ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w20 February ojú ìwé 14-19
  • O Lè Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Tó O Bá Sapá Láti Borí Ìlara

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Tó O Bá Sapá Láti Borí Ìlara
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ LÓ MÁA Ń FA ÌLARA?
  • JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀ KÓ O SÌ NÍ ÌTẸ́LỌ́RÙN
  • “MÁA LÉPA ÀWỌN OHUN TÓ Ń MÚ KÍ ÀLÀÁFÍÀ WÀ”
  • Ìlara Lè Mú Kéèyàn Ní Èròkerò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Bí o Ṣe Lè Láyọ̀
    Jí!—2015
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa Fi Ara Ẹ Wé Àwọn Ẹlòmíì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Onílara Ẹ̀dá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
w20 February ojú ìwé 14-19

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 8

O Lè Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Tó O Bá Sapá Láti Borí Ìlara

“Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà àti àwọn ohun tó ń gbé ẹnì kejì wa ró.”​—RÓÒMÙ 14:19.

ORIN 113 Àlàáfíà Tó Wà Láàárín Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

1. Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé Jékọ́bù nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe ìlara rẹ̀?

JÉKỌ́BÙ nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àmọ́ Jósẹ́fù ló nífẹ̀ẹ́ jù. Báwo ló ṣe rí lára àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù pé àbúrò wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ni bàbá wọn fẹ́ràn jù? Kò dùn mọ́ wọn nínú, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara rẹ̀, ìyẹn sì mú kí wọ́n kórìíra ẹ̀. Ó ṣe kedere pé Jósẹ́fù ò ṣe ohunkóhun tó mú kí wọ́n kórìíra ẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n tà á sóko ẹrú wọ́n sì pa irọ́ fún bàbá wọn pé ẹranko ti pa ààyò ọmọ rẹ̀ jẹ. Ìlara tí wọ́n ṣe yìí mú kí àlàáfíà tó wà ní ìdílé wọn bà jẹ́, wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá bàbá wọn.​—Jẹ́n. 37:3, 4, 27-34.

2. Bó ṣe wà nínú Gálátíà 5:19-21, kí nìdí tí ìlara fi burú?

2 Nínú Bíbélì, ìlarab wà lára “àwọn iṣẹ́ ti ara” tó léwu tó sì lè mú kéèyàn má jogún Ìjọba Ọlọ́run. (Ka Gálátíà 5:19-21.) Ìlara kì í bímọọre, ohun tó sábà máa ń yọrí sí ni ìkórìíra, wàhálà àti inú fùfù.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù yìí jẹ́ ká rí i pé ìlara lè ba àjọṣe àti àlàáfíà tó wà nínú ìdílé jẹ́. Òótọ́ ni pé kò sẹ́nì kankan nínú wa tó máa fẹ́ ṣe bíi tàwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù láé, àmọ́ ká rántí pé aláìpé ni gbogbo wa, ọkàn wa sì lè tàn wá jẹ. (Jer. 17:9) Ìdí nìyẹn tó fi máa ń ṣe wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi pé ká ṣe ìlara àwọn míì. Ní báyìí ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan nínú Bíbélì táá jẹ́ ká rí ìdí táwa èèyàn fi máa ń ṣe ìlara. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò àwọn ohun tá a lè ṣe ká lè borí ìlara ká sì jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà.

KÍ LÓ MÁA Ń FA ÌLARA?

4. Kí nìdí táwọn Filísínì fi ṣe ìlara Ísákì?

4 Tẹ́nì kan bá ní ọrọ̀. Ísákì ní ọrọ̀ gan-an, ìyẹn sì mú kí àwọn Filísínì máa ṣe ìlara rẹ̀. (Jẹ́n. 26:12-14) Kódà, wọ́n dí àwọn kànga tó ti máa ń fa omi fún àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀. (Jẹ́n. 26:15, 16, 27) Bíi tàwọn Filísínì, àwọn kan máa ń ṣe ìlara àwọn míì nítorí pé wọ́n ní nǹkan jù wọ́n lọ. Yàtọ̀ sí pé wọ́n fẹ́ ní ohun táwọn míì ní, wọ́n tún fẹ́ kóhun táwọn yẹn ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.

5. Kí nìdí táwọn aṣáájú ìsìn Júù fi ń ṣe ìlara Jésù?

5 Táwọn èèyàn bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan. Àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe ìlara Jésù nítorí pé àwọn èèyàn mọyì Jésù, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Mát. 7:28, 29) Aṣojú Ọlọ́run ni Jésù, òtítọ́ ló sì fi ń kọ́ni. Síbẹ̀, ńṣe ni àwọn aṣáájú ìsìn yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa, tí wọ́n sì ń bà á lórúkọ jẹ́. (Máàkù 15:10; Jòh. 11:47, 48; 12:12, 13, 19) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ yìí? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé ká rí i dájú pé a ò ṣe ìlara àwọn tí àwọn ará nífẹ̀ẹ́ torí àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká fara wé wọn.​—1 Kọ́r. 11:1; 3 Jòh. 11.

6. Kí ni Díótíréfè ṣe tó fi hàn pé onílara ni?

6 Tẹ́nì kan bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Díótíréfè ṣe ìlara àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ. Bíbélì sọ pé ó fẹ́ “fi ara rẹ̀ ṣe olórí” láàárín àwọn ará, ìyẹn sì mú kó máa sọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù àtàwọn míì tó ń múpò iwájú láìdáa. (3 Jòh. 9, 10) Òótọ́ ni pé kò sẹ́nì kankan lára wa tó máa ṣe bíi ti Díótíréfè, síbẹ̀ tá ò bá ṣọ́ra a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara àwọn ará tó ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù wá, pàápàá tá a bá ronú pé àwa náà kúnjú ìwọ̀n tàbí pé a lè ṣe é jù wọ́n lọ.

Fọ́tò: 1. Òdòdó tó rẹwà fìdí múlẹ̀ nínú iyẹ̀pẹ̀ tó dáa. 2. Ewéko búburú ti lọ́ mọ́ òdodo yìí. 3. Inú àwọn arábìnrin mẹ́ta kan ń dùn bí wọ́n ṣe ń bára wọn sọ̀rọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, àmọ́ arábìnrin kan dá dúró, ó sì jọ pé inú ń bí i.

Ọkàn wa dà bí ilẹ̀ ọ̀gbìn, àwọn ànímọ́ rere tá a ní sì dà bí òdòdó tó rẹwà. Àmọ́ ìlara dà bí ewéko búburú. Ìlara kì í jẹ́ kéèyàn fi àwọn ànímọ́ rere bí ìfẹ́, àánú àti ìgbatẹnirò hàn (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. Kí ni ìlara máa ń fà?

7 Ìlara dà bí ewéko búburú. Tó bá ti ta gbòǹgbò lọ́kàn èèyàn, ó máa ń ṣòro fà tu. Lára ohun tó ń fa ìlara ni kéèyàn máa jowú, kó máa gbéra ga, kó sì jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Ńṣe ni ìlara máa ń paná ànímọ́ rere, kì í jẹ́ kéèyàn fi ìfẹ́, àánú àti ìgbatẹnirò hàn. Gbàrà tá a bá ti kíyè sí i pé a fẹ́ máa ṣe ìlara ni ká ti fà á tu kúrò lọ́kàn wa. Kí la lè ṣe láti borí ẹ̀?

JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀ KÓ O SÌ NÍ ÌTẸ́LỌ́RÙN

Fọ́tò: 1. Òdòdó tó rẹwà fìdí múlẹ̀ nínú iyẹ̀pẹ̀ tó dáa. 2. Ẹnì kan ń tu ewéko búburú yìí kúrò lára òdòdó náà. 3. Inú àwọn arábìnrin mẹ́rin kan ń dùn bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Báwo la ṣe lè borí ẹ̀mí ìlara tó dà bí ewéko búburú? Ẹ̀mí mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti fa ìlara tu kúrò lọ́kàn wa, ká sì fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn rọ́pò rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 8-9)

8. Àwọn ànímọ́ wo lá jẹ́ ká borí ìlara?

8 A lè fa ẹ̀mí burúkú yìí tu lọ́kàn wa tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tá a sì ní ìtẹ́lọ́rùn. Àwọn ànímọ́ yìí ò ní jẹ́ kí ìlara ta gbòǹgbò lọ́kàn wa. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kò ní jẹ́ ká máa ro ara wa ju bó ti yẹ lọ. Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kò ní máa ronú pé òun ni gbogbo nǹkan tọ́ sí. (Gál. 6:​3, 4) Ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn máa ń mọyì ohun tó ní, kì í sì í fi ara rẹ̀ wé àwọn míì. (1 Tím. 6:7, 8) Inú ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn máa ń dùn nígbà táwọn míì bá ní àǹfààní tóun ò ní.

9. Bó ṣe wà nínú Gálátíà 5:16 àti Fílípì 2:3, 4, kí ni ẹ̀mí mímọ́ máa mú ká ṣe?

9 A nílò ẹ̀mí mímọ́ ká bàa lè borí ìlara ká sì tún ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. (Ka Gálátíà 5:16; Fílípì 2:3, 4.) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wa àti ohun tó ń mú wa ṣe nǹkan. Lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, a lè fa èròkerò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí tu lọ́kàn wa ká sì fi èyí tó dáa rọ́pò rẹ̀. (Sm. 26:2; 51:10) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Mósè àti Pọ́ọ̀lù ṣe tí wọn ò fi fàyè gba ìlara lọ́kàn wọn.

Mósè, Jóṣúà, àti àwùjọ àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì dúró níbi àgọ́ ìpàdé. Jóṣúà sọ fún Mósè pé kó pa àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ń ṣe bíi wòlíì lẹ́nu mọ́.

Ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì sáré lọ fẹjọ́ sun Mósè àti Jóṣúà pé àwọn ọkùnrin méjì kan ń ṣe bíi wòlíì nínú àgọ́. Jóṣúà wá ní kí Mósè bá wọn wí, àmọ́ Mósè kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó sọ fún Jóṣúà ni pé inú òun dùn bí Jèhófà ṣe fi ẹ̀mí Rẹ̀ sórí àwọn ọkùnrin méjì náà. (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Kí ló ṣẹlẹ̀ tó lè mú kí Mósè ṣe ìlara? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

10 Mósè ni aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run, àmọ́ kò ronú pé ọwọ́ òun nìkan ló yẹ kí àṣẹ wà. Bí àpẹẹrẹ lọ́jọ́ kan, Jèhófà mú lára ẹ̀mí mímọ́ tó wà lára Mósè ó sì fún àwùjọ àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì tó wà níbi àgọ́ ìpàdé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Mósè gbọ́ pé ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn àgbààgbà méjì kan tí wọn ò wá síbi àgọ́ ìpàdé náà, wọ́n sì ń ṣe bíi wòlíì. Kí ni Mósè ṣe nígbà tí Jóṣúà sọ fún un pé kó pa wọ́n lẹ́nu mọ́? Mósè kò ṣe ìlara àwọn méjì náà, kò sì bínú pé Jèhófà fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bá wọn yọ̀. (Nọ́ń. 11:24-29) Kí ni àpẹẹrẹ Mósè yìí kọ́ wa?

Fọ́tò: 1. Níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà, wọ́n pinnu pé kí arákùnrin àgbàlagbà tó ti ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ dá alàgbà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa bójú tó iṣẹ́ náà. 2. Arákùnrin àgbàlagbà tó ti ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ náà tẹ́lẹ̀ jókòó, ó pọkàn pọ̀, ó sì ń wo ọ̀dọ́ alàgbà náà bó ṣe ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. 3. Arákùnrin àgbàlagbà náà bọ ọ̀dọ́ alàgbà náà lọ́wọ́, ó sì gbóríyìn fún un.

Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Mósè? (Wo ìpínrọ̀ 11 àti 12)c

11. Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fara wé Mósè?

11 Ṣé alàgbà ni ẹ́? Ǹjẹ́ wọ́n ti sọ fún ẹ rí pé kó o dá ẹlòmíì nínú ìjọ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa bójú tó iṣẹ́ tó o gbádùn láti máa ṣe? Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ lò ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Tó o bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Mósè, o ò ní ronú pé ẹni tí wọ́n ní kó o dá lẹ́kọ̀ọ́ máa gbaṣẹ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ẹ á dùn, á sì yá ẹ lára láti dá onítọ̀hún lẹ́kọ̀ọ́ débi pé tó bá yá, á lè bójú tó iṣẹ́ náà dáadáa.

12. Báwo làwọn ará wa kan ṣe ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn hàn?

12 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ipò míì táwọn ará kan tó ti dàgbà ń kojú. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn kan lára wọn ti jẹ́ olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Àmọ́ tí wọ́n bá pé ọgọ́rin (80) ọdún, wọ́n máa ń fínnúfíndọ̀ fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Bákan náà, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń mú káwọn alábòójútó àyíká fínnúfíndọ̀ fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá pé àádọ́rin (70) ọdún, wọ́n á sì gba iṣẹ́ ìsìn míì. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ni ètò Ọlọ́run ní kí wọ́n lọ máa sìn ní pápá. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin olóòótọ́ yìí kì í fojú burúkú wo àwọn tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ táwọn ń ṣe tẹ́lẹ̀.

13. Kí ni nǹkan tó lè mú kí Pọ́ọ̀lù ṣèlara àwọn àpọ́sítélì méjìlá?

13 Àpẹẹrẹ ẹlòmíì tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Kò jẹ́ kí owú tàbí ìlara ta gbòǹgbò lọ́kàn òun. Ó ṣe gudugudu méje lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, síbẹ̀ kò gbéra ga, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Èmi ló kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì, mi ò sì yẹ lẹ́ni tí à ń pè ní àpọ́sítélì.” (1 Kọ́r. 15:9, 10) Àwọn àpọ́sítélì méjìlá yẹn ló wà pẹ̀lú Jésù nígbà tó ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ ẹ̀yìn ikú àti àjíǹde Jésù ni Pọ́ọ̀lù di Kristẹni. Òótọ́ ni pé Jésù yan Pọ́ọ̀lù láti jẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” síbẹ̀ kò di ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà. (Róòmù 11:13; Ìṣe 1:21-26) Kàkà kó jowú pé òun ò jẹ, òun ò sì mu pẹ̀lú Jésù bíi tàwọn àpọ́sítélì méjìlá yẹn, ó mọyì àǹfààní tó ní, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn.

14. Kí la máa ṣe tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a sì ní ìtẹ́lọ́rùn?

14 Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a sì ní ìtẹ́lọ́rùn, a máa ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù, àá sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn tí Jèhófà yàn sípò. (Ìṣe 21:20-26) Jèhófà ló ṣètò pé kí àwọn alàgbà máa múpò iwájú nínú ìjọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n, Jèhófà kà wọ́n sí “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.” (Éfé. 4:8, 11) Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tí Jèhófà yàn sípò tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń fún wa, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà á túbọ̀ gún régé, àlàáfíà á sì jọba nínú ìjọ.

“MÁA LÉPA ÀWỌN OHUN TÓ Ń MÚ KÍ ÀLÀÁFÍÀ WÀ”

15. Kí ló yẹ ká ṣe?

15 Àlàáfíà ò lè jọba níbi táwọn èèyàn bá ti ń ṣe ìlara. Nítorí náà, ó yẹ ká fa ẹ̀mí ìlara tu kúrò lọ́kàn wa ká má sì gbìn ín sọ́kàn àwọn míì. Èyí ṣe pàtàkì tá a bá máa ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà tó sọ pé ká “máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà àti àwọn ohun tó ń gbé ẹnì kejì wa ró.” (Róòmù 14:19) Kí làwọn nǹkan pàtó tá a lè ṣe tá ò fi ní mú káwọn míì máa jowú, ká sì jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà?

16. Kí la lè ṣe tá ò fi ní mú káwọn míì máa jowú tàbí ṣe ìlara?

16 Ìwà àti ìṣe wa lè mú káwọn míì ṣe ohun tó dáa, ó sì lè mú kí wọ́n ṣìwà hù. Ayé yìí ń fẹ́ ká máa “ṣe àṣehàn” àwọn ohun tá a ní. (1 Jòh. 2:16) Àmọ́ ṣe nirú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń fa owú tàbí ìlara. Tá ò bá fẹ́ káwọn míì máa jowú tàbí ṣe ìlara, kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ ṣáá nípa àwọn nǹkan tá a ní tàbí àwọn nǹkan tá a fẹ́ rà. Bákan náà, kò yẹ ká máa fi àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní ṣe fọ́rífọ́rí. Tá a bá ń fọ́nnu nípa iṣẹ́ ìsìn tá a ní, á mú káwọn míì bẹ̀rẹ̀ sí í jowú, kódà ó lè mú kí wọ́n ṣe ìlara. Àmọ́, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tọkàntọkàn, tá à ń fi hàn pé a mọyì wọn, tá a sì ń yìn wọ́n torí iṣẹ́ rere wọn, wọ́n á níyì lójú ara wọn, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan jọba nínú ìjọ.

17. Ìyípadà wo làwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe, kí nìyẹn sì yọrí sí?

17 Ó dájú pé a lè borí ẹ̀mí ìlara! Ẹ jẹ́ ká pa dà sórí àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n hùwà ìkà sí Jósẹ́fù, wọ́n pàdé ẹ̀ ní Íjíbítì. Kí Jósẹ́fù tó fara hàn wọ́n pé òun ni àbúrò wọn, ó dán wọn wò kó lè mọ̀ bóyá wọ́n ti yí pa dà. Ó ṣètò pé kí wọ́n bá òun jẹun, ó sì fún Bẹ́ńjámínì tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn ní oúnjẹ tó pọ̀ ju tàwọn yòókù lọ. (Jẹ́n. 43:33, 34) Àmọ́, kò sí ohunkóhun tó fi hàn pé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jowú Bẹ́ńjámínì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àbúrò wọn gan-an, wọn ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jékọ́bù bàbá wọn. (Jẹ́n. 44:30-34) Torí pé àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ti yíwà pa dà, tí wọn ò sì ṣe ìlara mọ́, wọ́n mú kí àlàáfíà pa dà jọba nínú ìdílé wọn. (Jẹ́n. 45:4, 15) Lọ́nà kan náà, tá a bá fa ẹ̀mí ìlara tu kúrò lọ́kàn wa, àlàáfíà á jọba nínú ìdílé wa àti nínú ìjọ.

18. Bó ṣe wà nínú Jémíìsì 3:17, 18, kí ló máa yọrí sí tá a bá ṣe ipa tiwa láti mú kí àlàáfíà jọba?

18 Jèhófà fẹ́ ká sapá gan-an ká lè borí ìlara, ká sì jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Èyí máa gba pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe. Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, àìpé máa ń mú ká jowú. (Jém. 4:5) Yàtọ̀ síyẹn, inú ayé tó kún fún owú àti ìlara là ń gbé. Àmọ́ tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a ní ìtẹ́lọ́rùn, tá a sì mọyì àwọn míì, a ò ní jowú, a ò sì ní ṣèlara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa mú kí àlàáfíà tó jẹ́ èso òdodo gbilẹ̀ yálà nínú ìdílé tàbí nínú ìjọ.​—Ka Jémíìsì 3:17, 18.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe lè mú ká borí ìlara?

  • Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ṣe lè mú ká borí ìlara?

  • Báwo ni ìwà àti ìṣe wa ṣe lè mú káwọn míì borí ìlara?

ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini

a Inú ètò tí àlàáfíà ti jọba la wà. Àmọ́ tá ò bá ṣọ́ra, ìlara lè mú kó ṣòro láti gbádùn àlàáfíà náà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ àwọn nǹkan tó ń fa ìlara. A sì tún máa jíròrò bá a ṣe lè borí ẹ̀mí burúkú yìí àti bá a ṣe lè jẹ́ kí àlàáfíà jọba.

b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Bó ṣe wà nínú Bíbélì, ìlara lè mú kéèyàn fẹ́ ní ohun táwọn míì ní, kó sì máa ronú pé kí ohun táwọn yẹn ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.

c ÀWÒRÁN: Níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà, wọ́n pinnu pé kí arákùnrin àgbàlagbà tó ti ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ dá alàgbà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa bójú tó iṣẹ́ náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin àgbàlagbà náà gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an, tinútinú ló fi fara mọ́ ìpinnu táwọn alàgbà yòókù ṣe. Ó dá arákùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́, ó fún un láwọn ìmọ̀ràn tó lè ràn án lọ́wọ́, ó sì gbóríyìn fún un tọkàntọkàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́