Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gileadi Ń Háragàgà Láti Tan Ìhìnrere Kálẹ̀
“ÓJẸ́ ohun àgbàyanu jùlọ tí a tí ì lálàá rẹ̀ rí.” Bí ìmọ̀lára Anders àti Amalia Groth ti rí nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì nìyẹn. Wọ́n sọ ìmọ̀lára gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege 48 ti kíláàsì kẹtàdínlọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead jáde ní àfikún sí i pé: “Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Gileadi ti ru wá sókè ó sì ti múra wa sílẹ̀, débi pé a ń háragàgà láti lọ sẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni wa titun.”
A lè kíyèsí ìdùnnú yìí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń sọ̀rọ̀ ìlóhùnsí nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà; àwọn 6,420 ni wọ́n péjọpọ̀ fún ti ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà, ní September 4, 1994.
David Abel àti aya rẹ̀, Kelli, wí pé: “Theodore Jaracz ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni ó ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nípa sísọ̀rọ̀ lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà ‘Jíjẹ́ Ẹni Tí Jehofa Kọ́.’ Kókó tí a kò jẹ́ gbàgbé láé ni ìgbà tí Arákùnrin Jaracz wí pé: ‘A gbọ́dọ̀ mọ bí àwa ti kéré tó ní ìfiwéra pẹ̀lú Jehofa,’ ó sì fi ẹ̀kọ́ lílágbára tí a rí nínú Jobu orí 38 àti 39 ṣe àkàwé rẹ̀. Arákùnrin Jaracz sọ ní pàtó pé nígbà tí ó jẹ́ pé a ti tipasẹ̀ Ilé-Ẹ̀kọ́ Gileadi mú òye wa nípa Bibeli pọ̀ síi, àwa kò mọ ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè. A gbọ́dọ̀ máa báa lọ ní kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.”
Nígbà yìí ni Christian àti Angele Coffy wá sọ̀rọ̀ pé: “Ọ̀rọ̀-àsọyé tí Max Larson sọ lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà ‘Kí Ni Ìníyelórí Ìpìlẹ̀ Rere?’ wú wa lórí. A gbádùn bí ó ṣe fi wá wé ilé kan tí ó nílò ìpìlẹ̀ tí ó jinlẹ̀ lórí ilẹ̀ líle kí ó baà lè dúró gbagidi kódà bí ìmìtìtì ilẹ̀ bá wáyé. Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ taápọn-taápọn, a lè mú ipò-ìbátan tí ó túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Jehofa a sì lè gbé ìgbàgbọ́ wa karí ìmọ̀ tí ó jinlẹ̀ kí a baà lè dúró gbagidi ní àwọn àkókó ìnira.”
Gary àti Lynn Elfers wí pé: “Ọ̀rọ̀-àsọyé tí Milton Henschel, ààrẹ ilé-ẹ̀kọ́ náà sọ, lórí ẹsin-ọ̀rọ̀ náà ‘Pápá Ti Funfun fún Ìkórè’ ni àwa yóò máa rántí fún ìgbà pípẹ́. Lájorí ìwé mímọ́ tí ó lò, Johannu 4:35-38, tẹnumọ́ àǹfààní tí a ní láti wọnú pápá kan tí àwọn òṣìṣẹ́ kan ti fúnrúgbìn sí tẹ́lẹ̀. Èyí yóò gún wa ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òye ìmọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú.” Ní gbígbà pẹ̀lú èyí, Jan àti Sirpa Vaahtola sọ̀rọ̀ ìlóhùnsí pé: “Arákùnrin Henschel ru ìfojúsọ́nà wa sókè sí ìkórè kan tí yóò wáyé ní ọjọ́ iwájú nípa fífúnni ní ìròyìn tí ó dé kẹ́yìn láti Baltic States. Ìbísí ní Estonia jẹ́ ìpín 51 nínú ọgọ́rùn-ún, ní Latvia ìpín 106 nínú ọgọ́rùn-ún, àti ní Lithuania ìpín 51 nínú ọgọ́rùn-ún. Ẹ wo bí ó ti runisókè tó! Àwọn ará tí wọ́n wà níbẹ̀ ń bẹ Ọ̀gá náà láti rán àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ síi jáde. A láyọ̀ gidigidi láti gbọ́ èyí, níwọ̀n bí Estonia ti jẹ́ ibi iṣẹ́ àyànfúnni wa!”
Kevin àti Evelyn Cortina rántí pé: “Joel Adams ni ó sọ̀rọ̀ tẹ̀lé e lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà ‘Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Jehofa.’ Ó gbà wá nímọ̀ràn pé a kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé, nígbà mìíràn a lè gbẹ́kẹ̀lé Jehofa, nígbà mìíràn a sì lè gbẹ́kẹ̀lé èrò tiwa. Nínú iṣẹ́ àyànfúnni wa àwa yóò dojúkọ ọ̀pọ̀ ìpèníjà—ìlera, oúnjẹ, èdè, àṣà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo wọn yóò béèrè pé kí a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa.”
Ẹni tí ó sọ̀rọ̀ tẹ̀lé e ni Gerrit Lösch, mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tí ó sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Ẹ Máa Báa Lọ Ní Gbígbé Àánú Jehofa Yọ.” Alen àti Ann Marie Gokavi wí pé: “Ó ṣàlàyé pé àpẹẹrẹ ìdàgbàdénú Kristian ni ó jẹ́ láti nawọ́ àánú sí àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wa àti àwọn wọnnì tí a ń ṣàjọpín ìhìnrere náà pẹ̀lú. Iṣẹ́ àyànfúnni ní ilẹ̀ àjèjì mú ìrúbọ dání, ṣùgbọ́n bí àánú kò bá sí, nígbà náà ìníyelórí ìrúbọ wa kì yóò tó nǹkan.” (Matteu 9:13) Peter àti Fleur Hupston fikún un pé: “Arákùnrin Lösch wí pé a níláti ní àánú fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa pẹ̀lú, ní fífi òdì awò tí ń sọ nǹkan di ńlá wò wọ́n, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, kí àwọn àṣìṣe wọn baà lè mọ níwọ̀n lójú wa dípò kí a sọ wọ́n di ńlá.”
Mickey àti Sherry Minsky rántí pé: “Jack Redford, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wa ní Gileadi, sọ̀rọ̀ tẹ̀lé e pẹ̀lú ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà ‘Ìwọ Ha Lè Fetísí Ìbáwí Bí?’ Ó ṣàlàyé pé ìgbéraga a máa mú kí ó ṣòro láti gba ìbáwí àti pé bí ara wa bá tètè máa ń kọ ìmọ̀ràn, àwa yóò kùnà láti jàǹfààní láti inú rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni ó fúnni ní àwọn ìdámọ̀ràn gbígbéṣẹ́ lórí gbígba ìbáwí èyí tí a gbékarí Ẹkún Jeremiah 3:27-31.” Charles àti Joan Held fikún un pé: “Ní ọ̀pọ̀ ìgbà jùlọ a kì í ṣàkíyèsí àwọn àìdójú ìwọ̀n tiwa funraawa; nítorí náà, a gbọ́dọ̀ fojú wo ìbáwí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan tí a gbà ń là wá lójú sí àwọn nǹkan tí a kò mọ̀. Ìbáwí tàbí ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Jehofa jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ rẹ̀ fún wa.”
Kenneth àti Lisbeth Ardkäll wí pé: “Olùkọ́ mìíràn, Ulysses Glass, sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà ‘Jèrè Ọgbọ́n Síṣeémúlò Tí Ń Sinni Lọ sí Ìye.’ Ó béèrè pé: ‘Kí ni ẹ̀yin yóò fi ohun tí ẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe?’ Lẹ́yìn náà ni ó fúnni ní àkàwé tí a gbékarí Owe 30:24-26 nípa gara kékeré orí àpáta àti bí Jehofa ṣe mú un gbaradì ní kíkún fún wíwàláàyè. Àwa, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kò gbọ́n lọ́nà ìtẹ̀sí ìwà àdánidá, nítorí náà a níláti lo araawa dé góńgó láti jèrè ọgbọ́n. Jehofa ti mú wa gbaradì pẹ̀lú ohun gbogbo tí a nílò láti ṣe ìyẹn. Níwọ̀n bí a bá ti ń bá a nìṣó láti máa fi pẹ̀lú ìfẹ́ súnmọ́ Jehofa àti araawa lẹ́nìkínní kejì pẹ́kípẹ́kí, àwa yóò ṣe àṣeparí ohun púpọ̀.”
Ọ̀rọ̀-Àsọyé Pàtàkì
Jay àti Gwen Abraczinskas wí pé: “Arákùnrin Karl F. Klein, mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, fi tọ̀yàyà-tọ̀yàyà ṣe àgbéyẹ̀wò Orin Dafidi Kọkàndínlógún pẹ̀lú wa nínú ọ̀rọ̀-àsọyé rẹ̀ ‘Òkúta Iyebíye Láàárín Àwọn Òkúta Iyebíye.’ Ó tẹnumọ́ ìmọrírì jíjinlẹ̀ tí Dafidi onipsalmu náà ní fún Jehofa àti bí ó ti fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tó.” Keith àti Donna Hornback sọ pé: “Arákùnrin Klein pín psalmu náà sí apá mẹ́ta. Apa 1 (ẹsẹ̀ 1-6) fi ìmọrírì Dafidi fún ìṣẹ̀dá Ọlọrun hàn, apá 2 (ẹsẹ̀ 7-10) sọ nípa ìmọrírì rẹ̀ fún àwọn òfin Ọlọrun, apá 3 (ẹsẹ̀ 11-14) sì rán wa létí pé, bíi ti Dafidi, a gbọ́dọ̀ fẹ́ láti ní ipò-ìbátan dídára pẹ̀lú Jehofa.”
David àti Raylene Long wí pé: “A gbádùn kókó náà pé ìbẹ̀rù Jehofa ṣekókó bí a bá níláti yẹra fún ohun tí ó burú. Èyí ń ṣamọ̀nà wa sí ṣíṣe ohun mímọ́ gaara ní ojú rẹ̀.” Frank àti Vibeke Madsen sì fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n wí pé: “Àlàyé Arákùnrin Klein nípa bí àwọn ìránnilétí, òfin, àti òfin-àṣẹ Jehofa ti ṣàǹfààní tó ní a ṣe àkópọ̀ rẹ̀ lọ́nà ṣíṣe wẹ́kú láti inú ohun tí a kọ́ ní Gileadi. Ìyẹn gan-an ni ó túbọ̀ mú wa pinnu láti dìrọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní ọjọ́-iwájú kí a sì fọwọ́ mú un gẹ́gẹ́ bí àpótí ìṣúra àwọn òkúta iyebíye.”
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀-àsọyé pàtàkì náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gba ìwé-ẹ̀rí wọn, a sì ṣèfilọ̀ àwọn iṣẹ́ àyànfúnni wọn ní ilẹ̀ àjèjì. Lẹ́yìn ìṣíwọ́ ráńpẹ́ fún jíjẹ ìpápánu, gbogbo wọn tún kórajọpọ̀ fún àkókò ìjókòó ti ọ̀sán. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà kópa nínú dídáhùn àwọn ìbéèrè tí a mú jáde lákòókò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà tí kò ní kíka ìpínrọ̀ nínú.
Bob àti Shannon Lakatos rántí pé, “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ‘Wọ́n Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Láti Di Olùpòkìkí Ìjọba ní Gbogbo Ilẹ̀-Ayé’ ni ó wáyé tẹ̀lé e. Apá àkọ́kọ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà níí ṣe pẹ̀lú ìrírí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́-ìsìn pápá láàárín oṣù márùn ún tí a fi gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó pa àfiyèsí pọ̀ sórí lílo àwọn ìbéèrè lọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa. Apá tí ó níí ṣe pẹ̀lú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fi àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tí a lè gbà dojúkọ àwọn ìpèníjà àti àwọn àyíká ipò tí ń yípadà nínú ìgbésí-ayé míṣọ́nnárì hàn. Àwọn ìgbékalẹ̀ àwòrán slide mẹ́ta náà, ti Costa Rica, India, àti Malawi, mú kí a rí ètò-àjọ Jehofa kárí-ayé fírí.”
Jesse àti Michelle Duncan sọ pé: “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí ó tẹ̀lé e, Ẹ Hùwà Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìṣàkóso Ọlọrun, Kì Í Ṣe Bí Ti Ayé, ṣe àkàwé ipa búburú tí àwọn ìbátan díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni ti ayé, tí wọ́n ń ronú lọ́nà tí ó wù wọ́n lè ní.” Wenzel àti Kelly Koula fikún un pé: “Ó fihàn pé àwọn Kristian gbọ́dọ̀ lóye pé àwọn ìlànà àti ìdarísọ́nà Ìṣàkóso Ọlọrun pọndandan wọ́n sì ṣàǹfààní.”
Orin àti àdúrà ìparí mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbígbádùnmọ́ni náà wá sí ìparí. Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ti ń fi ibẹ̀ sílẹ̀ ní ìfojúsọ́nà fún gbígbéralọ sí ibi àyànfúnni wọn ní ilẹ̀ àjèjì ní àwọn ilẹ̀ 18, èrò-inú wọn ni a sọ dáradára nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìdágbére Tommi àti Jael Kauko pé: “A ń háragàgà gidigidi láti lọ síbi iṣẹ́ àyànfúnni wa àti láti fi àwọn ohun tí a ti kọ́ sílò. A ti gba ohun tí ó pọ̀ gan-an—nísinsìnyí àwa ni ó kàn láti fifúnni.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kíláàsì Kẹtàdínlọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́yege
Nínú àkọsílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ ní ìsàlẹ̀, àwọn ìlà ni a tò láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to àwọn orúkọ lẹ́sẹẹsẹ láti òsì sí ọ̀tún ní ìlà kọ̀ọ̀kan. (1) Hong, J.; Hong, D.; Groth, A.; Cortina, E.; Lakatos, S.; Hornback, D.; Acevedo, L.; Coffy, A. (2) Elfers, L.; Gokavi, A.; Ardkäll, L.; Abraczinskas, G.; Knott, K.; Lizer, T.; Abel, K.; Abel, D. (3) Duncan, M.; Gokavi, A.; Held, J.; Hupston, F.; Lakatos, B.; Long, R.; Minsky, S.; Acevedo, E. (4) Ardkäll, K.; Kauko, J.; Vaahtola, S.; Cortina, K.; Carson, N.; Minsky, M.; Lizer, G.; Koula, K. (5) Duncan, J.; Abraczinskas, J.; Vaahtola, J.; Madsen, F.; Madsen, V.; Long, D.; Carson, C.; Elfers, G. (6) Kauko, T.; Hupston, P.; Held, C.; Groth, A.; Hornback, K.; Koula, W.; Knott, D.; Coffy, C.