Wọ́n Pé Jọ Gẹ́gẹ́ Bí Onídùnnú-ayọ̀ Olùyìn
APÀṢẸ fún àwọn ènìyàn Jehofa Ọlọrun ní ìgbàanì láti “ṣáà máa kún fún ìdùnnú-ayọ̀” nígbà tí wọ́n bá pé jọ fún ìjọsìn. (Deuteronomi 16:15, NW) Dájúdájú, àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti 1995 sí 1996 ti mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìdí rere láti kún fún ìdùnnú-ayọ̀.
Láti ìgbà tí ọ̀wọ́ àwọn àpéjọpọ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ti gbé ìgbàgbọ́ ró. Wọ́n tún ti fi bí a ṣe lè rí ayọ̀ nínú ayé aláìláyọ̀ hàn. Ẹ jẹ́ kí a gbé àpéjọpọ̀ náà yẹ̀ wò ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
‘Ẹ Yin Jehofa, Ẹ̀yin Ènìyàn . . . Ẹ Kún fún Ìdùnnú-Ayọ̀!’
Ẹṣin ọ̀rọ̀ òkè yí fún ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọpọ̀ náà ni a gbé karí Orin Dafidi 149:1, 2 (NW). Àsọyé náà, “A Ní Ìdí Láti Ké Jáde fún Ìdùnnú-Ayọ̀,” ṣàyẹ̀wò ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ inú Isaiah orí 35. Ó ní ìmúṣẹ ní Israeli ìgbàanì àti ní pàtàkì, ní ọjọ́ wa, pẹ̀lú mímú àwọn olùjọsìn Jehofa padà bọ̀ sípò aásìkí àti ìlera nínú paradise tẹ̀mí. Nípa báyìí, àwọn olùpéjọpọ̀ ní ìdí láti ké jáde fún ìdùnnú-ayọ̀ lórí ohun tí Ọlọrun ti pète fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú paradise tẹ̀mí àti nínú Paradise tí ó ṣeé fojú rí tí ó sún mọ́lé.
Lájorí ọ̀rọ̀ àsọyé, “A Yà Wọ́n Sọ́tọ̀ Gédégbé Gẹ́gẹ́ Bí Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn Kárí Ayé,” dáhùn ìbéèrè náà pé: Kí ni ó yà wá sọ́tọ̀ gédégbé kúrò lára ayé yìí? Ìjọsìn onísopọ̀ṣọ̀kan wa sí Jehofa ni. Láìka ibi yòówù tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń gbé lórí ilẹ̀ ayé sí, wọ́n ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì ń kọ́ni ní ìfohùnsọ̀kan. Wọ́n tún ń yọ̀ nínú ète kíkọyọyọ Jehofa láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ àti láti dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀. Ṣùgbọ́n, báwo ni Jehofa ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ipò kan nínú ète rẹ̀? Ó ti fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀ sí ìkáwọ́ wa. Ọlọrun ti fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ó ti fi ẹgbẹ́ ará kárí ayé àti ètò fún ìjọsìn mímọ́ gaara jíǹkí wa. Ìdílé wa kárí ayé ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ sin Jehofa pẹ̀lú ọkàn-àyà onídùnnú-ayọ̀ ńláǹlà.
“Yíya Ara Wa Sọ́tọ̀ Kí Á Sì Wà Láìní Èérí Kúrò Nínú Ayé” tẹnu mọ́ àìgbọdọ̀máṣe náà láti yẹra fún èérí ojúsàájú àti kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́. (Jakọbu 2:5-9) Àwọn kan lè máa bá kìkì àwọn tí ipò àtilẹ̀wá tàbí ipò ìṣúnná owó wọn bára mu ṣọ̀rẹ́, kí wọ́n sì máa pa àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n tòṣì tàbí tí wọn kò rí já jẹ tì. Àwọn mìíràn lè máa fẹ́ láti ṣojú rere sí àwọn tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Wọ́n gbàgbé pé àǹfààní títóbi jù lọ tí ẹnikẹ́ni lè ní ni, jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jehofa. Nítorí náà, a kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àwọn ìtẹ̀sí ti ayé kó èérí bá wa, kí ó sì ba àlàáfíà ìjọ jẹ́.—2 Peteru 3:14.
Àsọyé náà, “Mo Ha Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó Bí?” tọ́ka sí i pé, ọ̀pọ̀ ń kánjú kó wọnú ìgbéyàwó. Àwọn kan ń gbéyàwó láti lè bọ́ lọ́wọ́ ipò líle koko nílé tàbí nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ wọn ń gbéyàwó. Ṣùgbọ́n, àwọn ìdí fífẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbígbéyàwó wé mọ́ ìfẹ́ ọkàn àjùmọ̀ní láti lépa àwọn góńgó ti ìṣàkóso Ọlọrun, ojúlówó ìfẹ́, fífẹ́ alájùmọ̀ṣepọ̀ àti ààbò, àti ìfẹ́ ọkàn láti ní àwọn ọmọ. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí ṣe pàtàkì ní mímúra ìgbéyàwó sílẹ̀. Ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, a ní láti mú àwọn ànímọ́ dídára dàgbà nípa gbígbé àkópọ̀ ìwà tuntun nì wọ̀. Ó tún bọ́gbọ́n mu láti rí i dájú bóyá ẹni tí a ń wọ̀nà láti jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀ náà ń fi ẹ̀rí níní ìbáṣepọ̀ gidi pẹ̀lú Jehofa hàn àti pé ó ń bá àwọn mìíràn lò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ó tún bọ́gbọ́n mu láti wá ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristian tí ó dàgbà dénú.—Owe 11:14.
Àsọyé tí ó tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ alanilóye yìí ni a pe àkọlé rẹ̀ ní “Àwọn Òbí Tí Ń Rí Ìdùnnú Nínú Àwọn Ọmọ Wọn.” Ìgbà tí a bí ọmọ kan sábà máa ń jẹ́ àkókò ìdùnnú ńláǹlà. Ṣùgbọ́n, bíbí ọmọ tún máa ń mú ẹrù iṣẹ́ ńláǹlà wá. (Orin Dafidi 127:3) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a kọ́ àwọn ọmọ láti nífẹ̀ẹ́ Jehofa. Àwọn òbí lè ṣe èyí nípa sísọ̀rọ̀ déédéé nípa Jehofa fún àwọn ọmọ wọn àti nípa fífi àwọn ìlànà Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò nínú ìdílé.
Àpéjọpọ̀ ọjọ́ àkọ́kọ́ parí pẹ̀lú ìyàlẹ́nu—ìmújáde ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Jehovah’s Witnesses and Education. Ó ṣàlàyé ní kedere pé, àwọn Ẹlẹ́rìí “ń fún àwọn ọ̀dọ́ wọn níṣìírí láti ṣiṣẹ́ kára àti láti mú iṣẹ́ àyànfúnni wọn ní ilé ẹ̀kọ́ lọ́kùn-únkúndùn.” Ìtẹ̀jáde yìí tún ṣàlàyé ìyọrísí àgbàyanu tí kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti darí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ní Nigeria, Mexico àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní. Ìwé pẹlẹbẹ náà yẹ kí ó ran àwọn olùkọ́ lọ́wọ́ láti rí i pé a fi ojú pàtàkì wo ìmọ̀ ẹ̀kọ́.
“Máa Rú Ẹbọ Ìyìn sí Ọlọrun Nígbà Gbogbo”
Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a mẹ́nu kàn yí fún ọjọ́ kejì ni a gbé karí Heberu 13:15. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ gbé àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé lórí “Jíjẹ́ Ìpè náà Láti Yin Jehofa” kalẹ̀. Ọjọ́ orí kò gbọdọ̀ ṣe ìdílọ́wọ́ fún dídáhùn ìpè yìí. Orin Dafidi 148:12, 13 rọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin, àwọn wúndíá, àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn ọmọdékùnrin láti yin Jehofa. Ọ̀pọ̀ lára àwọn onídùnnú-ayọ̀, ìránṣẹ́ Jehofa ti lè fi kún ìyìn wọn. Lágbàáyé, èyí tí ó lé ní 600,000 ń nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò wíwàásù lákòókò kíkún tàbí iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Iye tí ó ju 15,000 ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, tí iye tí ó fi púpọ̀púpọ̀ lé ní 15,000 sì ń ṣiṣẹ́ ìsìn Beteli.
“Fífi Ìdúróṣinṣin Ṣiṣẹ́ Sìn Pẹ̀lú Ètò-Àjọ Jehofa” ni àsọyé tí ó fi hàn pé ìdúróṣinṣin ṣe pàtàkì fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun. Láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jehofa túmọ̀ sí dídìrọ̀ mọ́ ọn pẹ̀lú ìfọkànsìn tí ó lágbára, tí ń ṣiṣẹ́ bí àtè lílágbára. Ìdúróṣinṣin béèrè pé kí a yẹra fún mímọ̀ọ́mọ̀ tàpá sí àwọn àṣẹ Bibeli, bóyá àwọn mìíràn rí wa tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó tún béèrè pé kí a fi ìdúróṣinṣin gbé àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli, tí a rí nínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! àti àwọn oúnjẹ tẹ̀mí mìíràn tí Watch Tower Society ń pèsè, lárugẹ. Ìjíròrò batisí ni ó tẹ̀ lé àsọyé yìí. Ẹ wo irú ìdùnnú-ayọ̀ tí ó jẹ́ nígbà tí àwọn olùnàgà fún ìrìbọmi fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Jehofa hàn!
Àwọn ọ̀rọ̀ Hosea 4:1-3 pèsè ìlànà fún àsọyé ti ọ̀sán pé, “Ìwà Funfun Tàbí Ìwà Abèṣe—Èwo Ni Ìwọ Fi Ń Ṣèwàhù?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú ìwòye ayé nípa ìwà funfun ti bàjẹ́, àwọn Kristian ní láti ṣe “ìsapá àfi-taratara-ṣe” láti lépa ìwà híhù tí ó dára. (2 Peteru 1:5) Èyí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú bí ẹnì kan ti ń ronú. Bí ìrònú rẹ̀ bá jẹ́ ti oníwà funfun, yóò sọ̀rọ̀ mímọ́ tónítóní, tí ó gbámúṣé, tí ó sì gbéniró, yóò sì máa làkàkà láti jẹ́ aláìlábòsí nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Lílépa ìwà funfun tún wé mọ́ lílàkàkà láti jẹ́ ẹni tí ó gba tẹni rò àti oníyọ̀ọ́nú sí àwọn Kristian ẹlẹ́gbẹ́ ẹni tí ń jìyà ìrora ọkàn tàbí ìsoríkọ́.—1 Tessalonika 5:14.
Àsọyé mìíràn, “Yẹra fún Àwọn Ìdẹkùn Èṣù,” kìlọ̀ fún àwọn Kristian lòdì sí fífi ara wọn lé agbára ìdarí ẹ̀mí èṣù lọ́wọ́. Ní ti ìtọ́jú àìsàn, àwọn Kristian ní láti wà lójúfò ní ti àwọn ọ̀nà ìgbàṣe, bí i ìmúnimúyè, tí ó ní awo nínú. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe láti tọ́jú ìlera ara wọn jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni.
Ọjọ́ kejì parí pẹ̀lú ìyanu onídùnnú-ayọ̀—ìmújáde ìwé tuntun tí ó ṣeé tì bàpò, tí a ṣe láti ran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú kíákíá láti ṣe ìyàsímímọ́ àti batisí. Ìwé tuntun olójú ewé 192 yìí ni a pè ní Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ìwé Ìmọ̀ gbé òtítọ́ kalẹ̀ ní ọ̀nà tí ń gbéni ró. Kò sọ̀rọ̀ lórí jíjárọ́ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èké. Èdè tí ó ṣe kedere àti ìgbékalẹ̀ tí ó mọ́gbọ́n dání yẹ kí ó mú kí lílo ìwé náà rọrùn láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kí ó sì ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lóye ìmọ̀ amọ́kànyọ̀ nípa Ọlọrun.
“Kí Ẹ̀yin Kí Ó Yọ̀, Kí Inú Yín Kí Ó Sì Dùn Títí Láé”
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti inú Isaiah 65:18 ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ kẹta àpéjọpọ̀ náà. Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli tọ́ka sí 1914 gẹ́gẹ́ bí ọdún náà tí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí wọ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀. Nítorí náà, àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé tí a pè ní “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn ní Òpin Ètò Ìgbékalẹ̀ Yìí” gba àfiyèsí àwọn àwùjọ pátápátá. Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ fi bí ìwọra àti ẹ̀mí oníwà ipá ti ayé ṣe ń nípa lórí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn ènìyàn hàn. Láìpẹ́, a óò dá wọn lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí apá kan ayé tí Satani jẹ́ alákòóso rẹ̀. Nítorí náà, ìsinsìnyí ni àkókò láti ṣe yíyàn. Apá ibo ni a fẹ́ láti wà? Àwá ha fẹ́ láti jọ́sìn Jehofa, kí a sì gbé ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ lárugẹ bí, tàbí àwa yóò ha gba Satani láyè láti jẹ́ alákòóso wa nípa ṣíṣe ohun tí ó dùn mọ́ ọn nínú bí? Gbogbo wa ní láti mú ìdúró wa síhà ọ̀dọ̀ Jehofa láìṣe tàbítàbí.
Àwíyé fún gbogbo ènìyàn ti àpéjọpọ̀ náà, “Ẹ Yin Ọba Ayérayé!” fún gbogbo àwọn tí wọ́n pésẹ̀ ní ohun tí ó gbèrò gidigidi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò nípa ayérayé dà bí ohun tí ó kọjá agbára ìrònú ènìyàn aláìlera, Jehofa lóye rẹ̀ dáradára. Onipsalmu náà sọ pé: “Oluwa ni ọba láé àti láéláé.” (Orin Dafidi 10:16) Ọba ayérayé ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún aráyé láti gbádùn ìwàláàyè ayérayé nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi. (Johannu 17:3) Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá àti ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu.”
Bí àpéjọpọ̀ náà ti ń wá sí ìparí, àsọyé tí ó gbẹ̀yìn, tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Fífi Ìdùnnú-Ayọ̀ Yin Jehofa Láti Ọjọ́ dé Ọjọ́” gbé àwọn tí wọ́n pésẹ̀ ró. Ó jẹ́ ohun amọ́kànyọ̀ láti gbọ́ ìròyìn ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn jákèjádò ayé. A sì sún àwọn olùpéjọpọ̀ láti ‘fi ìbùkún fún Jehofa, kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ títí láéláé.’—Orin Dafidi 145:2.
Ìwà àìlójú àánú tí ó kọ sísọ, kì í jẹ́ kí aráyé ní ìdùnnú-ayọ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jehofa, lè ní ìdùnnú-ayọ̀ oníwà-bí-Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ará kárí ayé, nígbà náà àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè tún àwọn ọ̀rọ̀ inú Orin Dafidi 35:27, 28 tí ó tẹ̀ lé e sọ pé: “Jẹ́ kí wọn kí ó máa hó fún ayọ̀, kí wọn kí ó sì máa ṣe inú dídùn, tí ń ṣe ojú rere sí òdodo mi: lóòótọ́ kí wọn kí ó máa wí títí pé, Oluwa ni kí a máa gbé ga, tí ó ní inú dídùn sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀. Ahọ́n mi yóò sì máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ, àti ti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ìdílé yóò jàǹfààní láti inú ìwé pẹlẹbẹ náà, “Jehovah’s Witnesses and Education”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ìwé tuntun náà, “Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun,” ń pèsè àwọn òtítọ́ Bibeli ní ọ̀nà tí ń gbéni ró
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
A batisí ọ̀pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Jehofa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn olùpéjọpọ̀ ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, “Bíbọlá fún Àwọn Ẹni Yíyẹ ní Ọjọ́ Ogbó Wọn,” wú lórí púpọ̀