ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/1 ojú ìwé 6-8
  • Ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí Lọ́nà Yíyẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí Lọ́nà Yíyẹ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lọ́nà Yíyẹ—Báwo?
  • A Nílò Ìfòyemọ̀
  • Ìdí Tí A Fi Ń Lọ Síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kí Ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Túmọ̀ Sí Fún Ọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Idi Ti Ounjẹ Alẹ́ Oluwa Fi Ní Itumọ Fun Ọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Báwo Ni Wọ́n Ṣe Ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/1 ojú ìwé 6-8

Ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí Lọ́nà Yíyẹ

ÌRỌ̀LẸ́ Nisan 14, ọdún 33 ti Sànmánì Tiwa, ni Jesu dá Ìṣe Ìrántí sílẹ̀.a Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ṣíṣe ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá pẹ̀lú àwọn aposteli rẹ̀ 12 ni, nítorí náà, ọjọ́ náà dá wa lójú. Lẹ́yìn tí ó ti ní kí afinihàn náà, Judasi máa lọ, Jesu “mú ìṣù búrẹ́dì kan, ó súre, ó bù ú ó sì fi í fún wọn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà á, èyí túmọ̀ sí ara mi.’ Bí ó sì ti mú ife, ó dúpẹ́ ó sì fi í fún wọn, gbogbo wọ́n sì mu ninu rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé: ‘Èyí túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” mi, tí a óò tú jáde nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.’”—Marku 14:22-24.

Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa ṣayẹyẹ ikú rẹ̀ nítorí ìjẹ́pàtàkì rẹ̀. (Luku 22:19; 1 Korinti 11:23-26) Ẹbọ tirẹ̀ nìkan ni ó lè ra ìran ènìyàn padà kúrò nínú ègún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí a ti jogún. (Romu 5:12; 6:23) Búrẹ́dì àti wáìnì tí ó lò jẹ́ àmì ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ pípé. Ní mímọ ọjọ́ náà gan-an, a lè ṣayẹyẹ ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ọjọ tí ó ṣe déédéé pẹ̀lú rẹ̀ ní ọdọọdún, gan-an bí a ti ń ṣe ní ti Àjọ Ìrékọjá àwọn Júù. Ṣùgbọ́n a ní láti ṣe é lọ́nà yíyẹ. Èé ṣe?

Aposteli Paulu sọ pé àwọn tí wọ́n ń jẹ nínú búrẹ́dì àti wáìnì ìṣàpẹẹrẹ náà, “ń pòkìkí ikú Oluwa, títí oun yoo fi dé.” (1 Korinti 11:26) Nípa báyìí, ayẹyẹ náà yóò darí àfiyèsí sí ikú Jesu àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún aráyé. Ayẹyẹ náà yóò jẹ́ àkókó pàtàkì, àkókò tí ó yẹ kí a ronú lórí àwọn ìwà rere Ọlọrun àti lórí ìmọrírì tí ó yẹ kí á ní fún Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀. (Romu 5:8; Titu 2:14; 1 Johannu 4:9, 10) Nítorí náà, Paulu kìlọ̀ pé: “Nitori naa ẹni yòówù tí ó bá jẹ ìṣù búrẹ́dì naa tabi mu ife Oluwa láìyẹ yoo jẹ̀bi nipa ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa.”—1 Korinti 11:27.

Lọ́nà Yíyẹ—Báwo?

Dájúdájú, kì yóò dùn mọ́ Ọlọrun nínú bí a bá sọ ayẹyẹ náà di aláìmọ́, nípa lílọ́wọ́ nínú àwọn ìṣe tí ó gbé ìbéèrè dìde, tàbí nípa títẹ́wọ́ gba àwọn àṣà kèfèrí. (Jakọbu 1:27; 4:3, 4) Èyí yóò fagi lé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ olókìkí ìgbà Easter. Ní títẹ̀lé ìtọ́ni Jesu láti “máa ṣe èyí ní ìrántí [rẹ̀],” a ní láti ṣe Ìṣe Ìrántí náà gan-an bí o ti dá a sílẹ̀. (Luku 22:19; 1 Korinti 11:24, 25) Èyí yóò fagi lé àwọn ọ̀ṣọ́ ṣe-ká-rí-mi tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fi kún ayẹyẹ náà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia jẹ́wọ́ pé, “Máàsì òde òní yàtọ̀ gédégbé sí ayẹyẹ ráńpẹ́ tí Kristi àti àwọn Aposteli Rẹ̀ ṣe.” Àti nípa ṣiṣe Máàsì náà nígbà gbogbo, àní lójoojúmọ́ pàápàá, Kiriṣẹ́ńdọ̀mù ti yà bàrá kúrò nínú ohun tí Jesu pète, wọ́n sì ti sọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà di yẹpẹrẹ.

Paulu kọ̀wé sí àwọn Kristian ní Korinti nípa jíjẹ ẹ́ láìyẹ, nítorí pé ìṣòrò kan dìde nínú ìjọ ní ti Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa. Àwọn kan kò bọ̀wọ̀ fún ìjẹ́mímọ́ rẹ̀. Wọ́n ń gbé oúnjẹ alẹ́ wọn dání, wọ́n sì ń jẹ ẹ́ kí ìpàdé náà tó bẹ̀rẹ̀ tàbí nígbà tí ìpàdé náà ń lọ lọ́wọ́. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń jẹ àjẹjù, wọ́n sì ń mu àmuyíràá. Èyí mú kí oorun máa kùn wọ́n, kí agbára ìmòye wọn sì pòkúdu. Nítorí tí wọn kò wà lójúfò ní ti èrò orí àti tẹ̀mí, wọn kò lè “fi òye mọ ara naa,” wọ́n sì tipa báyìí “jẹ̀bi nipa ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa.” Lákòókò kan náà, ebi ń pa àwọn tí wọn kò tí ì jẹ oúnjẹ alẹ́, ọkàn wọ́n sì ń pínyà. Ó dájú pé kò sí ọ̀kankan lára wọn tí ó wà ní ipò tí ó fi lè jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà pẹ̀lú ìmọrírì àti mímọ ìjẹ́pàtàkì ayẹyẹ náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́—pé ayẹyẹ náà jẹ́ ní ìrántí ikú Oluwa. Èyí yọrí sí ìdájọ́ lòdì sí wọn, nítorí pé wọn kò bọ̀wọ̀ fún un, àní wọ́n tilẹ̀ fojú tẹ́ḿbẹ́lú rẹ̀ pàápàá.—1 Korinti 11:27-34.

A Nílò Ìfòyemọ̀

Àwọn kan ti jẹ lára àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí, ṣùgbọ́n, tí wọ́n wá rí í lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé, kò yẹ kí àwọn ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn tí wọ́n ń fẹ̀tọ́ jẹ lára àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí ni Ọlọrun ti yàn, wọ́n sì ní ẹ̀rí ẹ̀mí Ọlọrun ní ti èyí. (Romu 8:15-17; 2 Korinti 1:21, 22) Kì í ṣe dídé orí èrò ara wọn tàbí ìpinnu ara wọn ni ó mú wọn yẹ. Ọlọrun ti fi òté lé iye àwọn tí yóò ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní àwọn ọ̀run sí 144,000, iye tí ó kéré níye ní ìfiwéra pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n ń jàǹfààní ìràpadà Kristi. (Ìṣípayá 14:1, 3) Yíyàn náà bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Jesu, nítorí ìdí èyí, lónìí, díẹ̀ ni àwọn tí wọ́n ń jẹ ẹ́. Bí ikú sì ti ń mú àwọn kan nínú wọn lọ, iye wọn ní láti máa dín kù.

Èé ṣe tí ẹnì kan fi lè jẹ àwọn ohun àmì náà láìyẹ? Ó lè jẹ́ nítorí ojú ìwòye tí ó ní tẹ́lẹ̀ nípa ìsìn—pé gbogbo àwọn olùṣòtítọ́ ní ń lọ sí ọ̀run. Tàbí ó lè jẹ́ nítorí ìlépa àṣeyọrí tàbí ìmọtara-ẹni-nìkan—ìmọ̀lára pé ẹnì kan yẹ ju ẹlòmíràn lọ—àti ìfẹ́ ọkàn fún ìyọrí-ọlá. Bóyá ó jẹ́ ìyọrísí èrò ìmọ̀lára tí ó lágbára tí ń jẹ yọ láti ara ìṣòro líle koko tàbí ọ̀ràn ìbànújẹ́ ni ó mú kí ẹnì kan sọ ọkàn-ìfẹ́ nù nínú ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé. Ó tún lè jẹ́ nítorí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹnì kan tí ó ní ìpè ti ọ̀run. Gbogbo wá ní láti rántí pé, Ọlọrun nìkan ni ó ni ipinnu náà, kì í ṣe tiwa. (Romu 9:16) Nítorí náà, bí ẹnì kan, “lẹ́yìn ìyẹ̀wò fínnífínní,” bá rí i pé ní ti gidi, kò yẹ kí òún máa jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà, ó ní láti jáwọ́ nínú rẹ̀ nísinsìnyí.—1 Korinti 11:28.

Ìrètí ìyè ayérayé nínú paradise kan lórí ilẹ̀ ayé ni Ọlọrun fi lọ ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé. Ìyẹn jẹ́ ìbùkún tí ó ga lọ́lá láti fojú sọ́nà fún, àti èyí tí ó lè tètè fà wá mọ́ra. (Genesisi 1:28; Orin Dafidi 37:9, 11) Àwọn olùṣòtítọ́ yóò tún wà pa pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wọn tí wọ́n jí dìde, wọn yóò sì pàdé àwọn olódodo ẹni àtijọ́ bí Abrahamu, Sara, Mose, Rahabu, Dafidi, àti Johannu Olùbatisí—tí gbogbo wọ́n kú ṣáájú kí Jesu tó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìwàláàyè ti ọ̀run.—Matteu 11:11; fi wé 1 Korinti 15:20-23.

Àwọn tí wọ́n ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé ń ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa lọ́nà yíyẹ nípa pípésẹ̀ tí wọ́n ń pésẹ̀ àti fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fiyè sílẹ̀, àní bí wọn kò tilẹ̀ jẹ nínú búrẹ́dì àti wáìnì náà. Àwọn pẹ̀lú ń jàǹfààní nínú ẹbọ Kristi, èyí tí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìdúró rere níwájú Ọlọrun. (Ìṣípayá 7:14, 15) Bí wọ́n ti ń tẹ́tí sílẹ̀ sí àwíyé tí a ń sọ, a ń fún ìmọrírì wọn fún àwọn ohun mímọ́ lókun, ìfẹ́ ọkàn wọn láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọrun níbi gbogbo sì ń dàgbà sí i.

Ní ọdún yìí, lẹ́yìn tí oòrun bá wọ̀ ní Tuesday, April 2, a óò ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ni èyí tí ó ju 78,000 ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kárí ayé. Ìwọ yóò ha wà níbẹ̀ bí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọjọ́ àwọn Júù máa ń bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́. Ní ìbámu pẹ̀lú kàlẹ́ńdà wa, Nisan 14 yẹn jẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìrọ̀lẹ́ Thursday, March 31, títí di ìgbà tí oòrun bá wọ̀ ní ìrọ̀lẹ́ Friday, April 1. A dá Ìṣe Ìrántí sílẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ Thursday, ikú Jesu sì ṣẹlẹ̀ ní ọ̀sán Friday ní ọjọ́ kan náà ti àwọn Júù. A jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, ní kùtùkùtù òwúrọ̀ Sunday.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lẹ́ẹ̀kan lọ́dún

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́