ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 5/1 ojú ìwé 3-4
  • Ọlọrun, Orílẹ̀-èdè, àti Ìwọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun, Orílẹ̀-èdè, àti Ìwọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Kristẹndọm Ṣe Di apakan Ayé Yii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsìn Kristian Ìjímìjí àti Orílẹ̀-èdè
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ọlọrun àti Kesari
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì—Ìsìn Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 5/1 ojú ìwé 3-4

Ọlọrun, Orílẹ̀-èdè, àti Ìwọ

“Ṣọ́ọ̀ṣì àti Orílẹ̀-Èdè Fìwo Lùwo Lórí Àbá Nípa Ìkọ̀sílẹ̀ ní Ireland”

ÀKỌLÉ yìí, nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times, ṣàkàwé bí àwọn ènìyàn lónìí ṣe lè dojú kọ yíyàn náà láàárín ohun tí Orílẹ̀-Èdè ń fẹ́ àti ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì ń fi kọ́ni.

Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ní ohun tí kò tó oṣù kan ṣáájú dídá àbá lórí bóyá kí a mú òfin tí ó fi de ìkọ̀sílẹ̀ kúrò, Ireland tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ Roman Kátólíìkì ń nírìírí ìforígbárí gbígbóná janjan láàárín àwọn aṣáájú Ìjọba àti ti ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀.” Orílẹ̀-Èdè pète gbígbẹ́sẹ̀ kúrò lórí kíka ìkọ̀sílẹ̀ léèwọ̀, nígbà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sì ta ko ìkọ̀sílẹ̀ àti títún ìgbéyàwó ṣe. Àwọn Kátólíìkì ará Ireland ní láti yàn láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì àti Orílẹ̀-Èdè. Àbálọ àbábọ̀ rẹ̀ ni pé, Orílẹ̀-Èdè fi díẹ̀ ta ṣọ́ọ̀ṣì yọ.

Lọ́nà tí ó túbọ̀ múni jí gìrì, fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ènìyàn ní Àríwá Ireland ti dojú kọ ìforígbárí gbígbóná janjan ní ti ipò ìdádúró lómìnira orílẹ̀-èdè. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ti pa. Àwọn Roman Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ti ní ojú ìwòye tí ó ta kora lórí Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n ní láti tẹrí ba fún: ṣé ìṣàkóso ilẹ̀ Britain tí ń bá a nìṣó ní Àríwá Ireland ni tàbí ìjọba alágbára àpapọ̀ fún gbogbo ilẹ̀ Ireland.

Lọ́nà kan náà, níbi tí a ń pè ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀, àwọn aláṣẹ tí ń ṣàkóso ti béèrè pé kí àwọn mẹ́ḿbà onírúurú ìsìn, títí kan Kátólíìkì àti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì lọ́wọ́ nínú ìjà fún agbègbè ìpínlẹ̀. Ní ti àwọn aráàlú tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, kí ni ojúṣe wọn àkọ́kọ́? Wọ́n ha ní láti tẹ̀ lé àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọ́n ń ṣojú fún Orílẹ̀-Èdè, tàbí wọ́n ní láti ṣègbọràn sí Ọlọrun, ẹni tí ó sọ pé: “Iwọ kò gbọdọ̀ ṣìkàpànìyàn . . . Iwọ gbọdọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ”?—Romu 13:9.

Ìwọ́ lè rò pé irú ipò yìí kò lè ṣẹlẹ̀ sí ọ. Ṣùgbọ́n ó lè ṣẹlẹ̀ sí ọ. Ní tòótọ́, ó lè kàn ọ́ nísinsìnyí gan-an. Nínú ìwé rẹ̀, The State in the New Testament, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, Oscar Cullmann, sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ìpinnu ìyè òun ikú tí àwọn Kristian òde òní gbọ́dọ̀ ṣe tàbí tí a lè sọ pé kí wọ́n ṣe nínú ipò pípinnilẹ́mìí nígbà tí àwọn ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ bá ń dún kùkùlajà mọ́ wọn.” Ṣùgbọ́n, ó tún sọ nípa “ẹrù iṣẹ́ gidi, tí ó sì ṣe pàtàkì, tí ó kan Kristian kọ̀ọ̀kan—títí kan àwọn Kristian tí ń gbé lábẹ́ ipò tí a fẹnu lásán pè ní ‘èyí tí ó bára dé,’ ‘ti ojoojúmọ́’—láti kojú ìṣòro líle koko tí ó dojú kọ ọ́, kí ó sì wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá, kìkì nítorí pé òún jẹ́ Kristian.”

Nítorí náà, ipò ìbátan láàárín ìsìn àti Orílẹ̀-Èdè ha yẹ kí ó ru ọkàn-ìfẹ́ àwọn Kristian sókè lónìí bí? Dájúdájú, ó yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Láti ìgbà ìjímìjí, àwọn Kristian ti gbìyànjú láti mú ojú ìwòye tí ó wà déédéé nípa àwọn aláṣẹ ayé dàgbà. Orílẹ̀-Èdè Romu dá Aṣáájú wọn, Jesu Kristi, lẹ́jọ́, òun ni ó dá a lẹ́bi, tí ó sì ṣekú pa á. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní láti mú ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristian bá ojúṣe wọn sí Ilẹ̀ Ọba Romu mu. Nítorí náà, àyẹ̀wò ipò ìbátan wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ yóò pèsè ìlànà fún àwọn Kristian lónìí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Tom Haley/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́