Àwọn Ìdílé Olùṣèfẹ́ Ọlọrun Ní Ìgbà Àtijọ́—Àpẹẹrẹ Àwòkọ́ṣe Fún Ọjọ́ Wa
ÌDÍLÉ—Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbìyànjú láti fi í ṣe kókó àfiyèsí fún aráyé. Báwo? Nípa kíkéde 1994 gẹ́gẹ́ bí “Ọdún Ìdílé Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-Èdè.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ní àgbáyé, àwọn onímọ̀ nípa àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, àti àwọn onímọ̀ràn nípa ìdílé ti yára láti dárò irú àwọn nǹkan gẹ́gẹ́ bí ìlọsókè nínú bíbí ọmọ àlè àti ìwọ̀n ìyára ìkọ̀sílẹ̀ tí ń fò sókè fíofío, wọ́n ti lọ́ra láti mú àwọn ojútùú tí ó gbéṣẹ́, tí ó jẹ́ gidi sí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ jáde.
Ó ha lè jẹ́ pé Bibeli ní ojútùú sí àwọn ìṣòro ìdílé bí? Fún àwọn kan, láti dábàá pé Bibeli lè ṣèrànwọ́ nínú àwọn ìdílé òde òní lè dà bí ìgbàgbọ́ láìṣèwádìí. Ó ṣe tán, a ti kọ ọ́ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn pẹ̀lú ìṣètò àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ará Middle East. Ní apá tí ó pọ̀ jù lọ ní àgbáyé, ìgbésí ayé ti yí padà ní ọ̀nà tí ó yá kánkán láti àkókò Bibeli wá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bibeli ni a mí sí láti ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun, ẹni náà tí gbogbo ìdílé jẹ ní gbèsè fún orúkọ wọn. (Efesu 3:14, 15; 2 Timoteu 3:16) Kí ni Bibeli sọ nípa àwọn ìṣòro ìdílé?
Jehofa mọ ohun náà gan-an tí a nílò láti mú kí ìgbésí ayé ìdílé gbádùn mọ́ni kí ó sì tẹ́ni lọ́rùn. Nítorí náà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, ní púpọ̀ láti sọ nípa ìgbésí ayé ìdílé, àwọn kan ní ọ̀nà ìṣínilétí. Bibeli tún ní àpẹẹrẹ àwọn ìdílé tí wọ́n fi ìlànà ti Ọlọrun sílò. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, wọ́n gbádùn ìṣepọ̀ tímọ́tímọ́ àti ìtẹ́lọ́rùn ní ti gidi. Ẹ jẹ́ kí a wo ìgbésí ayé ìdílé ní àkókò Bibeli kí a sì rí àwọn ẹ̀kọ́ tí a lè rí kọ́.
Ipò Orí—Ó Ha Jẹ́ Ìnira Bí?
Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn ipò orí nínú ìdílé. Ní àkókò àwọn baba ńlá, àwọn ọkùnrin bí Abrahamu, Isaaki, àti Jekọbu láìṣe àníàní jẹ́ “olórí ìdílé.” (Ìṣe 7:8, 9; Heberu 7:4) Ìwé The New Manners and Customs of Bible Times, láti ọwọ́ Ralph Gower, sọ pé: “Ìdílé jẹ́ . . . ‘ìjọba kékeré’ kan tí bàbá ń ṣàkóso. Ó ń ṣàkóso lórí ìyàwó, àwọn ọmọ, àwọn ọmọ-ọmọ, àti àwọn ẹrú—gbogbo agbo ilé náà.” Nítòótọ́, àwọn baba ńlá máa ń sábà ní ọlá àṣẹ lórí ìdílé àwọn ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú.—Fi wé Genesisi 42:37.
Èyí kò ha fún àwọn ọkùnrin ní àṣẹ láti máa ni àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ wọn lára bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Lóòótọ́, Ọlọrun sọ fún obìnrin àkọ́kọ́ náà, Efa pé: “Lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ọkàn rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa jẹ gàba lé ọ lórí.” (Genesisi 3:16, NW) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi bí àwọn adélébọ̀ ní gbogbo gbòò yóò ti ṣe sí hàn, ṣùgbọ́n wọn kò ṣàpèjúwe bí nǹkan ṣe yẹ kí ó rí láàárín àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Ọlọrun. Ó yẹ kí àwọn ọkọ tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun ní ètè Jehofa ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ lọ́kàn. Jehofa ṣe obìnrin gẹ́gẹ́ bí “olùrànlọ́wọ́” ọkùnrin “àti àṣekún rẹ̀,” kì í ṣe ẹrú rẹ̀. (Genesisi 2:20, NW) Nítorí àwọn ọkùnrin olùṣèfẹ́ Ọlọrun ní àwọn àkókò ìbẹ̀rẹ̀ mọ ìtẹríba àti ìjíhìn tiwọn fún Ọlọrun, wọn kò ṣi ọlá àṣẹ wọn lò. Ní ìyàtọ̀ gedegbe sí bíbá àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ wọn lò bí ẹrú, àwọn baba ńlá tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun fi ojúlówó ìfẹ́ àti ìfẹ́ni hàn sí wọ́n.
Ìmọ́lẹ̀fìrí sínú ìfẹ́ni tí àwọn ọmọ sábà máa ń rí gbà ni a fúnni nínú Genesisi 50:23. (NW) Níbẹ̀ ni a ti sọ nípa àwọn ọmọ-ọmọ ọmọkùnrin Josefu pé: “A bí wọn lórí eékún Josefu.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè wulẹ̀ túmọ̀ sí pé Josefu tẹ́wọ́ gba àwọn ọmọ náà gẹ́gẹ́ bí ìrandíran rẹ̀, ó tún lè tọ́ka sí i pé ó bá àwọn ọmọ náà ṣeré pẹ̀lú ìfẹ́ni, tí ó ń gbé wọn jó lórí eékún rẹ̀. Àwọn bàbá lónìí yóò ṣe dáradára, bí wọ́n bá fi irú ìfẹ́ni kan náà hàn sí àwọn ọmọ wọn.
Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, àwọn baba ńlá tí ó bẹ̀rù Ọlọrun tún máa ń bójútó àìní nípa tẹ̀mí ti àwọn ìdílé wọn. Bí wọ́n ti bọ́ sílẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ áàkì lẹ́yìn Àkúnya Omi kárí ayé náà, “Noa sì tẹ́ pẹpẹ fún OLUWA; . . . ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun lórí pẹpẹ náà.” (Genesisi 8:20; fi wé Jobu 1:5.) Baba ńlá náà, Abrahamu, fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa fífún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ní ìtọ́ni ti ara ẹni. Ó ‘pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, kí wọn kí ó baà lè pa ọ̀nà OLUWA mọ́ láti ṣe òdodo àti ìdájọ́.’ (Genesisi 18:19) Ipò orí onífẹ̀ẹ́ tipa báyìí kó ipa pàtàkì nínú wíwà déédéé àwọn ìdílé náà nípa ti èrò ìmọ̀lára àti nípa tẹ̀mí.
Àwọn Kristian ọkùnrin lónìí ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe yìí. Wọ́n ń lo ipò orí nínú àwọn ọ̀ràn ìjọsìn, nípa ríran àwọn ìdílé wọn lọ́wọ́ láti fi àwọn ohun tí Ọlọrun béèrè fún sílò àti nípa fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fúnra wọn. (Matteu 28:19, 20; Heberu 10:24, 25) Gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá, àwọn Kristian ọkọ àti bàbá pẹ̀lú máa ń fara balẹ̀ láti fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn ní ìtọ́ni ti ara ẹni.
Gbígbé Ìgbésẹ̀ Onípinnu
Nígbà tí ó san gbèsè ńlá kan fún bàbá ìyàwó rẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, baba ńlá náà, Jekọbu, béèrè pé: “Nígbà wo ni èmi óò pèsè fún ilé mi?” (Genesisi 30:30) Gẹ́gẹ́ bíi gbogbo bàbá, Jekọbu ní ìmọ̀lára ìkìmọ́lẹ̀ ti kíkájú ìwọ̀n àìní ìdílé rẹ̀ nípa ti ara, ó sì ṣiṣẹ́ kára láti ṣe èyí. Genesisi 30:43 sọ pé: “Ọkùnrin náà sì pọ̀ gidigidi, ó sì ní ẹran ọ̀sìn púpọ̀, àti ìránṣẹ́bìnrin, àti ìránṣẹ́kùnrin, àti ìbákasíẹ, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí Jekọbu ti ṣí lọ sí ilẹ̀ Kenaani, dájúdájú, kò mọ̀ pé ọmọbìnrin rẹ̀ Dina ti mú àṣà líléwu tí kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà ará Kenaani dàgbà.a (Genesisi 34:1) Ó tún kùnà láti gbé ìgbésẹ̀ nígbà tí ó mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ti ìsìn tí ó wà ní agbo ilé rẹ̀. Ohun yòówù kí ó jẹ́, lẹ́yìn tí ará Kenaani kan fipá bá Dina lò pọ̀ lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, Jekọbu gbé ìgbésẹ̀ onípinnu. Ó pàṣẹ pé: “Ẹ mú àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́wọ́ yín kúrò . . . kí ẹ̀yin kí ó sì pa aṣọ yín dà.”—Genesisi 35:2-4.
Àwọn Kristian tí wọ́n jẹ́ bàbá ní láti wà lójúfò tí ó bá kan ọ̀ràn tẹ̀mí àwọn ìdílé wọn. Bí ìhalẹ̀mọ́ni líle koko bá wà fún ire nípa tẹ̀mí ti ìdílé náà, irú bíi tí ìwé oníwà pálapàla tàbí orin tí kò gbéni ró bá wà nínú ilé, wọ́n ní láti gbé ìgbésẹ̀ onípinnu.
Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, irú àwọn obìnrin ìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Sara, Rebeka, àti Rakeli pẹ̀lú lo agbára ìdarí tí ó ṣe pàtàkì nínú ìdílé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tẹrí ba fún àwọn ọkọ wọn, a kò ká wọn lọ́wọ́ kò láti má ṣe lo àtinúdá nígbà tí ó bá yẹ, tí ó sì pọndandan. Fún àpẹẹrẹ, Eksodu 4:24-26 sọ fún wa pé, nígbà tí Mose àti ìdílé rẹ̀ ń lọ sí Egipti, “OLUWA [“áńgẹ́lì Jehofa,” Septuagint] pàdé rẹ̀, ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á [ọmọkùnrin Mose].” Pẹ̀lú ẹ̀rí tí ó dájú, ọmọkùnrin Mose wà nínú ewu ti didi ẹni tí a pa nítorí pé Mose kọ̀ láti kọ ọ́ nílà. Sippora gbé ìgbésẹ̀ kíákíá, ó sì kọ ọmọkùnrin rẹ̀ nílà. Lójú ìwòye èyí, áńgẹ́lì náà jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lọ. Àwọn Kristian aya lónìí lè lo àtinúdá nígbà tí ipò náà bá mú kí èyí yẹ bẹ́ẹ̀.
Ìtọ́ni Bàbá Lábẹ́ Òfin Mose
Ní 1513 B.C.E., ìgbà àwọn baba ńlá dópin, bí Israeli ti di orílẹ̀-èdè kan. (Eksodu 24:3-8) Àwọn bàbá ń bá a lọ láti máa ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé. Bí ó ti wù kí ó rí, òfin ìdílé di èyí tí ó rẹlẹ̀ sí Òfin orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun fún Mose, tí àwọn onídàájọ́ tí a yàn sì ń mú lò. (Eksodu 18:13-26) Ẹgbẹ́ àlùfáà Lefi gba apá tí ó jẹ mọ́ ìrúbọ nínú ìjọsìn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bàbá ń bá a lọ láti máa kó ipa pàtàkì. Mose gbani níyànjú pé: “Àti ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo pa láṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà [ní] àyà rẹ: Kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ í sọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà, àti nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ bá dìde.”—Deuteronomi 6:6, 7.
Òfin náà pèsè àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀, irú bí Ìrékọjá, nígbà tí a lè fúnni ní ìtọ́ni elétò àṣà àti èyí tí kì í ṣe elétò àṣà. Bí Nisan 14, ọjọ́ Ìrékọjá, ti ń sún mọ́lé, àwọn ìdílé Júù yóò bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún ìrìn-àjò wọn lọ sí Jerusalemu gẹ́gẹ́ bí àṣà. (Deuteronomi 16:16; fi wé Luku 2:41.) Ọmọ wo ni irú ìpalẹ̀mọ́ bẹ́ẹ̀ kì yóò ru ìmọ̀lára rẹ̀ sókè? Ìrìn-àjò náà fúnra rẹ̀ yóò jẹ́ ohun tí ó gbádùn mọ́ni. Nígbà náà àkókò òjò ti parí, oòrùn ìgbà ìrúwé sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ká òtútù ọyẹ́ kúrò nílẹ̀. Bí àwọn òjò dídì orí Òkè Ńlá Hermoni ti ń yọ́, Odò Jordani yóò kún àkúnya.
Lójú ọ̀nà, kì í ṣe kìkì ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ilẹ̀ wọn nìkan ni àwọn bàbá lè kọ́ àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n tún lè kọ́ wọn ní àwọn ìtàn tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìran tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n kọjá lára wọn. Àwọn wọ̀nyí lè ní Òkè Ńlá Ebali àti ti Gerisimu níbi tí a ti ka àwọn ègún àti ìbùkún Òfin nínú. Wọ́n ti lè gba Beteli kọjá pẹ̀lú, níbi tí Jekọbu ti rí ìran àkàsọ̀ ti ọ̀run. Ẹ wo irú ìjíròrò amóríyá tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà! Bí ìrìn-àjò náà ti ń tẹ̀ síwájú, tí àwọn arìnrìn-àjò láti àwọn apá mìíràn láti ilẹ̀ náà sì ń dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwùjọ ìdílé, gbogbo wọn yóò gbádùn àjọṣepọ̀ tí ń gbéni ró.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín ìdílé náà yóò wọ Jerusalemu, ‘ẹlẹ́wà pípé’ náà. (Orin Dafidi 50:2) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan, Alfred Edersheim, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn arìnrìn-àjò wọ̀nyí ti ní láti dóbùdó síta àwọn ògiri ìlú-ńlá náà. Àwọn wọnnì tí a fi wọ̀ sínú ìlú náà ni a fún ní àyè lọ́fẹ̀ẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọ̀dọ́ Heberu gba ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n nínú ìfẹ́ ará àti aájò àlejò ní tààràtà. Àpéjọpọ̀ ọlọ́dọọdún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ń ṣiṣẹ́ tí ó fara jọ ète yìí lónìí.
Nisan 14 yóò wọlé dé nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ẹran Ìrékọjá náà ni a óò pa, tí a óò sì fi iná yan fún wákàtí mélòó kan. Bí ó ti ń sún mọ́ ọ̀gànjọ́ òru, ìdílé náà yóò jẹ ọ̀dọ́ àgùtàn náà, àkàrà aláìwú, àti ewébẹ̀ kíkorò. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, ọmọkùnrin kan yóò béèrè pé: “Èrèdí ìsìn yìí?” Àwọn bàbá yóò fúnni ní ìsọfúnni ti elétò àṣà, ní sísọ pé: “Ẹbọ ìrékọjá OLUWA ni, ẹni tí ó ré kọjá ilé àwọn ọmọ Israeli ní Egipti, nígbà tí ó kọlu àwọn ará Egipti, tí ó sì dá ilé wa sí.”—Eksodu 12:26, 27; 13:8.
Solomoni ọba Israeli sọ pé: ‘Ìgbà rírẹ́rìn-ín àti ìgbà jíjó wà.’ (Oniwasu 3:4) A fún àwọn ọmọ Israeli ní àyè fún eré ìnàjú. Ó hàn gbangba pé Jesu Kristi wo àwọn ọmọdé nígbà tí wọ́n ń ṣeré ní ibi ọjà. (Sekariah 8:5; Matteu 11:16) Kò sì ṣàjèjì fún àwọn òbí tí wọ́n ní lọ́wọ́ láti ṣètò fún ìpéjọpọ̀ ìdílé tí ó gbádùn mọ́ni tí yóò ní kíkọrin, jíjó, àti ṣíṣayẹyẹ nínú. (Luku 15:25) Àwọn Kristian òbí lónìí bákan náà ń lo àtinúdá nínú pípèsè eré ìnàjú àti ìkẹ́gbẹ́pọ̀ tí ó gbámúṣé fún àwọn ọmọ wọn.
Àwọn Ìyá àti Àwọn Ọmọ Nínú Ẹgbẹ́ Àwùjọ Àwọn Júù
Ipa wo ni àwọn ìyá ń kó lábẹ́ Òfin Mose? Owe 1:8 pàṣẹ pé: “Ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ bàbá rẹ, kí ìwọ kí ó má sì kọ òfin ìyá rẹ sílẹ̀.” Láìkọjá ìṣètò ìlànà ọlá àṣẹ ọkọ rẹ̀, ìyàwó Júù yóò fi àwọn ohun tí Ọlọrun béèrè fún sílò nínú ìgbésí ayé ìdílé. Àwọn ọmọ rẹ̀ ní láti bọlá fún un, àní lẹ́yìn tí ó ti darúgbó pàápàá.—Owe 23:22.
Ìyá náà tún ní apá tí ó pọ̀ nínú dídá àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Ó ń bójú tó ìkókó, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lóun nìkan títí tí yóò fi dàgbà tó já lẹ́nu ọmú, láìsí àníàní, ní yíyọrí sí àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ láàárín tọmọtìyá. (Isaiah 49:15) Bí àwọn bàbá ti ń kọ́ àwọn ọmọkùnrin wọn ní òwò, àwọn ìyá ń kọ́ àwọn ọmọbìnrin wọn ní iṣẹ́ ilé. Àwọn ìyá tún ní agbára ìdarí tí ó jinlẹ̀ lórí àwọn ọmọkùnrin wọn. Fún àpẹẹrẹ, Lemuẹli ọba jàǹfààní láti inú “ìhìn iṣẹ́ lílágbára tí ìyá rẹ̀ fún un ní ọ̀nà ìtọ́nisọ́nà.”—Owe 31:1, NW.
Ìyàwó Júù tí ó dáńgájíá kan tún ń gbádùn òmìnira ńláǹlà nínú fífi “ojú sílẹ̀ wo ìwà àwọn ará ilé rẹ̀.” Ní ìbámu pẹ̀lú Owe 31:10-31, ó lè ra àwọn ohun tí ìdílé nílò, kí ó dúnàá-dúrà ilé ńlá, kí ó tilẹ̀ bójú tó okòwò pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Fún ọkọ tí ó bá mọrírì, iye rẹ̀ “kọjá iyùn”!
Àpẹẹrẹ fún Ọjọ́ Òní
Ní àkókò Bibeli ìṣètò ìdílé ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè ti èrò ìmọ̀lára àti tẹ̀mí gbogbo mẹ́ḿbà rẹ̀. Àwọn bàbá ní láti lo ọlá àṣẹ wọn lọ́nà onífẹ̀ẹ́ kí àwọn ìdílé wọn lè jàǹfààní. Wọ́n ní láti mú ipò iwájú nínú ìjọsìn. Bàbá àti ìyá fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú àwọn ọmọ wọn—ní kíkọ́ àti dídá wọn lẹ́kọ̀ọ́, jíjọ́sìn pẹ̀lú wọn, àti pípèsè eré ìnàjú fún wọn. Àwọn ìyá olùṣèfẹ́ Ọlọrun fẹ̀rí jíjẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí ó ṣeyebíye hàn, ní bíbọ̀wọ̀ fún ipò orí àwọn ọkọ wọn, bí wọ́n ti ń lo àtinúdá ní ṣíṣojú fún ìdílé wọn. Àwọn ọmọ onígbọràn mú ìdùnnú-ayọ̀ wá fún àwọn òbí wọn àti fún Jehofa Ọlọrun. Nítòótọ́, ìdílé tí ó bẹ̀rù Ọlọrun ní àkókò Bibeli jẹ́ àpẹẹrẹ tí ó gbámúṣé fún ọjọ́ wa.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ní láti ṣàkíyèsí pé ṣáájú èyí, Jekọbu ti gbé ìgbésẹ̀ gírígírí láti dáàbò bo ìdílé rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ agbára ìdarí àwọn ará Kenaani. Ó kọ́ pẹpẹ kan, láìṣe àníàní ní àrà tí ó yà á sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀ ará Kenaani. (Genesisi 33:20; Eksodu 20:24, 25) Síwájú sí i, ó kọ́ ibùdó rẹ̀ síta ìlú ńlá Ṣekemu, ó sì gbẹ́ orísun omi tirẹ̀. (Genesisi 33:18; Johannu 4:6, 12) Dina yóò ti tipa báyìí mọ ìfẹ́ ọkàn Jekọbu dáradára, pé kí òun má ṣe bá àwọn ará Kenaani kẹ́gbẹ́ pọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìdílé rẹ lè jẹ́ aláyọ̀ bíi ti àwọn ìdílé tí ó jọ́sìn Jehofa ní àkókò Bibeli