Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Jesu wí pé: “Bí ẹ̀yin bá dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ ji ènìyàn èyíkéyìí, wọ́n wà ní èyí tí a dáríjì wọ́n; bí ẹ̀yin bá dá awọn ti ènìyàn èyíkéyìí dúró, wọ́n wà ní dídádúró síbẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ha túmọ̀ sí pé àwọn Kristian lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini bí?
Kò sí ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún píparí èrò sí pé àwọn Kristian ní gbogbogbòò, tàbí àwọn alàgbà tí a yàn sípò nínú ìjọ pàápàá, ní ọlá àṣẹ àtọ̀runwá láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini. Síbẹ̀, ohun tí Jesu sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú Johannu 20:23, tí a fà yọ ní òkè yìí, fi hàn pé Ọlọrun fún àwọn aposteli ní agbára àrà ọ̀tọ̀ lórí ọ̀ràn yìí. Ọ̀rọ̀ Jesu níbẹ̀ sì lè ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun tí ó sọ nínú Matteu 18:18 nípa àwọn ìpinnu tí a ṣe ní ọ̀run.
Àwọn Kristian lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan jini, ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn aposteli Paulu tí a kọ sílẹ̀ nínú Efesu 4:32 pé: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nìkínní kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dáríji ara yín lẹ́nìkínní kejì fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun pẹlu ti tipasẹ̀ Kristi dáríjì yín fàlàlà.” Níhìn-ín, Paulu ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro ara ẹni láàárín àwọn Kristian, irú bí ọ̀rọ̀ jàùjàù. Wọ́n ní láti tiraka láti yanjú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, ní dídáríji ara wọn. Rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Nígbà naa, bí iwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ wá síbi pẹpẹ tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà iwọ pẹlu arákùnrin rẹ, ati lẹ́yìn naa, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Matteu 5:23, 24; 1 Peteru 4:8.
Bí ó ti wù kí ó rí, àyíká ọ̀rọ̀ nínú Johannu 20:23 fi hàn pé Jesu ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jáì, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó tún sọ fún àwùjọ pàtó yìí ti fi hàn. Ẹ jẹ́ kí á wo bí ó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ní ọjọ́ tí a jí i dìde, Jesu fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní yàrá kan tí a tì pa ní Jerusalemu. Àkọsílẹ̀ náà wí pé: “Nitori naa, Jesu tún wí fún wọn pé: ‘Àlàáfíà fún yín o. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi jáde, ni emi pẹlu ń rán yín.’ Lẹ́yìn tí ó sì wí èyí ó fẹ́ atẹ́gùn sí wọn ó sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ gba ẹ̀mí mímọ́. Bí ẹ̀yin bá dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ ji ènìyàn èyíkéyìí, wọ́n wà ní èyí tí a dáríjì wọ́n; bí ẹ̀yin bá dá awọn ti ènìyàn èyíkéyìí dúró, wọ́n wà ní dídádúró síbẹ̀.’”—Johannu 20:21-23.
Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí a mẹ́nu kàn ní pàtàkì, ni àwọn aposteli rẹ̀ olùṣòtítọ́. (Fi wé ẹsẹ 24.) Nípa fífẹ́ atẹ́gùn sí wọn tí ó sì wí pé, “Ẹ gba ẹ̀mí mímọ́,” lọ́nà àpẹẹrẹ, Jesu fún wọn ní ìsọfúnni pé láìpẹ́ a óò tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí wọn. Jesu tẹ̀ síwájú láti sọ pé, wọn yóò ní ọlá àṣẹ ní ti dídárí ẹ̀ṣẹ̀ jini. Ó bọ́gbọ́n mu pé, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ méjèèjì ní ìsopọ̀, tí ọ̀kan ṣe amọ̀nà sí èyí tí ó tẹ̀ lé e.
Ní 50 ọjọ́ lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, ní ọjọ́ Pentekosti, Jesu tú ẹ̀mí mímọ́ jáde. Kí ni ìyẹ́n ṣàṣeparí rẹ̀? Ohun kan ni pé, àwọn tí wọ́n gba ẹ̀mí ni a tún bí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀mí Ọlọrun pẹ̀lú ìrètí jíjẹ́ alájùmọ̀ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Johannu 3:3-5; Romu 8:15-17; 2 Korinti 1:22) Ṣùgbọ́n ìtújáde ẹ̀mí náà ṣe ju ìyẹn lọ. Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n gbà á gba agbára iṣẹ́ ìyanu. Nípasẹ̀ ìyẹn, àwọn kan lè fi èdè tí wọn kò mọ̀ sọ̀rọ̀. Àwọn mìíràn lè sọ àsọtẹ́lẹ̀. Síbẹ̀ àwọn mìíran lè wo aláìsàn sàn tàbí jí òkú dìde sí ìwàláàyè.—1 Korinti 12:4-11.
Níwọ̀n bí àwọn ọ̀rọ̀ Jesu nínú Johannu 20:22 ti tọ́ka sí ìtújáde ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó so kọ́ra nípa dídárí ẹ̀ṣẹ̀ jì dà bí pé ó túmọ̀ sí pé ọlá àṣẹ aláìlẹ́gbẹ́ láti dárí jì tàbí láti má ṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni a ti pèsè fún àwọn aposteli látọ̀runwá.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, March 1, 1949 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 78.
Bibeli kò fún wa ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àkọsílẹ̀ gbogbo ìgbà tí àwọn aposteli lo irú ọlá àṣẹ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò kọ àkọsílẹ̀ gbogbo ìgbà tí wọ́n lo ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu náà láti fèdè fọ̀, láti sọ tẹ́lẹ̀, tàbí láti wò sàn.—2 Korinti 12:12; Galatia 3:5; Heberu 2:4.
Ọ̀ràn kan tí ó kan ọlá àṣẹ àwọn aposteli láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini tàbí láti má ṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini kan Anania àti Safira, tí wọ́n ṣèké sí ẹ̀mí. Peteru, ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kà nínú Johannu 20:22, 23 lẹ́nu Jesu, tú àṣírí Anania àti Safira. Peteru kọ́kọ́ bá Anania sọ̀rọ̀, ó sì kú lójú ẹsẹ̀. Nígbà tí Safira wọlé lẹ́yìn náà, tí òun náà sì ti èké náà lẹ́yìn, Peteru kéde ìdájọ́ rẹ̀. Peteru kò dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Wò ó! Ẹsẹ̀ awọn wọnnì tí wọ́n sin ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu ilẹ̀kùn, wọn yoo sì gbé ọ jáde.” Òun pẹ̀lú kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—Ìṣe 5:1-11.
Nínú ọ̀ràn yìí, aposteli Peteru lo ọlá àṣẹ àrà ọ̀tọ̀ láti sọ ní pàtó pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò ní ìdáríjì, ìmọ̀ àgbàyanu pé Ọlọrun kì yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ Anania àti Safira jì wọ́n. Ó tún dà bíi pé àwọn aposteli ní agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ láti rí òye àwọn ọ̀ràn níbi tí wọ́n ti ní ìdánilójú pé a ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Kristi. Nítorí náà, àwọn aposteli tí a fún ní ẹ̀mí náà lè polongo ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tàbí àìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.a
Èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn alàgbà ẹni àmì òróró nígbà náà lọ́hùn-ún ni wọ́n ní irú ọlá àṣẹ iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀. A lè rí ìyẹn nínú ohun tí aposteli Paulu sọ nípa ọkùnrin tí a yọ lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ Korinti. Paulu kò sọ pé, ‘Mo dárí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin yẹn jì í’ tàbí pé, ‘Mo mọ̀ pé a ti dárí ji ọkùnrin yẹn ní ọ̀run, nítorí náà, ẹ gbà á padà.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, Paulu rọ ìjọ lápapọ̀ láti dárí ji Kristian tí a gba padà náà, kí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn sí i. Paulu fi kún un pé: “Ohunkóhun tí ẹ bá fi inúrere dáríji ẹnikẹ́ni, emi naa ṣe bẹ́ẹ̀.”—2 Korinti 2:5-11.
Níwọ̀n ìgbà tí a ti gba ọkùnrin náà padà sínú ìjọ, gbogbo àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin lè dárí jì í ní ti ṣíṣàìní ìkùnsínú sí i ní ti ohun tí ó ṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ní láti ronú pìwà dà, kí a sì gbà á padà. Báwo ni ìyẹn yóò ṣe ṣẹlẹ̀?
Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo wà tí àwọn alàgbà nínú ìjọ ní láti bójú tó, irú bí olè jíjà, irọ́ pípa, tàbí ìwà pálapàla tí ó burú jáì. Wọ́n ń gbìyànjú láti tọ́ àwọn oníwà àìtọ́ náà sọ́nà, kí wọ́n sì bá wọn wí, ní sísún wọn láti ronú pìwà dà. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan bá ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jáì láìronú pìwà dà, àwọn alàgbà yóò lo ìtọ́ni àtọ̀runwá láti yọ oníwà àìtọ́ náà. (1 Korinti 5:1-5, 11-13) Ohun tí Jesu sọ nínú Johannu 20:23 kò ṣeé fi sílò nínú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Àwọn alàgbà wọ̀nyí kò ní ẹ̀bùn ẹ̀mí iṣẹ́ ìyanu, irú bí agbára láti wo àwọn aláìsàn nípa ti ara sàn tàbí jí òkú dìde; àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyẹn ṣiṣẹ́ fún ète tí a fi lò wọ́n ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n sì dópin. (1 Korinti 13:8-10) Síwájú sí i, àwọn alàgbà lónìí kò ní ọlá àṣẹ àtọ̀runwá láti dárí àwọn ìwà àìtọ́ búburú jáì jini ní ti pípolongo pé ẹlẹ́ṣẹ̀ bíburú jáì kan ti di ẹni mímọ́ ní ojú Jehofa. Irú ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yìí ní láti jẹ́ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà, Jehofa nìkan ni ó sì lè dárí jini lórí ìpìlẹ̀ yẹn.—Orin Dafidi 32:5; Matteu 6:9, 12; 1 Johannu 1:9.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ọ̀ràn ọkùnrin kan ní Korinti ìgbàanì, nígbà tí ẹnì kan tí ó dẹ́ṣẹ̀ bíburú lékenkà bá kọ̀ láti ronú pìwà dà, a ní láti yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Bí ó bá ronú pìwà dà lẹ́yìn náà, tí ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, ìdáríjì àtọ̀runwá ṣeé ṣe. (Ìṣe 26:20) Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ fún àwọn alàgbà ní ìdí láti gbà gbọ́ pé Jehofa ti dárí ji oníwà àìtọ́ náà ní ti gidi. Nígbà náà, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti gba ẹni náà padà, àwọn alàgbà lè ràn án lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí láti dúró gbọn-in-gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. Àwọn yòókù nínú ìjọ lè dárí jini ní ọ̀nà kan náà tí àwọn Kristian ní Korinti gbà dárí ji ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́ tí a sì gbà padà lẹ́yìn náà.
Ní bíbójú tó àwọn ọ̀ràn lọ́nà yìí, àwọn alàgbà kì yóò gbé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìdájọ́ tiwọn kalẹ̀. Wọ́n yóò lo àwọn ìlànà Bibeli, wọ́n yóò sì tẹ̀ lé àwọn ìgbésẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí Jehofa là sílẹ̀. Nítorí náà, dídáríjini tàbí ṣíṣàìdáríjini níhà ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà yóò jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu nínú Matteu 18:18 tí ó wí pé: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Awọn ohun yòówù tí ẹ bá dè lórí ilẹ̀-ayé ni yoo jẹ́ awọn ohun tí a ti dè ní ọ̀run, awọn ohun yòówù tí ẹ bá sì tú lórí ilẹ̀-ayé ni yoo jẹ́ awọn ohun tí a ti tú ní ọ̀run.” Àwọn ìgbésẹ̀ wọn yóò wulẹ̀ fi ojú ìwòye Jehofa lórí ọ̀ràn hàn gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ ọ́.
Lójú ìwòye èyí, ohun tí Jesu sọ, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Johannu 20:23, kò ta ko ìyókù Ìwé Mímọ́, ṣùgbọ́n ó fi hàn sí i pé àwọn aposteli ní ọlá àṣẹ àrà ọ̀tọ̀ ní ti dídárí jini, ní ìbámu pẹ̀lú àkànṣe iṣẹ́ wọn nígbà tí ìjọ Kristian wà ní ìkókó.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ṣáájú kí Jesu tó kú pàápàá tí ó sì pèsè ìràpadà, ó ní ọlá àṣẹ láti sọ pé a dárí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan jì í.—Matteu 9:2-6; fi wé “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, June 1, 1995.