Ìdí tí O fi Níláti Lọ
ÌWỌ yóò gba ìtọ́ni tẹ̀mí tí ń tẹ́nilọ́rùn fún ọjọ́ mẹ́rin ní àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá,” èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yìí nínú àwọn ìlú-ńlá yíká ayé. Ní Nigeria nìkan, iye tí ó tó mẹ́rìnlélọ́gọ́rin àwọn ìkórajọpọ̀ wọ̀nyí ni a ó ṣe ní November, December, àti January. Ní gbogbogbòò, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Thursday ní agogo kan kọjá ogún ìṣẹ́jú ní ọ̀sán yóò sì parí ní ọjọ́ Sunday ní agogo mẹ́rin kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ìrọ̀lẹ́. Apá pàtàkì ní àwọn àpéjọpọ̀ kan yóò jẹ́ ìròyìn láti ẹnu àwọn míṣọ́nárì, tí a ti ràn lọ́wọ́ láti padà sí orílẹ̀-èdè ìbílẹ̀ wọn fún ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ yìí.
Yálà ìwọ jẹ́ àgbàlagbà tàbí ọ̀dọ́—ọkọ, aya, bàbá, ìyá, ọ̀dọ́langba, tàbí ọmọdé—ìwọ yóò gba ẹ̀kọ́ tí a gbékalẹ̀ ní kedere, ní ọ̀nà tí ó fanimọ́ra tí yóò ṣàǹfààní fún ọ. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ lónìí ń béèrè pé, Kí ni ète ìgbésí-ayé? Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Friday, ìwọ yóò gbádùn gbígbọ́ ìjíròrò ìbéèrè yìí inú rẹ yóò sì dùn fún ohun tí ìwọ yóò rí gbà láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti lóye kókó-ẹ̀kọ́ náà.
Ní ọ̀sán ọjọ́ Friday ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò ṣe ìgbéjáde àwọn apá náà “Mimu Ki Igbeyawo Jẹ́ Isopọṣọkan Pipẹtiti,” “Ṣiṣẹ Kára fun Igbala Agbo-ile Rẹ,” ati “Ẹyin Òbí—Awọn Ọmọ Yin Nilo Afiyesi Akanṣe.” Tẹ̀lé ìwọ̀nyí gẹ́lẹ́, àfiyèsí pàtó ni a óò kójọ sórí àwọn ìṣòro tí àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn ń dojúkọ àti bí wọn ṣe lè yanjú wọn. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ òde-òní tí a fún ni àkọlé náà Awọn Èwe Ti Wọn Ranti Ẹlẹdaa Wọn Nisinsinyi níláti fún wọn níṣìírí.
Ní ọjọ́ Saturday ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò gbé àsọtẹ́lẹ̀ Jesu lórí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àti ní pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Lójúkan-náà lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọnnì ni oòrùn yóò ṣóòkùn” jáde lákànṣe. (Matteu 24:29) Ìwọ yóò fẹ́ láti gbọ́ ìjíròrò nípa ìgbà tí “ìpọ́njú” yẹn yóò wáyé. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Saturday yóò tún ṣàtúnyẹ̀wò àkọsílẹ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àkókò òde-òní yóò sì fi ohun tí wọ́n ti ṣàṣeparí rẹ̀ hàn.
Ní ọjọ́ Sunday àwòkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn, tí a fún ni àkọlé náà Maṣe Jẹ Ki A Tàn Ọ́ Jẹ́ Ma Sì Ṣe Gan Ọlọrun, yóò bójútó ìpèníjà sí ìwàtítọ́ ẹni gẹ́gẹ́ bíi Kristian nítorí àwọn fídíò àti orin gbígbajúmọ̀ òde-òní. Àwíyé fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀sán yóò gbé ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Ẹkọ Ti O Kun fun Iranlọwọ fun Awọn Akoko Lilekoko Wa” jáde lákànṣe. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò parí pẹ̀lú ìgbaniníyànjú náà “Ẹ Maa Baa Lọ Ní Dídìrọ̀ Mọ Ẹkọ Atọrunwa.”
Dájúdájú, ìwọ yóò jàǹfààní láti inú wíwàníbẹ̀ fún gbogbo ọjọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin! A fi tọ̀yàyà-tọ̀yàyà késí ọ láti wá. Láti rí ọ̀gangan ibi tí ó súnmọ́ ilé rẹ jùlọ, wádìí ní Gbọ̀ngàn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àdúgbò tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn òǹṣèwé ìwé-ìròyìn yìí tàbí kí o wonú ìtẹ̀jáde June 1 ti Ilé-Ìṣọ́nà, èyí tí yóò ní gbogbo àwọn ọ̀gangan àpéjọpọ̀ ní Nigeria nínú.