Pípinnu Àìlera, Ìwà Burúkú, àti Ìrònúpìwàdà
Ẹ̀ṢẸ̀ jẹ́ ohun kan tí àwọn Kristian kórìíra—àìdójú ìwọ̀n ọ̀pá-ìdiwọ̀n òdodo Jehofa. (Heberu 1:9) Kò múni láyọ̀ pé, gbogbo wa ni a ń dẹ́ṣẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà. Gbogbo wa ni a ń bá àìlera àti àìpé tí a jogun jìjàkadì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nínú àwọn ọ̀ràn tí ó pọ̀ jùlọ, bí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Jehofa tí a sì gbìyànjú gidigidi láti máṣe padà dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́, a lè tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ tónítóní. (Romu 7:21-24; 1 Johannu 1:8, 9; 2:1, 2) A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa pé, lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà, ó tẹ́wọ́gba iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wa láìka àìlera wa sí.
Bí ẹnì kan bá ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo nítorí àìlera ẹran-ara, ó nílò àbójútó olùṣọ́ àgùtàn ní kánjúkánjú ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ nínú Jakọbu 5:14-16 pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn [nípa tẹ̀mí] láàárín yín bí? Kí ó pe awọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ . . . Bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í. Nitori naa ẹ máa jẹ́wọ́ awọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbangba wálíà fún ara yín lẹ́nìkínní kejì kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín lẹ́nìkínní kejì, kí ẹ lè gba ìmúláradá.”
Nítorí náà, nígbà tí Kristian kan tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú lékenkà, ó nílò ohun kan tí ó ju jíjẹ́wọ́ ní òun nìkan fún Jehofa lọ. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan, níwọ̀n bí a ti wu ìmọ́tónítóní tàbí àlàáfíà ìjọ léwu. (Matteu 18:15-17; 1 Korinti 5:9-11; 6:9, 10) Àwọn alàgbà lè níláti pinnu pé: Ẹni náà ha ronúpìwàdà bí? Kí ni ó sún un dẹ́ṣẹ̀ náà? Ó ha jẹ́ ìyọrísí àkókò pàtó kan tí ó dá wà ní àìlera bí? Ó ha jẹ́ sísọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá di àṣà bí? Irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ kì í fìgbà gbogbo rọrùn tàbí ṣe pàtó ó sì máa ń béèrè ìfòyemọ̀ dé ìwọ̀n gíga.
Ṣùgbọ́n, kí ni bí ẹ̀ṣẹ̀ náà bá jẹ́ nítorí rírìn ní ipa-ọ̀nà ìwà àìtọ́ àti ìwà burúkú? Nígbà náà, ẹrù-iṣẹ́ àwọn alàgbà ṣe kedere. Nígbà tí ó ń darí mímójútó ọ̀ràn wíwúwo kan ní ìjọ Korinti, aposteli Paulu wí pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú naa kúrò láàárín ara yín.” (1 Korinti 5:13, NW) Àwọn ènìyàn burúkú kò ní àyè kankan nínú ìjọ Kristian.
Wíwọn Àìlera, Ìwà Burúkú, àti Ìrònúpìwàdà Wò
Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè mọ̀ bí ẹnì kan bá ronúpìwàdà?a Èyí kì í ṣe ìbéèrè kan tí ó rọrùn. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa Ọba Dafidi. Ó ṣe panṣágà àti lẹ́yìn náà, ó pànìyàn, níti gidi. Síbẹ̀, Jehofa gbà á láyè láti máa bá a lọ ní wíwàláàyè. (2 Samueli 11:2-24; 12:1-14) Tún ronú nípa Anania àti Safira. Wọ́n parọ́ ní gbígbìyànjú láti tan àwọn aposteli jẹ, ní fífi àgàbàgebè díbọ́n pé àwọn jẹ́ ọ̀làwọ́ ju bí àwọn ṣe jẹ́ níti gidi. Ìyẹn ha jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo bí? Bẹ́ẹ̀ni. Ó ha burú bí ìpànìyàn àti panṣágà bí? Rárá! Síbẹ̀, Anania àti Safira fi ìwàláàyè wọn dí i.—Iṣe 5:1-11.
Kí ni ìdí tí ìdájọ́ náà fi yàtọ̀? Dafidi ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo nítorí ẹran ara àìlera. Nígbà tí a gbé ohun tí ó ṣe kò ó lójú, ó ronúpìwàdà, Jehofa sì dáríjì í—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a bá a wí lọ́nà lílekoko nítorí àwọn ìṣòro nínú agbo ilé rẹ̀. Anania àti Safira dẹ́ṣẹ̀ níti pé wọ́n fi ìwà àgàbàgebè parọ́, ní gbígbìyànjú láti tan ìjọ Kristian jẹ tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ‘ṣèké sí ẹ̀mí mímọ́ àti sí Ọlọrun.’ Ẹ̀rí fihàn pé ìyẹn jẹ́ ọkàn-àyà burúkú. Nítorí náà, a ṣe ìdájọ́ wọn lọ́nà tí ó túbọ̀ múná.
Jehofa ni ó ṣe ìdájọ́ nínú àwọn ọ̀ràn méjèèjì, ìdájọ́ rẹ̀ sì tọ̀nà nítorí pé ó lè yẹ ọkàn-àyà wò. (Owe 17:3) Àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n jẹ́ alàgbà kò lè ṣe ìyẹn. Nítorí náà báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè fòyemọ̀ bóyá àìlera ni ó fa ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan tí kì í sìí ṣe ìwà burúkú?
Níti tòótọ́, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni ó burú, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó jẹ́ ẹni burúkú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan náà léraléra lè jẹ́ ẹ̀rí àìlera nínú ọ̀ràn ti ẹnì kan kí ó sì jẹ́ ẹ̀rí ìwà burúkú nínú ọ̀ràn ti ẹlòmíràn. Níti gidi, dídẹ́ṣẹ̀ sábà máa ń wémọ́ àìlera àti ìwà burúkú nínú ọ̀ràn ti ẹlẹ́ṣẹ̀ náà. Kókó abájọ kan tí a lè gbé ìpinnu kà ni ojú tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà fi wo ohun tí òun ti ṣe àti ohun tí ó wéwèé láti ṣe nípa rẹ̀. Ó ha fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn bí? Àwọn alàgbà nílò ìfòyemọ̀ láti rí èyí. Báwo ni wọ́n ṣe lè ní ìfòyemọ̀ yẹn? Aposteli Paulu ṣe ìlérí fún Timoteu pé: “Máa ronú nígbà gbogbo lórí ohun ti mo ń wí; Oluwa yoo fún ọ ní ìfòyemọ̀ níti gidi ninu ohun gbogbo.” (2 Timoteu 2:7, NW) Bí àwọn alàgbà bá ń fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ “ronú nígbà gbogbo” lórí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí Paulu àti àwọn òǹkọ̀wé Bibeli mìíràn, wọn yóò rí ìfòyemọ̀ tí wọ́n nílò láti fi ojú tí ó yẹ wo àwọn wọnnì tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ nínú ìjọ. Nígbà náà, ìpinnu wọn yóò fi ìrònú Jehofa hàn, kì í ṣe ti araawọn.—Owe 11:2; Matteu 18:18.
Báwo ni a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà kan ni láti yẹ bí Bibeli ṣe ṣàpèjúwe àwọn ènìyàn burúkú wò kí wọ́n sì rí i bóyá àpèjúwe náà bá ẹni náà tí wọ́n ń gbé ìgbésẹ̀ nípa rẹ̀ mu.
Títẹ́wọ́gba Ẹ̀bi àti Ríronúpìwàdà
Àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n kọ́kọ́ yan ipa-ọ̀nà ìwà burúkú ni Adamu àti Efa. Bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹni pípé tí wọ́n sì ní ìmọ̀ kíkúnrẹ́rẹ́ nípa òfin Jehofa, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ lòdìsí ipò ọba aláṣẹ àtọ̀runwá. Nígbà tí Jehofa gbé ohun tí wọ́n ṣe kò wọ́n lójú, ìhùwàpadà wọn yẹ fún àfiyèsí—Adamu dá Efa lẹ́bi, Efa pẹ̀lú dá ejò lẹ́bi! (Genesisi 3:12, 13) Fi èyí wéra pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn jíjinlẹ̀ tí Dafidi ní. Nígbà tí a gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbígbópọn kò ó lójú, ó gbà pé òun jẹ̀bi ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrònúpìwàdà, ní sísọ pé: “Èmi ṣẹ̀ sí Oluwa.”—2 Samueli 12:13; Orin Dafidi 51:4, 9, 10.
Yóò dára bí àwọn alàgbà bá lè gbé àwọn àpẹẹrẹ méjèèjì wọ̀nyí yẹ̀wò nígbà tí wọ́n bá ń mójútó àwọn ọ̀ràn tí ó jẹmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, ní pàtàkì níti ẹnì kan tí ó jẹ́ àgbàlagbà. Ǹjẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ náà—bíi ti Dafidi nígbà tí a mú kí ó dá a lójú pé ó ti dẹ́ṣẹ̀—ha gba ẹ̀bi rẹ̀ lójú-ẹsẹ̀ tí ó sì fi pẹ̀lú ìrònúpìwàdà yíjú sí Jehofa fún ìrànlọ́wọ́ àti ìdáríjì bí, tàbí ó ha ń wá ọ̀nà láti fojú kékeré wo ohun tí ó ti ṣe, bóyá ní dídá ẹlòmíràn lẹ́bi bí? Ní tòótọ́, ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ lè fẹ́ láti ṣàlàyé ohun tí ó fa ìwà tí òun hù, àwọn àyíká ipò sì lè wà, yálà ti àtẹ̀yìnwá tàbí ti lọ́ọ́lọ́ọ́, tí ó lè yẹ kí àwọn alàgbà gbéyẹ̀wò nígbà tí wọ́n bá ń pinnu bí wọn yóò ṣe ràn án lọ́wọ́. (Fiwé Hosea 4:14.) Ṣùgbọ́n ó níláti gbà pé òun ni ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ àti pé òun ni yóò dáhùn fún un níwájú Jehofa. Rántí pé: “Oluwa ń bẹ létí ọ̀dọ̀ àwọn tí í ṣe oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe onírora ọkàn là.”—Orin Dafidi 34:18.
Sísọ Ohun Búburú Dàṣà
Nínú ìwé Orin Dafidi, ọ̀pọ̀ àwọn ìtọ́kasí ni a ṣe sí àwọn ènìyàn burúkú. Irú àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ bẹ́ẹ̀ lè túbọ̀ ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti fòyemọ̀ bóyá ẹnì kan ní ìwà burúkú tàbí ó ní àìlera níti gidi. Fún àpẹẹrẹ, gbé àdúrà onímìísí ti Ọba Dafidi yẹ̀wò: “Máṣe fà mí lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú, àti pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn, ṣùgbọ́n ìwà-ìkà ń bẹ ní ọkàn wọn.” (Orin Dafidi 28:3) Ṣàkíyèsí pé a mẹ́nukan àwọn ènìyàn burúkú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú “àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tí ó dẹ́ṣẹ̀ nítorí àìlera ti ẹran-ara jáwọ́ ní gbàrà tí orí rẹ̀ bá ti wálé. Ṣùgbọ́n, bí ẹnì kan bá ‘sọ’ ṣíṣe ohun búburú ‘dàṣà’ dé àyè pé ó di apákan ìgbésí-ayé rẹ̀, èyí lè jẹ́ ẹ̀rí ọkàn-àyà burúkú.
Dafidi mẹ́nukan ohun mìíràn tí a lè fi dá ìwà burúkú mọ̀ yàtọ̀ nínú ẹsẹ yẹn. Bíi ti Anania àti Safira, ẹni burúkú ń fi ẹnu rẹ̀ sọ ohun rere ṣùgbọ́n ó ní ohun búburú nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Ó lè jẹ́ alágàbàgebè—bíi ti àwọn Farisi ọjọ́ Jesu tí wọ́n ‘farahàn lóde nítòótọ́ bí olódodo sí awọn ènìyàn ṣugbọn tí inú wọ́n kún fún àgàbàgebè ati ìwà-àìlófin.’ (Matteu 23:28, NW; Luku 11:39) Jehofa kórìíra àgàbàgebè. (Owe 6:16-19) Bí ẹnì kan bá fi ìwà àgàbàgebè gbìyànjú láti sẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wíwúwo àní nígbà tí ó bá ń bá àwọn ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ sọ̀rọ̀, tàbí tí ó fi pẹ̀lú ìkùnsínú gba kìkì ohun tí àwọn ẹlòmíràn ti mọ̀ nípa rẹ̀ ṣáájú, ní kíkọ̀ láti jẹ́wọ́ délẹ̀délẹ̀, èyí lè jẹ́ ẹ̀rí ọkàn-àyà burúkú.
Fífi Ìrera Ṣàìka Jehofa Sí
Àwọn nǹkan mìíràn tí a fi ń da ẹni burúkú mọ̀ yàtọ̀ ni a tò lẹ́sẹẹsẹ nínú Orin Dafidi 10. A kà níbẹ̀ pé: “Nínú ìgbéraga ni ènìyàn búburú ń ṣe inúnibíni sí àwọn tálákà: . . . ó sì ń kẹ́gàn Oluwa.” (Orin Dafidi 10:2, 3) Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo Kristian kan tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ tí kò sì ka Jehofa sí? Dájúdájú, ìwọ̀nyí jẹ́ ipò ìwà burúkú ti èrò-orí. Ẹnì kan tí ó dẹ́ṣẹ̀ nítorí àìlera yóò ronúpìwàdà yóò sì tiraka ní gbogbo ọ̀nà láti yí ìgbésí-ayé rẹ̀ padà, ní gbàrà tí ó bá ti mọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ tàbí tí a bá ti pe àfiyèsí rẹ̀ sí i. (2 Korinti 7:10, 11) Ní ìdàkejì, bí ènìyàn kan bá dẹ́ṣẹ̀ nítorí ìwà àìlọ́wọ̀ fún Jehofa, kí ni yóò dá a lẹ́kun láti máṣe padà sí ipa-ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ léraléra? Bí ó bá jẹ́ onírera láìka pé a ti fi ẹ̀mí ìwàtútù fún un ní ìmọrírì sí, báwo ni òun ṣe lè ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn tí ó nílò láti ronúpìwàdà tọkàn-tọkàn àti tòótọ́-tòótọ́?
Wàyí o gbé àwọn ọ̀rọ̀ Dafidi yẹ̀wò ní apá díẹ̀ tí ó gbẹ̀yìn psalmu kan náà: “Èéṣe tí ènìyàn búburú fi ń gan Ọlọrun? Ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé, Ìwọ kì yóò béèrè.” (Orin Dafidi 10:13) Nínú ọ̀ràn ti ìjọ Kristian, ènìyàn burúkú náà mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú, ṣùgbọ́n kò lọ́tìkọ̀ láti ṣe ohun búburú bí ó bá ronú pé òun lè ṣe é ní àṣegbé. Níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti sí ìbẹ̀rù pé àṣírí lè tú, yóò fún ìtẹ̀sí láti dẹ́ṣẹ̀ ní òmìnira pátápátá. Láìdà bíi ti Dafidi, bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ bá wá sí ojútáyé, òun yóò hùmọ̀ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti yẹra fún ìjìyà. Irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ aláìlọ́wọ̀ kankan fún Jehofa. “Ẹ̀rù Ọlọrun kò sí níwájú rẹ̀. . . . Òun kò kórìíra ibi.”—Orin Dafidi 36:1, 4.
Ṣíṣe Ìpalára fún Àwọn Ẹlòmíràn
Ó sábà máa ń jẹ́ pé, àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń nípa lé lórí máa ń ju ẹyọ ẹnì kan lọ. Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan tí ó ṣe panṣágà dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun; ó pọ́n aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ lójú; bí ẹni tí wọ́n jùmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ bá jẹ́ adélébọ̀, ó pọ́n ìdílé rẹ̀ lójú; ó sì kó àbàwọ́n bá orúkọ rere ti ìjọ. Ojú wo ni òun fi ń wo gbogbo ìyẹn? Ó ha fi ìbànújẹ́ àtọkànwá pẹ̀lú ojúlówó ìrònúpìwàdà hàn lẹ́sẹ̀ kan náà bí? Tàbí ó ha fi ẹ̀mí tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Orin Dafidi 94 hàn pé: “Gbogbo oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò máa fi ara wọn lérí. Oluwa, wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ túútúú, wọ́n sì ń yọ àwọn ènìyàn-ìní rẹ̀ lẹ́nu. Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò, wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìníbaba. Síbẹ̀ wọ́n wí pé, Oluwa kì yóò rí i, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun Jakobu kì yóò kà á sí”?—Orin Dafidi 94:4-7.
Ó ṣeé ṣe pé, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a bójútó nínú ìjọ kan kì yóò wémọ́ ìṣìkàpànìyàn àti ìpànìyàn. Síbẹ̀ ẹ̀mí tí a fihàn níhìn-ín—ẹ̀mí ṣíṣetán láti pọ́n àwọn ẹlòmíràn lójú fún èrè ara-ẹni—lè hàn gbangba bí àwọn alàgbà ṣe ń wádìí ìwà àìtọ́. Èyí pẹ̀lú jẹ́ ìwà ìfẹgẹ̀, àmì jíjẹ́ ènìyàn burúkú. (Owe 21:4) Ó jẹ́ òdìkejì pátápátá sí ẹ̀mí Kristian tòótọ́, tí ó múratán láti fi araarẹ̀ lélẹ̀ fún arákùnrin rẹ̀.—Johannu 15:12, 13.
Lílo Àwọn Ìlànà Ọlọrun
A kò pète pé kí ìwọ̀ǹba ìtọ́sọ́nà wọ̀nyí gbé àwọn òfin ìdíwọ̀n kalẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n pèsè òye nípa àwọn nǹkan tí Jehofa kà sí ohun burúkú níti gidi. Ẹni náà ha kọ̀ láti gbà pé òun jẹ̀bi ìwà àìtọ́ tí ó ti hù bí? Ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ ha ti fi ìmójúkuku ṣá ìmọ̀ràn tí a fún un níṣàájú lórí ọ̀ràn yìí gan-an tì bí? Ẹ̀rí fífẹsẹ̀rinlẹ̀ ha wà níti sísọ ìwà àìtọ́ kan tí ó wúwo dàṣà bí? Oníwà àìtọ́ náà ha fi àìnítìjú ṣàìka òfin Jehofa sí bí? Ó ha ti ṣe ìsapá onípètepèrò láti bo ìwà àìtọ́ náà mọ́lẹ̀, bóyá ní kíkó èèràn ran àwọn ẹlòmíràn ní àkókò kan náà bí? (Juda 4) Irú àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀ ha ń ga sí i nígbà tí ìwà àìtọ́ náà bá wá sí ojútáyé bí? Oníwà àìtọ́ náà ha fi àìlọ́wọ̀ pátápátá hàn fún ìpalára tí òun ti fà fún àwọn ẹlòmíràn àti sórí orúkọ Jehofa bí? Ìwà rẹ̀ ń kọ́? Lẹ́yìn tí a ti fi inúrere fún un ní ìmọ̀ràn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, ó ha jẹ́ onírera tàbí ọ̀fẹgẹ̀ bí? Ó ha ṣaláìní ọkàn-ìfẹ́ àtọkànwá láti yẹra fún pípadà hùwà àìtọ́ náà bí? Bí àwọn alàgbà bá rí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, tí ó fi àìní ìrònúpìwàdà hàn lọ́nà lílágbára, wọ́n lè dé ìparí èrò pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹni náà dá fi ẹ̀rí ìwà burúkú hàn dípò àìlera ti ẹran ara lásán.
Àní nígbà tí wọ́n bá ń gbọ́ tẹnu ẹnì kan tí ó farahàn bí ẹni tí ó ní ìtẹ̀sí láti hùwà burúkú, àwọn alàgbà kì í dẹ́kun láti máa gbà á níyànjú láti máa lépa òdodo. (Heberu 3:12) Ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹni burúkú lè ronúpìwàdà kí ó sì yípadà. Bí ọ̀ràn kò bá rí bẹ́ẹ̀, èéṣe tí Jehofa fi rọ àwọn ọmọ Israeli pé: “Jẹ́ kí ènìyàn búburú kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí ẹlẹ́ṣẹ̀ sì kọ ìrònú rẹ̀ sílẹ̀: sì jẹ́ kí ó yípadà sí Oluwa, òun ó sì ṣàánú fún un, àti sí Ọlọrun wa, yóò sì fi jì í ní ọ̀pọ̀lọpọ̀”? (Isaiah 55:7) Ó lè jẹ́ pé, nígbà tí ìgbẹ́jọ́ ń lọ lọ́wọ́, àwọn alàgbà yóò rí àmì ìyípadà nínú ipò ọkàn rẹ̀ bí ìrísí àti ìwà rẹ̀ ṣe fihàn.
Àní ní àkókò ìyọlẹ́gbẹ́ ẹnì kan, àwọn alàgbà, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn, yóò rọ̀ ọ́ láti ronúpìwàdà kí ó sì gbìyànjú láti wá ọ̀nà tí yóò gbà rí ojúrere Jehofa padà. Rántí “ènìyàn búburú” nì ní Korinti. Ó hàn gbangba pé ó yí ọ̀nà rẹ̀ padà, Paulu sì dámọ̀ràn rẹ̀ fún gbígbà padà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (2 Korinti 2:7, 8) Tún gbé ọ̀ràn ti Ọba Manasse yẹ̀wò. Nítòótọ́ ó burú yéye, ṣùgbọ́n nígbà tí ó ronúpìwàdà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jehofa tẹ́wọ́gba ìrònúpìwàdà rẹ̀.—2 Awọn Ọba 21:10-16; 2 Kronika 33:9, 13, 19.
Ní tòótọ́, ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí a kò lè dárí rẹ̀ jini—ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí ẹ̀mí mímọ́. (Heberu 10:26, 27) Jehofa nìkan ní ń pinnu ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ yẹn. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn kò ní ọlá-àṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹrù-iṣẹ́ àwọn alàgbà ni láti mú kí ìjọ wà ní mímọ́ tónítóní kí wọ́n sì mú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronúpìwàdà padà bọ̀ sípò. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìfòyemọ̀ àti ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, ní jíjẹ́ kí àwọn ìpinnu wọn fi ọgbọ́n Jehofa hàn, nígbà náà Jehofa yóò bùkún apá yìí nínú ṣíṣe olùṣọ́ àgùtàn wọn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú síi, wo Ilé-Ìsọ́nà ti January 1, 1982, ojú-ìwé 24 sí 26; Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 2, ojú-ìwé 772 sí 774.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Anania àti Safira fi ìwà àgàbàgebè ṣèké sí ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì fihàn pé àwọn ní ọkàn-àyà burúkú