A Nílò Àwọn Ọ̀rẹ́ Tòótọ́
JENNY àti Sue ń ní ìjíròrò amóríyá. Wọ́n ń bú sẹ́rìn-ín músẹ́, ojú wọn ń dán—gbogbo ìṣesí wọn fi hàn pé wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ sí ohun tí ẹnì kejì ní láti sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò àtilẹ̀wá wọn yàtọ̀ síra, ó dájú pé ohun kan náà ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọkàn sí, wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ara wọn.
Níbòmíràn, Eric àti Dennis ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lórí iṣẹ́ ìdáwọ́lé kan, ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ irú rẹ̀ tí wọ́n ti ṣe ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Ara wọ́n balẹ̀, ẹ̀rín sì ń bọ́. Bí ìjíròrò náà ti ń yí padà sí àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì, wọ́n fi pẹ̀lú òótọ́ inú sọ èrò wọn fún ara wọn. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Bíi Jenny àti Sue, Eric àti Dennis jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́.
Àwọn àpèjúwe yìí lè mú inú rẹ dùn, ní mímú kí o ronú nípa àwọn ọ̀rẹ́ tìrẹ. Ní òdì kejì, wọ́n lè mú kí o yánhànhàn fún irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìwọ pẹ̀lú lè ní wọn!
Ìdí Tí A Fi Nílò Àwọn Ọ̀rẹ́ Tòótọ́
Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ jíjọjú ṣe pàtàkì fún ire wa nípa ti èrò orí àti nípa ti ara. Ṣùgbọ́n, nígbà tí a bá nímọ̀lára ìdánìkanwà, èyí kò túmọ̀ sí pé nǹkan rọ́ lù wá. Àwọn oníwàádìí kan sọ pé ìdánìkanwà jẹ́ ebi, tí ń tọ́ka sí i lọ́nà ti ẹ̀dá pé a nílò ìbákẹ́gbẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, gan-an gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ ṣe ń mú ebi lọ sílẹ̀ tàbí mú un kúrò, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí ó tọ́ lè mú kí ìdánìkanwà rọlẹ̀, tàbí kí ó tilẹ̀ pa á rẹ́ pátápátá. Síwájú sí i, níní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí wọ́n mọrírì wa kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe.
A dá ẹ̀dá ènìyàn láti nílò ìbákẹ́gbẹ́. (Genesisi 2:18) Bibeli sọ pé ọ̀rẹ́ tòótọ́, tàbí alábàákẹ́gbẹ́, “ni a bí fún ìgbà ìpọ́njú.” (Owe 17:17) Nítorí náà, ó yẹ kí àwọn ojúlówó ọ̀rẹ́ lè béèrè fún ìrànlọ́wọ́ lọ́wọ́ ara wọn lẹ́nì kíní-kejì nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìbádọ́rẹ̀ẹ́ túmọ̀ sí ju kìkì níní ẹnì kan tí a lè yíjú sí tàbí jíjẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ nínú iṣẹ́ tàbí eré lọ. Àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà máa ń mú àwọn ànímọ́ dídára dàgbà nínú ẹnì kíní-kejì. Owe 27:17 sọ pé: “Irin a máa pọ́n irin: bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin ń pọ́n ojú ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Bí a ṣe lè lo irin láti pọ́n idà tí a fi irú mẹ́tàlì kan náà ṣe, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rẹ́ kan lè ṣàṣeyọrí ní pípọ́n ipò ìrònúmòye àti ipò tẹ̀mí ọ̀rẹ́ mìíràn. Bí ìjákulẹ̀ bá mú ọ sorí kọ́, ojú àánú, àti ìṣírí tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ kan, lè gbéni ró púpọ̀.
Nínú Bibeli, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ni a so pọ̀ mọ́ ìfẹ́, dídi ojúlùmọ̀ ẹni, ìfinútánni, àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀. Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ lè kan àwọn aládùúgbò, àwọn alájọṣiṣẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn mìíràn tún máa ń ka àwọn ìbátan kan mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn wọn jù lọ. Ṣùgbọ́n, fún ọ̀pọ̀ jù lọ lónìí, ó ṣòro láti rí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ àti láti máa bá a lọ. Èé ṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? O ha lè gbádùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́ pípẹ́ títí bí?