Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” Ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa
Ọjọ́ mẹ́ta tí ń mú èrè wá, tí ó kún fún ìtọ́ni Bibeli ń dúró dè ọ́. Pẹ̀lú àwọn àpéjọpọ̀ tí ó lé ní 90 tí a wéwèé fún Nigeria nìkan, ó ṣeé ṣe kí a ṣe ọ̀kan nítòsí ibi tí o ń gbé. Wà níbẹ̀ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin ní agogo 9:20 òwúrọ̀ ọjọ́ Friday.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Friday yóò gbé àwọn ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀ àti lájorí ọ̀rọ̀ àwíyé jáde, “A Yà Wọ́n Sọ́tọ̀ Gédégbé Gẹ́gẹ́ Bí Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn Kárí Ayé.” Ní ọ̀sán, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà darí àfiyèsí sí àwọn ọ̀dọ́, àwọn òbí, àti ẹ̀kọ́ ìwé. “Mo Ha Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó Bí?” jẹ́ ọ̀rọ̀ àwíyé kan tí àwọn ọ̀dọ́ yóò fẹ́ láti gbọ́. Àwọn òbí ní láti tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sí “Àwọn Òbí Tí Ń Rí Ìdùnnú Nínú Àwọn Ọmọ Wọn.” Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán yóò parí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọyé náà “Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́—Lò Ó Láti Fi Yin Jehofa.” Ohun tí a óò jí ròrò ní láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú ní ilé ẹ̀kọ́ lọ́nà tí ó yọrí sí rere.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Saturday yóò gbé ọ̀rọ̀ lórí ìrìbọmi kalẹ̀, a óò sì pèsè àǹfààní fún àwọn wọnnì tí ó bá tóótun láti ṣe ìrìbọmi. Ní ọ̀sán, ìjíròrò tí ó sọ ojú abẹ níkòó yóò wà nípa bí Satani ṣe ń lo ìfẹ́ ọkàn fún ìbálòpọ̀ láti dẹkùn mú àwọn ènìyàn láti ìgbà ìjímìjí. Ọ̀rọ̀ àsọyé lílágbára náà “Yẹra fún Àwọn Ìdẹkùn Èṣù” yóò wà pẹ̀lú. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà yóò parí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwíyé pàtàkì náà “Ìdí Tí Aráyé Fi Nílò Ìmọ̀ Ọlọrun.”
Ní òwúrọ̀ Sunday, àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn ní Òpin Ètò Ìgbékalẹ̀ Yìí” yóò darí àfiyèsí sórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò mi ayé jìgìjìgì, tí ń bẹ níwájú wa gan-an. Yóò nú ẹnu mọ́ ìjẹ́kánjúkánjú sísá lọ sí ibi ààbò, ṣáájú kí “ìpọ́njú ńlá” tí Jesu Kristi sọ tó bẹ̀rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ní Matteu 24:21.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Sunday yóò parí pẹ̀lú àwòkẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì náà “Bíbọlá fún Àwọn Ẹni Yíyẹ ní Ọjọ́ Ogbó Wọn.” Lẹ́yìn náà ní ọ̀sàn, ọ̀rọ̀ àwíyé fún gbogbo ènìyàn, “Ẹ Yin Ọba Ayérayé!” ni a óò gbé kalẹ̀. Yóò jẹ́ kókó pàtàkì tí a óò pe àfiyèsí sí ní àpéjọpọ̀ náà.
Wéwèé nísinsìnyí láti wà níbẹ̀. Láti rí ọ̀gangan àpéjọpọ̀ tí ó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó wà ní àdúgbò rẹ, tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tí ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde. Ìtẹ̀jáde Jí! tí June 8, ti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àdírẹ́sì gbogbo ọ̀gangan àpéjọpọ̀ ní Nigeria, Burkina Faso, Côte d’Ivoire, Ghana, àti Togo. Ní àfikún sí i, ìtẹ̀jáde Jí! ti October 8, ti to àdírẹ́sì gbogbo ọ̀gangan àpéjọpọ̀ ní Nigeria lẹ́sẹẹsẹ.