ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 8/15 ojú ìwé 31
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òǹtẹ̀wé Tí Ó Tayọlọ́lá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Èéṣe Tí A Fi Ń Wá Òtítọ́ Kiri?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àwọn Kristẹni Ń jọ́sìn Ní Ẹ̀mí Àti Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ọwọ́ Ha Lè Tó Òtítọ́ Ìsìn Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 8/15 ojú ìwé 31

Ìwọ Ha Rántí Bí?

O ha ti gbádùn kíka àwọn ìtẹ̀jáde lọ́ọ́lọ́ọ́ ti Ilé-Ìṣọ́nà bí? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, yóò gbádùnmọ́ ọ láti rántí àwọn ohun tí ó tẹ̀lé e wọ̀nyí:

▫ Ọwọ́ ha lè tó òtítọ́ ìsìn bí?

Jesu Kristi wí pé: “Ẹ óò sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yoo sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Johannu 8:32) Kì í ṣe kìkì pé Jesu tọ́ka sí i pé ọwọ́ lè tó òtítọ́ nìkan ni ṣùgbọ́n ó fi hàn pé rírí i ni a béèrè fún nínú ìjọsìn wa sí Ọlọrun. Ó sọ fún obìnrin ará Samaria kan pé: “Awọn olùjọsìn tòótọ́ yoo máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí ati òtítọ́.” (Johannu 4:23)—4/15, ojú-ìwé 5.

▫ Ta ni Robert Estienne, báwo sì ni ó ṣe tayọ lọ́lá?

Robert Estienne jẹ́ òǹtẹ̀wé kan tí ó gbé ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Ó fi ìgbésí-ayé rẹ̀ jìn fún títẹ Ìwé Mímọ́ jáde ó sì tiraka láti fi àwọn ọ̀rọ̀ Bibeli hàn bí a ṣe kọ ọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ètò-ìgbékalẹ̀ rẹ̀ ti pípín àwọn ẹsẹ̀-ìwé Bibeli sí àwọn ẹsẹ̀ tí a fi nọ́ḿbà sí ni ètò-ìgbékalẹ̀ tí a ń lò káàkiri àgbáyé lónìí.—4/15, ojú-ìwé 10, 14.

▫ Báwo ni a ṣe ń jàǹfààní láti inú Bibeli kíkà ojoojúmọ́?

Ìgbà gbogbo ni Ìwé Mímọ́ ń ní ìtumọ̀ titun sí wa, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn sì máa ń túbọ̀ wọ̀ wá lọ́kàn lójú ìwòye ohun tí a ti rí, tí a ti gbọ́, tí a sì ti ní ìrírí rẹ̀ fúnra wa. Bí a bá ṣe mú ìrírí àwa fúnra wa nínú ìgbésí-ayé gbòòrò síi tí a sì ń kojú àwọn ìṣòro, a túbọ̀ ń mọrírì ìmọ̀ràn Bibeli lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ síi. (Owe 4:18)—5/1, ojú-ìwé 15.

▫ Báwo ni a ṣe lè rántí àwọn ẹsẹ̀-ìwé Bibeli?

Bí o ṣe ń ka Bibeli, sàmì sí àwọn ẹsẹ̀-ìwé tí o ṣàyàn tí o fẹ́ láti rántí, tàbí kí o kọ wọ́n sórí káàdì kí o sì kó àwọn káàdì wọ̀nyí síbi tí o ti lè ri wọn lójoojúmọ́. Bí o ṣe ń gbìyànjú láti ha àwọn ẹsẹ̀-ìwé wọ̀nyí sórí, ṣàṣàrò lé wọn lórí kí o sì lò wọ́n. Máṣe gbìyànjú láti há púpọ̀ jù sórí lẹ́ẹ̀kan náà, bóyá kìkì ẹyọ kan tàbí méjì lọ́sẹ̀.—5/1, ojú-ìwé 16, 17.

▫ Ìsọfúnni wo ni Ìròyìnrere Luku ní nínú tí ó jẹ́ ní àfikún sí ohun tí àwọn òǹkọ̀wé Ìròyìnrere yòókù pèsè?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ ti Luku rí bákan náà pẹ̀lú ti inú àkọsílẹ̀ Matteu, ìpín 59 nínú ọgọ́rùn-ún yàtọ̀. Luku ṣàkọsílẹ̀ iṣẹ́-ìyanu mẹ́fà tí ó wà nínú kìkì ìwé rẹ̀, ó sì ròyìn iye tí ó ju ìlọ́po méjì àwọn àkàwé Jesu tí àwọn òǹkọ̀wé Ìròyìnrere mìíràn kò mẹ́nu kàn.—5/15, ojú-ìwé 12.

▫ Àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ó tayọ lọ́lá wo ni a ṣípayá ní 1935?

Ní ọdún náà ni àwọn ènìyàn Jehofa wá lóye pé ogunlọ́gọ̀ ńlá tí a mẹ́nu kàn nínú Ìṣípayá 7:9, 14 kò tọ́ka sí, ẹgbẹ́ onípò kejì ní òkè-ọ̀run, ṣùgbọ́n sí àwọn wọnnì tí ìrètí wọn jẹ́ lórí ilẹ̀-ayé. (Johannu 10:16)—5/15, ojú-ìwé 20.

▫ Ní àwọn ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ wo ni a fi lè tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú?

Tẹ́tísílẹ̀. Pèsè ìmúdánilójú. Wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Lo àtinúdá nígbà tí ó bá yẹ. Kọ lẹ́tà tàbí káàdì tí ń pèsè ìtùnú. Gbàdúrà pẹ̀lú wọn. (Jakọbu 5:16) Máa bá a nìṣó láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—6/1, ojú-ìwé 13, 14.

▫ Kí ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí lè ṣe láti ran àwọn wọnnì tí ń gbé nínú ìdílé tí ó yapa níti ìsìn lọ́wọ́ láti lo ìfaradà?

Máa sọ̀rọ̀ tí ń fúnni ní ìṣírí, tí ń gbéniró, àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ń tuni nínú fún wọn nígbà gbogbo. (1 Tessalonika 5:14) Èyí ń ṣiṣẹ́ bí ìtura fún ọkàn àti ara wọn. Nígbà tí ó bá gbéṣẹ́ tí ó sì yẹ, fi wọ́n kún àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọrun àti ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà rẹ. Rántí wọn nínú àdúrà rẹ. (Romu 1:9; Efesu 1:16)—6/1, ojú-ìwé 29.

▫ Àwọn èrè wo ní ń ti inú mímú sùúrù wá nígbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá?

Sùúrù ń ran àwọn akéde Ìjọba lọ́wọ́ láti farada ìdágunlá tàbí àtakò èyíkéyìí. Dípò jíjiyàn pẹ̀lú àwọn onílé tí inú ń bí, àwọn òjíṣẹ́ onísùúrù yóò lè fúnni ní ìdáhùn pẹ̀lẹ́ tàbí kí wọ́n rọra fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di àlàáfíà àti ìdùnnú-ayọ̀ mú. (Matteu 10:12, 13) Síwájú síi, àwọn ẹni-bí-àgùtàn ni ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà yóò fà mọ́ra.—6/15, ojú-ìwé 9.

▫ Èéṣe tí mímọ òtítọ́ Bibeli fi níye lórí tóbẹ́ẹ̀?

Mímọ òtítọ́ ń dá wa sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ irọ́, ìmúniṣìnà, àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Nígbà tí a bá gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀, òtítọ́ náà ń fún wa lókun láti farada ìnira ó sì ń ru wá sókè pẹ̀lú ìrètí tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti dúró tiiri lábẹ́ ìdánwò.—7/1, ojú-ìwé 8.

▫ Ẹrù-iṣẹ́ pàtàkì wo ni ìjọ Kristian ẹni-àmì-òróró gbà lọ́wọ́ Israeli àbínibí?

Àǹfààní ti jíjẹ́rìí ìtóbilọ́lá Jehofa láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. (Isaiah 43:21; 1 Peteru 2:9)—7/1, ojú-ìwé 19.

▫ Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Peteru náà dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé ọkọ níláti ‘fi ọlá’ fún aya rẹ̀?

(1 Peteru 3:7) Ọkọ tí ó bọlá fún aya rẹ̀ kì í tẹ́ ẹ lógo tàbí rẹ̀ ẹ́ nípò sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń fi hàn nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀—ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gbangba—pé òun buyì fún un. (Owe 31:10-31)—7/15, ojú-ìwé 19.

▫ Èéṣe tí a fi lè wí pé ó fi ìfẹ́ hàn láti lé oníwà àìtọ́ kan tí kò ronúpìwàdà kúrò nínú ìjọ Kristian?

Ìyọlẹ́gbẹ́ jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ fún Jehofa àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Orin Dafidi 97:10) Ó fi ìfẹ́ hàn fún àwọn wọnnì tí ń lépa ipa-ọ̀nà òdodo nítorí pé ó mú ẹni tí ó lè ní agbára ìdarí búburú lórí wọn kúrò láàárín wọn; èyí pẹ̀lú ń dáàbò bo ìjẹ́mímọ́ ìjọ náà. (1 Korinti 5:1-13)—7/15, ojú-ìwé 25.

▫ Báwo ni a ṣe lè dá “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” tí Jesu sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní Matteu 24:45-47 mọ̀ lónìí?

A dá wọn mọ̀ ní pàtàkì nípa iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní pípèsè àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbékarí Bibeli, nípa kíkọ́ni àti wíwàásù “ìhìnrere ìjọba,” àti nípa ìdìrọ̀ tímọ́tímọ́ wọn mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. (Matteu 24:14; 28:19, 20)—8/1, ojú-ìwé 16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́