ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 12/15 ojú ìwé 26-29
  • Òdodo Ní Ń gbé Orílẹ̀-èdè Lékè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òdodo Ní Ń gbé Orílẹ̀-èdè Lékè
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Israeli Tẹ̀mí
  • Ayé Lè Rí Ìyàtọ̀ Náà
  • Ìdí Tí A Fi Ń Yọ Àwọn Kan Lẹ́gbẹ́
  • Dídi Òdodo Jehofa Mú
  • Ní Inú Dídùn Sí Òdodo Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Máa Gba Ìbáwí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Nífẹ̀ẹ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Wíwá Òdodo Yóò Dáàbò Bò Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 12/15 ojú ìwé 26-29

Òdodo Ní Ń gbé Orílẹ̀-èdè Lékè

LẸ́YÌN tí òjò ti rọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ẹ wo bí yóò ti gbádùn mọ́ni tó láti jí, kí a sì rí oòrùn títàn yòò nínú àwọsánmà tí ó mọ́ kedere! Ilẹ̀ ayé ti rí ìtura, ewéko sì lè máa gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nísinsìnyí. Jehofa Ọlọrun ti lo irú àwòrán bẹ́ẹ̀ nígbà kan láti ṣàpèjúwe àwọn ìbùkún ìṣàkóso òdodo. Ó wí fún Ọba Dafidi pé: “Ẹnì kan tí ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Yóò sì dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùukùu, nígbà tí koríko tútù bá hù láti ilẹ̀ wá nípa ìtànṣán lẹ́yìn òjò.”—2 Samueli 23:3, 4.

Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ òtítọ́ nígbà ìṣàkóso òdodo ti ọmọkùnrin Dafidi, Ọba Solomoni. Bibeli ròyìn pé: “Juda àti Israeli ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, láti Dani títí dé Beerṣeba, ní gbogbo ọjọ́ Solomoni.”—1 Awọn Ọba 4:25.

Israeli ìgbàanì jẹ́ orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ Ọlọrun. Ó fún wọn ní òfin rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé, bí wọ́n bá fetí sí ohùn òun, òun yóò gbé wọn “ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ.” (Deuteronomi 28:1) Kì í ṣe òdodo Israeli fúnra rẹ̀ ni ó gbé e ga, bí kò ṣe òdodo Jehofa. Àwọn òfin tí Ọlọrun fún wọn ga fíìfíì ju òfin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká lọ. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, wọ́n jẹ́ aláìpé bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì. Nípa báyìí, Òfin Jehofa tí ó ga jù lọ, àti rírọ̀ tímọ́tímọ́ wọn mọ́ ọn ni ó yẹ kí a gbóṣùbà fún, fún gbígbé tí a gbé wọn ga ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ. Nígbà tí wọ́n ṣègbọràn sí òfin Jehofa, wọ́n gbádùn ojú rere àti ìbùkún rẹ̀. Ọba Solomoni nírìírí èyí nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Ó lè sọ pé: “Òdodo ní í gbé orílẹ̀-èdè lékè; ṣùgbọ́n,” ó kìlọ̀ pé, “ẹ̀ṣẹ̀ ni ẹ̀gàn orílẹ̀-èdè.”—Owe 14:34.

Ó bani nínú jẹ́ pé, nípa ṣíṣàìgbọràn léraléra, orílẹ̀-èdè Israeli tipa báyìí ní ìdúró rírẹlẹ̀. Wọ́n jìyà ìtìjú nílé lóko. Èyí ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ yọrí sí kíkọ̀ wọ́n sílẹ̀ pátápátá nítorí àtilè ṣojú rere sí orílẹ̀-èdè tẹ̀mí.—Matteu 21:43.

Israeli Tẹ̀mí

Nínú ìpàdé kan tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso Kristian ṣe ní Jerusalemu, Jakọbu, tí a bí gẹ́gẹ́ bíi Júù, sọ lábẹ́ ìmísí pé, Ọlọrun ti “yí àfiyèsí rẹ̀ sí awọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ lati mú awọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde lati inú wọn.” (Ìṣe 15:14) Aposteli Paulu pe orílẹ̀-èdè Kristian tuntun yìí ní “Israeli Ọlọrun.” (Galatia 6:16) Nípa ète tí a torí rẹ̀ pè wọ́n, Peteru kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà-ìran àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, awọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ̀yin lè polongo káàkiri awọn ìtayọlọ́lá’ ẹni naa tí ó pè yín jáde kúrò ninu òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Peteru 2:9) Gẹ́gẹ́ bí àwọn àyànfẹ́ ènìyàn Ọlọrun, wọ́n gbọ́dọ̀ tàn gẹ́gẹ́ bí olùtan ìmọ́lẹ̀ nínú ayé. Òdodo Jehofa yóò gbé wọn ga.—Filippi 2:15.

A lè fi yíyan àwọn ọmọ Israeli tẹ̀mí wọ̀nyí wé wíwa dáyámọ́ǹdì. Nígbà tí a bá wa kùsà tí ó ní dáyámọ́ǹdì jáde, ìwọ̀n kàráàtì 1 péré (200 mìlígíráàmù) ni a lè rí nínú tọ́ọ̀nù iyẹ̀pẹ̀ 3. Ọgbọ́n tí a ń lò nígbà kan láti ya dáyámọ́ǹdì sọ́tọ̀ ní, fífi omi po kùsà náà àti dída àpòpọ̀ náà sórí tábìlì tí a ti da gírísì sí nínú. Dáyámọ́ǹdì kì í dà pọ̀ mọ́ omi, wọ́n sì máà ń lẹ̀ mọ́ gírísì, nígbà tí àwọn ohun èlò tí a kò fẹ́ yóò sì ṣàn lọ. Ní ibí yìí, dáyámọ́ǹdì náà rí ṣágiṣàgi. Ṣùgbọ́n, nígbà tí a bá gé e, tí a sì dán an, gbogbo ara wọn yóò máa dán yinrinyinrin.

Bíi dáyámọ́ǹdì tí kò lè dà pọ̀ mọ́ omi, tí kì í ṣe apá kan ohun tí ó yí wọn ká, a ti ya àwọn ènìyàn Jehofa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé. (Johannu 17:16) Nígbà tí a kọ́kọ́ fà wọ́n sún mọ́ ìmọ́lẹ̀, wọ́n lè ṣàìdán yinrinyinrin. Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ àti ẹ̀mí Jehofa ti dá àkópọ̀ ìwà tuntun sínú wọn, wọ́n sì ń tàn bí olùtan ìmọ́lẹ̀ nínú ayé yìí. Nítorí òdodo Jehofa ni a fi gbé wọn ga, tí wọ́n sì fi ń tan ìmọ́lẹ̀ ológo ti òtítọ́ Ìjọba ní gbogbo ìhà, kì í ṣe nítorí òdodo ti ara wọn.

Síbẹ̀, láti apá ìparí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ìpẹ̀yìndà yọ́ wọ inú àwọn ìjọ, ó sì nípa lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀. Àwọn tí a fẹnu lásán pè ní Kristian dà pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé, a kò sì lè dá wọn mọ̀ yàtọ̀ sí ayé tí ó yí wọn ká.

Lónìí, a ti mú àṣẹ́kù àwọn olùṣòtítọ́, ọmọ Israeli tẹ̀mí padà bọ́ sínú ojú rere Jehofa. Wọ́n ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, wọ́n sì ti wẹ ara wọn mọ́ tónítóní kúrò nínú “gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran-ara ati ti ẹ̀mí.” (2 Korinti 7:1) Níwọ̀n bí wọ́n ti wà ní mímọ́ tónítóní, tí wọ́n sì dúró ṣánṣán níwájú Jehofa, wọ́n di òdodo rẹ̀ mú. Èyí ti gbé wọn sí ipò gíga ti ojú rere tí ó ga ju ti orílẹ̀-èdè ayé lọ. Nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà tìtaratìtara, a ti fa ogunlọ́gọ̀ ńlá káàkiri orílẹ̀-èdè sún mọ́ Jehofa, wọ́n sì ti di apá kan àwọn ènìyàn rẹ̀.—Ìṣípayá 7:9, 10.

Ayé Lè Rí Ìyàtọ̀ Náà

Nígbà míràn, àwọn aláṣẹ ayé máa ń gbóríyìn fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun. Láìpẹ́ yìí, ọ̀gá àwọn olùṣọ́ Gbàgede Ìpàtẹ Ọjà Pretoria, ní South Africa, sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, láti inú gbogbo ẹ̀yà ìran tí wọ́n lo àwọn ilé gbàgede yẹn fún àpéjọpọ̀ ọdọọdún. Lára àwọn ohun tí ó sọ, ó kọ̀wé pé: “Ọmọlúwàbí ni gbogbo wọn, àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ sí ẹnì kíní kejì lọ́nà tí ó dára, ìṣarasíhùwà tí wọ́n fi hàn ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn—gbogbo rẹ̀ jẹ́rìí sí irú ènìyàn tí ó jẹ́ mẹ́ḿbà àwùjọ yín, àti pé gbogbo wọn ń gbé pọ̀ bí ìdílé aláyọ̀.”

Àwọn ènìyàn Jehofa lè fi kún òdodo orílẹ̀-èdè rẹ̀, kì í ṣe ní irú ìpéjọpọ̀ ńlá bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n nínú ìgbésí ayé wọn pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀ka Watch Tower Society ní South Africa, rí lẹ́tà kan gbà láti ọ̀dọ̀ obìnrin kan ní Johannesburg, tí ó sọ pé: “Lọ́sẹ̀ tí ó kọjá, mo wa ọkọ̀ mi lọ pẹ̀lú àpò owó mi lórí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà. Ó fẹ́ sọnù ní Òpópónà Jan Smuts, mẹ́ḿbà ìjọ yín kan, Ọ̀gbẹ́ni R—, sì he é pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, ó tẹ̀ mí láago, ó sì dá a padà fún mi. . . . Mo mọrírì àìlábòsí yìí tí kò wọ́ pọ̀ mọ́ ní àkókò yìí gidigidi, mo sì gbóríyìn fún ìjọ yín, fún gbígbé àwọn ìlànà tí àwọn mẹ́ḿbà yín ń rọ̀ mọ́ kalẹ̀.”

Bẹ́ẹ̀ ni, rírọ̀ mọ́ àwọn ìlànà òdodo Jehofa, mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ dá yàtọ̀ gédégbé nínú ayé. Nítorí pé àwọn wọ̀nyí gbé òdodo Jehofa yọ, a ń fa àwọn aláìlábòsí ọkàn sún mọ́ ìjọ Kristian. Ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti ní ìfẹ́ ọkàn sí ohun mímọ́ tónítóní, tí ó sì mọ́ gaara. Fún àpẹẹrẹ, àlejò kan wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Zurich, Switzerland, nígbà kan, ó sì wí pé òún fẹ́ di mẹ́ḿbà ìjọ náà. Ó ṣàlàyé pé, a yọ arábìnrin òun lẹ́gbẹ́ fún ìwà pálapàla, ó sì fi kún un pé, òun fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ètò àjọ tí “kò gba ìwà búburú láyè.” Kódà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia jẹ́wọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọ̀kan nínú àwọn àwùjọ tí ó níwà ọmọlúwàbí jù lọ lágbàáyé.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òdodo ń gbéni ga, ẹ̀ṣẹ̀ lè mú ìtìjú wá bá orúkọ rere tí ẹnì kan ní, ní pàtàkì tí ìwà àìtọ́ bíburú jáì náà bá di mímọ̀ láwùjọ. Nígbà míràn, ìjọ Kristian ní láti gba ìtìjú tí a kó bá a náà mọ́ra, nígbà tí mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó burú lékenkà. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, àwọn olùṣòtítọ́ mẹ́ḿbà ìjọ náà lè gbèjà orúkọ rere ìjọ náà nípa fífi hàn pé, a ti bá oníwà àìtọ́ náà wí lọ́nà tí ó fi àánú hàn, ìyẹn ni pé, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́. Bí ẹnì kan bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà, tí kò sì ronú pìwà dà, a óò yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ—a óò yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.—1 Korinti 5:9-13.

Ìdí Tí A Fi Ń Yọ Àwọn Kan Lẹ́gbẹ́

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń yọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ Kristian lọ́dọọdún, wọ́n wulẹ̀ jẹ́ kìkì ìpín kéréje nínú àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù márùn-ún lágbàáyé. Èé ṣe tí a fi ní láti gbé irú ìgbésẹ̀ mímúná bẹ́ẹ̀ lòdì sí ẹnì kan nínú ìjọ Kristian? Bí ìwà àìtọ́ náà bá ṣe burú tó ni ọ̀kan nínú kókó abájọ tí yóò pinnu ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n kókó abájọ tí ó ṣe pàtàkì jù ni, yálà oníwà àìtọ́ náà fi ojúlówó ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn lórí ìwà àìtọ́ bíburú jáì tí ó ti hù. Bí ó bá dùn ún dé ọkàn ní tòótọ́, tí ó sì yíjú sí Jehofa nínú àdúrà àtọkànwá, tí ó bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá sí I, tí ó sì ti wá ìrànlọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tí a fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ, a lè ràn án lọ́wọ́ láti jèrè ojú rere Ọlọrun padà, kí ó sì máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ apá kan ìjọ náà.—Owe 28:13; Jakọbu 5:14, 15.

Nígbà tí ọmọ kan tí ó ní ipò ìbátan tí ó dára, tí ó sì gbámúṣé pẹ̀lú bàbá rẹ̀ bá ṣe ohun kan tí ó bí bàbá náà nínú, àwọn méjèèjì ní láti tètè mú ipò ìbátan ṣíṣeyebíye náà padà bọ̀ sípò. Bákan náà, nígbà tí a ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jehofa, a wọnú ipò ìbátan ṣíṣeyebíye jù lọ pẹ̀lú rẹ̀. Nípa báyìí, nígbà tí a bá ṣe ohun kan tí ó bí i nínú, a ní láti tètè wá ọ̀nà láti mú ipò ìbátan yẹn padà bọ̀ sípò pẹ̀lú Bàbá wa Ọ̀run.

Ó dùn mọ́ni pé, àwọn kan tí wọ́n wà ní ipò ìyọlẹ́gbẹ́ ti fi àkàwé ọmọ onínàákúnàá náà sọ́kàn. Níbẹ̀, a fi Jehofa wé Bàbá onífẹ̀ẹ́ kan tí ó ṣe tán láti tẹ́wọ́ gba ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà padà, bí ó bá yí padà, tí ó sì wá ìdáríjì Ọlọrun. (Luku 15:11-24) Ojúlówó, ìrònúpìwàdà àtọkànwá, àti yíyí padà kúrò nínú ohun búburú ti jẹ́ ọ̀nà kan láti padà sínú ojú rere Jehofa àti ti ìjọ Kristian. Àwọn oníwà àìtọ́ kan, tí wọ́n ti ronú pìwà dà, tí ọrùn ti wọ̀ lábẹ́ ẹrù ìnira ẹ̀bi wọn ni a ti sún láti ronú pìwà dà, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ láti padà wá sí àyíká onífẹ̀ẹ́ ti ìjọ Kristian. Wọ́n ti tipa bẹ́ẹ̀ mọrírì àwọn ọ̀rọ̀ Jehofa nínú Isaiah 57:15.

Láti dí àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti má ṣe padà wá sábẹ́ ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ Jehofa, Satani yóò fẹ́ láti díbọ́n pé, kò sí ìdáríjì kankan fún ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá. Ṣùgbọ́n ẹbọ ìràpadà Kristi Jesu tó láti kájú ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwà dà—àní, “ti gbogbo ayé,” tí ó jogún ẹ̀ṣẹ̀ pàápàá. (1 Johannu 2:1, 2) Ẹ̀ṣẹ̀ kan tí ìràpadà kò kájú ni ẹ̀ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun, èyí tí ó jẹ́ mímọ̀ọ́mọ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọ̀nà tí ẹ̀mí Ọlọrun gbà ń ṣiṣẹ́, irú bí ẹ̀ṣẹ̀ búburú lékenkà tí Judasi Iskariotu dá, àti ti ọ̀pọ̀ àwọn akọ̀wé àti Farisi.—Matteu 12:24, 31, 32; 23:13, 33; Johannu 17:12.

Dídi Òdodo Jehofa Mú

Láti ìgbà tí a ti mú àṣẹ́kù Israeli tẹ̀mí padà bọ̀ sípò sí ojú rere Jehofa ní 1919, a ti túbọ̀ ń gbé wọn ga ju ayé tí ó yí wọn ka lọ. Èyí kì í ṣe nítorí ìwà rere wọn, bí kò ṣe nítorí fífínnúfíndọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn òfin àti ọ̀pá ìdiwọ̀n Jehofa. Nítorí ìdí èyí, a ti fa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “awọn àgùtàn mìíràn” Kristi sún mọ́ inú àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Israeli tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin alábàákẹ́gbẹ́pọ̀. (Johannu 10:16) Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń mú ògo àti ọlá wá fún Jehofa nínú ayé kan tí ó jìnnà réré sí ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọrun. Bí ìwé ìròyìn South Africa kan, Personality, ṣe ṣàkíyèsí gan-an ni ó rí: “Ó dà bíi pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń kún fún àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn ànímọ́ búburú.”

Láti di ipò tí a ti gbé ga yìí mú nínú ayé aláìwà-bí-Ọlọ́run, mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ Kristian ní láti gbé ìgbésí ayé mímọ́ tónítóní, àti adúróṣánṣán níwájú Jehofa. Nínú Bibeli, a fi àwọn ohun mímọ́ tónítóní ṣàpèjúwe ètò àjọ Jehofa lókè ọ̀run. A rí i gẹ́gẹ́ bí arẹwà obìnrin tí a fi oòrùn ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, tí òṣùpá sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. (Ìṣípayá 12:1) A ṣàpèjúwe Jerusalemu Tuntun gẹ́gẹ́ bí ìlú ńlá mímọ́, tí ìrísí rẹ̀ rẹwà. (Ìṣípayá 21:2) A fún àwọn olùṣòtítọ́ mẹ́ḿbà ìyàwó Kristi ní “aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, títàn yòyò, tí ó mọ́.” (Ìṣípayá 19:8) A rí àwọn tí wọ́n jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá tí “wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà funfun.” (Ìṣípayá 7:9) A ń fa àwọn ènìyàn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí òdodo sún mọ́ ètò àjọ kan tí ó mọ́ tónítóní. Ní òdì kejì pátápátá, ètò àjọ Satani jẹ́ aláìmọ́. A ṣàpèjúwe ètò ìgbékalẹ̀ ìsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó, a sì ṣàpèjúwe àwọn tí ó wà lóde ìlú ńlá mímọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀bùn, aláìmọ́.—Ìṣípayá 17:1; 22:15.

A ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn olódodo. Àwọn ìjọ ènìyàn tí ń di òdodo Jehofa mú ní ìfojúsọ́nà líla òpin ètò ìgbékalẹ̀ burúkú yìí já. Ọlọrun ṣèlérí ní Owe 1:33 pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fetí sí mi yóò máa gbé láìléwu, yóò sì fara balẹ̀ kúrò nínú ìbẹ̀rù ibi.”

Ẹ wo bí yóò ti múni lórí yá tó nígbà tí Solomoni Títóbi Lọ́lá Jù, Kristi Jesu, bá ń ṣàkóso lórí ayé tuntun ní òdodo, nínú ìbẹ̀rù Jehofa! (2 Peteru 3:13) Yóò dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, nígbà tí oòrùn ń tàn yòò, òwúrọ̀ kan tí ó mọ́ kedere. Gbogbo olùgbé ilẹ̀ ayé yóò máa gbé láìléwu, olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ igi àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kí a sọ ọ́ lọ́nà àpèjúwe. Àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn olódodo yóò bẹwà kún ilẹ̀ ayé, wọ́n yóò sì gba àyè tí ó yẹ wọ́n ní àgbáálá ayé sí ògo àìnípẹ̀kun Ọlọrun wa, Jehofa.—Mika 4:3, 4; tún wo Isaiah 65:17-19, 25.

[Picture Credit Line on page 26]

Garo Nalbandian

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́