ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/15 ojú ìwé 30
  • Ìwọ́ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkojú Ìpènijà Ìdúróṣinṣin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́—Lò Ó Láti Yin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Kíyè Sí Àwọn Adúróṣinṣin!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/15 ojú ìwé 30

Ìwọ́ Ha Rántí Bí?

Àwọn ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ha ràn ọ́ lọ́wọ́ gidigidi bí? Nígbà náà, èé ṣe tí o kò fi àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí dán iyè ìrántí rẹ wò:

◻ Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti inú ìṣubú àwọn ará Ammoni? (Sefaniah 2:9, 10)

Jehofa kì í fi ojú kékeré wo fífi ibi san oore rẹ̀, nígbà tí ó bá sì tó àkókò lójú rẹ̀, yóò tún gbé ìgbésẹ̀, gan-an bí ó ti ṣe ní ìgbàanì. (Fi wé Orin Dafidi 2:6-12.)—12/15, ojú ìwé 10.

◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn Kristian fi ní àlàáfíà?

Èkíní, wọ́n ní “àlàáfíà pẹlu Ọlọrun nípasẹ̀ Oluwa [wọn] Jesu Kristi.” (Romu 5:1) Èkejì, wọ́n ní àlàáfíà láàárín ara wọn nípa mímú “ọgbọ́n tí ó wá lati òkè,” èyí tí ó “kọ́kọ́ mọ́níwà, lẹ́yìn naa [tí] ó lẹ́mìí-àlàáfíà” dàgbà. (Jakọbu 3:17)—1/1, ojú ìwé 11.

◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí a fi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wé, báwo sì ni èyí ṣe ṣèrànwọ́ fún wa?

A fi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wé wàrà tí ń ṣara lóore, oúnjẹ líle, omi tí ń tuni lára tí ó sì ń wẹni mọ́, jígí, àti idà mímú. Lílóye ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí ń ran òjíṣẹ́ kan lọ́wọ́ láti fòye lo Bibeli.—1/1, ojú ìwé 29.

◻ Kí ni ó yẹ kí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti ayé tí ó wà déédéé ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe?

Láti kàwé lọ́nà jíjá gaara, láti kọ̀wé lọ́nà tí ó ṣeé kà, láti dàgbà sókè ni ti èrò orí àti ìwà híhù, àti láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ó wúlò, tí a nílò fún ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àti iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ tí ó gbéṣẹ́.—2/1, ojú ìwé 10.

◻ Ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye wo nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ni a lè rí kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jesu?

A ní láti lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́, kì í ṣe láti mú ògo wá fún ara wa, ṣùgbọ́n láti mú ìyìn wá fún Olùkọ́ gíga lọ́lá jù lọ náà, Jehofa Ọlọrun. (Johannu 7:18)—2/1, ojú ìwé 10.

◻ Kí ni Ìjọba Ọlọrun?

Ìjọba náà jẹ́ ìṣàkóso ti ọ̀run tí Ọlọrun gbé kalẹ̀ láti mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ, láti mú ipa ìdarí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kúrò, kí ó sì mú ipò òdodo padà bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé. (Danieli 2:44; Ìṣípayá 11:15; 12:10)—2/1, ojú ìwé 16.

◻ Báwo ni Bibeli ṣe pèsè ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí a nílò fún mímú ìwà ipá wá sí òpin pátápátá?

Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, Jehofa ń kọ́ àwọn ènìyàn láti jẹ́ ẹni àlàáfíà àti olódodo. (Isaiah 48:17, 18) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní agbára láti dé inú ọkàn-àyà ẹni, kí ó sì gbún un ní kẹ́ṣẹ́, kí ó sì yí ìrònú àti ìwà rẹ̀ padà. (Heberu 4:12)—2/15, ojú ìwé 6.

◻ Ní ọ̀nà wo ni a fi lè sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah orí 35 ní ìmúṣẹ mẹ́ta?

Àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́ nígbà tí àwọn Júù padà láti ìgbèkùn Babiloni ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Ó ní ìmúṣẹ tí ń bá a lọ nípa tẹ̀mí lónìí láti ìgbà ìdásílẹ̀ àwọn Israeli nípa tẹ̀mí kúrò lọ́wọ́ ìgbèkùn Babiloni Ńlá. Yóò sì ní ìmúṣẹ kẹta ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìmúdánilójú tí Bibeli ṣe nípa ìmúpadàbọ̀sípò ipò paradise ní ti gidi lórí ilẹ̀ ayé. (Orin Dafidi 37:10, 11; Ìṣípayá 21:4, 5)—2/15, ojú ìwé 17.

◻ Báwo ni ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni tí Ọlọrun ní nínú ẹ̀dá ènìyàn ṣe hàn nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu, ṣe?

Níwọ̀n bí Jesu “kò” ti “lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bíkòṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe,” lọ́nà tí ó fi ìmọ̀lára hàn, ìyọ́nú rẹ̀ ṣàpèjúwe àníyàn Jehofa fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Johannu 5:19)—3/1, ojú ìwé 5.

◻ Kí ni ọ̀rọ̀ Jesu náà “ibojì ìrántí” tí a lò nínú Johannu 5:28, 29 dọ́gbọ́n túmọ̀ sí?

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà mne·mei’on (ibojì ìrántí) tí a lò níhìn-ín túmọ̀ sí pé Jehofa rántí àkọsílẹ̀ nípa ẹni náà tí ó ti kú, títí kan àwọn ìwà ànímọ́ tí ó jogún àti iyè ìrántí rẹ̀ látòkèdélẹ̀. Èyí fi ẹ̀rí lílágbára hàn pé Ọlọrun bìkítà nípa ẹ̀dá ènìyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan!—3/1, ojú ìwé 6.

◻ Ìhìn iṣẹ́ ìkìlọ̀ wo nínú àsọtẹ́lẹ̀ Sefaniah ni ó jẹ́ ìrànlọ́wọ́ gbígbéṣẹ́ fún wa?

Ìsinsìnyí kọ́ ni àkókò láti jẹ́ kí iyè méjì ta gbòǹgbò nínú ọkàn wa, kí a sì máa sún dídé ọjọ́ Jehofa síwájú nínú ọkàn wa. Bákan náà, a ní láti wà lójúfò lòdì sí jíjẹ́ kí ìdágunlá sọ wá di aláìlágbára. (Sefaniah 1:12, 13; 3:8)—3/1, ojú ìwé 17.

◻ Èé ṣe tí ìdúróṣinṣin sí Ọlọrun fi gbé ìpènijà ka iwájú wa?

Nítorí pé ìdúróṣinṣin forí gbárí pẹ̀lú ìtẹ̀sí ìmọtara-ẹni-nìkan tí a ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa. (Genesisi 8:21; Romu 7:19) Ní ọ̀nà tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì jù lọ, Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti pinnu láti mú wa jẹ́ aláìdúróṣinṣin sí Ọlọrun. (Efesu 6:12; 1 Peteru 5:8)—3/15, ojú ìwé 10.

◻ Ní àwọn ọ̀nà mẹ́rin wo ni a lè gbà kojú ìpènijà ìdúróṣinṣin, kí sì ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

Àwọn ọ̀nà mẹ́rin náà ni ìdúróṣinṣin sí Jehofa, sí ètò àjọ rẹ̀, sí ìjọ, àti sí ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó. Ìrànlọ́wọ́ kan ní kíkojú àwọn ìpènijà wọ̀nyí ni mímọ̀ pé kíkojú ìpènijà ìdúróṣinṣin ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jehofa.—3/15, ojú ìwé 20.

◻ Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti inú ìrírí Dafidi ní gbígbìyànjú láti gbé àpótí ẹ̀rí wá sí Jerusalemu? (2 Samueli 6:2-7)

Dafidi kò ka àwọn ìtọ́ni náà tí Jehofa ti fúnni nípa gbígbé Àpótí náà sí, èyí sì mú àjálù wá. Ẹ̀kọ́ náà ni pé a kò gbọdọ̀ dá Jehofa lẹ́bi fún àwọn ìṣòro tí ó jẹ́ ìyọrísí pé a kò ka ìtọ́ni rẹ̀ tí ó ṣe kedere sí. (Owe 19:3)—4/1, ojú ìwé 28, 29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́