Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Jáde Lọ Láti Máa Fi Ìtara Ṣiṣẹ́ Ìkórè!
“ÌKÓRÈ pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mátíù 9:37, 38) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ní ìtumọ̀ pàtàkì fáwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì kẹrìndínlọ́gọ́fà [116] ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead bí wọ́n ṣe ń múra àtilọ síbi iṣẹ́ míṣọ́nnárì tá a yàn wọ́n sí.
Ní Saturday, March 13, 2004, ẹgbẹ̀tàlélọ́gbọ̀n ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [6,684] èèyàn ló pésẹ̀ sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower ní Patterson, New York àti làwọn ibùdó mìíràn fún ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege, níbi tá a ti fi ọ̀rọ̀ ìṣítí àti ọ̀rọ̀ ìyànjú dágbére fáwọn akẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo wa la lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tá a fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe ń fi ìtara ṣiṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí yìí.
Nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú tí Theodore Jaracz, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tóun náà kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì keje ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ, ó mẹ́nu ba àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn bá a mu gan-an ni, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé orílẹ̀-èdè ogun ni a rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege wọ̀nyí lọ láti lọ máa sìn! Ó jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà mọ̀ pé ìtọ́ni látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti mú wọn gbára dì pátápátá láti di òṣìṣẹ́ tó ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì jù yìí.—Mátíù 5:16.
Bí A Ṣe Lè Di Olùkórè Tó Ṣàṣeyọrí
Olùbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni Robert Wallen, tó ti ń bá Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àkọlé náà “Ẹwà Ìyọ́nú,” ó sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé: “Ìyọ́nú jẹ́ èdè kan tí àwọn adití lè gbọ́ tí àwọn afọ́jú pàápàá lè rí.” Jésù mọ ìṣòro tó ń pọ́n àwọn èèyàn lójú, ó sì wá ọ̀nà láti dín ìṣòro ọ̀hún kù. (Mátíù 9:36) Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí yóò ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti ṣe bíi ti Jésù, nínú iṣẹ́ ìwàásù, nínú ìjọ, níbi táwọn míṣọ́nnárì ń gbé àti nínú ìgbéyàwó wọn. Olùbánisọ̀rọ̀ náà gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ máa jẹ́ kí ẹwà ìyọ́nú yọ nínú ìgbésí ayé yín bẹ́ ẹ ṣe ń lo ara yín fún àwọn ẹlòmíràn. Ìwà ọmọlúwàbí yín nìkan ló máa jẹ́ kẹ́ e lè gbé ilé míṣọ́nnárì. Nítorí náà, ẹ múra tán láti fi ìyọ́nú wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:12.
Ẹni tí ọ̀rọ̀ kàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni Gerrit Lösch, ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kọkànlélógójì ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, ó sọ̀rọ̀ lórí àkòrí náà “Àwọn Tó Ń Kéde Ìgbàlà.” (Aísáyà 52:7) Kí àwọn èèyàn tó lè rí ìgbàlà nígbà tí ètò nǹkan ìsinsìnyí bá pa run, wọ́n gbọ́dọ̀ gba ìmọ̀ pípéye látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n polongo ìgbàgbọ́ wọn ní gbangba, kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. (Róòmù 10:10; 2 Tímótì 3:15; 1 Pétérù 3:21) Àmọ́, olórí ìdí tá a fi ń polongo ìgbàlà, kì í ṣe nítorí kí èèyàn lè rí ìgbàlà, bí kò ṣe láti fi ìyìn fún Ọlọ́run. Nítorí náà, Arákùnrin Lösch gba àwọn tó máa tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì yìí níyànjú, ó ní: “Ẹ mú ọ̀rọ̀ Ìjọba náà dé ìkángun ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì máa fi ìtara kéde ìgbàlà fún ògo Jèhófà.”—Róòmù 10:18.
Ìbéèrè tí Lawrence Bowen, olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì béèrè ni pé “Báwo Lo Ṣe Ń Gbé Ìmọ́lẹ̀ Tẹ̀mí Yọ?” Ó tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 6:22, ó sì gba àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ kí ojú wọn “mú ọ̀nà kan” kí wọ́n bàa lè “ṣàgbéyọ ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tó ń fi ògo fún Jèhófà kí wọ́n sì ṣe àwọn èèyàn bíi tiwọn láǹfààní.” Látìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ló ti fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí nípa pípa ọ̀kan rẹ̀ pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àṣàrò tí Jésù máa ń ṣe lórí àwọn nǹkan ìyanu tí Baba rẹ̀ kọ́ ọ ní ọ̀run ràn án lọ́wọ́ láti fara da ìdánwò tí Sátánì gbé kò ó lójú nínú aginjù. (Mátíù 3:16; 4:1-11) Jésù fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá nípa píparí iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an wá ṣe. Bákan náà, kí àwọn míṣọ́nnárì yìí lè kójú òkè ìṣòro tí ń bẹ níwájú, wọ́n ní láti máa bá a lọ ní kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá.
Mark Noumair, olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì tí òun náà jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́yege ní kíláàsì kẹtàdínlọ́gọ́rin ló sọ ọ̀rọ̀ àsọkágbá àwọn àsọyé náà, àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ni “Àwa Rèé ní Ọwọ́ Rẹ.” (Jóṣúà 9:25) Ó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé kí wọ́n ní irú ẹ̀mí táwọn ará Gíbéónì ìgbàanì ní. Bí Gíbéónì tiẹ̀ jẹ́ “ìlú ńlá kan tí ó tóbi . . . [tí] gbogbo ọkùnrin rẹ̀ sì jẹ́ àwọn alágbára ńlá,” síbẹ̀ àwọn ará Gíbéónì ò wá òkìkí, wọn ò sì retí pé káwọn ní nǹkan bí àwọn ṣe fẹ́. (Jóṣúà 10:2) Tinútinú ni wọ́n fi sìn lábẹ́ àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí “aṣẹ́gi àti apọnmi” láti ti ìjọsìn Jèhófà lẹ́yìn. (Jóṣúà 9:27) Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun táwọn akẹ́kọ̀ọ́yege wọ̀nyí sọ fún Jésù Kristi, Jóṣúà Títóbi Jù náà ni pé, “Àwa rèé ní ọwọ́ rẹ.” Nísinsìnyí tí wọ́n ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn ní ilẹ̀ òkèèrè, ó yẹ kí wọ́n tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí Jóṣúà Títóbi Jù bá yàn fún wọn láti ṣe.
Ìrírí àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
Àkòrí ọ̀rọ̀ tí Wallace Liverance tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kọkànlélọ́gọ́ta ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, tó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ sọ ni “Ṣí Ìwé Mímọ́ Payá Lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.” Ọ̀rọ̀ náà si ní ìjíròrò pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bíi mélòó kan nínú. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ ìrírí tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́nu àkókò tí wọ́n fi wà nílé ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sì ṣe àṣefihàn àwọn ìrírí náà. Ó dájú pé ẹ̀kọ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n fi oṣù márùn-ún kọ́ látinú Ìwé Mímọ́ wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin, ó sì sún wọn láti sọ ohun tí wọ́n kọ́ fáwọn èèyàn. (Lúùkù 24:32) Láàárín oṣù márùn-ún tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà gbà, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ ohun tó kọ́ fún àbúrò rẹ̀ ọkùnrin. Èyí ló mú kí àbúrò rẹ̀ wá ìjọ tó wà níbi tó ń gbé kàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ti di akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi.
Lẹ́yìn ìrírí wọ̀nyẹn, Richard Ashe àti John Gibbard fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn bíi mélòó kan lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti pẹ́ nínú ètò, títí kan àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tí wọ́n ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower lásìkò náà. Àwọn náà ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní àwọn kíláàsì tí a ti ṣe ṣáájú ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ọ̀kan lára wọn rántí ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Knorr sọ nínú kíláàsì nígbà yẹn lọ́hùn pé: “Ẹ óò kàwé gan-an nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì yìí o. Àmọ́, tẹ́ ẹ bá wá ń ganpá lẹ́yìn tẹ́ ẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ yege, a jẹ́ pé iṣẹ́ wa ti já sásán nìyẹn. A fẹ́ kẹ́ ẹ jẹ́ ẹni tó ń kóni mọ́ra nígbà tí tẹ́ ẹ bá kúrò nílé ẹ̀kọ́ yìí.” Àwọn arákùnrin arìnrìn-àjò wọ̀nyí gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé kí wọ́n máa ṣaájò àwọn èèyàn, kí wọ́n máa bá àwọn ẹlòmíràn lò bíi ti Kristi, kí wọ́n sì fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá yàn fún wọn. Ó dájú pé tí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di míṣọ́nnárì yìí bá fi ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn sílò yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ tá a yàn fún wọn.
Ẹ Jáde Lọ Láti Máa Fi Ìtara Ṣiṣẹ́ Ìkórè!
Àwọn tó pé jọ ní àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Stephen Lett, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Òun ló sọ olórí ọ̀rọ̀ inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ẹ Jáde Lọ Láti Máa Fi Ìtara Ṣiṣẹ́ Ìkórè!” (Mátíù 9:38) Àkókò tá a fi ń kórè àwọn ohun ọ̀gbìn kì í fi bẹ́ẹ̀ gùn. Nítorí èyí, àwọn olùkórè ní láti tẹpá mọ́ṣẹ́ gan-an. Tó bá ṣe pàtàkì kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára bẹ́ẹ̀, ẹ ò rí pé ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn tó ń kórè tẹ̀mí ní ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ṣiṣẹ́ kára! Iṣẹ́ ìkórè gíga tó jẹ́ tẹ̀mí yìí jẹ́ ọ̀ràn ikú òun ìyè. (Mátíù 13:39) Arákùnrin Lett gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege níyànjú pé kí wọ́n má ṣe ‘ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ wọn,’ dípò ìyẹn, ó ní kí ‘iná ẹ̀mí máa jó nínú wọn’ kí wọn sì “máa sìnrú fún Jèhófà” nínú iṣẹ́ ìkórè tá ò tún ní padà ṣe mọ́ yìí. (Róòmù 12:11) Olùbánisọ̀rọ̀ náà fa ọ̀rọ̀ Jésù yọ, ó ní: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.” (Jòhánù 4:35) Lẹ́yìn náà, ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege láti ní ìtara fún iṣẹ́ ìkórè yìí nípa sísa gbogbo ipá wọn láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ní àkókò tí wọ́n bá wà nílé àti níbi tí wọ́n ti lè rí wọn. Ó tún rọ̀ wọ́n láti máa wàásù láìjẹ́-bí-àṣà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wíwà lójúfò fún àwọn àǹfààní lè mú kó ṣeé ṣe láti wàásù lọ́nà tó múná dóko. Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó nítara, ó sì ń retí pé kí gbogbo wa máa fara wé òun, kí á sì ṣíṣẹ kára nínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí yìí.—2 Àwọn Ọba 19:31; Jòhánù 5:17.
Nígbà tí Arákùnrin Jaracz, alága ayẹyẹ náà fẹ́ parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ó fi ìkíni tó wá láti onírúurú ẹ̀ka ọ́fíìsì jíṣẹ́, ó sì fún àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ìwé ẹ̀rí wọn. Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ka lẹ́tà tí kíláàsì náà kọ láti dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n rí gbà. Ní kedere, ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kẹrìndínlọ́gọ́fà mú kí gbogbo àwọn tí wọ́n pé jọ túbọ̀ pinnu láti jáde lọ láti máa fi ìtara ṣiṣẹ́ ìkórè.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ
Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 6
Iye orílẹ̀-èdè tá a yán wọ́n sí: 20
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 46
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 34.2
Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 17.2
Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 13.9
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kíláàsì Kẹrìndínlọ́gọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead
Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Ceansu, R.; Sparks, T.; Piña, C.; Turner, P.; Cheney, L. (2) Suardy, M.; Sjöqvist, Å.; Amadori, L.; Smith, N.; Jordan, A.; Boissonneault, L. (3) Matlock, J.; Ruiz, C.; Dular, L.; Vigneron, M.; Henry, K. (4) Sjöqvist, H.; Laux, J.; Ruzzo, J.; Gustafsson, K.; Boissonneault, R.; Jordan, M. (5) Henry, D.; Turner, D.; Kirwin, S.; Florit, K.; Ceansu, S. (6) Amadori, S.; Cheney, J.; Ross, R.; Nelson, J.; Ruiz, J.; Vigneron, M. (7) Florit, J.; Matlock, D.; Ross, B.; Laux, C.; Ruzzo, T.; Dular, D.; Kirwin, N. (8) Gustafsson, A.; Nelson, D.; Suardy, W.; Piña, M.; Smith, C.; Sparks, T.