ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/15 ojú ìwé 3-4
  • Ìròyìn Búburú TÍ Ń Pọ̀ Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìròyìn Búburú TÍ Ń Pọ̀ Sí I
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Pọ̀ Jàra Jálẹ̀ Ìtàn
  • Ìgasókè ní Àwọn Ọdún Àìpẹ́ Yìí
  • Ìròyìn Rere Ń Bẹ Níwájú!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Ìhìn Rere”!
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • ‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Bawo Ni Ihinrere naa Ṣe Lè Ṣanfaani fun Ọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/15 ojú ìwé 3-4

Ìròyìn Búburú TÍ Ń Pọ̀ Sí I

ÌWỌ́ ha ti fìgbà kankan ṣàkíyèsí pé àwọn àkọlé ẹ̀yìn ìwé ìròyìn tí ń polongo ìròyìn búburú túbọ̀ ń ru ọkàn-ìfẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé sókè ju ti àwọn tí ń gbé ìròyìn rere jáde lọ? Yálà àkọlé ẹ̀yìn ìwé ìròyìn tí ń sọ nípa ìjàm̀bá ti ìṣẹ̀dá tàbí àwọn òfófó arùmọ̀lárasókè kan tí a tẹ̀ gàdàgbà sẹ́yìn ìwé ìròyìn kan tí ó fani mọ́ra, ó dà bíi pé ìròyìn búburú tà ju ìròyìn rere lọ.

Lónìí, ìròyìn búburú pọ̀ rẹpẹtẹ. Ṣùgbọ́n, nígbà míràn, ẹnì kan lè ṣe kàyéfì bóyá ìròyìn búburú ni a dá àwọn akọ̀ròyìn àti oníròyìn lẹ́kọ̀ọ́ láti máa wá kiri, kí wọ́n sì máa hú jáde—kí wọ́n sì pa ìròyìn rere tì.

Ó Pọ̀ Jàra Jálẹ̀ Ìtàn

Ní tòótọ́, ìròyìn búburú pọ̀ jàra jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, ó sì tẹ̀wọ̀n ju ìròyìn rere èyíkéyìí lọ. Nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìtàn, òṣùwọ̀n náà fì sọ́dọ̀ ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn, ìjákulẹ̀, àti àìnírètí, èyí tí ó jẹ́ ìpín aráyé.

Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò. Ìwé náà, Chronicle of the World, tí Jacques Legrand hùmọ̀ rẹ̀, gbé onírúurú ìtàn kalẹ̀, tí a kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ kan pàtó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó wá dà bíi pé oníròyìn òde òní kan ní ń ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Láti inú àwọn ìròyìn tí a ṣe ìwádìí rẹ̀ jinlẹ̀ yìí, a ní ojú ìwòye tí ó ṣàǹfààní nípa ìtànkálẹ̀ ìròyìn búburú tí ènìyàn ti gbọ́ jálẹ̀ àkókò oníhílàhílo tí ó fi wà níhìn-ín lórí pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, gbé ìròyìn ìjímìjí yìí láti ilẹ̀ Gíríìkì ni ọdún 429 ṣáájú Sànmánì Tiwa yẹ̀ wò. Ó ń ròyìn nípa ogun tí ó jà nígbà náà láàárín Ateni àti Sparta pé: “A fipá mú ìpínlẹ̀ Potidaea láti túúbá fún àwọn ará Ateni tí wọ́n sàga tì í lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ ọ́ di ilẹ̀ elébi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àwọn ènìyàn rẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ òkú wọn.” Ẹ wo irú ìròyìn búburú tí ìyẹ́n jẹ́!

Tí a bá sún síwájú sí ọ̀rúndún kìíní ṣáájú Sànmánì Tiwa, a rí ìròyìn tí ó ṣe kedere nípa ikú Julius Caesar, tí ó ṣẹlẹ̀ ní Romu, ní March 15, ọdún 44 ṣáájú ìbí Kristi. “A ti dìtẹ̀ pa Julius Caesar. Àwùjọ àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan tí àwọn kan lára wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ̀ ni ó gún un pa, bí ó ṣe ń jókòó ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà lónìí, Ọjọ́ Kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù March.”

Ní àwọn ọ̀rúndún tí ó tẹ̀ lé e, ìròyìn búburú túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àpẹẹrẹ kan tí ó múni ta gìrì ni ìròyìn yìí láti Mexico ní ọdún 1487: “Nínú ìṣàfihàn ìrúbọ tí ó jẹ́ agbàfiyèsí jù lọ tí a tí ì rí rí ní olú ìlú Aztec, Tenochtitlan, a yọ 20,000 ọkàn-àyà ènìyàn jáde tí a sì fi rúbọ sí Huitzilopochtli, ọlọrun ogun.”

Kì í ṣe kìkì pé ìwà ìkà ènìyàn ti mú ìròyìn búburú wá nìkan ni, ṣùgbọ́n àìbìkítà rẹ̀ ti fi kún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń mú ìròyìn búburú náà wá. Iná ajólala tí ó jó ní London dà bí ọ̀kan nínú irú ìjàm̀bá bẹ́ẹ̀. Ìròyìn láti London, England, tí a kọ ní September 5, 1666, kà pé: “Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin gbáko, alákòóso York tí ó kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi wá pẹ̀lú ẹ̀tù ìbọn tí wọ́n fi fọ́ àwọn ilé tí wọ́n wà lójú ibi tí èéfín iná náà ń gbà ti pa iná London náà. Nǹkan bíi 400 éékà [160 hẹ́kítà] ilẹ̀ tí ó ní ṣọ́ọ̀ṣì 87 àti ilé tí ó lé ní 13,000 ni iná ti jó run. Ó yani lẹ́nu pé, ẹ̀mí mẹ́sàn-án péré ni ó ṣègbé.”

A gbọ́dọ̀ fi ìròyìn búburú àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí wọ́n ti jà káàkiri ọ̀pọ̀ kọ́ńtínẹ́ǹtì kún àwọn àpẹẹrẹ yìí—fún àpẹẹrẹ, àjàkálẹ̀ àrùn onígbáméjì ti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1830. Àkọlé ìròyìn kan tí a tẹ̀ jáde kà pé: “Àǹjọ̀nnú àrùn onígbáméjì kọ lu Europe.” Ìròyìn tí ó ṣeé gbára lé tí ó tẹ̀ lé e ṣàpèjúwe ìròyìn búburú ní ọ̀nà tí ó páni láyà jù lọ: “Àrùn onígbàméjì, tí a kò mọ̀ ní Europe títí di ọdún 1817, ti ń tàn lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn láti Asia. Ní báyìí, apá púpọ̀ lára àwọn olùgbé àwọn ìlú ńlá Rọ́ṣíà irú bíi Moscow àti St. Petersburg ti run—ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n fara gbá a ní ìlú ńlá náà jẹ́ òtòṣì.”

Ìgasókè ní Àwọn Ọdún Àìpẹ́ Yìí

Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn búburú ti jẹ́ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ti gidi jálẹ̀ àkọsílẹ̀ ìtàn, àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí nínú ọ̀rúndún ogún yìí fúnni ní ẹ̀rí pé ìròyìn búburú ń peléke sí i, ní tòótọ́, ó ń pọ̀ sí i lọ́nà yíyá kánkán.

Kò sí iyè méjì pé, ìròyìn ogun ni ìròyìn búburú jù lọ tí a tí ì gbọ́ ní ọ̀rúndún wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Dájúdájú, nínú ogun méjì tí ó burú jù lọ nínú ìtàn—tí a pè ní Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ogun Àgbáyé Kejì bí ó ti yẹ—ni ìròyìn búburú ti wáyé ní ìwọ̀n kan tí ń dáyà foni. Ṣùgbọ́n, ìyẹ́n wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ìròyìn búburú tí ọ̀rúndún aláìláyọ̀ yìí ti mú wá.

Ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ nínú àwọn àkọlé ìwé ìròyìn tí a wulẹ̀ ṣà yàn:

September 1, 1923: Ìmìtìtì ilẹ̀ run Tokyo pátápátá—300,000 ènìyàn bá a rìn; September 20, 1931: Yánpọnyánrin—Ilẹ̀ Britain ba owó pọ́ùn jẹ́; June 25, 1950: Àríwá Korea gbógun ti Gúsù Korea; October 26, 1956: Àwọn ará Hungary dìde ogun sí ìṣàkóso ilẹ̀ Soviet; November 22, 1963: A yìnbọn pa John Kennedy ní Dallas; August 21, 1968: A fi àwọn àgbá ọta ilẹ̀ Rọ́ṣíà ránṣẹ́ láti pa ìṣàkóso Prague lẹ́nu mọ́; September 12, 1970: A fọ́ ọkọ̀ òfuurufú tí a já gbà túútúú nínú aṣálẹ̀; December 25, 1974: Ìjì Líle Tracy run Darwin—ènìyàn 66 gbẹ́mìí mì; April 17, 1975: Cambodia ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Kọ́múníìsì; November 18, 1978: Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìṣekúpara-ẹni ní Guyana; October 31, 1984: A yìnbọn pa Ìyáàfin Gandhi; January 28, 1986: Ọkọ̀ gbalasa òfuurufú gbiná nígbà tí ó fẹ́ gbéra; April 26, 1986: Ẹ̀rọ tí ń darí agbára átọ́míìkì ti Soviet gbiná; October 19, 1987: Ọjà ìdókòwò bà jẹ́; March 25, 1989: Epo rọ̀bì tí ó tú sórí òkun kó ìdààmú bá Alaska; June 4, 1989: Àwọn ọmọ ogun pa àwọn afẹ̀hónúhàn ní Gbàgede Tiananmen.

Bẹ́ẹ̀ ni, ìtàn fi hàn pé ìròyìn búburú ti máa ń fìgbà gbogbo pọ̀, tí ìròyìn rere sì ṣọ̀wọ́n ní ìfiwéra. Bí ìròyìn búburú ṣe ń pọ̀ sí i ní àwọn ọ̀rúndún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, ìròyìn rere ti dín kù bí ọdún ti ń gorí ọdún.

Èé ṣe tí èyí fi ní láti rí bẹ́ẹ̀? Yóò ha máa fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀ bí?

Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò dáhùn àwọn ìbéèrè méjì wọ̀nyí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

WHO/League of Red Cross

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́