Ọwọ́ Ha Lè Tó Òtítọ́ Ìsìn Bí?
NÍ Sweden ọkùnrin kan tí ń ṣòfintótó nípa tẹ̀mí ní ìlú Uppsala tí yunifásítì wà pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ èrò-ìgbàgbọ́ àwọn oríṣiríṣi ìsìn tí ń bẹ ní ìlú rẹ̀, kódà o tilẹ̀ ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi ìjọsìn wọn. Ó ń tẹ́tísílẹ̀ bí àwọn àlùfáà wọn ṣe ń wàásù, ó sì fi ọ̀rọ̀ wá àwọn mẹ́ḿbà díẹ̀ lẹ́nu wò. Ó ṣàkíyèsí pé kìkì àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ó dàbí ẹni pé wọ́n gbàgbọ́ dájú pé àwọ́n ti “rí òtítọ́.” Ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò onírúurú èrò tí ń bẹ nípa ìsìn, ó ṣe kàyéfì nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe lè ṣe irú ìjẹ́wọ́ bẹ́ẹ̀.
Ìwọ fúnra rẹ ha rò pé ó ṣeé ṣe kí ọwọ́ tó òtítọ́ nípa ìsìn bí? Yóò ha tilẹ̀ ṣeé ṣe láti pinnu ohun tí a lè pè ní òtítọ́ pọ́ńbélé bí?
Ọgbọ́n Èrò-Orí àti Òtítọ́
Àwọn wọnnì tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọgbọ́n èrò-orí ti mú ojú-ìwòye náà dàgbà pé òtítọ́ pọ́ńbélé náà kò sí ní ìkáwọ́ aráyé. Ìwọ lè mọ̀ pé ọgbọ́n èrò-orí ni a ti ṣàlàyé gẹ́gẹ́ bí “ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ tí ń sakun láti ṣàlàyé bí àwọn nǹkan ṣe wáyé àti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìwàláàyè.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, níti gidi gan-an, ekukáká ni ó fi lọ jìnnà tó bẹ́ẹ̀. Nínú ìwé náà Filosofins Historia (Ọ̀rọ̀-Ìtàn Ọgbọ́n Èrò-Orí), Alf Ahlberg òǹkọ̀wé ará Sweden kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè tí ó dá lórí ọgbọ́n èrò-orí jẹ́ àwọn kan tí kò ṣeé ṣe láti pèsè ìdáhùn kan pàtó fún. . . . Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní èrò náà pé gbogbo ìṣòro tí ó rékọjá agbára ẹ̀dá ènìyàn [tí ó tan mọ́ ìlànà ìpìlẹ̀ àti ìlànà ẹ̀rí-wo-ni-a-tún-ń-fẹ́] wà lára . . . ọ̀wọ́ yìí.”
Gẹ́gẹ́ bí àbájáde rẹ̀, àwọn wọnnì tí wọ́n tí sakun láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí ó ṣe kókó wọ̀nyí nípa ìwàláàyè nípasẹ̀ ọgbọ́n èrò-orí ti parí rẹ̀ sí àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn tàbí àròdùn ọkàn. Nínú ìwé rẹ̀ Tankelinjer och trosformer (Ipa Ọ̀nà Ìrònú àti Ìgbàgbọ́ Ìsìn), Gunnar Aspelin òǹkọ̀wé ará Sweden sọ pé: “Ọkàn-ìfẹ́ tí ipá tí ń darí ẹ̀dá ní nínú ènìyàn kò ju èyí tí ó ní fún labalábá àti ẹ̀fọn lọ . . . Lójú awọn ipá wọ̀nyí tí ń ba ara wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ ní àgbáálá-ayé àti nínú ayé wa lọ́hùn-ún, a jẹ́ aláìlágbára, aláìlágbára kankan. Ojú-ìwòye náà nìyí nípa ìwàláàyè tí ó ti hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú àwọn ìwé gẹ́rẹ́ ṣáájú òpin ọ̀rúndún tí àwọn ènìyàn ti fi ìgbàgbọ́ wọn sínú ìtẹ̀síwájú tí wọ́n sì ń lálàá nípa ọjọ́-ọ̀la kan tí ó dára jù.”
A Ha Nílò Ṣíṣí Òtítọ́ Payá Bí?
Ó hàn gbangba pé àwọn ìsapá ẹ̀dá ènìyàn nìkan kò tí ì ṣe àṣeyọrí nínú rírí òtítọ́ nípa ìwàláàyè, ó sì dàbí ẹni pé wọn kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Nígbà náà, ìdí tí ó dára wà, láti parí èrò sí pé a nílò irúfẹ́ àwọn ìṣípayá kan látọ̀runwá. Ohun tí àwọn ènìyàn ń pè ní ìwé ipá tí ń darí ẹ̀dá pèsè àwọn ìṣípayá díẹ̀. Àní bí kò bá tilẹ̀ fúnni ní kúlẹ̀kúlẹ̀ ìparí èrò nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìwàláàyè, ó fi hàn pé ohun kan wà tí ó lè tẹ́nilọ́rùn lọ́nà púpọ̀ ju ṣíṣàlàyé pé kìkì ohun tí a lè fojúrí nìkan ni ìwàláàyè tòótọ́ gidi. Níti gidi ewé kan tí ń dàgbà sókè ń tẹ̀lé àwọn òfin tí ó yàtọ̀ sí èyí tí àwọn ìtòjọpelemọ àpáta ń tẹ̀lé nínú ihò tí ń yẹ̀ lulẹ̀. Àwọn ohun abẹ̀mí lọ́nà tí a gbà ṣẹ̀dá wọn ń di púpọ̀ síi wọ́n sì ń ṣètò ara wọn lọ́nà kan tí àwọn nǹkan aláìlẹ́mìí kò lè ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ òfin àti ìsìn kan tí a mọ̀ bí ẹni mowó ní ìdí fún píparí èrò sí pé: “Awọn ànímọ́ [Ọlọrun] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere lati ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nitori a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ awọn ohun tí ó dá.”—Romu 1:20.
Ṣùgbọ́n láti lè mọ ẹni tí ó wà lẹ́yìn ìmúpọ̀síi àti ìṣètò yìí, a nílò ìṣípayá síwájú síi. A kò ha níláti retí pé kí irú ìṣípayá bẹ́ẹ̀ wà bí? Kò ha ní lọ́gbọ́n nínú láti retí pé kí Ẹni náà tí ó mú kí ìwàláàyè wà lórí ilẹ̀-ayé ṣí ara rẹ̀ payá fún àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ bí?
Bibeli jẹ́wọ́ pé òun jẹ́ irú ìṣípayá bẹ́ẹ̀. Nínú ìwé ìròyìn yìí ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ti gbé àwọn ìdí rere kalẹ̀ fún títẹ́wọ́gba ìjẹ́wọ́ yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onírònú ènìyàn sì ti ṣe bẹ́ẹ̀. Òtítọ́ náà pé àwọn ènìyàn tí wọ́n kọ Bibeli háragàgà láti mú un ṣe kedere pé ohun tí àwọn kọ kì í ṣe tàwọn jẹ́ ohun tí ó pẹtẹrí gidigidi nínú ara rẹ̀. Ó lé ní 300 ìgbà, tí a rí i tí àwọn wòlíì Bibeli lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi, “Báyìí ni Oluwa wí.” (Isaiah 37:33; Jeremiah 2:2; Nahumu 1:12) Ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ń kọ àwọn ìwé àti ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ máa ń háragàgà lọ́pọ̀ ìgbà láti kọ orúkọ wọn sí ara ìwé wọn. Síbẹ̀, àwọn wọnnì tí wọ́n kọ Bibeli kò pariwo ara wọn; nínú àwọn ọ̀ràn kan ó ṣòro láti mọ ẹni tí ó kọ àwọn apá kan nínú Bibeli.
Apá ẹ̀ka mìíràn tí o lè rí pé ó ṣe pàtàkì nínú Bibeli ni ìbáramuṣọ̀kan tí ó wà nínú rẹ̀. Èyí pẹtẹrí níti gidi, bí a bá gbé e yẹ̀wò pé àwọn ìwé 66 tí ń bẹ nínú Bibeli ni a kọ ní sáà 1,600 ọdún. Kí a gbà pé o lọ sí ilé àkójọ-ìwé gbogbogbòò tí o sì yan ìwé 66 tí ó jẹ́ ti ìsìn tí a ti kọ ní sáà ọ̀rúndún 16. Lẹ́yìn náà o di àwọn ìwé tí ó wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ yẹn papọ̀ sí ìdìpọ̀ kanṣoṣo. Ìwọ yóò ha retí pé kí ìdìpọ̀ yẹn ní ẹṣin-ọ̀rọ̀ kan náà kí ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ sí báramu bí? Rárá. Ìyẹn yóò béèrè fún iṣẹ́-ìyanu. Gbé èyí yẹ̀wò: Àwọn ìwé inú Bibeli ní irú ẹṣin-ọ̀rọ̀ kan náà, wọ́n sì kín ara wọn lẹ́yìn. Èyí fi hàn pé olùdarí kan gbọ́dọ̀ wà, tàbí òǹṣèwé, tí ó darí ohun tí àwọn òǹkọ̀wé Bibeli kọ sílẹ̀.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ yóò rí apá-ẹ̀ka kan tí ó jẹ́rìí sí i ju ohunkóhun mìíràn lọ pé Bibeli pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀—ìsọfúnni tí a ti kọ ṣáájú nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ pàtó ní ọjọ́-ọ̀la. Àwọn ọ̀rọ̀ bíi, “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà” àti, “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ ìkẹyìn” jẹ́ ohun tí a mọ̀ mọ Bibeli nìkan. (Isaiah 2:2; 11:10, 11; 23:15; Esekieli 38:18; Hosea 2:21-23; Sekariah 13:2-4) Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí Jesu Kristi tó fara hàn lórí ilẹ̀-ayé, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu fún wa ní kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìgbésí-ayé rẹ̀—láti ìgbà ìbí rẹ̀ títí de ìgbà ikú rẹ̀. Kò sí ìparí èrò lílọ́gbọ́n nínú mìíràn tí a lè dé ju pé Bibeli ni orísun òtítọ́ nípa ìwàláàyè. Jesu fúnra rẹ̀ jẹ́rìí sí èyí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—Johannu 17:17.
Ìsìn àti Òtítọ́
Àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Bibeli pàápàá gbàgbọ́ pé ọwọ́ kò lè tó òkodoro òtítọ́. Àlùfáà kan ní United States, John S. Spong sọ pé: “A gbọ́dọ̀ . . . yí ìrònú padà kúrò lórí pé a ní òtítọ́ àti pé àwọn mìíràn gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́gba ojú-ìwòye wa ní mímọ̀ pé òtítọ́ pọ́ńbélé kò lè tó gbogbo wa lọ́wọ́.” Òǹṣèwé Roman Katoliki kan, Christopher Derrick, pèsè ìdì kan fún irú ojú-ìwòye òdì bẹ́ẹ̀ nípa rírí òtítọ́: “Mímẹ́nukan ‘òtítọ́’ ìsìn lọ́nàkọnà ń túmọ̀ sí jíjẹ́wọ́ pé o mọ nǹkan . . . O ń dọ́gbọ́n sọ pé ẹlòmíràn lè kùnà; a kì yóò sì tẹ́wọ́gba ìyẹn rárá.”
Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí onírònú ènìyàn, yóò dára bí o bá lè ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè kan tí ó jẹmọ́ ohun tí a ti ń jíròrò. Bí ọwọ́ kò bá lè tó òtítọ́, èéṣe tí Jesu Kristi yóò fi sọ pé: “Ẹ óò sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yoo sì dá yín sílẹ̀ lómìnira”? Èésìtiṣe tí ọ̀kan lára àwọn aposteli Jesu fi sọ pé ìfẹ́-inú Ọlọrun ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọn sì wá sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́”? Èéṣe tí ọ̀rọ̀ náà “òtítọ́” fi fara hàn ni iye tí ó ju ìgbà ọgọ́rùn-ún lọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Griki ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́? Bẹ́ẹ̀ni, èéṣe, bí ó bá jẹ́ pé ọwọ́ kò lè tó òtítọ́?—Johannu 8:32; 1 Timoteu 2:3, 4.
Dájúdájú, Jesu kò pe àfiyèsí sórí pé ọwọ́ lè tó òtítọ́ nìkan ṣùgbọ́n ó fi hàn pé rírí i jẹ́ ohun tí a ń béèrè fún bí ìjọsìn wa yóò bá jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọrun. Nígbà tí obìnrin ará Samaria kan ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìjọsìn tòótọ́ jẹ́—ìjọsìn tí àwọn Júù ń ṣe ní Jerusalemu tàbí tí àwọn ará Samaria ń ṣe ní Òkè Gerisimu—Jesu kò dáhùn nípa sísọ pé ọwọ́ kò lè tó òtítọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yoo máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí ati òtítọ́, nitori pé, nítòótọ́, irúfẹ́ awọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá lati máa jọ́sìn oun. Ọlọrun jẹ́ Ẹ̀mí, awọn wọnnì tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí ati òtítọ́.”—Johannu 4:23, 24.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ń jẹ́wọ́ pé, ‘A lè túmọ̀ Bibeli sí onírúurú ọ̀nà, nítorí náà ẹnì kan kò lè mọ ohun tí òtítọ́ jẹ́ ní àmọ̀dájú.’ Ṣùgbọ́n a ha kọ Bibeli lọ́nà òfegè bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ọ̀nà tí a lè gbà lóye rẹ̀ kò lè dá ọ lójú? A gbọ́dọ̀ gbà pé, àwọn èdè alásọtẹ́lẹ̀ àti alámì-ìṣàpẹẹrẹ lè ṣòro láti lóye. Fún àpẹẹrẹ, Ọlọrun sọ fún wòlíì Danieli pé ìwé rẹ̀, tí ó ní èdè alásọtẹ́lẹ̀ púpọ̀ nínú, ni a kò lè lóye rẹ̀ pátápátá títí yóò fi di “ìgbà ìkẹyìn.” (Danieli 12:9) Ẹ̀rí sì fi hàn pé ó yẹ kí a túmọ̀ àwọn òwe-àkàwé àti àmì-ìṣàpẹẹrẹ kan.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ṣe kedere pé Bibeli ṣe tààràtà níti àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Kristian àti ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwàhíhù tí ó ṣe kókó fún jíjọ́sìn Ọlọrun ní òtítọ́. Kò fi àyè kankan sílẹ̀ fún àwọn ìtumọ̀ tí ó forígbárí. Nínú lẹ́tà sí àwọn ará Efesu, a sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ Kristian pé ó jẹ́ ‘ọ̀kan,’ tí ó fi hàn pé kí yóò sí onírúurú ìgbàgbọ́. (Efesu 4:4-6) Bóyá o lè ṣe kàyéfì pé, ‘Bí ó bá jẹ́ pé a kò lè túmọ̀ Bibeli ní onírúurú ọ̀nà, èéṣe tí àwọn ẹ̀ka-ìsìn “Kristian” yíyàtọ̀ síra fi wà?’ A rí ìdáhùn náà bí a bá bojú wẹ̀yìn wo àkókò náà gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí àwọn aposteli Jesu ti kú tí ìpẹ̀yìndà sì gbèrú láti inú ìgbàgbọ́ Kristian tòótọ́.
‘Àlìkámà ati Èpò’
Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìpẹ̀yìndà yìí nínú òwe-àkàwé àwọn àlìkámà àti àwọn èpò. Jesu fúnra rẹ̀ ṣàlàyé pé “àlìkámà” dúró fún àwọn Kristian tòótọ́; “awọn èpò” dúró fún àwọn Kristian èké, tàbí apẹ̀yìndà. Jesu sọ pé: ‘Nígbà tí awọn ènìyàn bá ń sùn, ọ̀tá kan’ yóò wá tí yóò fún àwọn èpò sínú oko àlìkámà náà. Fífún náà bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn aposteli ti sùn nínú oorun ikú. Òwe-àkàwé náà fi hàn pé dída àwọn Kristian tòótọ́ pọ̀ mọ́ ti èké yóò máa bá a nìṣó títí di “ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” Nípa bẹ́ẹ̀, jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, àmì ìdánimọ̀ àwọn Kristian tòótọ́ ni a kò mọ̀ dáradára nítorí pé àwọn wọnnì tí wọ́n wulẹ̀ jẹ́ Kristian ajórúkọ lásán ti jọba lé pápá ìsìn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìyípadà kan yóò ṣẹlẹ̀ ní “ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” “Ọmọkùnrin ènìyàn” yóò “rán awọn áńgẹ́lì rẹ̀” láti ya àwọn èké Kristian sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn Kristian tòótọ́. Èyí túmọ̀ sí pé yóò rọrùn nígbà náà láti dá ìjọ Kristian mọ̀, ní wíwà ní ipò tí ó wà nígbà ayé àwọn aposteli.—Matteu 13:24-30, 36-43.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah àti Mika lápapọ̀ sọ nípa irú ìtúnkójọpọ̀ àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ bẹ́ẹ̀ “ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Isaiah sọ pé: “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ ìkẹyìn, a óò fi òkè ilé Oluwa kalẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a óò sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ; gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò sì wọ́ sí inú rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò sì lọ, wọn ó sì wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè Oluwa, sí ilé Ọlọrun Jakobu; Òun óò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa óò sì máa rìn ní ipa rẹ̀.” Fífi ojú ṣíṣe kedere wo àwọn òkodoro òtítọ́ náà fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah ti ń ní ìmúṣẹ ní àkókò wa.—Isaiah 2:2, 3; Mika 4:1-3.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìdàgbàsókè ìjọ Kristian kì í tipasẹ̀ àwọn ìsapá kan tí ó jẹ́ ti ẹ̀dá ènìyàn ṣẹlẹ̀. Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé òun yóò ‘rán awọn áńgẹ́lì òun jáde’ láti ṣiṣẹ́ ìkójọpọ̀ kan. Ó tún tọ́ka sí ète kan tí ó jẹ́ àkànṣe gidi fún un: “Ní àkókò yẹn awọn olódodo yoo máa tàn yòò gẹ́gẹ́ bí oòrùn ninu ìjọba Baba wọn.” (Matteu 13:43) Èyí fi hàn pé ìjọ Kristian yóò ṣe iṣẹ́ ìlanilóye, tàbí ìdánilẹ́kọ̀ọ́, kárí-ayé.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí nínú iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà tí wọ́n ń ṣe ní 232 ilẹ̀ lónìí. Bí a bá fi ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí, ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìwàhíhù wọn, àti ìṣètò nǹkan wọn wéra pẹ̀lú Bibeli, àwọn ènìyàn tí wọn kò mú ojú-ìwòye-ẹlẹ́tanú dàgbà lè rí i ní kedere pé àwọn wọ̀nyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ti ìjọ Kristian ti ọ̀rúndún kìn-ínní. Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí “òtítọ́” ṣùgbọ́n kì í ṣe ìwà ọ̀yájú olójú-ìwòye mo-sàn-jù-ọ́-lọ ni ó sún wọn ṣe é. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ jìnnà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, wọ́n sì ń tẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá-ìdiwọ̀n kanṣoṣo tí a fi lè wọn ìsìn lọ́nà tí ó tọ́.
Àwọn Kristian ìjímìjí tọ́ka sí ìgbàgbọ́ tiwọn gẹ́gẹ́ bí “òtítọ́.” (1 Timoteu 3:15; 2 Peteru 2:2; 2 Johannu 1) Ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ fún wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ òtítọ́ fún wa lónìí pẹ̀lú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń késí gbogbo ènìyàn láti rí ìyẹn dájú fúnra wọn nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. A retí pé nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò ní ìrírí ìdùnnú-ayọ̀ tí ń wá kì í ṣe kìkì láti inú rírí i pé a ti rí ìsìn kan tí ó ta àwọn mìíràn yọ bíkòṣe láti inú rírí i pé a ti rí òtítọ́!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
ÀWỌN ỌGBỌ́N ÈRÒ-ORÍ DÍẸ̀ NÍ ÌFIWÉRA PẸ̀LÚ ÒTÍTỌ́
ỌGBỌ́N ÈRÒ-ORÍ OHUN-TÍ-A-LÈ-FOJÚRÍ-NÌKAN-LÒÓTỌ́: Ojú-ìwòye pé ìranù gbáà tí kò sí ẹ̀rí fún ìjótìítọ́ rẹ̀ ní gbogbo èròǹgbà tí ó jẹmọ́ ti ìsìn jẹ́ àti pé ète ọgbọ́n èrò-orí ni láti so àwọn ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ohun-tí-a-lè-rí papọ̀ di odindi.
ỌGBỌ́N ÈRÒ-ORÍ YÍYÀN-JẸ́-TI-ARA-ẸNI: Ìpayà Ogun Àgbáyé II ní ipa ìdarí púpọ̀ lórí àwọn alágbàwí rẹ̀ wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ní ojú-ìwòye pé nǹkan-yóò-burú síi nípa ìgbésí-ayé. Ó tẹnumọ́ yíyẹ ìrora ènìyàn lójú ikú àti ìmúlẹ̀mófo ìgbésí-ayé wò. Òǹṣèwé lórí ọgbọ́n èrò-orí yíyàn-jẹ́-ti-ara-ẹni Jean-Paul Sartre sọ pé, níwọ̀n bí kò ti sí Ọlọrun, a fi ènìyàn sílẹ̀ ó sì ń gbé nínú àgbáyé kan tí ó jẹ́ aláìbìkítà pátápátá.
ỌGBỌ́N ÈRÒ-ORÍ TÀBÍ-TÀBÍ: Gbàgbọ́ pé kò ṣeé ṣe láti tipasẹ̀ ṣíṣàyẹ̀wò àti ríronú dé orí ipinnu kan, ìmọ̀ gbogbogbòò—òtítọ́ èyíkéyìí—nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀.
ỌGBỌ́N ÈRÒ-ORÍ ÈRÒǸGBÀ-GBÍGBÉṢẸ́-LỌ̀GÁ: Ń díwọ̀n bí àwọn ohun tí ó dá wa lójú ṣe níláárí tó kìkì nípa bí ìgbéṣẹ́ wọn ṣe tan mọ́ ọkàn-ìfẹ́ ẹ̀dá ènìyàn, irú bíi títún ètò-ẹ̀kọ́, ọ̀nà ìwàhíhù, àti òṣèlú ṣe. Kò gbà pé òtítọ́ ní ìníyelórí kankan nínú ara rẹ̀.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ojú-ìwé 3: Ìkejì láti ọwọ́ òsì: Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure ti The British Museum; Ọwọ́ ọ̀tún: Sung Kyun Kwan University, Seoul, Korea