ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 12/1 ojú ìwé 8
  • “Ṣe Iṣẹ́ Ajíhìnrere”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ṣe Iṣẹ́ Ajíhìnrere”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ṣe Iṣẹ́ Ajíhìnrere”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Gbogbo Awọn Kristian Tootọ Gbọdọ Jẹ́ Ajihinrere
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Máa Ṣe Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ajíhìnrere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ajíhìnrere Tòótọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 12/1 ojú ìwé 8

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

“Ṣe Iṣẹ́ Ajíhìnrere”

KÍ NI jíjẹ́ ajíhìnrere túmọ̀ sí? Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, eu·ag·ge·li·stesʹ, tí ó jọra gan-an pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà, eu·ag·geʹli·on, tí ó túmọ̀ sí “ìhìn rere.” Nítorí náà, ajíhìnrere jẹ́ oníwàásù, tàbí ìránṣẹ́, ìhìn rere.

Gbogbo àwọn Kristian tòótọ́ jẹ́ ajíhìnrere, nítorí pé wọ́n ń kéde ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọrun. Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, aposteli Paulu gba Timoteu nímọ̀ràn láti “ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere.” Timoteu ní láti mú iṣẹ́ yìí lọ́kùn-únkúndùn. Paulu rọ̀ ọ́ láti ‘pa agbára ìmòye rẹ̀ mọ́ nínú ohun gbogbo’ àti láti ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní kíkún.’—2 Timoteu 4:5.

Gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, àwa pẹ̀lú ní láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ́kùn-únkúndùn, kí a sì ‘pa agbára ìmòye wa mọ́,’ tàbí kí a wà lójúfò láti ṣàjọpín ìhìn rere ní gbogbo àkókò tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ti tipa bẹ́ẹ̀ mọ Jehofa àti àwọn ìlérí rẹ̀, lẹ́yìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá wọn pàdé nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Seymore, ọkùnrin kan ní Barbados, nìyí.

Seymore jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba. Charles, tí ó ń ṣe àbọ̀ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kan náà, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, jẹ́ ajíhìnrere tí ó wà lójúfò. Ó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tàbí aṣáájú ọ̀nà, ó sì ń lo gbogbo àǹfààní tí ó bá ní láti ṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú àwọn mìíràn. Nípasẹ̀ ìjẹ́rìí àìjẹ́ bí àṣà Charles ni Seymore fi kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà.

Láìpẹ́, Seymore pẹ̀lú pinnu láti ṣàjọpín òtítọ́ Bibeli pẹ̀lú iye ènìyàn tí ó bá lè ṣeé ṣe. Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò láìjẹ́ bí àṣà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní ibi iṣẹ́ẹ rẹ̀, ní pàtàkì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní àwọn ilẹ̀ kan, a kò gbọdọ̀ fi ẹ̀kọ́ nípa ìsìn kọ́ni ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba, síbẹ̀ a yan ọkùnrin yìí láti máa kọ́ni nípa ìsìn àti ìlànà ìwà rere. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ìmọ̀ Bibeli tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí gbà ti rọ́pò ojú ìwòye Seymore tẹ́lẹ̀ rí lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí. Nígbà ìsinmi ráńpẹ́, ó máa ń bá àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìlérí Ọlọrun fún ayé tuntun àti ìfojúsọ́nà ìwàláàyè títí láé.

Báwo ni àwọn ọmọ náà ṣe hùwà padà? Ọ̀pọ̀ fi ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ nínú ìhìn rere Ìjọba Jehofa hàn. Láìpẹ́, Seymore bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú 13 lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ọkàn-ìfẹ́ wọn pọ̀ débi pé, wọ́n ṣètò láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé Kristian ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ní àdúgbò. Ní báyìí, mẹ́sàn-án lára wọn ti di Ẹlẹ́rìí fún Jehofa tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì ti ṣe batisí. Ní ti Seymore, nísinsìnyí ó ń ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní kíkún nípa ṣíṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún àti alàgbà nínú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Barbados.

Èyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan lára bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jákèjádò àgbáyé ‘ṣe ń ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere,’ lápá kan nípa ṣíṣàjọpín nínú jíjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bibeli, tí ó wà nínú Kolosse 4:5‚ 6, tí ó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn ninu ọgbọ́n sí awọn wọnnì tí ń bẹ ní òde, kí ẹ máa ra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín. Nígbà gbogbo ẹ jẹ́ kí gbólóhùn àsọjáde yín máa jẹ́ pẹlu oore-ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹni kọ̀ọ̀kan.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́