ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 12/1 ojú ìwé 28-30
  • Títẹ́ Olórí Àìní Ẹ̀dá Ènìyàn Lọ́rùn Nípa Ìkanisí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Títẹ́ Olórí Àìní Ẹ̀dá Ènìyàn Lọ́rùn Nípa Ìkanisí
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìkanisí​—⁠Olórí Àìní Kan
  • Ṣe Àfarawé Àpẹẹrẹ Jehofa ní Kíkanisí
  • Ìkanisí Láàárín Agbo Ìdílé
  • Ìkanisí Láàárín Ìjọ Kristian
  • Sapá Láti Fúnni àti Láti Gba Ìkanisí tí Ó Yẹ
  • Ojúure Ta Lò Ń Wá?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Fífi Ìdúróṣinṣin Tẹrí Ba fún Ìṣàkóso Ọlọ́run
    Kọrin sí Jèhófà
  • Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • “Arákùnrin Ni Gbogbo Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 12/1 ojú ìwé 28-30

Títẹ́ Olórí Àìní Ẹ̀dá Ènìyàn Lọ́rùn Nípa Ìkanisí

“Okáre!” “Mo bá ọ yọ̀!” tàbí “O gbìyànjú; inú wa dùn gan-⁠an ni” tí ó wá láti inú-ọkàn máa ń ṣe púpọ̀ láti fikún iyì-ara-ẹni, ní pàtàkì nígbà tí ó bá wá láti ẹnu ẹnìkan tí o bọ̀wọ̀ fún. Ìkanisí máa ń gbádùn mọ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ, wọ́n ń ṣe púpọ̀ sí i wọ́n sì ń láyọ̀ sí i. Níti tòótọ́, bí oúnjẹ tí ó dára ṣe ṣekókó fún ara bẹ́ẹ̀ ni ìkanisí tí ó yẹ fúnni jẹ́ ohun tí ó ṣe kókó fún ìrònú àti ọkàn-àyà.

Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ ìkanisí gẹ́gẹ́ bí i “gbígbà pé ẹnì kan yẹ ni ẹni tí a ń gba tirẹ̀ rò tàbí tí ó yẹ fún àfiyèsí” àti “àkànṣe ìgbatẹnirò tàbí àfiyèsí.” Ó tan pẹ́kípẹ́kí mọ́ ọ̀wọ̀, ìmọ̀lára iyì-ara-ẹni, èyí tí ó jẹ́ pé nígbà tí a bá fúnni ó túmọ̀ sí ìdíwọ̀n tàbí ìdíyelé tí a fòye ṣe nípa ẹnìkan àti ìwọ̀n ìkanisí tí ó yẹ fún ẹni náà.

Ìkanisí​—⁠Olórí Àìní Kan

Fífúnni ní ìyìn níbi tí ìyìn bá ti yẹ lọ́gbọ́n nínú ó sì bójúmu. Jesu fi àpẹẹrẹ náà lélẹ̀ nínú àkàwé rẹ̀ nípa àwọn ẹrú tí ọ̀gá wọn fi àwọn ohun-ìní rẹ̀ sí ìkáwọ́ wọn. Ní mímọrírì ọ̀nà ìgbà mójútó àwọn dúkìá-ìní rẹ̀ lọ́nà tí ó tọ́, ó wí pé: “O káre láé ẹrú rere ati olùṣòtítọ́!” (Matteu 25:​19-⁠23, NW) Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́pọ̀ ìgbà ìwà-rere yíyẹ yìí ni a máa ń gbójúfòdá. Ìkùnà láti kanisí máa ń tẹ ìtara àti ọgbọ́n àtinúdá rì. Iona sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Ìkanisí máa ń mú kí o nímọ̀lára pé a nílò rẹ, a fẹ́ ọ, a sì mọrírì rẹ . . . Ó ń fún ọ ní ọgbọ́n àtinúdá. Bí a bá gbójúfò ọ́ dá, ìwọ yóò nímọ̀lára pé o kò jámọ́ nǹkankan àti pé a ti ṣá ọ tì.” Patrick fikún un pé: “Yóò nira nígbà náà láti ní ànímọ́ àti àmújáde tí ó wuyì.” Nítorí náà, ẹ wo bí ó ti ṣekókó tó kí a kọ́ bí a ṣe lè kanisí àti ìgbà tí a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo wa ni a ń yánhànhàn fún ìbàlẹ̀-ọkàn ti mímọ̀ pé a jámọ́ nǹkan. Ó jẹ́ olórí àìní ẹ̀dá ènìyàn.

Ọ̀rọ̀ ìyìn, àfikún ẹrù-iṣẹ́, tàbí ẹ̀bùn ohun ti ara pàápàá lè ru ọ sókè láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣe ìwọ̀n tí o bá lè ṣe. Èyí jẹ́ òtítọ́ yálà o jẹ́ òbí, ọkọ, aya, ọmọ, mẹ́ḿbà ìjọ, tàbí alábòójútó. Margaret sọ pé, “Nígbà tí a bá kà mi sí, inú mi máa ń dùn, mo ń nímọ̀lára pé a nílò mi, mo ń nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti ṣe dáradára síi.” Andrew pẹ̀lú fohùnṣọ̀kan, ní sísọ pé: “Inú mi máa ń dùn, ó sì máa ń pèsè ìsúnniṣe láti túbọ̀ tẹramọ́ iṣẹ́.” Bí ó ti wù kí ó rí, láti kanisí kí a sì fi ọ̀wọ̀ fún ẹnì kan ń béèrè fún ìrònú àti ìdájọ́ rere.

Ṣe Àfarawé Àpẹẹrẹ Jehofa ní Kíkanisí

Àpẹẹrẹ tí ó gba iwájú jùlọ níti kíka ìjámọ́ pàtàkì àwọn ẹlòmíràn sí ni ti Jehofa Ọlọrun. Ó mọ àwọn wọnnì tí wọ́n yẹ ní kíkàsí. Ó kíyèsí àwọn ọkùnrin bí Abeli, Enoku, àti Noa. (Genesisi 4:⁠4; 6:⁠8; Juda 14) Jehofa mọrírì Dafidi fún ìṣòtítọ́ títayọ rẹ̀. (2 Samueli 7:16) Samueli, gẹ́gẹ́ bíi wòlíì kan tí ó bọlá fún Jehofa fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ni Ọlọrun tún padà bọlá fún, ẹni tí ó tètè dáhùn àdúrà Samueli fún ìrànlọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn Filistini. (1 Samueli 7:​7-⁠13) Ìwọ kì yóò ha ní ìmọ̀lára ìbọláfún láti ní irú ìkanisí láti ọ̀run wá bẹ́ẹ̀ bí?

Ìmoore àti ìmọrírì ní ìsopọ̀ pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú ìkanisí. Bibeli rọ̀ wá láti ‘fi ara wa hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́’ àti láti jẹ́ olùmoore fún ohun tí a ṣe nítorí wa. (Kolosse 3:15, NW; 1 Tessalonika 5:18) Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ṣíṣọpẹ́ fún Jehofa ni èyí tọ́ka sí ní pàtàkì, bákan náà ni ó ṣe rí níti àwọn ọ̀ràn ojoojúmọ́ nínú ìgbésí-ayé. Aposteli Paulu mọrírì èyí. Ó ka Febe sí gẹ́gẹ́ bí “olùgbèjà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn” àti Priska àti Akuila fún ‘fífi ọrùn ara wọn wewu’ nítorí tirẹ̀ àti ti àwọn ẹlòmíràn. (Romu 16:​1-⁠4, NW) Ronú nípa bí ìmọ̀lára wọn yóò ti rí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gba irú ìmoore tí a sọ ní gbangba bẹ́ẹ̀. Ó jẹ́ ohun tí ó dára fún Paulu pẹ̀lú láti ní ayọ̀ tí ń jẹyọ láti inú kíkanisí, fífúnni ní ọlá, àti ìṣírí. Àwa pẹ̀lú lè ṣe àfarawé Jehofa àti àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ onímọrírì nípa fífi ìkanisí tí ó yẹ hàn fún àwọn wọnnì tí wọ́n tọ́ sí i.​—⁠Iṣe 20:⁠35.

Ìkanisí Láàárín Agbo Ìdílé

Mitchell, ọkọ àti Kristian alàgbà kan, sọ pé: “Ìwọn ìkanisí díẹ̀ máa ń ṣèrànlọ́wọ́ púpọ̀ láti mú kí ìgbésí-ayé gbádùnmọ́ni. Ó ń mú kí o nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ó kà ọ́ sí, ó tilẹ̀ lè jẹ́ títíláé.” Fún àpẹẹrẹ, Kristian ọkọ kan ń gbé ẹrù-iṣẹ́ wíwúwo ó sì ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tí ó wémọ́ ire ìdílé náà. Ó gbọ́dọ̀ pèsè fún àwọn àìní ìdílé náà, nípa tẹ̀mí, ti ara, ati ti èrò-ìmọ̀lára. (1 Timoteu 5:8) Ẹ wo bí yóò ti láyọ̀ tó nígbà tí a bá ka iṣẹ́ rẹ̀ tí Ọlọrun yàn fún un gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé sí lọ́nà yíyẹ àti nígbà tí aya rẹ̀ bá fún un ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀”!​—⁠Efesu 5:⁠33, NW.

Ohun kan tí a kò níláti gbójúfòdá ni iṣẹ́ ìyàwó-ilé kan, tí ó ń ṣe níbi tí kò sí ní ojútáyé. Àwọn ìpìlẹ̀-èrò ti òde-òní lè fojú yẹpẹrẹ wo irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ kí wọ́n sì fi iyì-ọlá àti ìtóye rẹ̀ dù ú. Síbẹ̀, ó dùn mọ́ Ọlọrun nínú. (Titu 2:​4, 5) Ẹ wo bí ó ṣe tunilára tó nígbà tí ọkọ kan tí ó ní ìfòyemọ̀ bá yin aya rẹ̀, ní pàtàkì ní gbogbo apá ìgbésí-ayé tí ó ti ń ṣe dáradára, ní fífún un ní irú ìkanisí bẹ́ẹ̀ lábẹ́ ipò orí rẹ̀! (Owe 31:28) Rowena sọ nípa ọkọ rẹ̀ pé: “Nígbà tí ó bá fi ìmọrírì hàn fún ohun tí mo ṣe, ó máa ń rọrùn fún mi láti tẹríba fún un àti láti bọlá fún un kí n sì bọ̀wọ̀ fún un.”

Olùkọ́ni ara America Christian Bovee sọ nígbà kan rí pé: “Bí oòrùn ti wúlò fún ìdàgbàsókè àwọn òdòdó bẹ́ẹ̀ ni ìyìn tí ó bójúmu ṣe ń gbádùnmọ́ àwọn ọmọdé.” Bẹ́ẹ̀ni, àní ọmọ kékeré pínníṣín kan nílò ìmúdánilójú léraléra pé òun jẹ́ mẹ́ḿbà kan tí a kà sí pàtàkì nínú ìdílé. Láàárín àwọn ọdún ìdàgbàsókè, tí ó kún fún àwọn èrò-ìmọ̀lára titun àti ìyípadà ti ara-ìyára, àfiyèsí-ara-ẹni púpọ̀ síi máa ń débá ìrísí ara-ẹni, papọ̀ pẹ̀lú ìyánhànhàn fún ìdádúró lómìnira àti ìkanisí. Ní pàtàkì ní àkókò yìí, ọ̀dọ́langba kan a máa fẹ́ láti nímọ̀lára pé àwọn òbí òun nífẹ̀ẹ́ òun àti pé kí a fi òye àti inúrere ti ẹ̀dá ènìyàn bá òun lò. Bákan náà àwọn òbí tí ń darúgbó àti àwọn òbì-àgbà ń fẹ́ kí a mú un dá wọn lójú pé wọ́n ṣì wúlò àti pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, pé a kò ‘ṣá wọn tì lọ́jọ́ ogbó.’ (Orin Dafidi 71:⁠9; Lefitiku 19:32; Owe 23:22) Títẹ́ àìní náà fún ìkanisí lọ́rùn lọ́nà bíbójúmu ń mú ayọ̀ àti àṣeyọrí púpọ̀ síi wá sínú agbo ìdílé.

Ìkanisí Láàárín Ìjọ Kristian

Ìníyelórí gígalọ́lá wà nínú mímú ọkàn-ìfẹ́ tí ó tọkànwá dàgbà nínú àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ Kristian àti sísọ̀rọ̀ ìmọrírì jáde fàlàlà fún àwọn iṣẹ́ àti ìsapá wọn. Àwọn Kristian alàgbà níláti mú ipò iwájú nípa fífi ìmọrírì hàn fún àṣeyọrí àti ìsapá àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Margaret wí pé, “Àyàfi ìgbà tí wọ́n ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùtàn sọ́dọ̀ mi ni mo tó wá mọ̀ bí àwọn ọ̀rọ̀ ìkanisí ti ń nípa lórí ẹni tó níti ìṣírí, ìtẹ́lọ́rùn, àti ayọ̀. Mo wá mọ ohun tí ẹnì kan pàdánù nígbà tí a bá fi ìkanisí tí ó yẹ dù ú.” Ẹ wo ìdí rere tí èyí jẹ́ fún níní ojúlówó, ọkàn ìfẹ́ nínú gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ìjọ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan! Mọrírì iṣẹ́ rere wọn. Gbóríyìn fún wọn kí o sì fún wọn ní ìṣírí ní fàlàlà. Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìjọ àwọn ìdílé anìkàntọ́mọ ń bẹ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti gbin àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n tẹ̀mí sínú àwọn ọmọ wọn. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ fún àkànṣe ìyìn. Tẹnumọ́ àwọn apá tí ó dára dípò àwọn tí kò dára. Jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn rí ìfẹ́ni-ará tí o ní fún wọn. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o bìkítà. Ní ọ̀nà yìí, àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ ń ṣiṣẹ́ láti gbé ìjọ ró. (2 Korinti 10:8) Mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan ń san án padà nípa fífún irú àwọn olùṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ kára nítorí wọ́n ní ìkanisí àti ọ̀wọ̀ tí ó yẹ.​—⁠1 Timoteu 5:17; Heberu 13:⁠17.

Ṣùgbọ́n apá, tàbí igun ìwòye mìíràn, wà lórí ọ̀ràn yìí. A gbà pé ìfẹ́-ọkàn fún ìkanisí lágbára púpọ̀ gan-⁠an. Ní ọjọ́ Jesu ó di kókó tí ó pàfiyèsí láàárín àwọn aṣáájú ìsìn. Jesu níláti tún ojú-ìwòye òdì tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní lórí ọ̀ràn yìí ṣe. (Marku 9:​33-⁠37; Luku 20:46) Àwọn Kristian nílò ìfòyebánilò àti ìwàdéédéé. Bí a kò bá káwọ́ rẹ̀, ìfẹ́-ọkàn fún ìkanisí lè léwu nípa tẹ̀mí. (Jakọbu 3:​14-⁠16) Fún àpẹẹrẹ, ẹ wo bí yóò ṣe baninínújẹ́ tó, bí alàgbà kan ba di onírera tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi dandan lé e pé kí àwọn ẹlòmíràn tẹ́wọ́gba ojú-ìwòye gíga tí ó ní nípa araarẹ̀!​—⁠Romu 12:⁠3.

Aposteli Paulu fi pẹ̀lú ọgbọ́n gba àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Romu níyànjú pé: “Ninu ìfẹ́ ará ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nìkínní kejì. Ninu bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nìkínní kejì ẹ mú ipò iwájú.” (Romu 12:10, NW) Lọ́nà títayọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tọ́ka sí àwọn Kristian alàgbà, tí wọ́n níláti ka Kristi sí gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ nígbà gbogbo. Ìtẹríba fún agbára ọlá-àṣẹ rẹ̀ ni a ń fihàn nípa wíwá ìtọ́sọ́nà Kristi nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, àwọn ìlànà Bibeli, àti ìdarí tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti “olùṣòtítọ́ ati ọlọgbọ́n-inú ẹrú” ń fi fúnni.​—⁠Matteu 24:​45-⁠47, NW; wo Ìṣípayá 1:16, 20; 2:⁠1.

Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí àwọn alàgbà bá pàdé, tí wọ́n sì gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Jehofa láti ṣolùṣọ́ àgùtàn agbo Ọlọrun, wọn yóò làkàkà láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó yèkooro lójú ìwòye Ìwé Mímọ́. Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Kristian, ìwàtútù, àti ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn kì yóò fàyègba alàgbà èyíkéyìí láti gbìyànjú láti gbé araarẹ̀ ga, kí ó jẹ gàba lórí àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó sì rinkinkin mọ́ èrò tirẹ̀ nínú àwọn ìpàdé wọ̀nyí. (Matteu 20:​25-⁠27; Kolosse 3:12) Nígbàkugbà tí ó bá ṣeéṣe, alága ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yóò ṣe rere láti béèrè fún ọ̀rọ̀-àjọrò ṣáájú àkókò láti ẹnu àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kí ó sì pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀rọ̀-àjọrò tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò kí ó lè fàyè sílẹ̀ fún ríronú lé kókó kọ̀ọ̀kan tí a tòlẹ́sẹẹsẹ lórí dáradára àti tàdúrà-tàdúrà. Lákòókò ìpàdé àwọn alàgbà, yóò gbìyànjú, kì í ṣe láti darí èrò àwọn alàgbà mìíràn, bíkòṣe pé kí ó fún wọn ní ìṣírí láti lo “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ” lórí àwọn ọ̀ràn tí wọ́n bá ń jíròrò. (1 Timoteu 3:13, NW) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn tí wọ́n jùmọ̀ jẹ́ alàgbà níláti tẹ́tísílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹnìkínní kejì wọn kí wọ́n sì fi tayọ̀tayọ̀ jàǹfààní láti inú ìjìnlẹ̀-òye àwọn alàgbà tí wọ́n ní ìrírí ọ̀pọ̀ ọdún gẹ́gẹ́ bí Kristian.​—⁠Eksodu 18:​21, 22.

Bí ó ti wù kí ó ri, àwọn alábòójútó lóye pé Kristi lè lo alàgbà èyíkéyìí nínú ẹgbẹ́ náà láti pèsè àwọn ìlànà Bibeli tí a nílò láti kojú àwọn ìpò kan tàbí lati ṣe ìpinnu kan tí ó ṣe pàtàkì. Ẹ̀mí tí ó dára yóò gbilẹ̀ láàárín ẹgbẹ́ náà nígbà tí a bá fún alàgbà kọ̀ọ̀kan ní ìkanisí tí ó bójúmu fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní bíbójútó ire tẹ̀mí ìjọ náà.​—⁠Iṣe 15:​6-⁠15; Filippi 2:​19, 20.

Sapá Láti Fúnni àti Láti Gba Ìkanisí tí Ó Yẹ

Ìkanisí ń gbéniró. Ó ń fúnni ní ìṣírí ó sì ń fi ìfẹ́ hàn. Mary sọ pé, “Bí a bá tilẹ̀ nímọ̀lára pé a kò jámọ́ nǹkankan, a nílò ìṣírí fún ìtóye ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.” Fi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún ìsapá ojoojúmọ́ tí àwọn ẹlòmíràn ń ṣe. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń mú kí ìgbésí-ayé túbọ̀ dára síi kí ó sì gbádùn mọ́ wọn. Ẹ̀yin òbí, ẹ̀yin ọmọ, ẹ̀yin alábòójútó, àti ẹ̀yin mẹ́ḿbà ìjọ Kristian, ẹ lè rí ìkanisí gbà nípa àwọn ọ̀nà tí ẹ ń gbà sọ̀rọ̀ tí ẹ sì ń gbà hùwà. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa àwọn òṣìṣẹ́ aláápọn, oníwọ̀ntunwọ̀nsì, àti onírẹ̀lẹ̀-ọkàn lọ́nà rere. (Owe 11:⁠2; 29:23; Heberu 6:​1-⁠12) Kọ́ láti fi ìmọrírì oníwàrere hàn fún ìníyelórí àwọn ẹlòmíràn. Gba ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn rò bí o ṣe ń bá wọn ṣisẹ́pọ̀. Aposteli Peteru fúnni ní ọ̀rọ̀-ìyànjú yìí pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan naa, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò-inú.” (1 Peteru 3:⁠8, NW) Èyí ń béèrè fún fífún àwọn ẹlòmíràn ní ìkanisí, kí a lè tipa bẹ́ẹ̀ tẹ́ olórí àìní ẹ̀dá ènìyàn lọ́rùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́