A Ha Dá Iyèméjì Nípa Jesu Láre Bí?
JESU ti Nasareti ha ṣe iṣẹ́-ìyanu níti tòótọ́ bí? A ha jí i dìde kúrò nínú òkú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti pòkìkí bí? Ó ha tilẹ̀ gbé ayé rárá bí? Ní ọjọ́ tiwa lóde-òní, ó dàbí pé ọ̀pọ̀ ni kò lè dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú. Èéṣe? Nítorí pé wọ́n ń ṣiyèméjì nípa Jesu, iyèméjì sì jẹ́ ìrònú àìdánilójú, láì mọ̀ bóyá ohun kan jẹ́ òtítọ́ tàbí pé ó ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n a ha dá ìrònú àìdánilójú nípa Jesu láre bí? Ẹ jẹ́ kí a wò ó ná.
Bí A Ṣe Fúnrúgbìn Iyèméjì Nípa Jesu
Àwọn ará Germany ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ní ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún àti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún ṣàpèjúwe Jesu gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀dá ìtàn-àròsọ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì ìgbàanì.” Títakò tí wọ́n tako jíjẹ́ tí Jesu jẹ́ ẹni ìtàn yọrí sí àríyànjiyàn láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú nígbà náà lọ́hùn-ún tí ó sì nípa lónìí síbẹ̀síbẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ìwádìí kan láìpẹ́ yìí ní Germany ṣípayá pé ìdá 3 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí a fọ̀rọ̀wálẹ́nuwò gbàgbọ́ pé Jesu “kò fìgbà kan gbé ayé rí” àti pé “àwọn aposteli ni wọ́n hùmọ̀ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn èso iyèméjì nípa Jesu tí a gbìn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí rí ilẹ̀ ọlọ́ràá ní ọkàn-àyà àwọn ènìyàn nísinsìnyí pàápàá.
Ní ṣókí, èéṣe tí a kò fi dá ìparí èrò náà pé a “hùmọ̀” Jesu láre? Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bibeli, Wolfgang Trilling, sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé: “Àríyànjiyàn náà níti bóyá Jesu ti gbé ayé rí, ní èdè mìíràn bóyá ó jẹ́ ẹni sàràkí nínú ìtàn tàbí ìtàn-àròsọ, ni a ti yanjú. Ìbéèrè náà ni a yanjú ní ọ̀nà ti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, ó kéré tán ní ọ̀nà tí ó fi jẹ́ pé àwọn onírònú ènìyàn kì yóò rí ìṣòro náà gẹ́gẹ́ bí àríyànjiyàn àwọn ọ̀mọ̀wé.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn kan ṣì ń ṣiyèméjì nípa bóyá Jesu tilẹ̀ gbé ayé rí. Lójú ìwòye èyí, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò bí ẹnì kan ṣe lè fìdí ẹ̀rí ìjótìítọ́ ìtàn Jesu múlẹ̀ àti láti mú àwọn iyèméjì mìíràn nípa rẹ̀ kúrò.
Àwọn Ẹ̀rí Tí Ó Lé Iyèméjì Dànù
Ìyà-ikú lọ́nà onítìjú tí a fi jẹ Jesu gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn tí a yọ ṣùtì sí fúnni ní “ẹ̀rí tí ó dájú jùlọ lòdì sí àwọn tí wọ́n tako ìjótìítọ́ ìtàn Jesu,” ni Trilling sọ. Èéṣe? Nítorí ìfìyà-ikú-jẹni náà “ṣe ìfàsẹ́yìn, ó tilẹ̀ ṣèdíwọ́, fún ìtàn-káàkiri ìgbàgbọ́ titun náà láàárín àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù.” (Fiwé 1 Korinti 1:23.) Bí ìfìyà-ikú-jẹni ti Jesu tí ó jẹ́ Messia náà bá jẹ́ àfojúdi fún àwọn Júù àti àwọn Kèfèrí, kò dájú pé èyí lè jẹ́ ohun tí àwọn aposteli hùmọ̀ rẹ̀! Síwájú síi, ikú Jesu ni a jẹ́rìí sí gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn kì í ṣe kìkì nípasẹ̀ àwọn Ìròyìnrere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nìkan ṣùgbọ́n àti láti ọwọ́ òǹkọ̀wé ará Romu náà Tacitus àti Talmud ti àwọn Júù.a
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn nígbà ayé Jesu pẹ̀lú ni a tún wò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tí ó wá láti inú fún ìṣeégbàgbọ àwọn ìwé Ìròyìnrere, ìdí rẹ̀ nìyẹn tí wọ́n fi sọ ohun tí wọ́n sọ fún wa nípa rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu yóò ha ti hùmọ̀ wíwá rẹ̀ láti Nasareti, ibì kan tí ó dàbí pé kò ṣe pàtàkì bí? Àbí ó ha ṣeé ṣe pé wọn yóò ti hùmọ̀ ìfinihàn rẹ̀ láti ọwọ́ Judasi, alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn, tí wọ́n fọkàntán bí? Ó ha dàbí ohun tí ó ṣeé ṣe láti ronú pé wọn yóò hùmọ̀ ìtàn kan nípa bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó ṣẹ́kù ṣe pa Jesu tì ní ọ̀nà ojo bẹ́ẹ̀ bí? Dájúdájú kò bọ́gbọ́n mu pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yóò gbé àwọn ìsọfúnni tí ó burú kalẹ̀ kí wọ́n sì pòkìkí wọn káàkiri! Ní àfikún síi, ọgbọ́n ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Jesu lò ni a mọ̀ bí èyí tí ó ṣàrà-ọ̀tọ̀. Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn Júù ní ọ̀rúndún kìn-ínní kò ní ohunkóhun tí a lè fiwé àwọn àkàwé rẹ̀. Ẹnì kan tí a kò mọ̀ wo ni ìbá ti “hùmọ̀” irú àgbà-iṣẹ́ bí Ìwàásù lórí Òkè? Gbogbo àríyànjiyàn wọ̀nyí papọ̀ ṣètìlẹyìn fún ìjóòótọ́ àwọn ìròyìn nípa ìgbésí-ayé Jesu tí a kọ sínú Ìròyìnrere.
Ẹ̀rí láti ìta tún wà fún jíjẹ́ tí Jesu jẹ́ ẹni ìtàn. Àwọn Ìròyìnrere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣàpèjúwe ipò àtilẹ̀wá ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí ó gbé ní ìgbà pàtó kan, tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ péye. Àwọn ibi, gẹ́gẹ́ bíi Betlehemu àti Galili; àwọn ènìyàn àti àwùjọ tí ó lókìkí, irú bí Pontiu Pilatu àti àwọn Farisi; àti pẹ̀lú àwọn àṣà-ìbílẹ̀ àwọn Júù àti àwọn ohun mìíràn tí a fi dá wọn mọ̀ yàtọ̀ kò wulẹ̀ jẹ́ ohun tí a hùmọ̀ wọn. Wọ́n parapọ̀ jẹ́ apákan ọ̀nà ìgbésí-ayé ní ọ̀rúndún kìn-ínní, àwọn orísun ìròyìn mìíràn tí kì í ṣe ti Bibeli àti ìwádìí àwọn awalẹ̀pìtàn sì ti jẹ́rìí sí wọn.
Nípa báyìí, àwọn ẹ̀rí tí ó dájú wà, nínú àti níta pé Jesu jẹ́ ẹ̀dá ìtàn kan.
Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì ń ṣiyèméjì nípa àwọn iṣẹ́-ìyanu tí ó ní Jesu nínú. Ní tòótọ́, ní ìbámu pẹ̀lú ìwádìí tí a tọ́ka sí lókè yìí, kìkì àwọn kéréje lára àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní Germany ni ó gbàgbọ́ pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn iṣẹ́-ìyanu àti àjíǹde Jesu “ṣẹlẹ̀ nítòótọ́.” A ha dá iyèméjì nípa àwọn iṣẹ́-ìyanu àti àjíǹde Jesu láre bí?
Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ń Ṣiyèméjì Nípa Àwọn Iṣẹ́-Ìyanu Jesu
Matteu 9:18-36 ròyìn pé lọ́nà ìyanu, Jesu wo àwọn aláìsàn sàn, ó jí òkú dìde, ó sì lé ẹ̀mí-èṣù jáde. Ọ̀jọ̀gbọ́n Hugo Staudinger, òpìtàn kan, sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé: “Ó jẹ́ ohun tí ó ṣòro gidigidi láti gbàgbọ́, àti ohun tí kò ṣe é ṣe lójú ìwòye ìtàn, pé àwọn ìròyìn tí ó pabambarì wọ̀nyí jẹ́ àbájáde èrò-orí ṣíṣe kedere lásán.” Èéṣe? Nítorí pé ó dàbí pé èyí tí ó ṣáájú jùlọ nínú àwọn Ìròyìnrere ni a kọ nígbà tí èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn olùfojúrí àwọn iṣẹ́-ìyanu wọ̀nyí ṣì wàláàyè! Ẹ̀rí síwájú síi ni a rí níti pé, gẹ́gẹ́ bí Staudinger ti tẹ̀síwájú láti sọ, àwọn Júù alátakò “kò fìgbà kan rí sẹ́ pé Jesu ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó pabambarì.” Bí a bá pa gbogbo àwọn ẹ̀rí tí ó kù tì tí a sì gbé ìdájọ́ wa karí kìkì àwọn ẹ̀rí tí ó wá láti ìta, dájúdájú a rí i pé ó yẹ kí a gba àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu gbọ́.—2 Timoteu 3:16.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ará Germany ni wọ́n ní ìdánilójú pé Jesu mú àwọn aláìsàn lára dá,” ọ̀pọ̀ ṣiyèméjì nípa agbára tí ó wà lẹ́yìn àwọn ìwòsàn wọ̀nyí. Fún àpẹẹrẹ, ará Germany ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tí a mọ̀-bí-ẹní-mowó sọ ní gbangba pé ìwòsàn tí Jesu ṣe jẹ́ ìyọrísí agbára ìmúnimúyè tí ó ní agbára ìdarí lórí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń jìyà wàhálà ọpọlọ. Àlàyé tí ó yèkooro ha ni èyí bí?
Rò ó wò ná. Marku 3:3-5 ròyìn pé Jesu wo ọwọ́ ọkùnrin kan tí ó rọ sàn. Ṣùgbọ́n ọwọ́ rírọ ha jẹ́ ìyọrísí wàhálà ọpọlọ bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ kọ́. Lójú ìwòye èyí, ìwòsàn yìí ni a kò lè kà sí ti agbára ìmúnimúyè. Nítorí náà kí ló mú kí ó ṣeé ṣe fún Jesu láti ṣe àwọn iṣẹ́-ìyanu? Ọ̀jọ̀gbọ́n Staudinger gbà pé: “Bí ó bá jẹ́ pé kò sí àwọn òfin kankan tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ pátápátá, bí ẹnì kan kò bá sì sẹ́ Ọlọrun látòkèdélẹ̀, nígbà náà lọ́nà tí ó fìdímúlẹ̀ ẹnì kan kò lè fagilé ìṣeéṣe náà pé Ọlọrun, ẹni tí agbára rẹ̀ ju ti ènìyàn lọ, lè ṣe àwọn ohun tí kò wọ́pọ̀.” Bẹ́ẹ̀ni, nítòótọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ “agbára Ọlọrun,” níti gidi Jesu wo àwọn ènìyàn tí ara wọn kò yá sàn. Nípa báyìí, kò sí ìdí kankan láti ṣiyèméjì nípa ìjójúlówó àwọn iṣẹ́-ìyanu rẹ̀.—Luku 9:43; Matteu 12:28.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The American Peoples Encyclopedia ṣe sọ ọ́, bí èyí tí ó kàmàmà jùlọ nínú gbogbo iṣẹ́-ìyanu—àjíǹde Jesu—bá ṣẹlẹ̀, gbogbo àwọn iṣẹ́-ìyanu yòókù tí a kọ sílẹ̀ nínú Ìròyìnrere “ṣeé ṣe.” A ha jí Jesu dìde kúrò nínú okú nítòótọ́ bí?
A Ha Dá Iyèméjì Nípa Àjíǹde Jesu Láre Bí?
Ṣàgbéyẹ̀wò lákọ̀ọ́kọ́ abala ẹ̀rí lílágbára tí ó bá àyíká ipò mu tí ó ṣètìlẹ́yìn fún ìjóòótọ́ àjíǹde Jesu—ibojì rẹ̀ tí ó ṣófo. Òtítọ́ náà pé sàréè Jesu ni a rí pé ó ṣófo ni àwọn ojúgbà rẹ̀, àní àwọn alátakò rẹ̀ pàápàá kò jiyàn rẹ̀. (Matteu 28:11-15) Ẹ̀tàn ni à bá ti túdìí rẹ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn! Iṣẹ́ ìtọ́kasí tí a mẹ́nu kàn lókè yìí parí lọ́nà tí ó tọ́ pé: “Kò sí àlàyé kankan tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ tí a tí ì dábàá rẹ̀ rí fún ibojì tí ó ṣófo náà yàtọ̀ sí àkọsílẹ̀ Bibeli pé, ‘Kò sí níhìn-ín; nitori a ti gbé e dìde’ (Matt. 28:6).”
Àwọn kan kọ̀, ní sísọ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu nìkan ni wọ́n polongo níbi gbogbo pé òun ni Messia tí a jí dìde náà. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ìṣeégbàgbọ́ ìhìn-iṣẹ́ wọn ha fìdímúlẹ̀ gbọn-in-gbọn-in nínú àwọn òkodoro òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ti ìtàn, ní pàtàkì ikú àti àjíǹde Jesu? Dájúdájú. Aposteli Paulu mọ̀ nípa ìsopọ̀ yìí nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Bí a kò bá tí ì gbé Kristi dìde, dájúdájú asán ni ìwàásù wa, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a rí wa pẹlu ní ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọrun, nitori a ti jẹ́rìí lòdì sí Ọlọrun pé ó gbé Kristi dìde.”—1 Korinti 15:14, 15; fiwé Johannu 19:35; 21:24; Heberu 2:3.
Ní ọ̀rúndún kìn-ínní, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wà tí a mọ̀ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ dáradára tí wọ́n sì lè jẹ́rìí sí ìfarahàn Jesu lẹ́yìn ikú rẹ̀. Lára wọn ni àwọn aposteli 12 àti Paulu, àti àwọn olùfojúrí tí wọ́n ju 500 lọ.b (1 Korinti 15:6) Tún rántí ìdí tí Mattia fi tóótun láti gbapò lẹ́yìn aposteli Judasi. Ìṣe 1:21-23 ròyìn pé Mattia lè jẹ́rìí sí àjíǹde Jesu àti sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣáájú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. Bí ìgbésí-ayé àti àjíǹde Jesu bá jẹ́ ìtàn-àròsọ dípò kí ó jẹ́ òkodoro òtítọ́, irú ohun àbéèrèfún bẹ́ẹ̀ fún ìyànsípò dájú pé kì bá má ti wúlò rárá.
Nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn olùfojúrí lè jẹ́rìí sí ìgbésí-ayé, iṣẹ́-ìyanu, ikú, àti àjíǹde Jesu, ìsìn Kristian tàn kálẹ̀ lọ́nà tí ó yára kánkán gan-an jákèjádò Ilẹ̀-Ọba Romu, láìka àwọn ìdínà tí a mẹ́nu kàn lókè yìí sí. Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣetán láti farada ìnira, inúnibíni, àti ikú pàápàá kí wọ́n baà lè kéde àjíǹde àti òtítọ́ tí ó fìdímúlẹ̀ tí ó ti inú rẹ̀ jáde wá níbi gbogbo. Òtítọ́ wo ni? Pé àjíǹde rẹ̀ ṣeé ṣe kìkì nípa agbára Ọlọrun. Èésìtiṣe tí Jehofa Ọlọrun fi jí Jesu dìde kúrò nínú òkú? Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn fi irú ẹ̀dá inú ìtàn tí Jesu jẹ́ hàn.
Ní ọjọ́ Pentekosti, aposteli Peteru kéde ní fàlàlà sí ìyàlẹ́nu àwọn Júù ní Jerusalemu pé: “Jesu yii ni Ọlọrun jí dìde, òkodoro òtítọ́ tí gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́rìí fún. Nitori naa nitori pé a gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun tí ó sì gba ẹ̀mí mímọ́ naa tí a ṣèlérí lati ọ̀dọ̀ Baba, oun tú èyíyìí tí ẹ rí tí ẹ sì gbọ́ jáde. Níti gàsíkíá Dafidi kò gòkè lọ sí awọn ọ̀run, ṣugbọn oun fúnra rẹ̀ wí pé, ‘Jehofa wí fún Oluwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí emi yoo fi gbé awọn ọ̀tá rẹ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpótí-ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.”’ Nitori naa kí gbogbo ilé Israeli mọ̀ dájúdájú láìsí tabi ṣugbọn pé Ọlọrun fi í ṣe Oluwa ati Kristi, Jesu yii tí ẹ̀yin kànmọ́gi.” (Ìṣe 2:32-36) Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa Ọlọrun fi Jesu ti Nasareti ṣe “Oluwa ati Kristi.” A ha dá iyèméjì nípa ipa-iṣẹ́ rẹ̀ nínú apákan ète Ọlọrun láre bí?
Èéṣe Tí A Fi Ń Ṣiyèméjì Nípa Ipa-Iṣẹ́ Jesu ti Ìsinsìnyí?
Báwo ni a ṣe lè tú gbogbo iyèméjì nípa irú ẹni tí Jesu jẹ́ àti ipa-iṣẹ́ rẹ̀ ká? Níti òkodoro òtítọ́ náà pé dájúdájú òun jẹ́ wòlíì tòótọ́. Ó sàsọtẹ́lẹ̀ ogun, ìyàn, ìmìtìtì-ilẹ̀, ìwà-ọ̀daràn, àti àìsí ìfẹ́ ti a ń rí lónìí. Ní àfikún sí i, ó sọtẹ́lẹ̀ pé: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.” (Matteu 24:3-14) Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí fi ẹ̀rí hàn pé Jesu ni Kristi tí a jí dìde náà, tí ń ṣàkóso lọ́nà tí a kò lè fojúrí ‘láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀,’ àti pé láìpẹ́ yóò sì mú ayé titun Ọlọrun wá.—Orin Dafidi 110:1, 2; Danieli 2:44; Ìṣípayá 21:1-5.
Nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ, aráyé nílò Olùgbàlà kan ní kíákíá tí a mú gbaradì pẹ̀lú ọgbọ́n tí ó ju ti ènìyàn lọ. Èéṣe tí a fi níláti ṣiyèméjì pé Jesu ni ẹni náà tí a yàn láti gba aráyé là? Johannu, ẹni tí ó jẹ́ olùfojúrí àwọn iṣẹ́-ìyanu amọ́kànyọ̀ náà àti àjíǹde Jesu, kéde pé: “Ní àfikún, awa fúnra wa ti rí a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọkùnrin rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà ayé.” (1 Johannu 4:14; fiwé Johannu 4:42.) Gan-an bí a kò ti ní ìdí tí ó bọ́gbọ́n mu láti ṣiyèméjì nípa wíwà, iṣẹ́-ìyanu, ikú, àti àjíǹde Jesu, a kò ní ìdí kankan láti ṣiyèméjì pé Jehofa Ọlọrun ti gbé e gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀. Láìsí àníàní, Jesu ti Nasareti ni Ọba Ìjọba Ọlọrun àti “Olùgbàlà ayé.”—Matteu 6:10.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ìtọ́kasí alátakò gbígbóná janjan lòdì sí Jesu nínú Talmud ni kìkì àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ìtọ́kasí Jesu láti ọwọ́ Tacitus, Suetonius, Pliny the Younger, àti ó kéré tán ọ̀kan láti ọwọ́ Flavius Josephus, ni a tẹ́wọ́gbà ní gbogbogbòò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí nípa wíwà Jesu bí ẹ̀dá inú ìtàn.
b Nínú ọ̀ràn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, Jesu tí a jí dìde náà jẹ ẹja pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, èyí tí ó jẹ́rìí sí i pé ìfarahàn rẹ̀ kì í wulẹ̀ ṣe ìran lásán, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan tí sọ lónìí.—Luku 24:36-43.