Ìsìn Rẹ Ọkọ̀ Ojú-Omi Tí O Kò Gbọdọ̀ Kúrò Nínú Rẹ̀ Ha Ni Bí?
ỌKỌ̀ ojú-omi kan wà láàárín ẹ̀fúùfù líle. Ìpinnu kánjúkánjú dojúkọ àwọn agbo òṣìṣẹ́, tí ń ṣe kìràkìtà láti yọ ọkọ̀ wọn nínú ewu: yálà láti dúró sínú ọkọ̀ tàbí kí wọ́n kúrò nínú ọkọ̀ náà kí wọ́n sì dáàbòbo ara wọn. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń jániláyà yìí ni a lò gẹ́gẹ́ bí àkàwé kan fún ètò-ìgbékalẹ̀ ìsìn?
Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn, ní pàtàkì jùlọ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ onísìn Katoliki, sábà máa ń fi ṣọ́ọ̀ṣì wọn wé ọkọ̀ ojú-omi kan tí ń la ìjì kọjá. Wọ́n sọ pé ọkọ̀ ojú-omi tí Jesu tàbí Peteru wà níbi àgbá ìtọ́kọ̀ rẹ̀ yìí, ni ó dúró fún ọ̀nà kanṣoṣo tí a lè gbà rí ìgbàlà. Ipò tí àwùjọ àlùfáà dìmú ni, ‘Máṣe kúrò nínú ọkọ̀ ojú-omi náà láé. Ṣọ́ọ̀ṣì yìí ti la yánpọnyánrin líléwu kọjá rí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọkọ̀ ojú-omi kan tí ó ti la ìjì gbogbo ẹ̀fúùfù líle nínú ọ̀rọ̀-ìtàn kọjá.’ Àwọn kan sọ pé, ‘Èéṣe tí o fi níláti kúrò nínú rẹ̀? Yíyàn mìíràn wo ni ó wà? Èéṣe tí o kò fi dúró kí o sì ṣèrànwọ́ láti tukọ̀ náà lọ sí ibi tí omi ti túbọ̀ parọ́rọ́?’
Ní ìbámu pẹ̀lú èdè ìṣàpẹẹrẹ yìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn, tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà onírúurú ìsìn mìíràn, ronú pé, ‘Mo mọ̀ pé ìsìn mi kò tọ̀nà nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n mo ní ìrètí pé yóò yípadà. Èmi kò fẹ́ láti kúrò nínú rẹ̀. Èmi yóò fẹ́ láti kópa nínú ríràn án lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá àwọn ìṣòro rẹ̀.’ Ìfẹ́ àtọkànwá fún ìsìn àwọn babańlá ẹni tàbí ìbẹ̀rù láti máṣe “hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí i” lè múni ronú lọ́nà yìí.
Àpẹẹrẹ kan tí ó bá a mu ni ti Hans Küng, gbajúgbajà ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Katoliki kan tí ó yapa, ẹni tí ó dánúrò pé: “Mo ha níláti fi ọkọ ojú-omi náà sílẹ̀ nígbà tí ìjì ń jà, kí n sì fi àwọn wọnnì tí a ti jọ wà nínú ọkọ̀ náà títí di ìsinsìnyí sílẹ̀, láti kojú ìjì náà, láti gbọ́n omi jáde, àti bóyá láti ja àjàbọ́ bí?” Ó fèsì pé: “Èmi kì yóò kọ ojúṣe mi láàárín ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀.” Yíyàn mìíràn yóò jẹ́ “láti yapa kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì yìí, nítorí àbùkù rẹ̀, nítorí ìfẹ́ fún ìlànà gíga jù, ó sì ṣeé ṣe kí ó jẹ́, nítorí àtilè di Kristian kan tí ó túbọ̀ ṣeé gbáralé.”—Die Hoffnung bewahren.
Ṣùgbọ́n ẹnì kan ha lè dúró sínú ọkọ̀ ojú-omi ṣọ́ọ̀ṣì tirẹ̀ kí ó sì nírètí pé Ọlọrun, nínú àánú rẹ̀, yóò yọ̀ọ̀da àkókò tí kò ní ààlà fún gbogbo ìsìn láti ṣe àtúnṣe bí? Ìyẹn jẹ́ ìbéèrè kan tí ń múni ronu jinlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àkàwé náà ti fihàn, fífi ìwàǹwára fi ọkọ̀ ojú-omi kan tí ó wà nínú ewu sílẹ̀ nípa wíwọ ọkọ̀ òbèlè tí ààbò rẹ̀ kò dánilójú yóò léwu bíi dídúró sínú ọkọ̀ ojú-omi kan tí ń rì. Ó ha bọ́gbọ́nmu láti fi dandangbọ̀n dúró sínú ṣọ́ọ̀ṣì kan, láìka bí ipò rẹ̀ ti rí sí? Ìrètí wo fún àtúnṣe ni àwọn ìsìn nawọ́ rẹ̀ síni lónìí? Báwo ni Ọlọrun yóò ṣe fàyègbà wọ́n láti ṣiṣẹ́ lòdìsí ìfẹ́-inú rẹ̀ pẹ́ tó?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Chesnot/Sipa Press