Ìgbà Tí Ó Sàn Jù Ń Bẹ Níwájú
OBÌNRIN kan sọ pé: “A ń jẹun lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́.”
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dáhùn pé: “Nǹkan tilẹ̀ tún burú jáì fún mi. Mo ń jẹun lálẹ́ nìkan.”
Ní àwọn apákan Ìwọ̀-Oòrùn Africa, irú ìjíròrò báyìí kò nílò àlàyé kankan. Dípò jíjẹun lẹ́ẹ̀mẹta lójúmọ́ (láàárọ̀, lọ́sàn-án, lálẹ́), ẹnì kan tí ń jẹun láàárọ̀ àti lálẹ́ ni agbára rẹ̀ ká láti jẹ kìkì oúnjẹ ẹ̀ẹ̀mejì lójúmọ́—ẹ̀ẹ̀kan láàárọ̀ àti ẹ̀ẹ̀kan lálẹ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń jẹun lálẹ́ nìkan ṣàlàyé ipò rẹ̀ pé: “Mo máa ń jẹun lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́. Mo ń rọ omi kún ẹ̀rọ̀ amú-nǹkan-tutù mi. Mo ń jẹ ẹ̀bà lálẹ́ ṣáájú kí n tó lọ sùn. Bí mo ṣe ń kó o pá á nìyẹn.”
Bẹ́ẹ̀ ni ìṣòro iye àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ síi lónìí ṣe rí. Owó ọjà ń ga sókè, iye tí owó sì lè rà ń lọ sílẹ̀.
A Sàsọtẹ́lẹ̀ Àìtó Oúnjẹ
Nínú ọ̀wọ́ àwọn ìran tí a fi han aposteli Johannu, Ọlọrun sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ipò tí ó ṣòro tí ọ̀pọ̀ ń dojúkọ lónìí. Lára wọn ni àìtó oúnjẹ. Johannu ròyìn pé: “Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀.” (Ìṣípayá 6:5) Ẹṣin alájàálù-ibi yìí àti ẹni tí ó gùn ún ṣàpẹẹrẹ ìyàn—oúnjẹ yóò ṣọ̀wọ́n débi pé a óò máa fi òṣùwọ̀n wọ̀n ọ́n.
Lẹ́yìn náà aposteli Johannu sọ pé: “Mo sì gbọ́ tí ohùn kan . . . wí pé: ‘Ìlàrin òṣùwọ̀n àlìkámà fún owó dinari kan, ati ìlàrin òṣùwọ̀n mẹ́ta ọkà báálì fún owó dinari kan.’” Ní ìgbà ayé Johannu, ìlàrin òṣùwọ̀n àlìkámà jẹ́ oúnjẹ ojúmọ́ fún sójà kan, owó dinari kan sì ni owó tí a máa ń san fún iṣẹ́ ojúmọ́ kan. Nípa báyìí, ìtumọ̀ Richard Weymouth túmọ̀ ẹsẹ̀ náà pé: “Owó-iṣẹ́ odidi ọjọ́ kan fún ìṣù búrẹ́dì kan, owó-iṣẹ́ odidi ọjọ́ kan fún àkàrà báálì mẹ́ta.”—Ìṣípayá 6:6.
Éèló ni owó-iṣẹ́ odidi ọjọ́ kan lónìí? Ìròyìn State of World Population, 1994 ṣàkíyèsí pé: “Nǹkan bí 1.1 billion àwọn ènìyàn, nǹkan bí ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún iye àwọn olùgbé ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ń ná $1 lójúmọ́.” Nípa báyìí, níti àwọn òtòṣì ní àgbáyé, ní òwuuru owó-iṣẹ́ ojúmọ́ lọ́nà kan ṣáá, ra ìṣù búrẹ́dì kan.
Àmọ́ ṣáá o, èyí kò ya àwọn tí wọ́n tòṣì lẹ́nu. Ọkùnrin kan ṣe sáàfúlà pé: “Búrẹ́dì! Ta ni ń jẹ búrẹ́dì? Lóde-òní búrẹ́dì jẹ́ oúnjẹ olówó!”
Lọ́nà ìjẹ́nilẹ́gọ̀ọ́, kò sí àìtó oúnjẹ. Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìsọfúnni ètò-àjọ UN, ní àwọn ọdún mẹ́wàá tí ó kọjá, iye ìpèsè oúnjẹ ní àgbáyé ti lọ sókè ní ìpín 24 nínú ọgọ́rùn-ún, iye tí ó ju ìdàgbàsókè iye àwọn olùgbé ayé lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ní ń gbádùn ìpèsè oúnjẹ tí ń lọ sókè yìí. Fún àpẹẹrẹ, ní Africa, nítòótọ́ ìpèsè oúnjẹ lọ sílẹ̀ ní ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún, nígbà tí iye àwọn olùgbé lọ sókè ní ìpín 34 nínú ọgọ́rùn-ún. Nítorí náà láìka ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ lágbàáyé sí, àìtó oúnjẹ ń báa lọ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.
Àìtó oúnjẹ túmọ̀ sí owó-oúnjẹ tí ó ga síi. Àìsí iṣẹ́, owó-ọ̀yà tí ó kéré, àti owó-ọjà tí ń fò sókè lálá mú kí ó túbọ̀ ṣòro láti rí owó láti fi ra ohun tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Àkọsílẹ̀ ìròyìn Human Development Report 1994 sọ pé: “Ebi ń pa àwọn ènìyàn kì í ṣe nítorí kò sí oúnjẹ lárọ̀ọ́wọ́tó—ṣùgbọ́n nítorí agbára wọn kò ká a.”
Lọ́nà tí ń tẹ̀síwájú, àìnírètí, ìjákulẹ̀, àti ìsọ̀rètínù wà. Glory, tí ń gbé ní Ìwọ̀-Oòrùn Africa, sọ pé: “Àwọn ènìyàn nímọ̀lára pé òní kò dára, ṣùgbọ́n ọ̀la yóò burú jáì.” Obìnrin mìíràn sọ pé: “Àwọn ènìyàn ń wòye pé wọ́n ń dojúkọ àjálù kan. Wọ́n ń wòye pé ọjọ́ náà yóò dé nígbà tí kì yóò sí ohun kankan tí ó ṣẹ́kù ní ọjà láti rà.”
Jehofa Bìkítà fún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Ní Ìgbà Àtijọ́
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun mọ̀ pé Jehofa ń san èrè fún àwọn tí wọ́n ṣòtítọ́ sí i nípa pípèsè fún àìní wọn àti nípa fífún wọn lókun láti kojú àwọn ipò tí ó ṣòro. Ní tòótọ́, irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ nínú agbára Ọlọrun láti pèsè jẹ́ apá tí ó ṣe pàtàkì nínú ìgbàgbọ́ wọn. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọrun wá gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé ó ń bẹ ati pé oun di olùsẹ̀san fún awọn wọnnì tí ń fi taratara wá a.”—Heberu 11:6.
Jehofa ti máa ń fìgbà gbogbo bìkítà nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́. Nígbà ọ̀gbẹlẹ̀ ọlọ́dún mẹ́ta àti ààbọ̀, Jehofa pèsè oúnjẹ fún wòlíì Elija. Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọrun pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ iwò láti mú àkàrà àti ẹran wá fún Elija. (1 Awọn Ọba 17:2-6) Lẹ́yìn náà, lọ́nà ìyanu Jehofa mú kí ìpèsè ìyẹ̀fun àti òróró opó tí ń pèsè oúnjẹ fún Elija máa pọ̀ síi. (1 Awọn Ọba 17:8-16) Nígbà ìyàn kan náà, láìka inúnibíni tí ó gbóná janjan níti ìsìn tí Jesebeli Ayaba búburú mú wá sórí wọn sí, Jehofa tún rí síi pé àwọn wòlíì rẹ̀ ni a pèsè àkàrà àti omi fún.—1 Awọn Ọba 18:13.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí ọba Babiloni sàgati Jerusalemu apẹ̀yìndà, àwọn ènìyàn níláti “jẹ àkàrà nípa ìwọ̀n, àti pẹ̀lú ìtọ́jú.” (Esekieli 4:16) Ipò náà burú débi pé àwọn obìnrin kan jẹ ẹran-ara àwọn ọmọ wọn tìkara wọn. (Ẹkún Jeremiah 2:20) Síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wòlíì Jeremiah wà ní àtìmọ́lé nítorí ìwàásù rẹ̀, Jehofa rí síi pé “a . . . fún [Jeremiah] ní ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan lójoojúmọ́, láti ìta àwọn alákàrà, títí gbogbo àkàrà fi tán ní ìlú.”—Jeremiah 37:21.
Jehofa ha gbàgbé Jeremiah nígbà tí ìpèsè àkàrà tán bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́, níti pé nígbà tí ìlú náà ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Babiloni, Jeremiah ni a fún ní ‘owó oúnjẹ àti ẹ̀bùn; a sì jọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́wọ́.’—Jeremiah 40:5, 6; tún wo Orin Dafidi 37:25.
Ọlọrun Ń Ti Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Lẹ́yìn Lónìí
Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àwọn ìran tí ó kọjá dúró, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣe lónìí, ní bíbìkítà fún wọn nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ìrírí Lamitunde, tí ń gbé ní Ìwọ̀-Oòrùn Africa. Ó sọ pé: “Nígbà kan rí mo ní ọgbà adìyẹ tí ó tóbi díẹ̀. Ní ọjọ́ kan, àwọn adigunjalè wá sí oko náà wọ́n sì jí èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn adìyẹ náà, ẹ̀rọ tí ń múná wá fún ìlò pàjáwìrì, àti owó tí a ní. Kété lẹ́yìn náà, ìwọ̀nba àwọn adìyẹ tí ó kù ni àìsàn pa. Ìyẹn ba okòwò adìyẹ mi jẹ́. Fún ọdún méjì mo gbìyànjú láti wá iṣẹ́ láìsí àṣeyọrí. Nǹkan ṣòro gan-an, ṣùgbọ́n Jehofa mú wa dúró.
“Ohun tí ó mú mi kojú àwọn àkókò lílekoko náà ni pé mo mọ̀ pé Jehofa ń fàyègba nǹkan láti ṣẹlẹ̀ sí wa láti lè mú wa sunwọ̀n síi. Èmi àti ìyàwó mi mú ìṣedéédéé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé wa tẹ̀síwájú, èyí sì ràn wá lọ́wọ́ gidigidi. Àdúrà tún jẹ́ orísun okun ńlá kan. Nígbà mìíràn àdúrà kì í wù mí í gbà, ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá gbàdúrà, ara mi a yá yàtọ̀.
“Nígbà àkókò lílekoko náà, mo kẹ́kọ̀ọ́ ìníyelórí ṣíṣàṣàrò lórí Ìwé Mímọ́. Mo máa ń ronú púpọ̀ nípa Orin Dafidi 23, tí ó sọ̀rọ̀ Jehofa gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùtàn wa. Ìwé mímọ́ mìíràn tí ó fún mi ní ìṣírí ni Filippi 4:6, 7, tí ó tọ́ka sí ‘àlàáfíà Ọlọrun tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.’ Àyọkà mìíràn tí ó fún mi lókun ni 1 Peteru 5:6, 7, tí ó sọ pé: ‘Nitori naa, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọrun, kí oun lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ̀yin ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nitori ó ń bìkítà fún yín.’ Gbogbo àwọn ẹsẹ̀ wọ̀nyí ràn mí lọ́wọ́ láàárín àwọn àkókò tí ó ṣòro wọ̀nyẹn. Nígbà tí o bá ṣàṣàrò, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti yí gbogbo èrò-inú rẹ tí ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì padà.
“Nísinsìnyí mo ti níṣẹ́ padà, ṣùgbọ́n láti sọ tòótọ́, kì í ṣe pé nǹkan rọrùn. Gan-an bí Bibeli ti sọtẹ́lẹ̀ nínú 2 Timoteu 3:1-5, a ń gbé ní ‘awọn ọjọ́ ìkẹyìn,’ tí ‘awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò’ sàmì sí. A kò lè yí ohun tí ìwé mímọ́ sọ padà. Nítorí náà èmi kò retí pé kí ìgbésí-ayé rọrùn. Síbẹ̀, mo wòye pé ẹ̀mí Jehofa ń ràn mí lọ́wọ́ láti borí.”
Láìka àwọn àkókò lílekoko tí a ń gbé sí, àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀ Ọba, Kristi Jesu, ni a kì yóò jákulẹ̀. (Romu 10:11) Jesu fúnra rẹ̀ mú un dá wa lójú pé: “Nítìtorí èyí mo wí fún yín pé: Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nipa ọkàn yín níti ohun tí ẹ̀yin yoo jẹ tabi ohun tí ẹ̀yin yoo mu, tabi nipa ara yín níti ohun tí ẹ̀yin yoo wọ̀. Ọkàn kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ ati ara ju aṣọ lọ? Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí awọn ẹyẹ ojú ọ̀run, nitori wọn kì í fún irúgbìn tabi ká irúgbìn tabi kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pamọ́; síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níyelórí jù wọ́n lọ bí? Ta ni ninu yín nipa ṣíṣàníyàn tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀? Pẹ̀lúpẹ̀lù, níti ọ̀ràn ti aṣọ, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn?”—Matteu 6:25-28.
Dájúdájú àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn jẹ́ awádìí-ọkàn-wò ní àwọn àkókò lílekoko wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n Jesu tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìdánilójú wọ̀nyí pé: “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n lára awọn òdòdó lílì pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú; ṣugbọn mo wí fún yín pé àní Solomoni pàápàá ninu gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe ní ọ̀ṣọ́-ẹ̀yẹ bí ọ̀kan lára awọn wọnyi. Wàyí o, bí Ọlọrun bá wọ ewéko pápá láṣọ bayii, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí tí a sì sọ sínú ààrò ní ọ̀la, oun kì yoo ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré? Nitori naa ẹ máṣe ṣàníyàn láé kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni awa yoo jẹ?’ tabi, ‘Kí ni awa yoo mu?’ tabi, ‘Kí ni awa yoo wọ̀?’ Nitori gbogbo iwọnyi ni nǹkan tí awọn orílẹ̀-èdè ń lépa pẹlu ìháragàgà. Nitori Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọnyi. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà naa, ní wíwá ìjọba naa ati òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọnyi ni a óò sì fi kún un fún yín.”—Matteu 6:28-33.
Ìgbà Tí Ó Sàn Jù Ń Bẹ Níwájú
Ìtọ́kasí tí ó dájú wà pé ní apá tí ó pọ̀ jùlọ ní ayé, ètò ọrọ̀-ajé àti àwọn ipò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tí ń burú síi yóò máa bá a lọ láti máa burú síi. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn Ọlọrun mọ̀ pé àwọn ipò wọ̀nyí jẹ́ fún ìgbà kúkúrú. Ìṣàkóso ológo Ọba Solomoni ṣàpẹẹrẹ agbára ìṣàkóso òdodo ti Ọba kan tí ó tóbi lọ́lá ju Solomoni lọ tí yóò ṣàkóso lórí gbogbo ayé. (Matteu 12:42) Ọba náà ni Kristi Jesu, “Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa.”—Ìṣípayá 19:16.
Orin Dafidi 72, tí ó ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ní ìbámu pẹ̀lú Ọba Solomoni, ṣàpèjúwe ìṣàkóso ọlọ́lá-ńlá Jesu Kristi. Ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun ìyanu tí ó sọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́-iwájú ayé lábẹ́ Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba.
Ipò Alálàáfíà Kárí-Ayé: “Ní ọjọ́ rẹ̀ ni àwọn olódodo yóò gbilẹ̀: àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà níwọ̀n bí òṣùpá yóò ti pẹ́ tó. Òun óò sì jọba láti òkun dé òkun, àti láti odò nì dé òpin ayé.”—Orin Dafidi 72:7, 8.
Àníyàn fún Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀: “[Òun] yóò [gba] aláìní nígbà tí ó bá ń ké: tálákà pẹ̀lú, àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun óò dá tálákà àti aláìní sí, yóò sì [gba] ọkàn àwọn aláìní là. Òun óò [ra] ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ìwà-agbára: iyebíye sì ni ẹ̀jẹ̀ wọn ní ojú rẹ̀.”—Orin Dafidi 72:12-14.
Ọ̀pọ̀ Yanturu Oúnjẹ: “Ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀.”—Orin Dafidi 72:16.
Ògo Jehofa Yóò Kún Ayé: “Olùbùkún ni Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun Israeli, ẹnì kanṣoṣo tí ń ṣe ohun ìyanu. Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó ní ògo títí láé: kí gbogbo ayé kí ó sì kún fún ògo rẹ̀.”—Orin Dafidi 72:18, 19.
Nítorí náà nítòótọ́ ìgbà tí ó sàn jù ń bẹ níwájú.