‘Mo Ha Já Mọ́ Nǹkan Kan Lójú Ọlọrun Bí?’
“MO HA Já Mọ́ Nǹkan Kan Bí? Ọlọrun Ha Bìkítà Bí?” Báyìí ni àkọlé ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ kan tí ó jẹyọ nínú ìwé ìròyìn Christianity Today ṣe kà. Philip Yancey, tí ó kọ ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà, sọ pé: “Ìṣòro ìrora ni kókó ọ̀rọ̀ ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àgbéṣe mi gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé. Mo máa ń padà nígbà gbogbo sórí ìbéèrè kan náà, bí ẹni ń dẹ egbò tí kò tí ì jiná tán. Mo máa ń gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn òǹkàwé mi, àwọn làásìgbò ìtàn wọn sì máa ń fìdí iyè méjì mi múlẹ̀.”
Bóyá ìwọ pẹ̀lú ti ṣe kàyéfì nípa ọkàn-ìfẹ́ Ọlọrun nínú ìgbésí ayé rẹ. O lè mọ Johannu 3:16 dáradára, tí ó sọ pé “Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni.” Tàbí o lè ti ka Matteu 20:28, tí ó sọ pé Jesu wá láti “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kan ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” Síbẹ̀ o lè béèrè pé, ‘Ọlọrun ha kà mí sí bí? Ó ha bìkítà nípa mi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan bí?’ Ìdí rere wà láti gbà gbọ́ pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a óò ti rí i.