Mishnah àti Òfin Tí Ọlọ́run fún Mósè
“A BẸ̀RẸ̀ bí ẹni pé a dara pọ̀ mọ́ ìjíròrò kan tí ń lọ lọ́wọ́ nípa kókó kan tí a kò lè lóye láéláé . . . A . . . nímọ̀lára bíi pé a wà nínú ilé èrò pápákọ̀ òfuurufú kan ní ilẹ̀ òkèèrè. A ń gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n fẹ́ sọ gan-an tàbí ohun tí wọ́n ní lọ́kàn, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú tí ó hàn nínú ohùn wọn rú wa lójú.” Bí Júù ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, Jacob Neusner, ṣe ṣàpèjúwe ìmọ̀lára tí àwọn òǹkàwé lè ní nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ ka Mishnah nìyẹn. Neusner fi kún un pé: “Mishnah kò ní ìbẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe gúnmọ́. Ó sì parí lójijì.”
Nínú ìwé A History of Judaism, Daniel Jeremy Silver pe Mishnah ní “lájorí ìwé àwọn rábì ẹlẹ́sìn Júù.” Àní, ó sọ síwájú sí i pé: “Mishnah ni ó rọ́pò Bíbélì gẹ́gẹ́ bíi lájorí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ fún mímú ẹ̀kọ́ [àwọn Júù] tẹ̀ síwájú.” Èé ṣe tí ìwé kan tí a kọ lọ́nà rírúnilójú bẹ́ẹ̀ ṣe wá di ohun pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?
Apá kan ìdáhùn náà wà nínú gbólóhùn yí tí a sọ nínú Mishnah: “Mósè gba Tórà ní Sínáì ó sì fi lé Jóṣúà lọ́wọ́, Jóṣúà fi lé àwọn àgbààgbà lọ́wọ́, àwọn àgbààgbà fi lé àwọn wòlíì lọ́wọ́. Àwọn wòlíì sì fi lé àwọn ọkùnrin àpéjọ ńlá lọ́wọ́.” (Avot 1:1) Mishnah ni a sọ pé ó kún fún ìsọfúnni tí a fi lé Mósè lọ́wọ́ lórí Òkè Sínáì—apá kan nínú Òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì, tí a kò kọ sílẹ̀. A ka àwọn ọkùnrin àpéjọ ńlá (tí a wá ń pè ní Sànhẹ́dírìn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn) sí ara ọ̀wọ́ àwọn ọlọgbọ́n tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀, tàbí àwọn amòye, tí wọ́n fi ẹnu tàtaré àwọn ẹ̀kọ́ kan láti ìran kan sí èkejì títí tí ìwọ̀nyí fi di ohun tí a kọ sínú Mishnah. Ṣùgbọ́n ìyẹn ha jẹ́ òtítọ́ bí? Ta ni o tilẹ̀ kọ Mishnah gan-an, èé sì ti ṣe? Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ha wá láti ọ̀dọ̀ Mósè ní Sínáì bí? Ó ha ní ìtumọ̀ fún wa lónìí bí?
Ẹ̀sìn Àwọn Júù Láìsí Tẹ́ńpìlì
Nígbà tí a ń kọ Ìwé Mímọ́ lábẹ́ ìmísí, a kò mọ ohunkóhun nípa ìgbàgbọ́ nínú òfin àtẹnudẹ́nu tí Ọlọ́run fúnni ní àfikún sí Òfin Mósè tí a kọ sílẹ̀.a (Ẹ́kísódù 34:27) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, àwọn Farisí ni ẹgbẹ́ tí ó pilẹ̀ èròǹgbà yí, tí ó sì gbé e lárugẹ, nínú ẹ̀sìn àwọn Júù. Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àwọn Sadusí àti àwọn Júù míràn ta ko ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu yìí. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù bá ṣì jẹ́ ojúkò fún ìjọsìn àwọn Júù, ọ̀ràn òfin àtẹnudẹ́nu kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Ìjọsìn ní tẹ́ńpìlì mú kí ìgbésí ayé àwọn Júù wà létòlétò kí ó sì nítumọ̀.
Ṣùgbọ́n, ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, orílẹ̀-èdè Júù dojú kọ rògbòdìyàn ìsìn tí ó gadabú. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run, a sì pa iye tí ó lé ní mílíọ̀nù kan àwọn Júù. Tẹ́ńpìlì náà, ojúkò ìgbésí ayé tẹ̀mí wọn, kò sí mọ́. Títẹ̀lé Òfin Mósè, tí ó béèrè fún ẹbọ àti iṣẹ́ àlùfáà ní tẹ́ńpìlì, kò ṣeé ṣe mọ́. Ìpìlẹ̀ ẹ̀sìn àwọn Júù kò sí mọ́. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Talmud, Adin Steinsaltz, kọ̀wé pé: “Ìparun . . . tí ó wáyé ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, ti mú kí ṣíṣe àtúnkọ́ gbogbo ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé wọn ní ti ìsìn di ọ̀ràn kánjúkánjú.” Wọ́n sì tún un kọ ní tòótọ́.
Àní ṣáájú kí a tó pa tẹ́ńpìlì náà run, Yohanan Ben Zakkai, ọmọ ẹ̀yìn olórí àwọn Farisí náà, Hillel, tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi, gba àṣẹ láti ọwọ́ Vespasian (tí ó máa tó di olú ọba) láti gbé ojúkò tẹ̀mí ti ẹ̀sìn àwọn Júù àti Sànhẹ́dírìn kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Yavneh. Gẹ́gẹ́ bí Steinsaltz ti ṣàlàyé, lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù, Yohanan Ben Zakkai “dojú kọ ìpèníjà ti gbígbé ibùdó tuntun mìíràn kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti ti ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ara wọn bá àwọn àyíká ipò tuntun mu, níbi tí a ti ní láti darí ìtara ìsìn sórí ohun mìíràn nísinsìnyí tí kò sí Tẹ́ńpìlì mọ́.” Ohun tuntun tí a darí àfiyèsí sí yẹn ni òfin àtẹnudẹ́nu.
Lẹ́yìn tí tẹ́ńpìlì náà ti di òkìtì àlàpà, àwọn Sadusí àti ẹ̀ya ẹ̀sìn àwọn Júù míràn kò fúnni ní ohun àfidípò tí ó dájú. Àwọn Farisí wá di ògúnná gbòǹgbò láàárín àwọn Júù, ní bíborí àwọn alátakò. Ní títẹnumọ́ ìṣọ̀kan, àwọn òléwájú lára àwọn rábì dẹ́kun pípe ara wọn ní Farisí, ọ̀rọ̀ kan tí ìtumọ̀ rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú àwọn adáyapasílẹ̀ àti agbawèrèmẹ́gbẹ́. A wá mọ̀ wọ́n sí rábì, “àwọn amòye Ísírẹ́lì.” Àwọn amòye wọ̀nyí yóò gbé ẹ̀kọ́ kalẹ̀ láti lè fàyè gba èròǹgbà òfin àtẹnudẹ́nu. Èyí yóò sì di ètò tẹ̀mí tí ogun ẹ̀dá ènìyàn kò lè pa run bí ó ṣe pa tẹ́ńpìlì run.
Fífi Ìdí Òfin Àtẹnudẹ́nu Náà Múlẹ̀
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì tí ó wà ní Yavneh (40 kìlómítà sí ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù) ni ó wá di ojúkò gan-an nísinsìnyí, àwọn ilé ẹ̀kọ́ mìíràn tí a ti ń fi òfin àtẹnudẹ́nu kọ́ni bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ yọ jákèjádò Ísírẹ́lì, àní títí lọ dé Bábílónì àti Róòmù. Àmọ́, èyí dá ìṣòro kan sílẹ̀. Steinsaltz ṣàlàyé pé: “Níwọ̀n bí àwọn amòye bá ṣì wà pa pọ̀, tí ó sì jẹ́ pé àwùjọ àwọn ọkùnrin kan [ní Jerúsálẹ́mù] ni ó ń darí lájorí ètò ẹ̀kọ́, a ṣì lè mú kí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ṣọ̀kan. Ṣùgbọ́n wíwà káàkiri àwọn olùkọ́ àti dídá àwọn ilé ẹ̀kọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sílẹ̀ dá . . . ìlànà tí ó pọ̀ jáǹtìrẹrẹ àti onírúurú ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ sílẹ̀.”
Àwọn olùkọ́ òfin àtẹnudẹ́nu ni a pè ní Tannaim, ọ̀rọ̀ kan tí a mú wá láti inú ọ̀rọ̀ èdè Árámáìkì kan tí ó túmọ̀ sí “láti kẹ́kọ̀ọ́” “láti sọ ní àsọtúnsọ,” tàbí “láti kọ́ni.” Èyí tẹnu mọ́ ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìkọ́ni ní òfin àtẹnudẹ́nu wọn nípa sísọ ọ̀rọ̀ ní àsọtúnsọ léraléra àti híhá ọ̀rọ̀ sórí. Láti lè mú híhá àwọn òfin àtẹnudẹ́nu sórí rọrùn, wọ́n gé òfin tàbí àṣà kọ̀ọ̀kan kúrú sí gbólóhùn ṣókí, tí ó mọ níwọ̀n. Bí àwọn ọ̀rọ̀ náà bá ṣe kúrú tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe rọrùn tó láti há wọn sórí. Wọ́n hùmọ̀ ọ̀nà kan tí ó jọ ti ewì, wọ́n sì máa ń ké e léwì, tàbí kọ ọ́ lórin lọ́pọ̀ ìgbà. Síbẹ̀, àwọn òfin wọ̀nyí kò wà létòlétò, wọ́n sì yàtọ̀ síra láti ọ̀dọ̀ olùkọ́ kan sí èkejì.
Rábì àkọ́kọ́ tí ó hùmọ̀ ọ̀nà pàtó àti ìgbékalẹ̀ kan fún ọ̀pọ̀ onírúurú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ni Akiba ben Joseph (nǹkan bí ọdún 50 sí 135 Sànmánì Tiwa). Nípa rẹ̀, Steinsaltz kọ̀wé pé: “Àwọn alájọgbáyé rẹ̀ fi ìgbòkègbodò rẹ̀ wé iṣẹ́ alágbàṣe kan tí ó lọ sí oko, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í kó ohunkóhun tí ó rí sínú agbọ̀n láìyẹ̀ wọ́n wò, tí ó wá pa dà sílé, tí ó sì to ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Akiba ti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ kókó ẹ̀kọ́ tí kò wà létòlétò, ó sì kó wọn jọ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí.”
Ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa—60 ọdún lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù—Bar Kokhba ṣagbátẹrù ọ̀tẹ̀ kejì lílágbára tí àwọn Júù gbé dìde sí Róòmù. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọ̀tẹ̀ mú ìjábá wá. Akiba àti ọ̀pọ̀ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wà lára àwọn Júù tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn. Ìrètí èyíkéyìí tí àwọn Júù ní láti tún tẹ́ńpìlì náà kọ́ wọmi, bí Olú Ọba Róòmù, Hadrian, ṣe kéde pé wọn kò gbọdọ̀ fẹsẹ̀ tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́, àyàfi ní ọjọ́ àyájọ́ ìparun tẹ́ńpìlì náà.
Àwọn Tannaim tí wọ́n gbé lẹ́yìn Akiba kò rí tẹ́ńpìlì náà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù rí. Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí a ṣètò láti gbà kọ́ àṣà òfin àtẹnudẹ́nu wọn di “tẹ́ńpìlì” wọn, tàbí ojúkò ìjọsìn. Ẹni tí ó kẹ́yìn nínú àwọn Tannaim, Judah ha-Nasi, ni ó tẹ́rí gba iṣẹ́ tí Akiba àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ti fífìdí ètò òfin àtẹnudẹ́nu múlẹ̀.
Ṣíṣe Mishnah
Judah ha-Nasi jẹ́ àtọmọdọ́mọ Hílẹ́lì àti Gàmálíẹ́lì.b A bí i nígbà ìṣọ̀tẹ̀ Bar Kokhba, ó sì di olórí àwùjọ Júù ní Ísírẹ́lì títí di apá ìparí ọ̀rúndún kejì àti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa. Orúkọ oyè náà, ha-Nasi, túmọ̀ sí “ọmọ aládé,” tí ó ń tọ́ka sí ipò rẹ̀ lójú àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. A sábà máa ń pè é ní Rábì. Judah ha-Nasi ni ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ tirẹ̀ àti ti Sànhẹ́dírìn, lákọ̀ọ́kọ́ ní Bet She’arim, lẹ́yìn náà ní Sepphoris ní Gálílì.
Ní mímọ̀ pé ìforígbárí ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú Róòmù lè ṣèdíwọ́ fún títàtaré òfin àtẹnudẹ́nu náà, Judah ha-Nasi pinnu láti fún un ní ètò kan tí kì yóò jẹ́ kí ó run. Ó kó àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí ó ta yọ lọ́lá jù lọ ní ọjọ́ rẹ̀ jọ sí ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n jíròrò lórí kókó àti àṣà òfin àtẹnudẹ́nu kọ̀ọ̀kan. Àkópọ̀ àwọn ìjíròrò wọ̀nyí ni a pa pọ̀ sínú àwọn gbólóhùn tí ó ṣe rẹ́gí lọ́nà tí ó yani lẹ́nu, ní títẹ̀lé ọ̀nà lílekoko ti ewì ọlọ́rọ̀ geere ti èdè Hébérù.
A ṣètò àwọn àkópọ̀ wọ̀nyí sí ìsọ̀rí tàbí Abala mẹ́fà, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àkòrí. Judah tún pín ìwọ̀nyí sí apá tàbí àpilẹ̀kọ 63. Ìṣètò ẹ̀kọ́ tẹ̀mí náà ti parí báyìí. Títí di àkókò yí, àtẹnudẹ́nu ni a ń gbà tàtaré irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n láti túbọ̀ rí i pé kò run, ìgbésẹ̀ ìyípadà tegbò tigaga àṣekẹ́yìn wáyé—ti kíkọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀. Ìwé elétò àkọsílẹ̀ fífanimọ́ra tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, tí ó ní òfin àtẹnudẹ́nu nínú yìí ni a pè ní Mishnah. Orúkọ náà Mishnah wá láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà sha·nahʹ, tí ó túmọ̀ sí “láti sọ ní àsọtúnsọ,” “láti kẹ́kọ̀ọ́,” tàbí “láti kọ́ni.” Ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Árámáìkì náà, tenaʼʹ, tí ọ̀rọ̀ náà, tan·na·ʼimʹ, ti inú rẹ̀ jáde, ọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí àwọn tí ń fi Mishnah kọ́ni.
Kì í ṣe ète Mishnah láti gbé òfin pàtó kalẹ̀. Àwọn àyàfi ni ó pọ̀ jù nínú rẹ̀, ní gbígbà pé òǹkàwé náà mọ àwọn ìlànà ìpìlẹ̀. Ní tòótọ́, ó ṣàkópọ̀ ohun tí a jíròrò, tí a sì fi kọ́ni nínú ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì ní àkókò Judah ha-Nasi. Ète tí a fi ṣe Mishnah ni kí ó lè jẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ òfin àtẹnudẹ́nu fún ìjíròrò síwájú sí i, tàbí ìpìlẹ̀ kan, tí a lè gbé èrò kà.
Kàkà tí yóò fi mú ohunkóhun tí a fún Mósè ní Òkè Sínáì ṣe kedere, Mishnah fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ òfin àtẹnudẹ́nu, èròǹgbà kan tí ó bẹ̀rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn Farisí. Ìsọfúnni tí a kọ sínú Mishnah lani lóye díẹ̀ nípa àwọn gbólóhùn inú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì àti lórí àwọn ìjíròrò kan tí ó wáyé láàárín Jésù Kristi àti àwọn Farisí. Àmọ́, ó gba ìsọ́ra gidigidi, nítorí pé, àwọn èrò tí ó wà nínú Mishnah fi ojú ìwòye àwọn Júù láti ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa hàn. Mishnah ni ó so sáà tẹ́ńpìlì kejì àti ìgbà tí a kọ Talmud pa pọ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àfikún ìsọfúnni, wo ojú ìwé 8-11 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Will There Ever Be a World Without War?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Gàmálíẹ́lì—Ó Kọ́ Sọ́ọ̀lù Ará Tásù Lẹ́kọ̀ọ́,” nínú Ilé Ìṣọ́ ti July 15, 1996.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn Ìsọ̀rí Mishnah
A pín Mishnah sí Abala mẹ́fà. Ìwọ̀nyí ní ìwé kéékèèké tàbí àpilẹ̀kọ 63 nínú, tí a pín sí àwọn àkórí àti mishnayot, tàbí ìpínrọ̀ (kì í ṣe ẹsẹ).
1. Zeraim (Òfin Iṣẹ́ Àgbẹ̀)
Àpilẹ̀kọ wọ̀nyí ní ìjíròrò tí a ṣe nípa àdúrà tí wọ́n ń gbà sórí oúnjẹ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ àgbẹ̀ nínú. Wọ́n tún ní àwọn òfin lórí ìdámẹ́wàá, ìpín àlùfáà, pípèéṣẹ́, àti àwọn ọdún Sábáátì nínú.
2. Moed (Àwọn Ayẹyẹ Mímọ́, Àwọn Àjọyọ̀)
Àwọn àpilẹ̀kọ tí ó wà ní Abala yìí jíròrò àwọn òfin tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Sábáàtì, Ọjọ́ Ètùtù, àti àwọn àjọyọ̀ míràn.
3. Nashim (Àwọn Obìnrin, Òfin Ìgbéyàwó)
Ìwọ̀nyí ni àwọn àpilẹ̀kọ tí ó jíròrò ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀, ẹ̀jẹ́, àwọn Násírì, àti àwọn ọ̀ràn panṣágà tí a fura sí.
4. Nezikin (Ọ̀ràn Gbà-Máà-Bínú àti Òfin Ojúṣe Aráàlú)
Àwọn àpilẹ̀kọ tí ó wà ní Abala yìí kárí kókó ẹ̀kọ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú òfin ojúṣe aráàlú àti ti dúkìá, àwọn kóòtù àti ìyà tí wọ́n lè fi jẹni, iṣẹ́ àwọn Sànhẹ́dírìn, ìbọ̀rìṣà, ìbúra, àti Ìlànà Ìwà Híhù ti Àwọn Àgbà Ìlú (Avot).
5. Kodashim (Ìrúbọ)
Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí jíròrò ìlànà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹranko àti ìrúbọ ọkà àti wíwọn tẹ́ńpìlì.
6. Toharot (Ààtò Ìwẹ̀nùmọ́)
Abala yìí ní àpilẹ̀kọ tí ó jíròrò ààtò ìwẹ̀nùmọ́, wíwẹ̀, wíwẹ ọwọ́, àwọn àrùn awọ ara, àti onírúurú ohun ìdọ̀tí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Mishnah àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì
Mátíù 12:1, 2: “Ní àsìkò yẹn Jésù la àwọn pápá ọkà kọjá ní sábáàtì. Ebi ń pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn erín ọkà jẹ. Ní rírí èyí àwọn Farisí wí fún un pé: ‘Wò ó! Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bófin mu láti ṣe ní sábáàtì.’” Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kò ka ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe léèwọ̀. Ṣùgbọ́n nínú Mishnah a rí àkójọ àwọn ìgbòkègbodò 39 tí àwọn rábì kà léèwọ̀ lọ́jọ́ Sábáàtì.—Shabbat 7:2.
Mátíù 15:3: “Ní ìfèsìpadà [Jésù] wí fún wọn pé: ‘Èé ṣe tí ẹ̀yin pẹ̀lú ń ré kọjá ìlà àṣẹ Ọlọ́run nítorí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín?’” Mishnah jẹ́rìí sí ìṣarasíhùwà yí. (Sanhedrin 11:3) A kà pé: “Rírinkinkin mọ́ [títẹ̀lé] ọ̀rọ̀ àwọn Akọ̀wé ṣe pàtàkì ju [títẹ̀lé] ọ̀rọ̀ Òfin [tí a kọ sílẹ̀] lọ. Bí ènìyàn kan bá sọ pé, ‘Kò pọn dandan láti so àpótí aláwọ mọ́ra’ kí ó baà lè tẹ ọ̀rọ̀ inú Òfin lójú, kò yẹ ní dídálẹ́bi; [ṣùgbọ́n bí ó bá wí pé], ‘Àwọn àpótí aláwọ náà gbọ́dọ̀ ní apá márùn-ún’, kí ó baà lè fi kún ọ̀rọ̀ àwọn Akọ̀wé, ó yẹ ní dídálẹ́bi.”—The Mishnah, láti ọwọ́ Herbert Danby, ojú ìwé 400.
Éfésù 2:14: “Òun [Jésù] ni àlàáfíà wa, ẹni tí ó ṣe àjọ ẹgbẹ́ méjèèjì ní ọ̀kan tí ó sì pa ògiri tí ń bẹ ní àárín run èyí tí ó yà wọ́n nípa.” Mishnah sọ pé: “Àgánrándì onírin (Soreg), tí ó ga ní ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, wà nínú Òkè Tẹ́ńpìlì.” (Middot 2:3) Àwọn Kèfèrí kò gbọ́dọ̀ kọjá ọ̀gangan yìí, kí wọ́n sì wọnú àgbàlá inú lọ́hùn-ún. Ó lè jẹ́ ògiri yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tí ó kọ lẹ́tà sí àwọn ará Éfésù nípa rẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ní ọdún 60 tàbí 61 Sànmánì Tiwa, nígbà tí a kò tí ì wó o lulẹ̀. Ògiri ìṣàpẹẹrẹ náà ni májẹ̀mú Òfin, tí ó ti fìyàtọ̀ sáàárín àwọn Júù àti àwọn Kèfèrí tipẹ́tipẹ́. Ṣùgbọ́n, lórí ìpìlẹ̀ ikú Kristi ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, a wó ògiri náà.