti inú ọjọ́ ìsinmi Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. (Eksodu 20:10) Síwájú síi, Ọlọrun ṣàkíyèsí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń bá àwọn ẹni rírẹlẹ̀ lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Owe 19:17 sọ pé: “Ẹni tí ó ṣàánú fún tálákà Oluwa ni ó wín; àti ìṣeun rẹ̀, yóò san án padà fún un.”

Àwọn Ààlà Ìyọ́nú Àtọ̀runwá

6. Èéṣe tí Jehofa fi rán àwọn wòlíì àti ońṣẹ́ sí àwọn ènìyàn rẹ̀?

6 Àwọn ọmọ Israeli jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọrun wọ́n sì jọ́sìn ní tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní Jerusalemu, èyí tí ó jẹ́ “ilé kan fún orúkọ Oluwa.” (2 Kronika 2:⁠4; 6:33) Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, wọ́n fàyègba ìwà pálapàla, ìbọ̀rìṣà, àti ìṣìkàpànìyàn, ní mímú ẹ̀gàn ńlá wá sórí orúkọ Jehofa. Ní ìbámu pẹ̀lú àkópọ̀ ìwà oníyọ̀ọ́nú rẹ̀, Ọlọrun fi sùúrù gbìyànjú láti tún ipò búburú yìí ṣe láìmú àjálù-ibi wá sórí gbogbo orílẹ̀-èdè náà pátápátá. Ó “sì ránṣẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ońṣẹ́ rẹ̀, ó ń dìde ní kùtùkùtù ó sì ń ránṣẹ́, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀, àti sí ibùgbé rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n fi àwọn ońṣẹ́ Ọlọrun ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín, títí ìbínú Oluwa fi ru sí àwọn ènìyàn rẹ̀, tí kò fi sí àtúnṣe.”​—⁠2 Kronika 36:​15, 16.

7. Nígbà tí ìyọ́nú Jehofa dé ìpẹ̀kun rẹ̀, kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọba Juda?

7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa jẹ́ oníyọ̀ọ́nú tí ó sì lọ́ra láti bínú, ó máa ń bínú lọ́nà òdodo nígbà tí ó bá pọndandan. Nígbà náà lọ́hùn-⁠ún, ìyọ́nú àtọ̀runwá ti dé ìpẹ̀kun rẹ̀. A kà nípa àbájáde náà pé: “Nítorí náà ni [Jehofa] ṣe mú ọba àwọn ará Kaldea wá bá wọn, ẹni tí ó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn ní ilé ibi mímọ́ wọn, kò sì ní ìyọ́nú sí ọ̀dọ́mọkùnrin tàbí wúńdíá, arúgbó, tàbí ẹni tí ó ba fún ogbó: òun fi gbogbo wọn lé e ní ọwọ́.” (2 Kronika 36:17) Nípa báyìí, Jerusalemu àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀ ni a parun, a sì kó orílẹ̀-èdè náà lọ sí ìgbèkùn ní Babiloni.

Ìyọ́nú fún Orúkọ Rẹ̀

8, 9. (a) Èéṣe tí Jehofa fi polongo pé òun yóò ní ìyọ́nú nítorí orúkọ òun? (b) Báwo ni a ṣe pa àwọn ọ̀tá Jehofa lẹ́nu mọ́?

8 Àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká yọ̀ nítorí àjálù yìí. Ní ọ̀nà ìfiniṣẹlẹ́yà, wọ́n wí pé: “Àwọn wọ̀nyí ni ènìyàn Oluwa, wọ́n sì ti jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.” Níwọ̀n bí ẹ̀gàn yìí kò ti bá a lára mu, Jehofa polongo pé: “Èmi yóò sì ní ìyọ́nú sí orúkọ mímọ́ mi . . . Èmi óò sì sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́ nítòótọ́, . . . àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì níláti mọ̀ pé èmi ni Jehofa.”​—⁠Esekieli 36:​20-⁠23, NW.

9 Lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè yìí ti wà ní oko-òǹdè fún 70 ọdún, Ọlọrun oníyọ̀ọ́nú náà, Jehofa, dá wọn sílẹ̀ ó sì yọ̀ọ̀da fún wọn láti padà lọ kí wọ́n sì tún tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní Jerusalemu kọ́. Èyí pa àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká tí wọ́n sì ń wò wọ́n pẹ̀lú kàyéfì lẹ́nu mọ́. (Esekieli 36:​35, 36) Ṣùgbọ́n, ó baninínújẹ́ pé, orílẹ̀-èdè Israeli tún padà ṣubú sínú àwọn àṣà búburú. Nehemiah, Ju olùṣòtítọ́ kan, ṣèrànwọ́ láti tún ọ̀ràn náà ṣe. Nínú àdúrà ìtagbangba kan, ó mẹ́nukan àwọn ìbálò oníyọ̀ọ́nú Ọlọrun pẹ̀lú orílẹ̀-èdè náà, ní sísọ pé:

10. Báwo ni Nehemiah ṣe tẹnumọ́ ìyọ́nú Jehofa?

10 “Ní àkókò ìpọ́njú wọn, nígbà tí wọ́n kígbe pè ọ́, ìwọ gbọ́ láti ọ̀run wá; àti gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí wọ́n gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Ṣùgbọ́n ní ẹ̀yìn tí wọ́n ní ìsinmi, wọ́n sì tún ṣe búburú níwájú rẹ: nítorí náà ni ìwọ fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n jọba ní orí wọn: ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n padà, tí wọ́n sì kígbe pè ọ́, ìwọ gbọ́ láti ọ̀run wá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ìwọ sì gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àánú rẹ. . . . Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi mú sùúrù fún wọn.”​—⁠Nehemiah 9:​26-⁠30; tún wo Isaiah 63:​9, 10.

11. Ìyàtọ̀ wo ni ó wà láàárín Jehofa àti àwọn ọlọrun àwọn ènìyàn?

11 Ní àkótán, lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ Ọmọkùnrin Ọlọrun sílẹ̀ lọ́nà ìkà, orílẹ̀-èdè Ju náà pàdánù ipò àǹfààní rẹ̀ títíláé. Ìsopọ̀ onídùúróṣinṣin tí Ọlọrun ní pẹ̀lú wọn ti wà fún ohun tí ó ju 1,500 ọdún lọ. Ó dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ayérayé sí òtítọ́ náà pé nítòótọ́ ni Jehofa jẹ́ Ọlọrun aláàánú. Ẹ sì wo bí èyí ṣe yàtọ̀ gedegbe sí àwọn ọlọrun ìkà àti àwọn ọlọrun àjọ́sìnfún aláìláàánú tí àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ hùmọ̀ tó!​—⁠Wo ojú-ìwé 8.

Ọ̀nà Gíga Jùlọ Tí A Gbà Fi Ìyọ́nú Hàn

12. Ní ọ̀nà gíga jùlọ wo ni Ọlọrun gbà fi ìyọ́nú hàn?

12 Ọ̀nà gíga jùlọ tí Ọlọrun gbà fi ìyọ́nú hàn jẹ́ nípa rírán tí ó rán àyànfẹ́ Ọmọkùnrin rẹ̀ wá sórí ilẹ̀-ayé. Lóòótọ́, ìgbésí-ayé oníwàtítọ́ tí Jesu gbé mú ìdùnnú ńlá wá fún Jehofa, ní fífún un ní ìdáhùn pípé pérépéré lòdìsí àwọn ẹ̀sùn èké tí Eṣu fi kàn án. (Owe 27:11) Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí iyèméjì pé jíjìyà tí àyànfẹ́ Ọmọkùnrin rẹ̀ jìyà ikú oníkà tí ń tẹ́nilógo níṣojú rẹ̀ mú kí Jehofa ní ìrora tí ó túbọ̀ pọ̀ síi ju ohun tí òbí ènìyàn kan tíì faradà rí lọ. Ó jẹ́ ìrúbọ onífẹ̀ẹ́ gan-⁠an, tí ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìgbàlà aráyé. (Johannu 3:16) Gẹ́gẹ́ bí Sakariah, bàbá Johannu Oníbatisí, ti sọtẹ́lẹ̀, ó gbé “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọrun wa” ga.​—⁠Luku 1:​77, 78, NW.

13. Ní ọ̀nà ṣíṣe pàtàkì wo ni Jesu ti gbà ṣe ìgbéyọ àkópọ̀ ìwà Bàbá rẹ̀?

13 Rírán tí a rán Ọmọkùnrin Ọlọrun wá sórí ilẹ̀-ayé tún fún aráyé ní ojú-ìwòye tí ó túbọ̀ ṣe kedere síi nípa àkópọ̀ ìwà Jehofa. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀? Níti pé Jesu ṣe ìgbéyọ àkópọ̀ ìwà Bàbá rẹ̀ lọ́nà pípé pérépéré, pàápàá jùlọ ní ọ̀nà ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ó gbà bá àwọn ẹni rírẹlẹ̀ lò! (Johannu 1:14; 14:9) Fún ìdí yìí, àwọn òǹkọ̀wé Ìhìnrere mẹ́ta náà Matteu, Marku, àti Luku lo ọ̀rọ̀-ìṣe Griki kan, splag·khniʹzo·mai, tí ó wá láti inú ọ̀rọ̀ Griki náà fún “ìwọ́rọ́kù.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Bibeli William Barclay ṣàlàyé pé, “Láti ibi tí a ti fà á yọ gan-⁠an, a lè rí i pé kò ṣàpèjúwe àánú tàbí ìyọ́nú lásán, bíkòṣe ìmí-ẹ̀dùn kan tí ń sún ènìyàn kan láti ní ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ nínú ara rẹ̀. Òun ni ọ̀rọ̀ tí ó lágbára jùlọ nínú èdè Griki fún ìmọ̀lára ìyọ́nú.” Lónírúurú ọ̀nà ni a ti túmọ̀ rẹ̀ sí “àánú . . . ń ṣe” tàbí “àánú . . . ṣe.”​—⁠Marku 6:34, NW; 8:⁠2, NW.

Nígbà tí Àánú Ń Ṣe Jesu

14, 15. Nínú ìlú-ńlá kan ní Galili, báwo ni àánú ṣe ṣe Jesu, kí sì ni èyí mú ṣe kedere?

14 Ní ìlú-ńlá Galili ni ìran náà ti wáyé. Ọkùnrin kan “tí ó kún fún ẹ̀tẹ̀” tọ Jesu wá láìfún un ní ìkìlọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà. (Luku 5:12, NW) Jesu ha bá a wí lọ́nà lílekoko fún àìkébòsí pé, “Aláìmọ́, aláìmọ́,” gẹ́gẹ́ bí Òfin Ọlọrun ti sọ pé kí ó ṣe bí? (Lefitiku 13:45) Bẹ́ẹ̀kọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jesu tẹ́tísílẹ̀ sí ẹ̀bẹ̀ onígbèékútà ti ọkùnrin náà pé: “Bí iwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, iwọ lè mú kí emi mọ́.” Bí “àánú [ti] ṣe é,” Jesu na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì fọwọ́kan adẹ́tẹ̀ náà, ní sísọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí iwọ mọ́.” Lọ́gán ni a mú ìlera ọkùnrin náà padàbọ̀sípò. Nípa báyìí kìí ṣe pé Jesu fi agbára ìyanu rẹ̀, tí Ọlọrun fifún un hàn nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún fi ìmọ̀lára jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ó sún un láti lo irú agbára bẹ́ẹ̀ hàn pẹ̀lú.​—⁠Marku 1:​40-⁠42, NW.

15 A ha gbọ́dọ̀ tọ Jesu lọ ṣáájú kí ó tó fi ìmọ̀lára ìyọ́nú hàn bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Ní àkókò mìíràn lẹ́yìn náà, ó ṣe alábàápàdé ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ àwọn tí ń lọ sìnkú tí wọ́n ń jáde bọ̀ láti ìlú-ńlá Naini. Láìsí iyèméjì, Jesu ti rí ọ̀pọ̀ ìsìnkú rí, ṣùgbọ́n eléyìí baninínújẹ́ gan-⁠an ni. Olóògbé náà ni ọmọkùnrin kanṣoṣo tí opó náà ní. Bí “àánú [ti] ṣe é,” Jesu súnmọ́ ọn ó sì wí pé: “Dẹ́kun sísunkún.” Lẹ́yìn náà ni ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àrà-ọ̀tọ̀ ti mímú ọmọkùnrin rẹ̀ padàbọ̀ sí ìwàláàyè.​—⁠Luku 7:​11-⁠15, NW.

16. Èéṣe ti àánú ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń wọ́ tọ̀ ọ́ lẹ́yìn fi ṣe Jesu?

16 Ẹ̀kọ́ amúnijígìrì tí a rí kọ́ láti inú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wà lókè yìí ni pé nígbà tí “àánú . . . ṣe” Jesu, ó ṣe ohun gidi kan láti ṣèrànlọ́wọ́. Ní àkókò mìíràn lẹ́yìn náà, Jesu bojúwo ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń wọ́ tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Matteu ròyìn pé “àánú wọ́n ṣe é, nitori a bó wọn láwọ a sì fọ́n wọn ká bí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn.” (Matteu 9:36, NW) Ìwọ̀nba ni ohun tí àwọn Farisi ń ṣe láti tẹ́ ebi tẹ̀mí ti àwọn gbáàtúù lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n di ẹrù ọ̀pọ̀ àwọn ìlànà tí kò pọndandan ru àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn. (Matteu 12:1, 2; 15:1-⁠9; 23:4, 23) A ṣí ojú-ìwòye wọn nípa àwọn gbáàtúù payá nígbà tí wọ́n sọ nípa àwọn tí ń tẹ́tísílẹ̀ sí Jesu pé: “Ṣugbọn ogunlọ́gọ̀ yii tí kò mọ Òfin jẹ́ awọn ẹni ègún.”​—⁠Johannu 7:⁠49, NW.

17. Báwo ni àánú Jesu fún ogunlọ́gọ̀ náà ṣe sún un, ìtọ́sọ́nà lílọ jìnnà wo ni ó sì pèsè níbẹ̀?

17 Ní ìyàtọ̀, ipò ìṣòro tẹ̀mí ti àwọn ogunlọ́gọ̀ náà mú kí Jesu ní ìmọ̀lára jíjinlẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn olùfìfẹ́hàn tí ń bẹ ti pọ̀ jù fún un láti lè bójútó wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Nítorí náà ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún òṣìṣẹ́ púpọ̀ síi. (Matteu 9:​35-⁠38) Ní ìbámu pẹ̀lú irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀, Jesu rán àwọn aposteli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ìhìn-iṣẹ́ náà pé: “Ìjọba awọn ọ̀run ti súnmọ́lé.” Àwọn ìtọ́ni tí ó fún wọn ní àkókò yẹn ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìtọ́sọ́nà ṣíṣeyebíye fún àwọn Kristian títí wá di òde ìwòyí. Láìsí iyèméjì, ìmọ̀lára ìyọ́nú tí Jesu ní sún un láti tẹ́ ebi tẹ̀mí tí ń pa aráyé lọ́rùn.​—⁠Matteu 10:​5-⁠7, NW.

18. Báwo ni Jesu ṣe hùwàpadà nígbà tí àwọn ogunlọ́gọ̀ já wọ ibi kọ́lọ́fín tí ó wà, ẹ̀kọ́ wo ni a sì rí kọ́ nínú èyí?

18 Ní àkókò mìíràn, Jesu tún ní ìmọ̀lára fún àwọn àìní tẹ̀mí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà. Ní àkókò yìí ó ti rẹ òun àti àwọn aposteli rẹ̀ lẹ́yìn ìrìn-àjò ìwàásù tí ó ti mú kí ọwọ́ wọ́n dí, wọ́n sì wá ibìkan láti sinmi. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí àwọn ènìyàn fi wá wọn rí. Dípò kí Jesu bínú nítorí jíjá tí wọ́n jáwọ ibi kọ́lọ́fín tí wọ́n wà yìí, Marku kọ̀wé pé “àánú . . . ṣe é.” Kí sì ni ìdí fún ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí Jesu ní? “Wọ́n dàbí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn.” Lẹ́ẹ̀kan síi, Jesu gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀lára tí ó ní ó sì bẹ̀rẹ̀ síí kọ́ ogunlọ́gọ̀ náà “nipa ìjọba Ọlọrun.” Bẹ́ẹ̀ni, ebi tẹ̀mí tí ń pa wọ́n mú kí ó ní ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi ìsinmi tí ó nílò rúbọ láti kọ́ wọn. ​—⁠Marku 6:34, NW; Luku 9:11, NW.

19. Báwo ni àníyàn Jesu fún ogunlọ́gọ̀ náà ṣe lọ rékọjá àwọn àìní tẹ̀mí wọn pàápàá?

19 Nígbà tí ó jẹ́ pé àìní tẹ̀mí àwọn ènìyàn ni ó kọ́kọ́ jẹ ẹ́ lógún, Jesu kò gbójúfo àwọn àìní ti ara wọn tí ó ṣekókó. Ní àkókò yẹn kan náà, ó tún “mú awọn wọnnì tí wọ́n nílò ìwòsàn láradá.” (Luku 9:11, NW) Ní àkókò mìíràn, àwọn ogunlọ́gọ̀ ti wà pẹ̀lú rẹ̀ fún àkókò gígùn, wọ́n sì ti rìn jìnnà sílé. Bí ó ti nímọ̀lára nípa àìní ti ara wọn, Jesu wí fún àwọn aposteli rẹ̀ pé: “Àánú ogunlọ́gọ̀ naa ń ṣe mí, nitori pé ó ti di ọjọ́ mẹ́ta nísinsìnyí tí wọ́n ti wà pẹlu mi wọn kò sì ní nǹkankan lati jẹ; emi kò sì fẹ́ rán wọn lọ ní gbígbààwẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí okun wọ́n tán ní ojú ọ̀nà.” (Matteu 15:32, NW) Wàyí o, Jesu wá ṣe ohun kan láti mú ìjìyà tí ó ṣeéṣe kí ó wà kúrò. Ó fi ìṣù búrẹ́dì méje àti ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pèsè oúnjẹ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé lọ́nà ìyanu.

20. Kí ni a rí kọ́ láti inú àpẹẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọsílẹ̀ kẹ́yìn nípa bí àánú tí ń ṣe Jesu?

20 Àpẹẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọsílẹ̀ kẹ́yìn nípa bí àánú ti ṣe Jesu jẹ́ nígbà ìrìn-àjò ráńpẹ́ tí ó ṣe kẹ́yìn sí Jerusalemu. Ogunlọ́gọ̀ ńlá ń rìnrìn-àjò pẹ̀lú rẹ̀ láti ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá. Ní ojú-ọ̀nà lẹ́bàá Jeriko, àwọn afọ́jú oníbárà méjì kan ń kígbe tòò pé: “Oluwa, ṣàánú fún wa.” Àwọn ogunlọ́gọ̀ náà gbìyànjú láti pa wọ́n lẹ́nu mọ́, ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n ó sì béèrè ohun tí wọ́n fẹ́ kí òun ṣe. Wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé, “‘Oluwa, jẹ́ kí ojú wá là.’ Bí àánú ti ṣe é,” ó fọwọ́kan ojú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí ríran. (Matteu 20:​29-⁠34, NW) Ẹ wo ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a rí kọ́ láti inú èyí! Jesu ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ ọ̀sẹ̀ tí ó kẹ́yìn nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Ó ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe ní àṣeparí ṣáájú kí ó tó jìyà ikú oníkà láti ọwọ́ àwọn aṣojú Satani. Síbẹ̀, kò yọ̀ọ̀da fún ìkìmọ́lẹ̀ àkókò ṣíṣe pàtàkì yìí láti mú kí òun máṣe fi ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú hàn fún àwọn àìní tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tí àwọn ènìyàn ní.

Àwọn Àkàwé Tí Wọ́n Tẹnumọ́ Ìyọ́nú

21. Kí ni fífà tí ọ̀gá náà fagilé gbèsè rẹpẹtẹ ẹrú rẹ̀ mú ṣe kedere?

21 Ọ̀rọ̀-ìṣe Griki náà splag·khniʹzo·mai, tí a lò nínú àwọn ìròyìn ìgbésí-ayé Jesu wọ̀nyí, ni a tún lò nínú mẹ́ta lára àwọn àkàwé Jesu. Nínú ìtàn kan ẹrú kan bẹ̀bẹ̀ fún àkókò láti san gbèsè rẹpẹtẹ kan padà. Ọ̀gá rẹ̀, tí “àánú . . . ṣe,” fagilé gbèsè náà. Èyí ṣàpèjúwe pé Jehofa Ọlọrun ti fi ìyọ́nú ńláǹlà hàn nípa fífagilé gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹpẹtẹ ti Kristian kọ̀ọ̀kan tí ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu.​—⁠Matteu 18:27, NW; 20:⁠28.

22. Kí ni òwe-àkàwé ọmọkùnrin onínàákúnàá náà mú ṣe kedere?

22 Ìtàn ti ọmọkùnrin onínàákúnàá tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Rántí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọmọkùnrin aṣetinúurẹ̀ náà padà sílé. “Nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn, baba rẹ̀ tajúkán rí i àánú sì ṣe é, ó sì sáré ó sì rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀ ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.” (Luku 15:20, NW) Èyí fihàn pé nígbà tí Kristian kan tí ó ti di aṣetinú-ẹni bá fi ojúlówó ìrònúpìwàdà hàn, àánú yóò ṣe Jehofa yóò sì gba onítọ̀hún padà lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Nípa báyìí, nípasẹ̀ àwọn àkàwé méjì wọ̀nyí, Jesu fihàn pé Bàbá wa, Jehofa, “jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ oníyọ̀ọ́nú.”​—⁠Jakọbu 5:11, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé, NW.

23. Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ láti inú àkàwé Jesu nípa aládùúgbò rere ará Samaria?

23 Ọ̀nà kẹta tí a gbà lo splag·khniʹzo·mai lọ́nà ìṣàkàwé nííṣe pẹ̀lú oníyọ̀ọ́nú ará Samaria náà tí “àánú ṣe” nígbà tí ó rí ipò ìṣòro Ju kan tí a ti jàlólè tí a si fi sílẹ̀ láìkú tán. (Luku 10:33, NW) Ní gbígbé ìgbésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí, ará Samaria náà ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní agbára rẹ̀ láti ran àlejò náà lọ́wọ́. Èyí fihàn pé Jehofa àti Jesu retí pé kí àwọn Kristian tòótọ́ tẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn nínú fífi ìwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ìyọ́nú hàn. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí a lè gbà ṣe èyí ni a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.

Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò

◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti jẹ́ aláàánú?

◻ Báwo ni Jehofa ṣe fi ìyọ́nú hàn nítorí orúkọ rẹ̀?

◻ Ní ọ̀nà gíga jùlọ wo ni a gbà fi ìyọ́nú hàn?

◻ Ní ọ̀nà àrà-ọ̀tọ̀ wo ni Jesu gbà ṣe àgbéyọ àkópọ̀ ìwà Bàbá rẹ̀?

◻ Kí ni a rí kọ́ láti inú ìgbésẹ̀ oníyọ̀ọ́nú tí Jesu gbé àti láti inú àwọn àkàwé rẹ̀?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

ÈDÈ-ÌSỌ̀RỌ̀ ALÁPẸẸRẸ FÚN “ÀBÓJÚTÓ ONÍFẸ̀Ẹ́ LỌ́NÀ JẸ̀LẸ́ŃKẸ́”

WÒLÍÌ Jeremiah kígbe pé, “Inú mi, inú mi!” Òun ha ń ṣàròyé nípa inú rírun nítorí ohun kan tí kò dára tí ó ti jẹ bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Jeremiah ń lo àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ti èdè Heberu kan láti ṣàpèjúwe àníyàn rẹ̀ jíjinlẹ̀ nítorí àjálù tí ń bọ̀wá sórí ìjọba Juda.​—⁠Jeremiah 4:⁠19.

Níwọ̀n bí Jehofa Ọlọrun ti ní àwọn ìmọ̀lára jíjinlẹ̀, ọ̀rọ̀ Heberu náà fún “ìwọ́rọ́kù,” tàbí “ìfun” (me·ʽimʹ), ni a tún lò láti ṣàpèjúwe àwọn ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ṣáájú àwọn ọjọ́ Jeremiah, ìjọba ẹlẹ́yà mẹ́wàá ti Israeli ni ọba Assiria kó nígbèkùn. Jehofa yọ̀ọ̀da èyí gẹ́gẹ́ bí ìjìyà fún àìṣòtítọ́ wọn. Ṣùgbọ́n Ọlọrun ha gbàgbé wọn sí ìgbèkùn bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Ọkàn rẹ̀ ṣì fà mọ́ wọn típẹ́típẹ́ gẹ́gẹ́ bí apákan lára àwọn ènìyàn májẹ̀mú rẹ̀. Ní fífi orúkọ ẹ̀yà yíyọrí-ọlá náà Efraimu pè wọ́n, Jehofa béèrè pé: “Ọmọ ọ̀wọ́n ha ni Efraimu fún mi, tàbí ọmọ tí mo ń lò sí pẹ̀lú ìkúdùn-fẹ́ràn? Nítorí pé bí mo ti sọ̀rọ̀ sí i tó nì èmi kì yóò kùnà láti rántí rẹ̀ síwájú síi. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ìwọ́rọ́kù mi fi ń pariwo líle nítorí rẹ̀. Ní gbogbo ọ̀nà ni èmi yóò ṣàánú rẹ̀.”​—⁠Jeremiah 31:⁠20, NW.

Nípa sísọ pé ‘ìwọ́rọ́kù mi ń pariwo líle,’ Jehofa lo àkànlò-èdè ayàwòrán láti ṣàpèjúwe ìmọ̀lára ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ tí ó ní fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a kó lọ sí ìgbèkùn. Nínú àlàyé rẹ̀ lórí ẹsẹ yìí, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún E. Henderson kọ̀wé pé: “Kò sí ohun kan tí ó lè tayọ ìfihàn ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ bíi ti òbí sí ọmọ onínàákúnàá tí ó padà wálé, èyí tí Jehofa mú wá sójútáyé níhìn-⁠ín. . . . Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti sọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀ lòdìsí [àwọn ọmọ Efraimu abọ̀rìṣà] tí ó sì ti fìyà jẹ wọ́n . . . , òun kò jẹ́ gbàgbé wọn, ṣùgbọ́n, dípò èyíinì, ó ní inúdídùn nínú ìfojúsọ́nà fún ìmúpadàbọ̀sípò wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.”

Ọ̀rọ̀ Griki náà fún “ìfun,” tàbí “ìwọ́rọ́kù,” ni a lò ní ọ̀nà kan náà nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki. Nígbà tí a kò bá lò ó ní olówuuru, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú Iṣe 1:18, ó ń tọ́ka sí èrò ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìfẹ́ni tàbí ìyọ́nú. (Filemoni 12) Nígbà mìíràn ọ̀rọ̀ náà ni a máa ń sopọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ Griki náà tí ó túmọ̀sí “dídára” tàbí “sísunwọ̀n.” Aposteli Paulu àti Peteru lo àpapọ̀ àwọn gbólóhùn náà nígbà tí ó ń fún àwọn Kristian ní ìṣírí láti ní “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́,” ní olówuuru “nítẹ̀sí gidigidi síhà àánú.” (Efesu 4:32, NW; 1 Peteru 3:8, NW) Ọ̀rọ̀ Griki náà fún “ìfun” ni a tún lè so pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ Griki náà pol·yʹ. Àpapọ̀ èyí tí ó túmọ̀sí “níní ìfun púpọ̀” ní olówuuru. Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a lo gbólóhùn ọ̀rọ̀ Griki tí kò wọ́pọ̀ yìí nínú Bibeli, ó sì tọ́ka sí Jehofa Ọlọrun. Bibeli New World Translation fúnni ni ìtumọ̀ yìí: “Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni.”​—⁠Jakọbu 5:⁠11, NW.

Ẹ wo bí ó ti yẹ kí a kún fún ọpẹ́ tó pé ẹni alágbára jùlọ lágbàáyé, Jehofa Ọlọrun, kò dàbí àwọn ọlọrun oníkà tí àwọn ènìyàn aláìníyọ̀ọ́nú hùmọ̀ rárá! Ní àfarawé Ọlọrun wọn “oníyọ̀ọ́nú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́,” àwọn Kristian tòótọ́ ni a sún láti gbégbèésẹ̀ bákan náà nínú ìbálò wọn pẹ̀lú araawọn lẹ́nìkínní kejì.​—⁠Efesu 5:⁠1.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nígbà tí ìyọ́nú àtọ̀runwá dé ìpẹ̀kun rẹ̀, Jehofa yọ̀ọ̀da fún àwọn ará Babiloni láti ṣẹ́gun àwọn ènìyàn rẹ̀ aṣetinú-ẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Kíkú tí àyànfẹ́ Ọmọkùnrin rẹ̀ kú níṣojú rẹ̀ ti níláti mú kí Jehofa Ọlọrun ní ìrora tí ó ga ju èyí tí ẹnikẹ́ni tíì faradà rí lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jesu ṣe ìgbéyọ àkópọ̀ ìwà Bàbá rẹ̀ oníyọ̀ọ́nú lọ́nà pípé pérépéré

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́