Onílara Ẹ̀dá
ÈDÈ Heberu ní ẹyọ ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan fún “owú.” Nígbà tí a bá ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀, a lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ Heberu náà sí “ìlara” tàbí “ìbánidíje.” (Genesisi 26:14; Oniwasu 4:4) Bí ó ti wù kí ó rí, èdè Griki ní ju ẹyọ ọ̀rọ̀ kan lọ fún “owú.” Ọ̀rọ̀ náà zeʹlos, bíi ti èdè Heberu tí ó bá a mu, lè tọ́ka sí owú òdodo àti èyí tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Ọ̀rọ̀ Griki mìíràn, phthoʹnos, ní ìtumọ̀ òdì pátápátá. Nínú Bibeli New World Translation, ìgbà gbogbo ní a sábà ń túmọ̀ rẹ̀ sí “ìlara.”
Báwo ni a ṣe lo ọ̀rọ̀ náà phthoʹnos, nínú èdè Griki ìgbàanì? Ìwé atúmọ̀-èdè The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Ní ìyàtọ̀ sí oníwọra ẹ̀dá, ẹ̀dá tí phthonos bá ń yọ lẹ́nu kò fi dandan fẹ́ àwọn dúkìá tí ó bínú pé ẹlòmíràn ní; kò wulẹ̀ fẹ́ kí ẹni náà ní wọn ni. Ó yàtọ̀ sí ẹ̀dá abánidíje ní ti pé, ní ìyàtọ̀ sí ẹ̀dá abánidíje, ète rẹ̀ kì í ṣe láti borí, ṣùgbọ́n láti ṣèdíwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn láti má ṣe borí.”
Onílara ẹ̀dá kì í sábà mọ̀ pé ìṣarasíhùwà òun gan-an ni olórí okùnfà ìṣòro òun. Ìwé atúmọ̀-èdè kan náà ṣàlàyé pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó jẹ́ ànímọ́ phthonos ni ti àìmọ bí òun ṣe rí. Bí a bá pe phthoneros ẹ̀dá láti fi ẹ̀rí ìlọ́gbọ́nnínú ìwà rẹ̀ hàn, yóò fi ìgbà gbogbo sọ fún ara rẹ̀ àti àwọn ẹlòmíràn pé àwọn wọnnì tí òun ń gbéjà kò yẹ fún un àti pé àìbójúmu ipò náà ni ó sún un láti ṣe lámèyítọ́. Bí a bá béèrè ìdí tí ó fi lè sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rẹ́ kan ní irú ọ̀nà tí ó gbà sọ ọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, yóò sọ pé ìṣe lámèyítọ́ òun jẹ́ fún ire ọ̀rẹ́ náà.”
Àwọn òǹkọ̀wé Ìhìnrere Matteu àti Marku lo ọ̀rọ̀ Griki náà phthoʹnos láti ṣàpèjúwe ète ìsúnniṣe àwọn wọnnì tí wọ́n ṣokùnfà pípa Jesu. (Matteu 27:18; Marku 15:10) Bẹ́ẹ̀ ni, ìlara ni ó sún wọn. Èrò ìmọ̀lára tí ń pani lára kan náà ti sọ àwọn apẹ̀yìndà di òǹrorò olùkórìíra àwọn arákùnrin wọn tẹ́lẹ̀ rí. (1 Timoteu 6:3-5) Abájọ tí a kò fi gba àwọn onílara ẹ̀dá láyè láti wọnú Ìjọba Ọlọrun! Jehofa Ọlọrun ti pàṣẹ pé gbogbo àwọn tí ń bá a lọ láti “kún fún ìlara . . . yẹ fún ikú.”—Romu 1:29, 32; Galatia 5:21.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Máṣe jẹ́ kí ìlara ba ìgbésí ayé rẹ jẹ́