ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/15 ojú ìwé 5-7
  • Ìròyìn Rere Ń Bẹ Níwájú!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìròyìn Rere Ń Bẹ Níwájú!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Okùnfà Gbogbo Ìròyìn Búburú
  • Èé Ṣe Tí Ìròyìn Búburú Fi Ń Pọ̀ Sí I?
  • Kì Yóò Máa Fìgbà Gbogbo Rí Bẹ́ẹ̀
  • Ìròyìn Búburú TÍ Ń Pọ̀ Sí I
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Ìhìn Rere”!
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Iṣọtẹ ni Ilẹ Akoso Ẹmi
    Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
  • Àwọn Olùṣàkóso Ní Ilẹ̀-Àkóso Ẹ̀mí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/15 ojú ìwé 5-7

Ìròyìn Rere Ń Bẹ Níwájú!

GBOGBO wa ni ọkàn wa máa ń bà jẹ́ nígbà tí a bá gbọ́ ìròyìn búburú kan tí ó kàn wá. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, inú wá máa ń dùn nígbà tí a bá gba ìròyìn rere—ìròyìn ayọ̀ fún ara wa àti fún àwọn olólùfẹ́ wa. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìròyìn búburú bá dé bá àwọn ẹlòmíràn tí kò sì dé bá wa, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn máa ń fẹ́ rí fìn-ín ìdí kókò; àwọn kan tilẹ̀ ń gbádùn gbígbọ́ nípa òfò àwọn ẹlòmíràn. Èyí lè ṣàlàyé ìdí tí ìròyìn búburú kì í fi í kùtà rárá!

Ní àkókò tí Ogun Àgbáyé Kejì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a rí àpẹẹrẹ ṣíṣe kedere nípa ọkàn-ìfẹ́ bíbani lẹ́rù tí àwọn kan ní nínú àjálù. Ọkọ̀ ogun ojú omi oní 10,000 tọ́ọ̀nù, Graf Spee, ni ohun tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Germany fi ń yangàn ní ọdún 1939. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, ọkọ̀ ogun ojú omi yìí ti ń dá wàhálà púpọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn àkànṣe ọkọ̀ ojú omi Onígbèjà ní Gúúsù Àtìláńtíìkì àti Agbami Òkun India. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ọkọ̀ ojú omi ayára-bí-àṣá mẹ́ta tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ Britain dá Graf Spee lọ́nà, wọ́n sì kọ lù ú, èyí tí ó yọrí sí òfò ẹ̀mí àti fífipá mú ọkọ̀ ojú omi náà láti forí lé èbúté Uruguay ti Montevideo fún àtúnṣe. Ìjọba Uruguay pàṣẹ kí ọkọ̀ ogun ojú omi náà padà sí orí òkun kíá mọ́sá, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ òun kì yóò jẹ́ kí ó lọ mọ́. Nítorí náà, ó dà bíi pé ìjà rírorò rọ̀ dẹ̀dẹ̀ dípò ìjà tí ilẹ̀ Britain rò pé òun yóò borí.

Nígbà tí wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́rọ̀ oníṣòwò ní United States háyà ọkọ̀ òfuurufú kan, tí ó ná ẹnì kọ̀ọ̀kan ní 2,500 dọ́là, láti lọ sí Uruguay láti lọ wo ìjà tí ẹ̀jẹ̀ ti ń ṣàn náà. Sí ìjákulẹ̀ wọn, ìjà náà kò ṣẹlẹ̀. Adolf Hitler pàṣẹ pé kí a lu ihò sí ara Graf Spee. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òǹwòran tí wọ́n pé jọ sí èbúté náà, tí wọ́n ń retí láti wòran ìjà rírorò lórí òkun rí, wọ́n sì gbọ́ ìbúgbàù tí ó lè dini létí, tí ó ri Graf Spee, tí àwọn atukọ̀ náà fúnra wọn lu ihò sí. Ọ̀gákọ̀ náà yin ọta ìbọn kan lu ara rẹ lágbárí, ó sì pa ara rẹ̀.

Láìka ìwà akópayàbáni tí àwọn kan ní sí, ọ̀pọ̀ jù lọ yóò gbà pé àwọ́n fẹ́ràn ìròyìn rere ju ìròyìn búburú lọ. Ìwọ kò ha ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ bí? Nígbà náà, èé ṣe tí ìtàn fi ní àkọsílẹ̀ ìròyìn búburú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí ó sì wá ní àkọsílẹ̀ ìròyìn rere díẹ̀? Ipò náà ha lè yí padà bí?

Àwọn Okùnfà Gbogbo Ìròyìn Búburú

Bibeli sọ nípa àkókò náà nígbà tí ó jẹ́ pé ìròyìn rere nìkan ni ó wà. A kò mọ ìròyìn búburú, a kò gbọ́ ọ rí. Nígbà tí Jehofa Ọlọrun parí àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀, pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé ti wà ní sẹpẹ́ fún ènìyàn àti ẹranko láti gbádùn. Àkọsílẹ̀ Genesisi sọ fún wa pé: “Ọlọrun sì rí ohun gbogbo tí ó dá, sì kíyè sí i, dáradára ni.”—Genesisi 1:31.

Àìsí ìròyìn búburú kò wà pẹ́ lẹ́yìn dídá ènìyàn. Ṣáájú kí Adamu àti Efa tó bí ọmọ kankan, a ròyìn ìròyìn búburú nípa ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun àti ìṣètò àgbáyé ohun rere rẹ̀. Ọmọkùnrin ẹ̀mí onípò gíga kan di ọ̀dàlẹ̀ sí ipò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, ó sì kẹ́sẹ járí nínú sísún tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ láti dara pọ̀ nínú ipa ọ̀nà ìṣọ̀tẹ̀, ọ̀dàlẹ̀ rẹ̀.—Genesisi 3:1-6.

Àkókò yẹn ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìròyìn búburú tí aráyé rí bẹ̀rẹ̀. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, ìdìtẹ̀, ẹ̀tàn, irọ́, èké, àti irọ́ díẹ̀ òun òtítọ́ díẹ̀ ti fara hàn lọ́nà títayọ nínú àwọn ìròyìn búburú tí ó ti gba ayé kan láti ìgbà náà wá. Jesu Kristi di ẹ̀bi náà ru Satani Èṣù gẹ́gẹ́ bí olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìròyìn búburú, ní sísọ fún àwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ Rẹ̀ pé: “Lati ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ lati ṣe awọn ìfẹ́-ọkàn baba yín. Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin ninu òtítọ́, nitori pé òtítọ́ kò sí ninu rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹlu ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nitori pé oun jẹ́ òpùrọ́ ati baba irọ́.”—Johannu 8:44.

Bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ìròyìn búburú ń pọ̀ sí i. Àmọ́ ṣáá o, èyí kò túmọ̀ sí pé kò sí àkókò ìdùnnú àti ayọ̀, nítorí ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan wà nínú ìgbésí ayé tí wọ́n jẹ́ orísun ìdùnnú. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ wàhálà àti ìbànújẹ́ ti wà jálẹ̀ gbogbo ìran aráyé títí di ìsinsìnyí.

Ìdí mìíràn tí ó fara sin wà fún ipò bíbani nínú jẹ́ yìí. Ìyẹn ni ìtẹ̀sí àjogúnbá wa síhà ìwà àìtọ́ àti àjálù. Jehofa fúnra rẹ̀ mọ ìdí tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ yìí fún ìròyìn búburú ní sísọ pé: “Ìrò ọkàn ènìyàn ibi ni láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”—Genesisi 8:21.

Èé Ṣe Tí Ìròyìn Búburú Fi Ń Pọ̀ Sí I?

Bí ó ti wù kí ó rí, ìdí wà tí ìròyìn búburú fi ń pọ̀ sí i ní ọ̀rúndún ogún yìí. A sọ ìdí yìí ní kedere nínú Bibeli, èyí tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé aráyé ní ọ̀rúndún ogún yóò wọnú sáà aláìlẹ́gbẹ́ tí a mọ̀ sí “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” tàbí “ìgbà ìkẹyìn.” (2 Timoteu 3:1; Danieli 12:4) Àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bibeli fi “sáà òpin” yìí hàn, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1914. Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹ̀rí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu nípa èyí, jọ̀wọ́ wo orí 11, ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn náà ní láti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò mú kí ìròyìn búburú pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé lójijì. Kí ni ìyẹn? Ó jẹ́ lílé Satani Èṣù àti agbo àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jù sísàlẹ̀ láti ọ̀run. O lè ka àpèjúwe kedere yìí ti ìròyìn búburú tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tí yóò máa peléke sí i ní Ìṣípayá 12:9, 12: “A fi diragoni ńlá naa sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa, ẹni tí a ń pè ní Èṣù ati Satani, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀-ayé, a sì fi awọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹlu rẹ̀. . . . ‘Ègbé ni fún ilẹ̀-ayé ati fún òkun, nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.’”

Nítorí náà, bí àkókò tí ó kù kí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn náà wá sí òpin ti lè kúrú tó, a lè retí pé kí ìròyìn búburú máa bá a nìṣó, àní kí ó máa peléke sí i ní iye àti ìwọ̀n tí ó fi ń ṣẹlẹ̀.

Kì Yóò Máa Fìgbà Gbogbo Rí Bẹ́ẹ̀

Ó mú àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé láyọ̀ pé, ipò òṣì tí ń fa ìròyìn búburú tí ń tàn kálẹ̀ lónìí kì yóò máa bá a lọ títí láé. Ní tòótọ́, a lè sọ pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé, àwọn ọjọ́ ìròyìn búburú tí kò mọ́wọ́ dúró ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. Ìrètí ń bẹ, láìka ohun yòówù tí ipò náà lè jẹ́ sí. Òpin gbogbo ìròyìn búburú kù sí dẹ̀dẹ̀, yóò sì dé dandan nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọrun.

Èyí lè dá wa lójú nítorí pé a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò dé òtéńté rẹ̀ tàbí yóò dópin nígbà tí Ọlọrun bá pa gbogbo okùnfà ìròyìn búburú run, tí ó sì kásẹ̀ rẹ̀ nílẹ̀. Yóò mú ẹ̀dá ènìyàn burúkú tí ń rúná sí gbọ́nmisi-omi-òto kúrò, àwọn tí wọ́n kọ̀ láti yí padà, kí wọ́n sì kúrò nínú ipa ọ̀nà ìwà àìtọ́ wọn. Èyí yóò dé òtéńté rẹ̀ nínú ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olodumare, tí a mọ̀ bí-ẹni-mowó sí ogun Armageddoni. (Ìṣípayá 16:16) Kété lẹ́yìn náà, Satani Èṣù àti ẹgbẹ́ agbo àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kì yóò lè ta pútú mọ́. Ìṣípayá 20:1-3 ṣàpèjúwe dídé Satani, olùpilẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ìròyìn búburú pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì kan tí ń sọ̀kalẹ̀ lati ọ̀run wá pẹlu kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ati ọ̀gbàrà-ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbá diragoni naa mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa, ẹni tí í ṣe Èṣù ati Satani, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó sì fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ naa ó sì tì í ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má baà ṣi awọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́.”

Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amúnijígìrì wọ̀nyí, àkókò ìròyìn rere tí kò ní àfiwé yóò wà fún ilẹ̀ ayé àti àwọn olùgbé rẹ̀. Àwọn olùgbé wọ̀nyí yóò ní nínú àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n la Armageddoni ogun ìkẹyìn náà já àti ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tí a óò jí dìde láti inú oorun ikú nínú ibojì. Ìròyìn rere tí ó dára jù lọ yìí ni a ṣàpèjúwe nínú ìwé tí ó kẹ́yìn Bibeli pé: “Àgọ́ Ọlọrun wà pẹlu aráyé, oun yoo sì máa bá wọn gbé, wọn yoo sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọrun fúnra rẹ̀ yoo sì wà pẹlu wọn. Oun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Ìwọ́ ha lè finú wòye àkókò aláyọ̀ yẹn bí? Ní tòótọ́, ó jẹ́ ọjọ́ ọ̀la ológo ní ibi tí kì yóò ti sí ìròyìn búburú mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìròyìn búburú yóò ti dópin, a kì yóò sì gbúròó rẹ̀ mọ́. Ìròyìn rere yóò gbòde kan nígbà náà, yóò sì wà títí ayérayé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́