Òǹtẹ̀wé Tí Ó Tayọlọ́lá
ÌWỌ ha ti fìgbà kan rí fẹ́ láti wá ẹsẹ̀ kan nínú Bibeli ṣùgbọ́n tí o kò lè rántí ibi tí ó wà? Síbẹ̀, nípa rírántí ọ̀rọ̀ kan péré, ìwọ lè rí i nípa lílo atọ́ka Bibeli. Tàbí bóyá o ti lọ sí àpéjọ Kristian níbi tí ó ti ṣeé ṣe fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún, tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún pàápàá, tí ó pésẹ̀ láti ṣí Bibeli wọn láti ka ẹsẹ̀ kan lẹ́yìn ìṣẹ́jú àáyá péré tí a ti pè é.
Nínú ọ̀ràn méjèèjì, o jẹ ọkùnrin kan tí ó ṣeé ṣe kí o má mọ̀ ní gbèsè ohun kan. Ó mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ rọrùn síi, ó sì tún kó ipa kan ní rírí i dájú pé àwa lónìí ní Bibeli tí ó péye. Ó tilẹ̀ ní ipa ìdarí lórí ìrísí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Bibeli.
Robert Estienne ni ọkùnrin náà.a Òǹtẹ̀wé ni, ọmọ bíbí òǹtẹ̀wé sì ni, ní Paris, France, ní nǹkan bí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Ó jẹ́ ní sànmánì Ìmúsọjí-Ọ̀làjú àti Àtúnṣe-Ìsìn. Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé wá di ohun tí ó mú kí Ìmúsọjí-Ọ̀làjú àti Àtúnṣe-Ìsìn kẹ́sẹjárí. Henri Estienne, bàbá Robert, jẹ́ òǹtẹ̀wé tí a mọ̀ bí ẹni mowó, tí ń pèsè díẹ̀ lára àwọn ẹ̀dà ìwé dídára jùlọ tí ó jáde nígbà Ìmúsọjí-Ọ̀làjú. Ìwé nípa ètò-ẹ̀kọ́ àti Bibeli fún University of Paris àti ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa ẹ̀kọ́-ìsìn—Sorbonne, wà lára ìwé rẹ̀.
Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a darí àfiyèsí wa sí ọmọkùnrin náà, Robert Estienne. A kò mọ púpọ̀ nípa ẹ̀kọ́-ìwé rẹ̀ ní tààràtà. Síbẹ̀síbẹ̀, láti kékeré, ó mọ èdè Latin dunjú kò pẹ́ kò jìnnà ó kọ́ èdè Griki àti Heberu pẹ̀lú. Robert kọ́ bí a ṣe ń tẹ̀wé, láti ọwọ́ bàbá rẹ̀. Nígbà tí ó jogún ẹ̀rọ ìtẹ̀wé Henri ní 1526, Robert Estienne ni a ti mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti ó ní ìmọ̀ gíga nípa èdè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tẹ àwọn ìtẹ̀jáde aṣelámèyítọ́ nípa ìwé èdè Latin àti àwọn ìwé mìíràn tí ó dá lórí ìmọ̀-ẹ̀kọ, Bibeli ní ohun tí ó kọ́kọ́ ní ìfẹ́ tí a kò lè ṣiyèméjì nípa rẹ̀ sí. Bí ó ti ń háragàgà láti ṣàṣeparí ohun tí a ti ṣe fún àwọn ìwé àtijọ́ ní èdè Latin fún Bibeli èdè Latin, Estienne wéwèé láti tún fi ìdí Bibeli Vulgate ti Jerome tí a kọ lédè Latin ní ọ̀rúndún karùn-ún múlẹ̀ lọ́nà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dàbíi ti ojúlówó.
Ẹ̀dà Vulgate Tí A Túnṣe
Jerome ti túmọ̀ Bibeli láti inú èdè Heberu àti Griki ti ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fi di ọjọ́ Estienne, ẹ̀dà Vulgate ti wà fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ọ̀pọ̀ àṣìṣe àti àlèébù ti yọ́ wọ inú rẹ nítorí ṣíṣe àdàkọ lórí àdàkọ ẹ̀dà Vulgate. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà Sànmánì Agbedeméjì, àwọn ìtàn-àròsọ sànmánnì agbedeméjì tí ó lójúpọ̀, àwọn ẹsẹ̀ tí a sọ ní ọ̀rọ̀ mìíràn, àti àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi màgòmágó mú wọ inú rẹ̀, ti bo àwọn ọ̀rọ̀ Bibeli onímìísí àtọ̀runwá mọ́lẹ̀. Àwọn wọ̀nyí ti wá dàpọ̀ mọ́ ẹsẹ̀ Bibeli tóbẹ́ẹ̀ tí a fi bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́wọ́gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé tí ó ní ìmísí.
Láti lè palẹ̀ àwọn tí kì í ṣe ojúlówó mọ́ kúrò nílẹ̀, Estienne lo ọgbọ́n ṣíṣe lámèyítọ́ àwọn ẹsẹ̀ ìwé tí a ń lò nínú ẹ̀kọ́ àwọn ìwé ìtàn àtijọ́. Ó ṣàwárí àwọn ìwé-àfọwọ́kọ tí ọjọ́ wọn pẹ́ jùlọ tí ó sì dára jùlọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ní àwọn ilé àkójọ-ìwé ní Paris àti ní agbègbè rẹ̀ àti ní àwọn ibi bíi Évreux àti Soissons, ó wú ọ̀pọ̀ àwọn ìwé-àfọwọ́kọ ìgbàanì jáde, ọ̀kan tilẹ̀ dàbí èyí tí ó wà láti ọ̀rúndún kẹfà. Estienne fi tìṣọ́ra tìṣọ́ra ṣe ìfiwéra àwọn ẹsẹ̀ tí ó yàtọ̀ síra náà ní èdè Latin lẹ́sẹẹsẹ, ní yíyan kìkì àwọn ẹsẹ̀ tí ó dàbí pé wọ́n ní ọlá-àṣẹ gíga jùlọ. Ìwé tí ó tìdí rẹ̀ jáde, Bibeli Estienne, ni a kọ́kọ́ tẹ̀jáde ní 1528 ó sì jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì síhà ṣíṣe àtúnṣe ìpéye àwọn ẹsẹ̀ Bibeli. Àwọn ìtẹ̀jáde tí Estienne mú sunwọ̀n síi jáde tẹ̀lé e. Àwọn mìíràn tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ ti gbìdánwò láti tún ẹ̀dà Vulgate ṣe, ṣùgbọ́n tirẹ̀ ní ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ tí ó pèsè irin-iṣẹ́ ìṣelámèyítọ́ tí ó gbéṣẹ́. Nínú àwọn ìlà-àárín, Estienne fi ibi tí ó ti fo awọn ẹsẹ̀ kan tí ó ń ṣiyèméjì nípa rẹ̀ hàn tàbí ibi tí ó ti ṣeé ṣe kí a lo ọ̀rọ̀ tí ó ju ẹyọ kan lọ. Ó tún ṣe àkọsílẹ̀ orísun àwọn ìwé-àfọwọ́kọ tí ó fún un ní ọlá-àṣẹ fún ṣíṣe àwọn àtúnṣe wọ̀nyí.
Estienne gbé àwọn apá púpọ̀ mìíràn tí ó jẹ́ titun pátápátá ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún jáde. Ó fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àwọn ìwé Apocryphal àti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó fi ìwé Ìṣe sẹ́yìn àwọn ìwé Ìhìnrere àti ṣáájú àwọn lẹ́tà Paulu. Ní òkè ojú-ìwé kọ̀ọ̀kan, ó pèsè àwọn kókó ọ̀rọ̀ láti ran àwọn òǹkàwé lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹsẹ̀ pàtó kan. Èyí ni àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ nípa ohun tí a sábà ń pè ní àkọlé ojú-ìwé lónìí. Dípò lílo Ọ̀nà Ìkọ̀wé ọlọ́rọ̀ gàdàgbà gàdàgbà, tàbí ọlọ́rọ̀ ńláńlá, tí ó pilẹ̀ ní Germany, Estienne jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹni àkọ́kọ́ tí ó tẹ odindi Bibeli ní àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wẹ́ tí ó sì nàró ṣánṣán tí ó rọrùn láti kà irú èyí tí ó wọ́pọ̀ báyìí. Ó tún pèsè àwọn ìtọ́kasí àti àlàyé àwọn ọ̀rọ̀-èdè láti lè mú kí àwọn ẹsẹ̀ kan ṣe kedere.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti olórí ìjọ mọrírì Bibeli Estienne, nítorí pé ó dára ju ìtẹ̀jáde èyíkéyìí mìíràn tí ó jẹ́ ti ẹ̀dà Vulgate lọ. Bí ó bá jẹ́ ti ẹwà, iṣẹ́ tí ó pójú owó, àti bí ó ṣe wúlò tó, ìtẹ̀jáde rẹ̀ di ọ̀pá-ìdiwọ̀n kò sì pẹ́ tí ó fi di èyí tí a ń ṣàwòkọ rẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Europe.
Òǹtẹ̀wé Kábíyèsí
Owe 22:9 sọ pé: “Ìwọ rí ènìyàn tí ń fi àìṣèmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀? Òun óò dúró níwájú àwọn ọba.” Ọgbọ́n ìhùmọ̀ oníṣẹ́-ọnà àti òye èdè tí Estienne ní kò ṣàì pé àfiyèsí Francis I, ọba France. Estienne di òǹtẹ̀wé fún ọba náà ní èdè Latin, Heberu, àti Griki. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, Estienne ṣe ìmújáde ohun tí a ṣì kà sí àgbà-iṣẹ́ nínú ìmọ̀-ìwé-títẹ̀ lédè French títí di òní olónìí. Ní 1539 ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe Bibeli àkọ́kọ́ tí ó sì dára jùlọ Lédè Heberu tí a tẹ̀ ní France. Ní 1540 ó gbé àwòràn jáde nínú Bibeli lédè Latin. Ṣùgbọ́n dípò àwòrán mèremère ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bibeli tí ó wọ́pọ̀ nígbà Sànmánnì Agbedeméjì, Estienne pèsè àwọn àwòrán tí ń fúnni ní ìtọ́ni tí a gbéka ẹ̀rí àwọn awalẹ̀pìtàn tàbí tí a gbéka ìdíwọ̀n àti àpèjúwe tí a rí nínú Bibeli fúnra rẹ̀. Àwọn ìtẹ̀wé tí a gbẹ́ sórí igi wọ̀nyí ṣàpèjúwe àwọn kókó-ẹ̀kọ́ bíi àpótí ẹ̀rí, ẹ̀wù olórí àlùfáà, àgọ́ àjọ, àti tẹ́ḿpìlì Solomoni ní kúlẹ̀kúlẹ̀.
Ní lílo àkànṣe àwọn lẹ́tà Griki tí òun ránṣẹ́ fún láti fi tẹ àkójọ ìwé-àfọwọ́kọ ti ọba, Estienne tẹ̀síwájú ní ṣíṣe ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ tí ń ṣe lámèyítọ́ nípa Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé méjì àkọ́kọ́ nínú àwọn ìtẹ̀jáde ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ lédè Griki tí Estienne ṣe kò fi bẹ́ẹ̀ dára ju ìwé tí Desiderius Erasmus ṣe lọ, nínú ìtẹ̀jáde kẹta ti 1550, Estienne fi àwọn àkójọ àti ìtọ́kasí láti inú ìwé-àfọwọ́kọ 15 kún un, títíkan Codex Bezae ti ọ̀rúndún karùn-ún C.E. àti Bibeli Septuagint. A tẹ́wọ́gba ìtẹ̀jáde ti Estienne yìí níbi púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé lẹ́yìn náà ó di ìpìlẹ̀ fún ohun tí a ń pè ní Textus Receptus, tàbí Ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ Tí A Rí Gbà, ní orí èyí tí a gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtumọ̀ kà, títíkan ti King James Version ti 1611.
Ìforígbárí Sorbonne Pẹ̀lú Àtúnṣe-Ìsìn
Bí àwọn èròǹgbà Luther àti ti àwọn Alátùn-únṣe-Ìsìn mìíràn ti ń tànká gbogbo ilẹ̀ Europe, Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki gbìyànjú láti darí ìrònú àwọn ènìyàn nípa dídíwọ̀n ohun tí wọ́n ń kà. Ní June 15, 1520, Póòpù Leo X ti gbé òfin kan jáde tí ó pàṣẹ pé a kò gbọ́dọ̀ tẹ̀, tà, tàbí ka ìwé kankan tí ó bá ní “àdámọ̀” nínú, ní ilẹ̀ Katoliki kankan ó sì fi dandan béèrè pé kí àwọn aláṣẹ ayé rí i pé òfin náà múlẹ̀ ní pápá àkóso wọn. Ní England, Ọba Henry VIII fi iṣẹ́ àyẹ̀wò lé bíṣọ́ọ̀bù Katoliki Cuthbert Tunstall lọ́wọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ibi tí ó pọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ Europe, ọlá-àṣẹ tí a kò lè ṣiyèméjì nípa rẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn tí ó jẹmọ́ ẹ̀kọ́-ìsìn, tí ó tẹ̀lé ti póòpù, ni ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní University of Paris—Sorbonne.
Sorbonne ni agbọ̀rọ̀sọ fún ìjẹ́wọ́ gbogbogbòò ti Katoliki. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún a ti wò ó gẹ́gẹ́ bí òpómúléró fún ìgbàgbọ́ Katoliki. Àwọn aṣàyẹ̀wò tí wọ́n wà ní Sorbonne tako gbogbo ìtẹ̀jáde tí ń ṣe lámèyítọ́ àti Vulgate tí a túmọ̀ sí èdè ìbílẹ̀, wọn kò ka irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí kìkì “ohun tí kò níláárí fún ṣọ́ọ̀ṣì náà bíkòṣe apanilára.” Èyí kò yanilẹ́nu ní àkókò kan nígbà tí àwọn Alátùn-únṣe-Ìsìn ń gbé ìbéèrè dìde sí àwọn ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́, ayẹyẹ, àti àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí a kò gbé karí ọlá-àṣẹ Ìwé Mímọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tí ń bẹ ní Sorbonne ka àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì náà ń bọlá fún gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ṣe pàtàkì ju ìtumọ̀ Bibeli fúnra rẹ̀ lọ́nà pípéye lọ. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan wí pé: “Gbàrà tí a bá ti gba ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ náà, Ìwé Mímọ́ yóò dàbí pèpéle àgùnṣiṣẹ́ tí a gbé kúrò lẹ́yìn tí a mọ ògiri tán.” Ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà kò mọ nǹkan kan nípa èdè Heberu àti Griki, síbẹ̀ wọ́n fojú tẹ́ḿbẹ́lú ẹ̀kọ́ Estienne àti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti ìgbà Ìmúsọjí-Ọ̀làjú tí wọ́n ń walẹ̀jìn nínú ìtumọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú Bibeli. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Sorbonne wòye pé “láti tan ìmọ̀ èdè Griki àti Heberu kálẹ̀ yóò yọrí sí ìparun gbogbo ìsìn.”
Sorbonne Gbógun
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀jáde ẹ̀dà Vulgate ìjímìjí ti Estienne ṣe la àyẹ̀wò ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà kọjá, kò lọ láì sí awuyewuye. Ní ọ̀rúndún kẹtàlá, ẹ̀dà Vulgate ni a tọ́jú pamọ́ gẹ́gẹ́ bíi Bibeli tí yunifásítì náà ń lò, àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ ìwé rẹ̀ sì jẹ́ aláìlálèébù lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà tilẹ̀ ti dẹ́bi fún Erasmus ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí a bọ̀wọ̀ fún nítorí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ẹ̀dà Vulgate. Ó ṣe àwọn kan ní kàyéfì pé òǹtẹ̀wé lásán tí kì í ṣe àlùfáà yóò lórí-láyà tóbẹ́ẹ̀ láti ṣe àtúnṣe àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ ìwé tí a fi àṣẹ sí.
Ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwọn àkọsílẹ̀ àárín ọrọ ẹsẹ̀ iwé tí Estienne kọ ni ó kó ìdààmú bá àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn. Ìkọ̀wé náà mú kí a ṣiyèméjì nípa ìbófinmu àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ ìwé ẹ̀dà Vulgate. Ìfẹ́-ọkàn Estienne láti mú àwọn apá àyọkà kan ṣe kedere yọrí sí fífi ẹ̀sùn kàn án pé ó ń yọjúràn sí ilẹ̀ àkóso ẹ̀kọ́-ìsìn. Kò gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn náà, ní jíjẹ́wọ́ pé àwọn àkọsílẹ̀ òun wulẹ̀ jẹ́ àkópọ̀ kúkúrú tàbí ìmọ̀ èdè. Fún àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ rẹ̀ lórí Genesisi 37:35 ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ náà “hẹ́ẹ̀lì” [infernum, ní èdè Latin] ni a kò lè lóye rẹ̀ níbẹ̀ pé ó jẹ́ ibi tí a ti ń jẹ àwọn ẹni ibi níyà. Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà fẹ̀sùn kàn án pé ó sẹ àìleèkú ọkàn àti agbára jíjẹ́ alárinà tí “àwọn ẹni mímọ́” ní.
Bí ó ti wù kí ó rí, Estienne rí ojúrere àti ààbò ọba. Francis I fi ọkàn-ìfẹ́ tí ó ga hàn nínú ẹ̀kọ́ nípa Ìmúsọjí-Ọ̀làjú, ní pàtàkì iṣẹ́ òǹtẹ̀wé kábíyèsí tí ó ní. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ti sọ, Francis I tilẹ̀ bẹ Estienne wò ó sì fi sùúrù dúró nígbà tí Estienne ń ṣe àwọn àtúnṣe ìkẹyìn lórí ọrọ ẹsẹ̀ ìwé kan. Pẹ̀lú ìtìlẹyìn ọba náà, Estienne kò sá fún Sorbonne.
Àwọn Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Ìsìn Fòfinde Bibeli Rẹ̀
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní 1545, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìrunú ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ Sorbonne rú sí Estienne. Ní rírí àǹfààní gbígbé ogun àpawọ́pọ̀ jà dìde sí àwọn Alátùn-únṣe-Ìsìn, àwọn yunifásítì Katoliki ti Cologne (Germany), Louvain (Belgium), àti Paris ti gbà ṣáájú láti lẹ̀dí àpò pọ̀ nínú ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ tí gbogbogbòò kò tẹ́wọ́gbà. Nígbà tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn ní Louvain University kọ̀wé sí Sorbonne láti fi ìyàlẹ́nu wọn hàn pé Bibeli Estienne kò tí ì farahàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìwé tí a sọ pé kò dára ní Paris, Sorbonne fi irọ́ fèsì pé ká ní àwọn rí i tẹ́lẹ̀ ni àwọn ìbá ti sọ pé kò dára. Àwọn ọ̀tá Estienne láàárín ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà wá ní ìgboyà báyìí pé àwọn aláṣẹ ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ Louvain àti Paris tí wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ yóò tó láti mú kí Francis I gbàgbọ́ dájú pé òǹtẹ̀wé rẹ̀ ti ṣe àṣìṣe.
Ní àkókò yìí, níwọ̀n bí a ti kìlọ̀ fún un nípa ìpètepèrò àwọn ọ̀tá rẹ̀, Estienne ni ó kọ́kọ́ dé ọ̀dọ̀ ọba. Estienne dábàá pé bí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn bá lè pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àṣìṣe èyíkéyìí tí wọ́n ti rí, òun ti ṣetán dé ìwọ̀n àyè kan láti tẹ àwọn wọ̀nyí jáde papọ̀ mọ́ àwọn àtúnṣe àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn àti láti fi kún ọ̀kọ̀ọ̀kan Bibeli tí a bá tà. Ojútùú náà ni ojúrere ọba. Ó sọ fún Pierre du Chastel, òǹkàwé kábíyèsí, láti rí sí ọ̀ràn náà. Ní October 1546 ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà kọ̀wé sí Du Chastel ní fífi ẹ̀hónú hàn pé Bibeli Estienne jẹ́ “oúnjẹ fún àwọn wọnnì tí wọ́n sẹ́ Ìgbàgbọ́ wa tí wọ́n sì ti àwọn àdámọ̀ . . . lọ́ọ́lọ́ọ́ lẹ́yìn” tí wọ́n sì kún fun àṣìṣe tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi yẹ fún “píparẹ́ ráúráú kí a sì run wọ́n látòkèdélẹ̀.” Níwọ̀n bí a kò ti lè mú èyí dá a lójú, ọba náà fúnra rẹ̀ pàṣẹ pé kí ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà pèsè àyẹ̀wò náà kí wọ́n baà lè tẹ̀ wọ́n jáde pẹ̀lú Bibeli Estienne. Èyí ni wọ́n ṣèlérí láti ṣe, ṣùgbọ́n dájúdájú wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti lè yẹra fún pípèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àṣìṣe tí wọ́n lérò pé ó wà.
Francis I kú ní March 1547, ajùmọ̀gbóguntini lílágbára jùlọ fún Estienne lòdì sí agbára Sorbonne sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tí Henry II gorí ìtẹ́, ó tún àṣẹ bàbá rẹ̀ pa pé kí ẹ̀ka-ẹ̀kọ̀ náà pèsè àyẹ̀wò wọn. Síbẹ̀, ní ṣíṣàkíyèsí bí àwọn ọmọkùnrin ọba Germany ṣe ń lo Àtúnṣe-Ìsìn fún góńgó ti òṣèlú, mímú kí Katoliki France máa bá a nìṣó kí ó sì wà ní ìṣọ̀kan lábẹ́ ọba rẹ titun ká Henry II lára ju àwọn àǹfààní àti òfò tí a rò pé Bibeli òǹtẹ̀wé kábíyèsí ní lọ. Ní December 10, 1547, Ìgbìmọ̀ Abọ́ba-Dámọ̀ràn pinnu pé a gbọ́dọ̀ gbẹ́sẹ̀lé títa àwọn Bibeli Estienne títí di ìgbà tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn bá tó pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ àyẹ̀wò wọn.
A Fẹ̀sùn Kàn Án Pé Ó Jẹ́ Aládàámọ̀
Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà wá ọ̀nà nísinsìnyí láti gbé ẹjọ́ Estienne lọ sí kóòtù àkànṣe tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ láti máa gbẹ́jọ́ àdámọ̀. Estienne kò nílò ìránnilétí èyíkéyìí nípa ewu tí òun wà nínú rẹ̀. Láàárín ọdún méjì tí a ti dá a sílẹ̀, kóòtù náà di èyí tí a mọ̀ sí chambre ardente, tàbí “iyàrá gbígbóná janjan.” Nǹkan bí 60 àwọn ti ọwọ́ tẹ̀ ni a kàn mọ́ igi títíkan àwọn òǹtẹ̀wé àti òǹtàwé díẹ̀ tí a dáná sun láàyè ní Place Maubert ibi tí kò jìnnà púpọ̀ sí ẹnu ọ̀nà Estienne. A gbọn ilé Estienne yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ léraléra láti lè rí ẹ̀rí bí ó ṣe wù kí ó kéré tó lòdì sí i. Ó lé ní 80 ẹlẹ́rìí tí a fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò. A ṣèlérí ìdámẹ́rin ohun-ìní rẹ̀ fún àwọn gbọ́yìí-sọ̀yìí bí wọ́n bá lè mú kí a dá a lẹ́bi àdámọ̀. Síbẹ̀, kìkì ẹ̀rí tí wọ́n ní ni ohun tí Estienne ti tẹ̀ kedere nínú Bibeli rẹ̀.
Lẹ́ẹ̀kan síi ọba pàṣẹ pé kí a kó gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àyẹ̀wò ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà fún Ìgbìmọ̀ Abọ́ba-Dámọ̀ràn òun. Láì jẹ́ kí a dọ́gbọ́n darí wọn, ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà dáhùn pé ‘àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kò ní àṣà ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìdí tí wọ́n fi sọ pé àwọn ohun kan kò dára, pé wọ́n jẹ́ àdámọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan ni wọ́n fi ń dáhùn, èyí tí o gbọ́dọ̀ gbàgbọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ìkọ̀wé kì yóò ní òpin.’ Henry gbà. A fòfindè é pátápátá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo iṣẹ́ ti Estienne tí ì ṣe rí lórí Bibeli ní a sọ pé kò dára. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìsun-níná ní Place Maubert, ó pinnu láti fi France sílẹ̀ lójú ìfòfindè Bibeli rẹ̀ pátápátá àti ṣíṣeé ṣe pé kí a tún halẹ̀ mọ́ ọn.
Òǹtẹ̀wé Tí A Lé Jáde Nílùú
Ní November 1550, Estienne ṣí lọ sí Geneva, Switzerland. Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ náà ti sọ títẹ Bibeli èyíkéyìí yàtọ̀ sí Vulgate jáde bí ohun tí kò bófinmu ní France. Ní báyìí tí ó ti wà ní òmìnira láti tẹ ohun tí ó bá fẹ́, Estienne tún “Májẹ̀mú Titun” rẹ̀ Lédè Griki tẹ̀ ní 1551, pẹ̀lú àwọn ìtẹ̀jáde méjì ní èdè Latin (ti ẹ̀dà Vulgate àti ti Erasmus) ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Èyí ni òun tẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Griki lédè French tẹ̀lé, ní 1552, ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ ti Erasmus lédè Latin. Nínú àwọn ìtẹ̀jáde méjì wọ̀nyí, Estienne fi ètò bí ó ṣe pín àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ Bibeli sí ẹsẹ̀ tí ó ní nọ́ḿbà hàn—ètò kan náà tí a ń lò káàkiri àgbáyé lónìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn ti gbìyànjú oríṣiríṣi àwọn ọ̀nà tí a lè gbà fi nọ́ḿbà sí ẹsẹ̀ ṣáájú, ti Estienne di irú kan tí a tẹ́wọ́gbà. Bibeli rẹ̀ lédè French ti 1553 ni Bibeli àkọ́kọ́ tí ó fi nọ́ḿbà sí ẹsẹ̀.
Ìtẹ̀jáde méjì ti Bibeli èdè Latin tí Estienne ṣe ní 1557 tún yẹ ní kíkan sáárá sí fún lílo orúkọ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, Jehova, jálẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Ní ìlà-àárín psalmu kejì, ó kọ̀wé pé ọ̀rọ̀ tí a fi rọ́pò ʼAdho·naiʹ fún àmì ọ̀rọ̀ Tetragrammaton Heberu náà (יהוה) ni a gbéka ìgbàgbọ́ asán ti àwọn Júù tí a sì níláti kọ́ ọ́ sílẹ̀. Nínú ìtẹ̀jáde yìí, Estienne lo ìkọ̀wé wínníwínní láti ṣàfihàn àwọn ọ̀rọ̀ Latin tí a fi kún un láti gbé ìtumọ̀ èdè Heberu náà yọ. Àwọn Bibeli mìíràn lo ọgbọ́n yìí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ogún-ìní kan tí ó sábà ń jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ọ̀pọ̀ òǹkàwé òde-òní àwọn tí wọ́n ti di ojúlùmọ̀ lílo ìkọ̀wé wínníwínní lóde-ìwòyí láti fi ìtẹnumọ́ hàn.
Nítorí tí ó pinnu láti jẹ́ kí ẹ̀kọ́ rẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ẹlòmíràn, Estienne fi ìgbésí-ayé rẹ̀ jin títẹ Ìwé Mímọ́ jáde. Àwọn wọnnì tí wọ́n ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sí lónìí lè ṣọpẹ́ fún ìsapá rẹ̀ àti fún akitiyan àwọn mìíràn tí wọ́n fi tokunra tokunra làkàkà láti gbé àwọn ọ̀rọ̀ Bibeli jáde gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ọ̀nà tí wọ́n là sílẹ̀ náà ń bá a nìṣó bí a ṣe ń túbọ̀ ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn èdè àtijọ́ tí a sì ń rí àwọn ìwé-àfọwọ́kọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó ti wà tipẹ́ tí ó sì tún péye ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Gẹ́rẹ́ ṣáájú ikú rẹ̀ (1559), Estienne ń ṣiṣẹ́ lórí ìtumọ̀ titun ti Ìwé Mímọ́ Lédè Griki. A bi í pé: “Ta ni yóò rà á? Ta ni yóò kà á?” Ó fi tìgboyà tìgboyà dáhùn pé: ‘Gbogbo àwọn olùfọkànsin Ọlọrun tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé.’
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tún fi orúkọ rẹ̀ ní èdè Latin, Stephanus, àti orúkọ rẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, Stephens mọ̀ ọ́n.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìsapá Robert Estienne ti ran ọ̀pọ̀ ìran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ́wọ́
[Credit Line]
Bibliothèque Nationale, Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
A ṣe àwòṣe àwòrán afúnni ní ìtọ́ni tí Estienne yà fún ìgbà pípẹ́
[Credit Line]
Bibliothèque Nationale, Paris