Owú Fẹ́rẹ̀ẹ́ Ba Ìgbésí Ayé Mi Jẹ́
NÍ TI gidi owú bẹ̀rẹ̀ sí nípa lórí mi lọ́nà tí ó burú jáì nígbà tí mo fẹ́ ọkọ mi kejì, Mark.a Àwa méjèèjì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti bójú tó àwọn ọmọ mélòó kan tí a ti bí tẹ́lẹ̀, a sì ní láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn alábàáṣègbéyàwó wa tẹ́lẹ̀. Ipò náà nígbà mìíràn kì í ṣeé fara dà. Nígbàkigbà tí àtakò ìdílé bá wáyé, ó ń dà bí pé Mark kì í kín mi lẹ́yìn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀. Dípò ṣíṣàkóso owú mi, mo yọ̀ǹda fún un láti darí ìgbésí ayé mi. Mo máa ń nímọ̀lára ìwuléwu nígbàkigbà tí aya Mark tẹ́lẹ̀ bá wà nítòsí.
Èmi yóò máa ṣọ́ Mark nígbà gbogbo, àní tí n óò máa ṣọ́ ẹyinjú rẹ̀ láti rí ibi tí ó bá ń wò. Mo máa ń túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó ń wò sí ohun mìíràn tí kò ní lọ́kàn. Nígbà mìíràn, èmi yóò fẹ̀sùn kàn án ní gbangba pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan èyí kó wàhálà bá a débi pé ó dìde, ó sì fi àpéjọ Kristian sílẹ̀. Mo nímọ̀lára pé mo jẹ̀bi níwájú Jehofa. Mo sọ ìgbésí ayé mi di aláìláyọ̀ nítorí pé níkẹyìn ó nípa lórí àwọn ọmọ. Mo kórìíra ara mi fún ohun tí mo ń ṣe, ṣùgbọ́n láìka bí mo ti gbìyànjú tó sí, èmi kò ṣáà lè ṣàkóso owú mi.
Dípò ríràn mí lọ́wọ́, Mark bẹ̀rẹ̀ sí foró yáró. Nígbà tí mo bá fẹ̀sùn kàn án, yóò jágbe mọ́ mi, “Òjòwú, owú ní ń yọ ọ́ lẹ́nu.” Ó tilẹ̀ dà bíi pé ó máa ń mọ̀ọ́mọ̀ mú mi jowú. Bóyá ó rò pé èyí yóò wo owú mi sàn, ṣùgbọ́n kàkà kí ewé àgbọn dẹ̀, pípele ló ń pele sí i. Ó bẹ̀rẹ̀ sí wo àwọn obìnrin mìíràn, ní sísọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe rẹwà tó. Èyí mú kí ń túbọ̀ nímọ̀lára jíjẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ àti ẹni tí a kò fẹ́. Ó dé orí ibi tí èrò ìmọ̀lára mìíràn—ìkórìíra—ti jẹ yọ. Ní ibi yìí, ọkàn mí dà rú débi pé n kò ṣáà fẹ́ òun àti ìdílé rẹ̀ nínú ìgbésí-ayé mi mọ́.
Nígbà tí Bibeli sọ pé: “[Owú, NW] ni ìbàjẹ́ egungun,” bí ó ti ri gan-an nìyẹn. (Owe 14:30) Wàyí o, ó bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí ìlera mi. Ọgbẹ́ inú tí ó gba àkókò gígùn kí ó tó san bẹ̀rẹ̀ sí yọ mí lẹ́nu. Mo ń bá a lọ láti mú kí ìgbésí ayé mi jẹ́ aláìláyọ̀ nípa fífura sí ohun gbogbo tí Mark bá ṣe. Èmi yóò yẹ àwọn àpò rẹ̀ wò, bí mo bá sì rí nọ́ḿbà tẹlifóònù, èmi yóò fóònù láti mọ ẹni tí yóò dáhùn. Nínú lọ́hùn-ún, ojú ara mi tì mí, èmi yóò sọkún nítorí ìtìjú náà níwájú Jehofa. Síbẹ̀ n kò lè dá ara mi dúró. Èmi ni ọ̀tá ara mi tí ó burú jù lọ.
Ipò tẹ̀mí mi jìyà dé ibi tí n kò ti lè gbàdúrà mọ́. Mo nífẹ̀ẹ́ Jehofa mo sì nífẹ̀ẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́. Mo mọ gbogbo ìwé mímọ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọkọ àti aya, ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe fún mi láti fi wọ́n sílò. Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi, n kò fẹ́ láti wà láàyè mọ́, láìka òkodoro òtítọ́ náà sí pé mo ní àwọn ọmọ àtàtà.
Àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristian jẹ́ ìṣírí ńláǹlà wọ́n sì gbìyànjú láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ràn mí lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá mú ọ̀ràn owú mi wá sí ojútáyé, èmi yóò sẹ́ ẹ jálẹ̀jálẹ̀ nítorí ìtìjú, ní ṣíṣàìfẹ́ láti gbà pé mo ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀.
Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìlera mi jó rẹ̀yìn débi pé mo ní láti lọ sí ilé ìwòsàn fún iṣẹ́ abẹ. Nígbà tí mo wà níbẹ̀ mo rí i pé ìgbésí ayé kò lè máa bá a lọ bí ó ti ṣe wà rí. Èmi àti Mark pinnu láti pínyà fún oṣù mẹ́ta láti yẹ ipò wa wò láìjẹ́ pé a mú èrò ìmọ̀lára wọ̀ ọ́. Láàárín àkókò yìí, ohun àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! (Gẹ̀ẹ́sì) tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ìrànwọ́ fún Àwọn Àgbàlagbà Tí Wọ́n Jẹ́ Ọmọ Onímukúmu.”b
Ṣé ó rí i, onímukúmu ni màmá mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò hùwà ìkà sí mi nípa ti ara, àwọn òbí mi kò fi ìgbà kankan rí fi ìfẹ́ni nípa ti ara hàn sí ẹnì kìíní-kejì wọn tàbí sí mi. N kò lè rántí ìgbà tí màmá mi fọwọ́ gbá mi mọ́ra rí tàbí kí ó sọ fún mi pé òun nífẹ̀ẹ́ mi. Nítorí náà, ní tòótọ́, mo dàgbà di aláìmọ bí a ti í fìfẹ́ hàn, àti pẹ̀lú ìjẹ́pàtàkì kan náà, bí a ṣe lè jẹ́ ẹni tí a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Màmá mi sábà máa ń sọ fún mi nípa ìṣekúṣe bàbá mi àti pé òun kò lè gbẹ́kẹ̀ lé e. Nítorí náà, mo rò pé mo dàgbà di ẹni tí kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọkùnrin ní gbogbo gbòò. Nítorí ọ̀nà tí a gbà tọ́ mi dàgbà, mo máa ń nímọ̀lára pé mo rẹlẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn, ní pàtàkì, sí àwọn obìnrin mìíràn. Kíka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Jí! yẹn ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ìjẹ́pàtàkì àwọn nǹkan wọ̀nyí. Fún ìgbà àkọ́kọ́, mo lóye gbòǹgbò àwọn ìṣòro mi ní ti owú.
Mo fi ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Jí! náà han ọkọ mi, Mark, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti lóye mi sí i. Láìpẹ́, ó ṣeé ṣe fún èmi àti òun láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bibeli fún àwọn lọ́kọláya tí wọ́n ń gbèrò láti pínyà. A padà bá ara wa rẹ́. (1 Korinti 7:10, 11) Wàyí o, ìgbéyàwó wa dára ju bí ó ti rí tẹ́lẹ̀ lọ. A ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan papọ̀, ní pàtàkì, nígbà tí ó bá kan àwọn ìgbòkègbodò Kristian. Mark fi ìfọ̀rànrora-ẹni-wò púpọ̀ sí i hàn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni ó ń sọ fún mi bí òun ti nífẹ̀ẹ́ mi tó, mo sì gbà á gbọ́ nísinsìnyí ní ti tòótọ́.
Níbikíbi tí mo bá mọ̀ pé a óò ti bá aya Mark tẹ́lẹ̀ pàdé, n óò gbàdúrà sí Jehofa fún okun, ní bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ láti ràn mí lọ́wọ́ láti hùwà ní ọ̀nà ti Kristian tí ó dàgbà dénú. Ó sì ṣiṣẹ́. Àní ìmọ̀lára ẹ̀tanú mi sí i ń dín kù. N kò ronú lórí èrò òdì mọ́ tàbí kí n jẹ́ kí ìronúwòye mi ré kọjá ohun tí mo lè ṣàkóso.
Mo ṣì ní ìmọ̀lára owú tí kò dára díẹ̀. Ìwàláàyè pípé nínú ayé titun Ọlọrun nìkan ni ó lè gbà á lọ́wọ́ mi pátápátá. Nísinsìnyí ná, mo ti kọ́ láti ṣàkóso owú, dípò yíyọ̀ǹda fún un láti ṣàkóso mi. Bẹ́ẹ̀ ni, owú fẹ́rẹ̀ẹ́ ba ìgbésí ayé mi jẹ́, ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Jehofa àti ètò-àjọ rẹ̀, mo jẹ́ ẹni tí ó túbọ̀ láyọ̀ sí i nísinsìnyí, ìlera mi sì ti padà sí bí ó ti yẹ. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo ní ipò ìbátan tí ó lágbára pẹ̀lú Ọlọrun mi, Jehofa.—A fi ṣèrànlọ́wọ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ padà.
b Wo Jí! May 22, 1992 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú-ìwé 8 sí 12.