Ọjọ́ Jehofa Tí Ń Múnikún-fún-Ẹ̀rù Súnmọ́lé
“A sì kọ ìwé-ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Oluwa, tí wọ́n sì ń ṣe àṣàrò orúkọ rẹ̀.”—MALAKI 3:16.
1, 2. Ọjọ́ tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù wo ni Malaki kìlọ̀ rẹ̀ ṣáájú?
AMÚNIKÚN-FÚN-Ẹ̀RÙ! Bí ilẹ̀ ti mọ́ ní August 6, 1945, ìlú-ńlá kan ni a wó palẹ̀ bẹẹrẹbẹ ní ìṣẹ́jú akàn. Nǹkan bíi 80,000 kú! Ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá farapa yánna-yànna! Iná ń sọ kẹ̀ù! Bọ́m̀bù átọ́míìkì ti pa itú ọwọ́ rẹ̀. Báwo ní nǹkan ti rí fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà àjálù yẹn? Kìkì Ẹlẹ́rìí kan ni ó wà ní Hiroshima—tí a hámọ́ àárín ògiri tí ó dènà ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìwàtítọ́ Kristian rẹ̀. Ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ, ṣùgbọ́n arákùnrin wa kò farapa. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ ọ́, bọ́m̀bù átọ́míìkì fí i sọ̀kò jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n—bóyá ohun rere kanṣoṣo tí bọ́m̀bù náà ṣàṣeyọrí rẹ̀ nìyẹn.
2 Bí ìbúgbàù bọ́m̀bù yẹn ti banilẹ́rù tó, kò jámọ́ nǹkankan nígbà tí a bá fi wéra pẹ̀lú “ọjọ́ Jehofa tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù” tí ó wà níwájú. (Malaki 4:5, NW) Óò, bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọjọ́ tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù ti wà ní àtijọ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ Jehofa yìí yóò tayọ gbogbo wọn.—Marku 13:19.
3. Ìyàtọ̀ wo ni ó yẹ kí a ṣàkíyèsí láàárín “olúkúlùkù ènìyàn” àti ìdílé Noa ṣáájú Àkúnya Omi?
3 Ní ọjọ́ Noa “olúkúlùkù ènìyàn ti ba ìwà rẹ̀ jẹ́ ní ayé,” Ọlọrun sì polongo pé: “Ayé kún fún ìwà-agbára láti ọwọ́ wọn; sì kíyèsí i, èmi óò sì pa wọ́n run pẹ̀lú ayé.” (Genesisi 6:12, 13) Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Matteu 24:39, Jesu sọ pé àwọn ènìyàn “kò . . . fiyèsí i títí ìkún-omi fi dé tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” Ṣùgbọ́n Noa olùṣòtítọ́, “oníwàásù òdodo,” papọ̀ pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ olùbẹ̀rù Ọlọrun, la Àkúnya Omi yẹn já.—2 Peteru 2:5.
4. Àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ wo ni Sodomu ati Gomorra pèsè?
4 Juda 7 sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ naa ni Sodomu ati Gomorra ati awọn ìlú-ńlá tí ó yí wọn ká, lẹ́yìn tí [wọ́n] . . . ti ṣe àgbèrè lọ́nà tí ó pọ̀ lápọ̀jù tí wọ́n sì ti jáde tọ ẹran-ara lẹ́yìn fún ìlò tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, a gbé wọn kalẹ̀ níwájú wa gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ akininílọ̀ nipa fífaragba ìyà ìdájọ́ iná àìnípẹ̀kun.” Àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọrun wọ̀nyẹn ṣègbé nítorí ọ̀nà ìgbésí-ayé ẹlẹ́gbin tí ń súni fún ìríra tí wọ́n ń gbé. Èyí yẹ kí ó jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwùjọ àwọn ènìyàn tí ìbálòpọ̀ ti gbà lọ́kàn nínú ayé òde-òní! Bí ó ti wù kí ó rí, ṣàkíyèsí pé Loti olùbẹ̀rù Ọlọrun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ni a pamọ́ láàyè lákòókò àjálù yẹn, àní bí a óò ti dáàbò bo àwọn olùjọsìn Jehofa lákòókò ìpọ́njú ńlá tí ń yára kánkán bọ̀ yìí.—2 Peteru 2:6-9.
5. Kí ni a lè kọ́ láti inú ìdájọ́ tí a mú ṣẹ sórí Jerusalemu?
5 Lẹ́yìn náà ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ tí a pèsè nígbà tí Jehofa lo àwọn ọmọ-ogun tí ń wọlégbóguntini láti nu Jerusalemu, ìlú-ńlá ológo tí ó ti fìgbà kan rí jẹ́ “ayọ̀ gbogbo ayé” kúrò. (Orin Dafidi 48:2) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ apanilẹ́kún wọ̀nyí ṣẹlẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́ ní 607 B.C.E. àti lẹ́yìn náà ní 70 C.E., nítorí pé àwọn tí wọ́n fẹnu jẹ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ ènìyàn Ọlọrun fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀. Ó múniláyọ̀ pé, àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jehofa làájá. Ìjábá ti 70 C.E. (tí a yàwòrán rẹ̀ sísàlẹ̀) ni a ṣàpèjúwe rẹ̀ bí “ìpọ́njú irúfẹ́ èyí ti kò ṣẹlẹ̀ lati ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọrun dá títí di àkókò yẹn.” Ó mú ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan Júù apẹ̀yìndà kúrò láìkùsíbìkan, dájúdájú ní ọ̀nà yẹn “kì yoo . . . tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Marku 13:19) Ṣùgbọ́n ìmúdàájọ́ àtọ̀runwá ṣẹ yìí pàápàá wulẹ̀ jẹ́ òjìji “ìpọ́njú ńlá naa” tí ń dẹ́rùba gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ayé yìí nísinsìnyí.—Ìṣípayá 7:14
6. Èéṣe tí Jehofa fi fàyègba àwọn àjálù-ibi?
6 Èéṣe tí Ọlọrun yóò fi fàyègba àjálù-ibi bíbanilẹ́rù, tí ó ní òfò ẹ̀mí púpọ̀ bẹ́ẹ̀? Nínú ọ̀ràn ti Noa, ti Sodomu àti Gomorra, àti ti Jerusalemu, Jehofa ń mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn tí wọ́n ti ba ọ̀nà wọn jẹ́ ní ilẹ̀-ayé, tí wọ́n ti sọ planẹẹti ẹlẹ́wà yìí di ẹlẹ́gbin pẹ̀lú èérí níti gidi àti ìjẹràbàjẹ́ ìwàrere, tí wọ́n sì ti pẹ̀yìndà sí, tàbí kọ ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀. Lónìí a wà ní bèbè ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ìmúṣẹ ìdájọ́ tí yóò bo gbogbo ayé mọ́lẹ̀ pátápátá.—2 Tessalonika 1:6-9.
“Ní Awọn Ọjọ́ Ìkẹyìn”
7. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ kí ni àwọn ìdájọ́ àtọ̀runwá ìgbàanì jẹ́? (b) Ìfojúsọ́nà ológo wo ni ó wà níwájú?
7 Àwọn ìparun àkókò ìgbàanì wọ̀nyẹn jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ìpọ́njú ńlá tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù tí a ṣàpèjúwe ní 2 Peteru 3:3-13. Aposteli náà sọ pé: “Ẹ̀yin mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́, pé ní awọn ọjọ́ ìkẹyìn awọn olùyọṣùtì yoo wá pẹlu ìyọṣùtì wọn, wọn yoo máa rìn ní ìbámu pẹlu ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn.” Lẹ́yìn náà, ní dídarí àfiyèsí sí ọjọ́ Noa, Peteru kọ̀wé pé: “Ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀. Ṣugbọn nipa ọ̀rọ̀ kan naa awọn ọ̀run ati ilẹ̀-ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tòjọ pamọ́ fún iná a sì ń fi wọ́n pamọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ ati ti ìparun awọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọrun.” Tẹ̀lé ìpọ́njú tí ó ju gbogbo ìpọ́njú lọ yẹn, ìṣàkóso Ìjọba ti Messia náà tí a ti ń dúró dè tipẹ́tipẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ìhà titun—“awọn ọ̀run titun ati ilẹ̀-ayé titun . . . , ninu awọn wọnyi ni òdodo yoo sì máa gbé.” Ìfojúsọ́nà onídùnnú-ayọ̀ ni èyí jẹ́!
8. Báwo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé ṣe ń súnmọ́ òtéńté kan?
8 Lákòókò ọ̀rúndún ogún wa, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé ti sún kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ síhà òtéńté kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìparun tí ó débá Hiroshima kì í ṣe ìbẹ̀wò àtọ̀runwá, ó lè wà lára “ìran akúnfúnbẹ̀rù” tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ fún àkókò òpin. (Luku 21:11) Ó tú ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ ewu agbára átọ́míìkì tí ó ṣì ń fì dùgbẹ̀ bí ìjì lórí aráyé jáde. Nítorí èyí, àkọlé kan nínú ìwé ìròyìn The New York Times ti November 29, 1993, kà pé: “Àwọn Ìbọn Lè Ti Dípẹtà Díẹ̀ Ṣùgbọ́n Àwọn Ohun Ìjà Agbára Átọ́míìkì Ṣì Ń Dán Gbinrin.” Ní báyìí ná, àwọn ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ìran, àti ẹ̀yà ṣì ń bá a nìṣó láti kó ìkórè ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan. Ní àwọn ọ̀rúndún tí ó ti kọjá, iye tí ó pọ̀jù lára àwọn abógunrìn jẹ́ àwọn sójà. Lónìí, ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn abógunrìn ni a ròyìn pé wọ́n jẹ́ àwọn aráàlú, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí wọ́n sá fi ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn sílẹ̀ bí àwọn olùwá ibi ìsádi.
9. Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn ṣe fi ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé hàn?
9 Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn aṣáájú ìsìn ti fi “ìṣọ̀rẹ́ pẹlu ayé” hàn, wọ́n sì ń bá a nìṣó láti fi hàn nípa fífi tokunra tokunra kówọnú àwọn ogun àti àwọn ìyípadà àfọ̀tẹ̀ṣe ọlọ́gbàrá ẹ̀jẹ̀. (Jakọbu 4:4) Àwọn kan ti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn baba ìsàlẹ̀ oníwà wọ̀bìà nínú ayé ìṣòwò bí àwọn wọ̀nyí ti ń ṣe àwọn ohun ìjà lọ́pọ̀ yanturu tí wọ́n sì ń mú ilẹ̀-ọba oògùn líle gbòòrò síi. Fún àpẹẹrẹ, ní ríròyìn lórí ìdìtẹ̀pa ògbóǹtagí olówò oògùn líle ara South America kan, ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Bí ó ti ń fi òwò oògùn líle rẹ̀ pamọ́ lábẹ́ ọrọ̀ tí ó fẹnu sọ pé ó jẹ́ láti inú òwò tí ó bófinmu tí ó sì ń fi òjìji olóore kan bojú, ó ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí rédíò tirẹ̀ àwọn àlùfáà Roman Katoliki sì máa ń wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal ròyìn pé ní àfikún sí bíba ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ti di ajòògùnyó jẹ́, ògbóǹtagí olówò oògùn yìí fúnra rẹ̀ ti pàṣẹ ìṣekúpa ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Ìwé ìròyìn The Times ti London ṣàkíyèsí pé: “Àwọn aṣekúpani náà sábà máa ń sanwó fún àkànṣe Máàsì ìdúpẹ́ kan . . . ní àkókò kan náà tí máàsì ìsìnkú òjìyà náà ń lọ lọ́wọ́ níbòmíràn.” Ẹ wo irú ìwà burúkú tí èyí jẹ́!
10. Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo ipò tí ń burú síi nínú ayé?
10 Ta ni ó mọ irú ọṣẹ́ tí àwọn ẹni tí ẹ̀mí-èṣù mísí yóò ṣì ṣe lórí ilẹ̀-ayé yìí? Bí 1 Johannu 5:19 ṣe sọ ọ́, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa,” Satani Èṣù. Lónìí “ègbé ni fún ilẹ̀-ayé ati fún òkun, nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Bí ó ti wù kí ó rí, ó múniláyọ̀ pé Romu 10:13 mú un dá wa lójú pé “olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jehofa ni a óò gbàlà.”
Ọlọrun Súnmọ́tòsí Láti Ṣe Ìdájọ́
11. Àwọn ipò wo ní Israeli ní o tannáran àsọtẹ́lẹ̀ Malaki?
11 Níti ọjọ́-ọ̀la aráyé tí kò jìnnà mọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Malaki tànmọ́lẹ̀ sórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Malaki ni a to orúkọ rẹ̀ kẹ́yìn nínú ìlà gígùn ti àwọn wòlíì Heberu ti ìgbà láéláé. Israeli ti ní ìrírí ìsọdahoro Jerusalemu ní 607 B.C.E. Ṣùgbọ́n 70 ọdún lẹ́yìn náà Jehofa fi inúrere-ìfẹ́ aláàánú hàn ní dídá orílẹ̀-èdè yẹn padà sí ilẹ̀ rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún, Israeli tún ti bẹ̀rẹ̀ síi súlọ sínú ìpẹ̀yìndà àti ìwà burúkú. Àwọn ènìyàn náà ń ṣàìbọlá fún orúkọ Jehofa, wọn ń ṣàìfiyèsí àwọn òfin òdodo rẹ̀, wọ́n sì ń sọ tẹ́ḿpìlì rẹ̀ di eléèérí nípa mímú afọ́jú, arọ, àti olókùnrùn ẹran wá fún ìrúbọ. Wọ́n ń kọ àwọn ìyàwó ìgbà èwe wọn sílẹ̀ kí wọ́n báa lè fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì.—Malaki 1:6-8; 2:13-16.
12, 13. (a) Ìwẹ̀nùmọ́ wo ni ó ti pọndandan fún agbo àlùfáà ẹni-àmì-òróró? (b) Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá pẹ̀lú ṣe jàǹfààní láti inú ìwẹ̀mọ́ náà?
12 Iṣẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kan ni a nílò. A ṣàpèjúwe rẹ̀ ní Malaki 3:1-4. Bíi ti Israeli ìgbàanì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lóde-ìwòyí nílò ìwẹ̀mọ́, nítorí náà iṣẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ ní Malaki lè kàn wọ́n. Bí ogun àgbáyé kìn-ínní tí ń súnmọ́ òpin rẹ̀, àwọn kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí sí nígbà náà, kò di àìdásí tọ̀tún tòsì tí kò gba gbẹ̀rẹ́ kedere mú nínú àwọn àlámọ̀rí ayé. Ní 1918, Jehofa rán “ońṣẹ́ májẹ̀mú” Rẹ̀, Kristi Jesu, wá sí ìṣètò tẹ́ḿpìlì tẹ̀mí Rẹ̀ láti wẹ àwùjọ kékeré àwọn olùjọsìn Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú àbàwọ́n ayé. Lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, Jehofa béèrè pé: “Ta ni ó lè gba ọjọ́ wíwà [ońṣẹ́ náà]? ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? nítorí òun dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà, àti bí ọṣẹ afọṣọ. Òun óò sì jókòó bí ẹni tí ń yọ́, tí ó sì ń da fàdákà: yóò sì [wẹ] àwọn ọmọ Lefi [àwùjọ àlùfáà ẹni-àmì-òróró] mọ́, yóò sì yọ́ wọn bíi wúrà òun fàdákà, kí wọn kí ó lè mú ọrẹ òdodo wá fún Oluwa.” Bí àwọn ẹni tí a ti wẹ̀nùmọ́, wọ́n ti ṣé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!
13 Àwùjọ àlùfáà ẹni-àmì-òróró yẹn jẹ́ 144,000 péré. (Ìṣípayá 7:4-8; 14:1, 3) Bí ó ti wù kí ó rí, kí ni nípa ti àwọn Kristian olùṣèyàsímímọ́ mìíràn lónìí? Iye wọn ti ń lọ sí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ nísinsìnyí, àwọn wọ̀nyí parapọ̀ di “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan” tí a tún níláti wẹ̀mọ́ kúrò nínú àwọn ọ̀nà ayé, ‘ní fífọ aṣọ ìgúnwà wọn tí wọ́n sì sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa.’ (Ìṣípayá 7:9, 14) Nípa báyìí, nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Ọ̀dọ́ Àgùtàn náà, Kristi Jesu, wọ́n lè di ìdúró mímọ́ tónítóní mú níwájú Jehofa. A ṣèlérí líla gbogbo ìpọ́njú ńlá náà, ọjọ́ Jehofa tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù já fún wọn.—Sefaniah 2:2, 3.
14. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni àwọn ènìyàn Ọlọrun níláti kọbiara sí lónìí bí wọ́n ti ń bá a nìṣó láti mú àkópọ̀-ìwà titun dàgbà?
14 Papọ̀ pẹ̀lú àwọn àlùfáà àṣẹ́kù náà, ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí gbọ́dọ̀ kọbiara sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun sọ tẹ̀lé e yìí: “Èmi óò sì súnmọ́ yín fún ìdájọ́, èmi óò sì ṣe ẹlẹ́rìí yíyára sí àwọn oṣó, àti sí àwọn panṣágà, àti sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó ni alágbàṣe lára nínú ọ̀yà rẹ̀, àti opó, àti aláìníbaba, àti sí ẹni tí ó ń rẹ́ àlejò jẹ, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi . . . Nítorí èmi ni Oluwa, èmi kò yípadà.” (Malaki 3:5, 6) Ó tì o, ọ̀pá-ìdiwọ̀n Jehofa kò yípadà, nítorí náà nínú ìbẹ̀rù Jehofa, àwọn ènìyàn rẹ̀ gbọ́dọ̀ kọ gbogbo onírúurú ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ kí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́, aláìlábòsí, kí wọ́n sì jẹ́ ọ̀làwọ́ bí wọ́n ti ń bá a nìṣó láti mú àkópọ̀-ìwà Kristian dàgbà.—Kolosse 3:9-14.
15. (a) Ìkésíni aláàánú wo ni Jehofa ń nawọ́ rẹ̀ jáde? (b) Báwo ni a ṣe lè yẹra fún ‘jíja’ Jehofa “ní olè”?
15 Jehofa ń nawọ́ ìkésíni sí ẹnikẹ́ni tí ó ti lè yípadà kúrò ní ọ̀nà òdodo rẹ̀, ní sísọ pé: “Ẹ yípadà sí ọ̀dọ̀ mi, èmi óò sì yípadà sí ọ̀dọ̀ yín.” Bí àwọn wọ̀nyí bá béèrè pé: “Nípa báwo ni àwa óò yípadà?” ó dáhùn pé: “Ẹ̀yín sa ti jà mí ní olè.” Àti ní ìdáhùn sí ìbéèrè síwájú síi náà: “Nípa báwo ni àwa fi jà ọ́ ní olè?” Jehofa sọ pé wọ́n ti ja òun ní olè nípa kíkùnà láti mú ìrúbọ wọn tí ó dára jùlọ wá fún iṣẹ́-ìsìn tẹ́ḿpìlì rẹ̀. (Malaki 3:7, 8) Níwọ̀n ìgbà tí a ti di apákan àwọn ènìyàn Jehofa, nítòótọ́ a níláti fẹ́ láti ya èyí tí ó dára jùlọ nínú okun, agbára, àti ọrọ̀ wa nípa ti ara sọ́tọ̀ fún iṣẹ́-ìsìn Jehofa. Nípa báyìí, kàkà kí a ja Ọlọrun lólè, a ‘ń bá a nìṣó ní wíwá ìjọba naa ati òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.’—Matteu 6:33.
16. Ìṣírí wo ni a rí ní Malaki 3:10-12?
16 Èrè ẹ̀san títóbilọ́lá wà fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí àwọn ọ̀nà ìṣiṣẹ́sin ara-ẹni, onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì ti ayé yìí, bí Malaki 3:10-12 ti fi hàn: “Ẹ . . . fi èyí dán mi wò nísinsìnyí, [ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí], bí èmi kì yóò bá ṣí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yín, kí n sì tú ìbùkún jáde fún yín, tóbẹ́ẹ̀ tí kì yóò sí àyè tó láti gbà á.” Jehofa ṣèlérí aásìkí àti ìmésojáde nípa tẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ó ní ìmọrírì. Ó fikún un pé: “Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò sì pè yín ní alábùkún fún, nítorí ẹ̀yin óò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wuni.” Ìyẹn kò ha ti jóòótọ́ láàárín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn Ọlọrun tí wọ́n mọpẹ́ẹ́dá jákèjádò ilẹ̀-ayé lónìí?
Àwọn Olùpàwàtítọ́mọ́ Nínú Ìwé Ìyè
17-19. (a) Báwo ni rúkèrúdò ní Rwanda ti ṣe kan àwọn arákùnrin wa níbẹ̀? (b) Pẹ̀lú ìgbàgbọ́dájú wo ni àwọn ẹni olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ti fi ń bá a nìṣó?
17 Níbi tí ọ̀rọ̀ dé yìí, a lè mẹ́nuba ìwàtítọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Rwanda. Nígbà gbogbo ni wọ́n ń mú ìrúbọ tí ó jọjú jùlọ wá sínú ilé ìjọsìn tẹ̀mí ti Jehofa. Fún àpẹẹrẹ, ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” wọn ní December 1993, àwọn akéde Ìjọba wọn tí wọ́n jẹ́ 2,080 kórè àròpọ̀ 4,075 tí wọ́n pésẹ̀. Àwọn 230 Ẹlẹ́rìí titun ni a batisí, lára àwọn wọ̀nyí, 150 forúkọsílẹ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù tí ó tẹ̀lé e.
18 Nígbà tí ìkórìíra ẹ̀yà-ìran bẹ́ sílẹ̀ ní April 1994, ó kéré tan 180 àwọn Ẹlẹ́rìí, títíkan alábòójútó ìlú ní Kigali, olú-ìlú náà, àti gbogbo ìdílé rẹ̀, ni a pa. Àwọn olùtumọ̀ èdè mẹ́fà tí wọ́n wà ní ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Kigali, tí mẹ́rin nínú wọ́n jẹ́ Hutu tí méjì sì jẹ́ Tutsi, ń bá a nìṣó láti ṣiṣẹ́ fún àwọn ọ̀sẹ̀ mélòókan lábẹ́ ìhalẹ̀mọ́ni lílekoko, títí tí àwọn Tutsi náà fi níláti sálọ, ní ìgbẹ̀yìn rẹ̀ a pa wọ́n ní ibùdó ìyẹkọ̀wò. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, ní gbígbé ohun tí ó kù sílẹ̀ lára ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà wọn, àwọn mẹ́rin tí ó kù sálọ sí Goma, ní Zaire, níbi tí wọ́n ti ń fi pẹ̀lú ìdúróṣinṣin bá a nìṣó láti máa tú Ilé-Ìṣọ́nà sí èdè Kinyarwanda.—Isaiah 54:17.
19 Àwọn Ẹlẹ́rìí olùwá ibi ìsádi wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wà lábẹ́ àyíká ipò tí ń múni soríkodò, wọ́n máa ń fìgbà gbogbo béèrè fún oúnjẹ tẹ̀mí ṣáájú àwọn ìpèsè ti ara. Pẹ̀lú ìrúbọ gíga, ó ṣeé ṣe fún àwọn arákùnrin onífẹ̀ẹ́ láti àwọn ilẹ̀ mélòókan láti gbé àwọn ohun tí wọ́n nílò dé ọ̀dọ̀ wọn. Nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wọn àti ìwàlétòlétò lábẹ́ másùnmáwo, àwọn olùwá ibi ìsádi wọ̀nyí ti pèsè ẹ̀rí yíyanilẹ́nu. Nítòótọ́ wọ́n ti ń bá a nìṣó láti mú èyí tí ó dára jùlọ wọn wá sínú ìjọsìn Jehofa. Wọ́n ti fi ìdálójú ìgbàgbọ́ bíi ti Paulu hàn tí a sọ nínú Romu 14:8 pé: “Bí awa bá wà láàyè, awa wà láàyè fún Jehofa, bí awa bá sì kú, awa kú fún Jehofa. Nitori naa bí awa bá wà láàyè ati bí awa bá kú, awa jẹ́ ti Jehofa.”
20, 21. (a) Orúkọ àwọn wo ni a kò kọ sínú ìwé ìrántí Jehofa? (b) Orúkọ àwọn wo ni ó fara hàn nínú ìwé náà, èésìtiṣe?
20 Jehofa pa àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn tí ó fi ìwàtítọ́ ṣiṣẹ́sìn ín mọ́. Àsọtẹ́lẹ̀ Malaki ń bá a nìṣó pé: “Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Oluwa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nígbàkugbà; Oluwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́, a sì kọ ìwé-ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí ó bẹ̀rù Oluwa, tí wọ́n sì ń ṣe àṣàrò orúkọ rẹ̀.”—Malaki 3:16.
21 Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó lónìí pé kí a fi ìbẹ̀rù Ọlọrun hàn ní bíbọlá fún orúkọ Jehofa! Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a kò ní jìyà ìdájọ́ aláìbáradé, bíi ti àwọn wọ̀nni tí wọ́n ń fi ìkansáárá ṣètìlẹyìn fún ètò-ìgbékalẹ̀ ayé yìí. Ìṣípayá 17:8 sọ pé “a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè.” Ó bọ́gbọ́n mu pé, orúkọ títayọlọ́lá jùlọ tí a kọ sínú ìwé ìyè Jehofa ni ti Olórí Aṣojú ìyè, Ọmọkùnrin Ọlọrun fúnra rẹ̀, Jesu Kristi. Matteu 12:21 polongo pé: “Nítòótọ́, ninu orúkọ rẹ̀ ni awọn orílẹ̀-èdè yoo ní ìrètí.” Ẹbọ ìràpadà Jesu mú ìyè àìnípẹ̀kun dájú fún gbogbo àwọn tí ó lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ wo àǹfààní tí ó jẹ́ láti ní orúkọ wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan tí a fikún orúkọ Jesu nínú àkájọ ìwé yẹn!
22. Ìyàsọ́tọ̀ wo ni yóò fara hàn nígbà tí Jehofa bá mú ìdájọ́ ṣẹ?
22 Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun yóò ṣe ṣàṣeyọrí lákòókò ìdájọ́ náà? Jehofa dáhùn ní Malaki 3:17, 18 pé: “Èmi óò sì dá wọn sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti máa dá ọmọ rẹ̀ sí tí ó ń sìn ín. Nígbà náà ni ẹ̀yin óò yípadà, ẹ óò sì mọ ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni búburú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọrun, àti ẹni tí kò sìn ín.” Ìpinyà náà yóò hàn gbangba sí gbogbo ènìyàn: àwọn ẹni burúkú, tí a yàsọ́tọ̀ fún ìkékúrò àìnípẹ̀kun, àti àwọn olódodo, tí a fọwọ́ sí fún ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ àkóso Ìjọba náà. (Matteu 25:31-46) Nípa bẹ́ẹ̀ ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn ẹni-bí-àgùtàn yóò la ọjọ́ ńlá Jehofa tí ń múnikún-fún-ẹ̀rù já.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Ìdájọ́ wo ni Jehofa múṣẹ ní àwọn àkókò Bibeli?
◻ Báwo ni àwọn ipò lónìí ṣe bá ti àkókò ìgbàanì mu?
◻ Ìwẹ̀nùmọ́ wo ni ó ti ṣẹlẹ̀ ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Malaki?
◻ Orúkọ àwọn wo ni a kọ sínú ìwé ìrántí Ọlọrun?