Ta ni Ó Tọ́ Kí A Pè ní Rábì?
ÀFÀÌMỌ̀ ni arìnrìn àjò tí kò ronú sún kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀ yóò fi lè dé pápákọ̀ òfuurufú lákòókò. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọlọ́pàá gbìyànjú láti darí ọkọ̀ bí wọ́n ti ń dáàbò bo àwọn aṣọ̀fọ̀ tí ó ju 300,000 tí wọ́n kún àwọn òpópónà Jerúsálẹ́mù fọ́fọ́. Ìwé agbéròyìnjáde The Jerusalem Post pè é ní “ìtọ́wọ̀ọ́rìn ètò ìsìnkú tí ó wà fún kìkì àwọn ààrẹ, àwọn ọba tàbí àwọn alákòóso aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀ ní gbogbogbòò.” Ta ni ì bá ti fa irú ìtújáde ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀, tí ó fa àìlè lọ síwá sẹ́yìn ní olú ìlú Ísírẹ́lì fún ọ̀pọ̀ wákàtí? Rábì kan tí a bọ̀wọ̀ fún ni. Èé ṣe tí ipò rábì fi jèrè irú ọ̀wọ̀ àti ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn Júù? Nígbà wo ni a kọ́kọ́ lo gbólóhùn náà, “rábì”? Ta ni a lò ó fún lọ́nà títọ́?
Mósè Ha Jẹ́ Rábì Bí?
Orúkọ tí a bọ̀wọ̀ fún jù lọ nínú ìsìn àwọn Júù ni Mósè, alárinà májẹ̀mú Òfin ti Ísírẹ́lì. Àwọn Júù onísìn pè é ni “Mósè ‘Rábì wa.’” Ṣùgbọ́n, kò sí ibikíbi nínú Bíbélì tí a ti lo orúkọ oyè náà “Rábì,” fún Mósè. Ní tòótọ́, gbólóhùn náà, “rábì,” kò fa ra hàn rárá nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Nígbà náà, báwo ní àwọn Júù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí tọ́ka sí Mósè lọ́nà yìí?
Ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ẹrù iṣẹ́ àti ọlá àṣẹ láti kọ́ni àti láti ṣàlàyé Òfin ní a fi fún àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì, àwọn àlùfáà ẹ̀yà Léfì. (Léfítíkù 10:8-11; Diutarónómì 24:8; Málákì 2:7) Ṣùgbọ́n, ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, ìyípadà tegbò tigaga bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ lábẹ́lẹ̀ nínú ìsìn àwọn Júù, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí ìrònú àwọn Júù lọ́nà tí kò ṣeé gbàgbé láti ìgbà yẹn wá.
Nípa ìyípadà nípa tẹ̀mí yìí, Daniel Jeremy Silver kọ̀wé nínú A History of Judaism pé: “Ní àkókò [yẹn] ẹgbẹ́ àwọn akọ̀wé àti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí wọn kì í ṣe àlùfáà bẹ̀rẹ̀ sí í pe ẹ̀tọ́ àwọn àlùfáà láti máa dá túmọ̀ Tórà [Òfin Mósè] níjà. Gbogbogbòò fohùn ṣọ̀kan pé àwọn àlùfáà ṣe pàtàkì gẹ́gẹ́ bí olùṣekòkáárí Tẹ́ḿpìlì, ṣùgbọ́n èé ṣe tí ó fi ní láti jẹ́ pé ohun tí wọ́n bá sọ lórí àwọn ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Tórà ni abẹ́ gé?” Àwọn wo ni ó súnná sí pípe ọlá àṣẹ ẹgbẹ́ àlùfáà níjà? Àwùjọ tuntun kan láàárín ìsìn àwọn Júù tí ń jẹ́ Farisí ni. Silver ń bá a nìṣó pé: “Àwọn Farisí gbé gbígbani wọlé sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ wọn karí ìtóótun, kì í ṣe lórí ìbí [ìlà ìran àlùfáà], wọ́n sì mú ẹgbẹ́ tuntun ti àwọn Júù wọnú ipò aṣáájú ìsìn.”
Nígbà tí ó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, a bẹ̀rẹ̀ sí í mọ àwọn olùgboyèjáde ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ Farisí wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, tàbí ọ̀gá, nínú òfin àwọn Júù. Gẹ́gẹ́ bí àmì ọ̀wọ̀, àwọn Júù míràn bẹ̀rẹ̀ sí í pè wọ́n ní “olùkọ́ mi,” tàbí “ọ̀gá mi,” ní èdè Hébérù, rabbi.
Kò sí ohun tí ó lè túbọ̀ fún orúkọ oyè tuntun yìí ní ọlá àṣẹ ju láti lò ó fún ẹni náà tí a kà sí olùkọ́ títóbi lọ́lá jù lọ nínú ìtàn àwọn Júù, Mósè. Ìyọrísí rẹ̀ yóò túbọ̀ dín ìjẹ́pàtàkì lórí ipò àlùfáà kù, nígbà tí yóò máa gbé èrò gbogbogbòò nípa ipò olórí onípa ìdarí tí àwọn Farisí ní, tí ń pọ̀ sí i lárugẹ. Nípa báyìí, ní èyí tí ó lé ní 1,500 ọdún lẹ́yìn ikú rẹ̀, a fún Mósè ní orúkọ náà, “Rábì,” lọ́nà tí ó nípa ìdarí.
Ṣíṣàfarawé Ọ̀gá Náà
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn máa ń lo gbólóhùn náà, “rábì,” (“ọ̀gá mi”) nígbà míràn láti tọ́ka sí àwọn olùkọ́ mìíràn tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún, a sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà fún àwọn olùkọ́ tí wọ́n yọrí ọlá láàárín àwọn Farisí, “àwọn amòye.” Bí ìparun tẹ́ḿpìlì ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa ti mú ọlá àṣẹ ipò àlùfáà wá sí òpin pátápátá, àwọn rábì Farisí di olórí ìsìn àwọn Júù tí a kò bá du ipò. Àìbá wọn du ipò ṣèrànwọ́ fún ìdàgbàsókè irú ẹgbẹ́ awo kan tí àwọn rábì amòye jẹ́ agbátẹrù rẹ̀.
Nígbà tí ó ń jíròrò sáà ìyípadà ti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, Ọ̀jọ̀gbọ́n Dov Zlotnick sọ pé: “‘Àfiyèsí jíjinlẹ̀ tí a fún àwọn Amòye,’ wá ṣe pàtàkì ju ìkẹ́kọ̀ọ́ Tórà.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí í ṣe Júù, Jacob Neusner, ṣàlàyé síwájú sí i pé: “‘Ọmọ ẹ̀yìn fún àwọn amòye’ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ti so ara rẹ̀ mọ́ rábì kan. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ‘Tórà.’ . . . A kì í kẹ́kọ̀ọ́ Tórà nípasẹ̀ òfin, ṣùgbọ́n nípa rírí òfin tí ó ti di apá kan ìwà àti ìṣe àwọn amòye tí ń bẹ̀ láàyè. Wọ́n ń fi òfin kọ́ni nípa ohun tí wọ́n ń ṣe, kì í ṣe kìkì nípa ohun tí wọ́n ń sọ.”
Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Talmud, Adin Steinsaltz, jẹ́rìí sí èyí, ní kíkọ̀wé pé: “Àwọn amòye fúnra wọn sọ pé, ‘A gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ní gbogbogbòò, ẹ̀fẹ̀, tàbí gbólóhùn ṣákálá àwọn amòye.’” Dé àyè wo ní a fi lè fi èyí sílò? Steinsaltz sọ pé: “Àpẹẹrẹ kan tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ lórí èyí jẹ́ ti ọmọ ẹ̀yìn kan tí a ròyìn rẹ̀ pé ó fara pamọ́ sábẹ́ ibùsùn olùkọ́ ńlá rẹ̀ kí ó baà lè mọ bí ó ṣe ń bá ìyàwó rẹ̀ lò pọ̀. Nígbà tí a bi í léèrè lórí òfíntótó rẹ̀, ọmọ ẹ̀yìn kékeré náà dáhùn pé: ‘Tórà ni, ó sì yẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀,’ ìgbésẹ̀ kan tí àwọn rábì àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbà pé ó tọ́.”
Bí a ti tẹnu mọ́ rábì dípò Tórà—kíkẹ́kọ̀ọ́ Tórà nípasẹ̀ rábì—láti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa síwájú, ìsìn àwọn Júù wá di ìsìn rábì. Ẹnì kan lè mọ Ọlọ́run, kì í ṣe nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀ onímìísí, ṣùgbọ́n, nípasẹ̀ ẹnì kan tí ó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, ọ̀gá kan, rábì. Nípa báyìí, ìtẹnumọ́ náà rọra yí láti orí Ìwé Mímọ́ onímìísí sórí òfin àtẹnudẹ́nu àti àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí àwọn rábì wọ̀nyí fi ń kọ́ni. Láti ìgbà náà lọ, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti àwọn Júù, irú bíi Talmud, túbọ̀ gbé àfiyèsí karí ìjíròrò, ìtàn, àti ìhùwàsí àwọn rábì dípò ohun tí Ọlọ́run sọ.
Àwọn Rábì Jálẹ̀ Àwọn Sànmánì
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lo ọlá àṣẹ àti ipa ìdarí gíga lọ́lá, àwọn rábì àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò gbọ́ bùkátà wọn láti inú ìgbòkègbodò ìsìn wọn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé: “Rábì Talmud . . . yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tí ń jẹ́ orúkọ oyè yẹn lónìí. Rábì ti Talmud jẹ́ ògbufọ̀ àti alálàyé Bíbélì àti Òfin Àtẹnudẹ́nu, ó sì sábà máa ń ní iṣẹ́ tí ó fi ń gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Kìkì nígbà Sànmánì Agbedeméjì ni rábì di . . . olùkọ́, oníwàásù, àti olórí nípa tẹ̀mí fún ìjọ tàbí àwùjọ Júù.”
Nígbà tí àwọn rábì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ipò wọn di iṣẹ́ olówó oṣù, àwọn kan ta kò ó. Maimonides, gbajúmọ̀ rábì ọ̀rúndún kejìlá, tí ó fi iṣẹ́ ìṣègùn gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, ta ko irú àwọn rábì bẹ́ẹ̀ pátápátá. “[Wọ́n] béèrè iye owó kan pàtó láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwùjọ, wọ́n sì mú kí àwọn ènìyàn ronú lọ́nà ẹ̀gọ̀ pé, ojúṣe wọn ni àti pé ó tọ́ láti ran àwọn amòye àti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àti àwọn ènìyàn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ Tórà lọ́wọ́ [ní ti ìṣúnná owó], nípa báyìí Tórà wọn ni iṣẹ́ ajé wọn. Ṣùgbọ́n gbogbo èyí lòdì. Kò sí ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo, yálà nínú Tórà tàbí nínú ọ̀rọ̀ àwọn amòye, láti mú un jóòótọ́.” (Commentary on the Mishnah, Avot 4:5) Ṣùgbọ́n àwọn ìran rábì tí ó dé lẹ́yìn náà kò kọbi ara sí àtakò ti Maimonides ṣe.
Bí ìsìn àwọn Júù ti wọnú sànmánì òde òní, ó pín sí àwọn àwùjọ alátùn-únṣe, arọ̀mófin àtọwọ́dọ́wọ́, àti onígbàgbọ́ nínú ìlànà. Fún ọ̀pọ̀ àwọn Júù, ìgbàgbọ́ àti àṣà ìsìn Júù kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì mọ́. Ní ìyọrísí rẹ̀, a jin ipò àwọn rábì lẹ́sẹ̀. Ní pàtàkì, àwọn rábì di olórí ìjọ tí a fi joyè, ní ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amọṣẹ́dunjú olùkọ́ tí a ń sanwó fún, àti olùgbaninímọ̀ràn fún àwọn mẹ́ḿbà àwùjọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n láàárín àwọn aláṣerégèé atẹ̀lé ìlànà ìsìn ti àwùjọ Hasid, èròǹgbà àwọn rábì gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àti àwòfiṣàpẹẹrẹ túbọ̀ ní ìyípadà jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ṣàkíyèsí gbólóhùn Edward Hoffman nínú ìwé rẹ̀ nípa ẹgbẹ́ Chabad-Lubavitch ti ìsìn Hasid pé: “Àwọn onísìn Hasid àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú tẹnu mọ́ ọn pé, nínú ìran kọ̀ọ̀kan, olórí Júù kan ṣoṣo máa ń wà, zaddik [ẹni olódodo], tí ó jẹ́ ‘Mósè’ ìgbà ayé rẹ̀, ẹni tí ìrànwọ́ ẹ̀kọ́, àti ìyọ̀ǹda ara rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn kò ní ọ̀gbà. Nípasẹ̀ ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tí ó ní, àwùjọ kọ̀ọ̀kan ti ìsìn Hasid rò pé, Rebbe [èdè Yiddish fún “rábì”] wọn lè nípa lórí àwọn àṣẹ Olódùmarè pàápàá. Kì í ṣe kìkì pé a bọ̀wọ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí àwòfiṣàpẹẹrẹ nítorí àwọn àwíyé oníṣìípayá rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n ànímọ́ tirẹ̀ gan-an (‘bí ó ṣe ń di okùn bàtà rẹ̀,’ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́) ni a rí i pé ó ń gbé ẹ̀dá ènìyàn lékè, tí ó sì ń fúnni ní àmì ẹlẹgẹ́ nípa ọ̀nà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
“Kí A Má Ṣe Pè Yín Ní Rábì”
Jésù, Júù ọ̀rúndún kìíní tí ó dá ìsìn Kristẹni sílẹ̀, gbé ayé nígbà tí èròǹgbà àwọn Farisí nípa rábì bẹ̀rẹ̀ sí í wọnú ìsìn àwọn Júù. Òun kì í ṣe Farisí, bẹ́ẹ̀ ni a kò dá a lẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ wọn, síbẹ̀, a pe òun pẹ̀lú ní Rábì.—Máàkù 9:5; Jòhánù 1:38; 3:2.
Nígbà tí ó ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìtẹ̀sí láti jẹ́ rábì nínú ìsìn àwọn Júù, Jésù sọ pé: “Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí mú ara wọn jókòó ní ìjókòó Mósè. Wọ́n fẹ́ ibi yíyọrí ọlá jù lọ níbi àwọn oúnjẹ alẹ́ àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù, àti ìkíni ní àwọn ibi ọjà àti kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní Rábì. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.”—Mátíù 23:2, 6-8.
Jésù kìlọ̀ nípa fífi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn àlùfáà àti ọmọ ìjọ tí ń gbèrú nínú ìsìn àwọn Júù. Ó bu ẹnu àtẹ́ lu fífún àwọn ènìyàn ní irú ìyọrí ọlá tí kò tọ́ bẹ́ẹ̀. Ó fi ìgboyà polongo pé: “Ọ̀kan ni olùkọ́ yín.” Ta ni Ẹni yìí?
Mósè, “ẹni tí OLÚWA mọ̀ ní ojúkojú,” tí àwọn amòye fúnra wọn sì pè ní “Rábì wa” jẹ́ ènìyàn aláìpé. Ó ṣe àṣìṣe pàápàá. (Diutarónómì 32:48-51; 34:10; Oníwàásù 7:20) Dípò títẹnu mọ́ Mósè gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ gíga jù lọ, Jèhófà sọ fún un pé: “Èmi óò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàárín àwọn arákùnrin wọn, bí ìwọ; èmi óò sì fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, òun óò sì sọ fún wọn gbogbo èyí tí mo pa láṣẹ. Yóò sì ṣe, ẹni tí kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi tí òun óò máa sọ ní orúkọ mi, èmi óò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”—Diutarónómì 18:18, 19.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fẹ̀rí hàn pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìmúṣẹ wọn nínú Jésù, Mèsáyà náà.a Kì í ṣe kìkì pé Jésù dà “bíi” Mósè nìkan ni; ó tóbi lọ́lá ju Mósè lọ. (Hébérù 3:1-3) Ìwé Mímọ́ fi hàn pé a bí Jésù ní ènìyàn pípé, láìkò sì dà bíi Mósè, ó ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run ‘láìlẹ́ṣẹ̀.’—Hébérù 4:15.
Tẹ̀ Lé Àwòfiṣàpẹẹrẹ Náà
Kíkẹ́kọ̀ọ́ gbogbo ìṣe àti ọ̀rọ̀ rábì jinlẹ̀ kò tí ì mú kí àwọn Júù túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Bí ènìyàn aláìpé tilẹ̀ lè jẹ́ àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin, bí a bá kọ́ gbogbo ìṣe rẹ̀, tí a sì fara wé wọn, a óò fara wé àwọn àṣìṣe àti àìpé rẹ̀ títí kan àwọn ànímọ́ rere rẹ̀ pẹ̀lú. A óò máa fi ògo tí kò tọ́ fún ẹni tí a ṣẹ̀dá dípò Ẹlẹ́dàá.—Róòmù 1:25.
Ṣùgbọ́n Jèhófà pèsè Àwòfiṣàpẹẹrẹ kan fún aráyé. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, Jésù ti wà láàyè ṣááju dídi ẹ̀dá ènìyàn. Ní tòótọ́, a pè é ni “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí, àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣẹ́ sìn nínú ọ̀run fún ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rúndún gẹ́gẹ́ bí “ọ̀gá oníṣẹ́” Ọlọ́run, Jésù wà ní ipò tí ó dára jù lọ láti ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà.—Òwe 8:22-30, NW; Jòhánù 14:9, 10.
Nítorí náà, Pétérù lè kọ̀wé pé: “Kristi . . . jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (Pétérù Kìíní 2:21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni níṣìírí láti máa “fi tọkàntara wo Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù.” Ó tún ṣàlàyé pé “ní inú rẹ̀ ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pamọ́ sí.” (Hébérù 12:2; Kólósè 2:3) Kò sí ènìyàn míràn—kì í tilẹ̀ ṣe Mósè tàbí àwọn rábì amòye—ni ó yẹ fún irú àfiyèsí bẹ́ẹ̀. Bí a bá ní láti fara wé ẹnikẹ́ni pẹ́kípẹ́kí, Jésù ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò nílò orúkọ oyè bíi rábì, ní pàtàkì lójú ìwòye ìtumọ̀ rẹ̀ lóde òní, ṣùgbọ́n bí ó bá yẹ láti pe ẹnikẹ́ni ní Rábì, Jésù ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí ẹ̀rí pé Jésù ni Mèsáyà tí a ṣèlérí, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Will There Ever Be a World Without War?, ojú ìwé 24 sí 30, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
© Brian Hendler 1995. Gbogbo Ẹ̀tọ́ Jẹ́ Tiwa