Kí Ni Talmud?
“Láìsí àní-àní, Talmud jẹ́ ọ̀kan lára àwọn lítíréṣọ̀ tí ó gbayì jù lọ nínú ìtàn.” —The Universal Jewish Encyclopedia.
“[Talmud jẹ́] ọ̀kan lára àwọn àṣeyọrí olóye tí ó ga jù lọ tí ènìyàn ṣe, ó jẹ́ ìwé àkọsílẹ̀ tí ó díjú, tí ó kún fọ́fọ́ fún ìmọ̀, tí ó jẹ́ àdììtú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó ti di ẹtì fún àwọn onílàákàyè fún ohun tí ó ju ẹgbẹ̀rúndún kan àti ààbọ̀.”—Jacob Neusner, tí í ṣe Júù ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àti òǹkọ̀wé.
“Talmud ni òpómúléró [ẹ̀sìn àwọn Júù], òun ni igi lẹ́yìn ọgbà fún gbogbo ilé tẹ̀mí àti ti ìmọ̀ ti ìgbésí ayé àwọn Júù.”—Adin Steinsaltz, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Talmud àti rábì.
LÁÌSÍ tàbí-ṣùgbọ́n, Talmud ti ní ipa ńláǹlà lórí àwọn Júù fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Àmọ́ ṣáá o, ní ìyàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn tí a fà yọ lókè yìí, Talmud ni a ti tẹ́, tí a sì pè ní “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òwúsúwusù àti ìdàrúdàpọ̀.” A ti fi í bú pé ó jẹ́ ìwé ọ̀rọ̀ òdì láti ọwọ́ Èṣù. Nípasẹ̀ àṣẹ póòpù, léraléra ni wọ́n tẹ̀ ẹ́ rì, tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé e, kódà tí wọ́n tilẹ̀ sun púpọ̀ rẹ̀ nínú iná ní àwọn ojúde ìlú ní Yúróòpù.
Irú ìwé wo gan-an ni ìwé yìí tí ó ti ru àríyànjiyàn tí ó pọ̀ tó yìí sókè? Kí ni ó mú kí Talmud jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ láàárín ìwé àwọn Júù? Kí ni ìdí tí a fi kọ ọ́? Báwo ni ó ṣe wá ní irú ipa yìí lórí ẹ̀sìn Júù? Ó ha ni ìtumọ̀ fún àwọn tí kì í ṣe Júù bí?
Láàárín 150 ọdún tí ó tẹ̀ lé ìparun tẹ́ńpìlì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ti àwọn rábì amòye jákèjádò Ísírẹ́lì kù gìrì ṣàwárí ìpìlẹ̀ tuntun fún bíbá àṣà Júù nìṣó. Wọ́n ṣe àríyànjiyàn, wọ́n sì wá ṣàkópọ̀ onírúurú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó wà nínú òfin àtẹnudẹ́nu. Ní títẹ̀síwájú láti orí ìpìlẹ̀ yìí, wọ́n gbé àwọn ààlà àti ohun àbéèrèfún tuntun kalẹ̀ fún ẹ̀sìn àwọn Júù, wọ́n pèsè ìtọ́sọ́nà fún ìgbésí ayé ìjẹ́mímọ́ láti ọjọ́ dé ọjọ́ láìsí tẹ́ńpìlì. Ìṣètò tẹ̀mí tuntun yìí ni a lànà sílẹ̀ nínú Mishnah, tí Judah ha-Nasi kó jọ nígbà tí ó máa fi di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa.a
Mishnah dá dúró gedegbe, láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá kí àwọn ìtọ́ka sí Bíbélì dá òun láre. Ọ̀nà tí ó gbà ń jíròrò, àní ọ̀nà tí ó gbà ń sọ Hébérù tirẹ̀ kò ní àfiwé, ó yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Àwọn ìpinnu rábì tí a fà yọ láti inú Mishnah yóò nípa lórí ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àwọn Júù níbi gbogbo. Ní tòótọ́, Jacob Neusner sọ pé: “Mishnah ni ó pèsè àkójọ òfin Ísírẹ́lì. . . . Ó fi dandan gbọ̀n béèrè pé kí o gbà, kí o sì fara mọ́ àwọn òfin tí òun gbé kalẹ̀.”
Ṣùgbọ́n bí ó bá wá ṣẹlẹ̀ ń kọ́, pé àwọn kan gbé ìbéèrè dìde pé ṣé lóòótọ́ ni ọlá àṣẹ àwọn amòye tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ nínú Mishnah tó ọlá àṣẹ ti Ìwé Mímọ́ tí a ṣí payá? Àwọn rábì yóò ní láti fi hàn pé àwọn ẹ̀kọ́ àwọn Tánnáímù (àwọn olùkọ́ òfin tí a sọ lọ́rọ̀ ẹnu) tí a rí nínú Mishnah bá Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù mu rẹ́gí. Yóò wá di dandan láti ṣàlàyé síwájú sí i. Wọ́n nímọ̀lára pé ó yẹ kí wọ́n ṣàlàyé, kí wọ́n sì dá Mishnah láre, kí wọ́n sì fi ẹ̀rí tì í pé inú Òfin tí a fi fún Mósè ní Sínáì ni ó ti pilẹ̀ṣẹ̀. Àwọn rábì nímọ̀lára pé ó pọndandan láti fẹ̀rí hàn pé òfin tí a sọ lọ́rọ̀ ẹnu àti èyí tí a kọ sílẹ̀ ní ìtumọ̀ àti ète kan náà. Nítorí náà, dípò tí ì bá jẹ́ pé ohun tí Mishnah sọ nípa ẹ̀sìn àwọn Júù ni abẹ gé, ó wá di ìpìlẹ̀ tuntun fún ìjíròrò àti àríyànjiyàn nípa ẹ̀sìn.
Ṣíṣe Àkójọ Talmud
Àwọn rábì tí ó tẹ́rí gba ìpèníjà tuntun yìí ni a mọ̀ sí àwọn Àmóráímù—“àwọn olùtúmọ̀,” tàbí “àwọn alálàyé” Mishnah. Ilé ẹ̀kọ́ gíga kọ̀ọ̀kan fi rábì olókìkí kan ṣe olórí. Ìwọ̀n kéréje àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ a máa jíròrò pa pọ̀ jálẹ̀ ọdún. Ṣùgbọ́n àwọn ìpàdé tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni a máa ń ṣe lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, ní oṣù Ádárì àti Élúlì, nígbà tí iṣẹ́ oko ti dín kù, tí yóò sì ṣeé ṣe fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún pàápàá láti pésẹ̀.
Adin Steinsaltz ṣàlàyé pé: “Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ ni ó máa ń ṣe alága, yóò jókòó sórí àga tàbí sórí àwọn ẹní àkànṣe. Orí ìjókòó iwájú tí ó dojú kọ ọ́ ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn yóò jókòó sí, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tàbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ta yọ, ẹ̀yìn gbogbo wọn sì ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ yòókù yóò jókòó sí. . . . Ètò ìjókòó ni a gbé ka ipò tí a là sílẹ̀ kedere [bí olúkúlùkù ti ṣe pàtàkì sí].” A ó ka àkọ́sórí apá kan Mishnah. A óò wá fi èyí wéra pẹ̀lú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ alábàádọ́gba tàbí àfikún tí àwọn Tánnáímù kó jọ ṣùgbọ́n tí kò sí nínú Mishnah. A óò wá bẹ̀rẹ̀ ìfọ́síwẹ́wẹ́. A óò gbé àwọn ìbéèrè dìde, a óò sì tú àwọn àtakò palẹ̀ kí àwọn ẹ̀kọ́ lè bára mu. A óò wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí ó ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹ̀kọ́ rábì.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣètò àwọn ìjíròrò wọ̀nyí, wọ́n máa ń gbóná janjan, nígbà mìíràn wọ́n sì máa ń fa arukutu. Amòye kan tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú Talmud sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ẹ̀ta iná” tí ń ṣẹ́ yọ láti ẹnu àwọn rábì nígbà àríyànjiyàn kan. (Hullin 137b, Talmud ti Babilóníà) Steinsaltz sọ nípa àwọn ìjókòó náà pé: “Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ gíga náà, tàbí amòye tí ń sọ àsọyé lọ́wọ́, yóò gbé ìtumọ̀ ti ara rẹ̀ kalẹ̀ nípa àwọn ìṣòro náà. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí ń bẹ ní ìjókòó yóò bẹ̀rẹ̀ sí da ìbéèrè bò ó lórí ìpìlẹ̀ àwọn orísun mìíràn, èròǹgbà àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ alóhùnsọ́rọ̀, tàbí àwọn ìparí èrò bíbọ́gbọ́nmu tí wọ́n dé. Nígbà mìíràn, àríyànjiyàn náà máa ń ṣe ṣókí gan-an, a sì máa ń fi í mọ sórí ìdáhùn tí ó sọ ojú abẹ níkòó tí ó sì ń fòpin sí iyàn jíjà lórí ìbéèrè pàtó kan. Ní àwọn ìgbà mìíràn, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ yòókù á pèsè àwọn ojútùú mìíràn, àríyànjiyàn ńlá a sì bẹ́ sílẹ̀.” Gbogbo àwọn tí ó wà ní ìjókòó ní àǹfààní láti dá sí i. A ó fi àwọn àríyànjiyàn tí a yanjú ránṣẹ́ sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga yòókù kí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ yòókù lè tún un yẹ̀ wò.
Síbẹ̀, ìpàdé wọ̀nyí kì í kàn ṣe àkókò fún iyàn jíjà olófìn-ín-dé tí kò lópin. Àwọn ọ̀ràn òfin tí ó jẹ mọ́ àwọn àṣẹ àti ìlànà ìgbésí ayé àwọn Júù ni a ń pè ní Hálákà. Ọ̀rọ̀ yìí wá láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà “láti lọ,” ó sì tọ́ka sí ‘ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó yẹ kí èèyàn tọ̀.’ Gbogbo ọ̀ràn yòókù—ìtàn nípa àwọn rábì àti àwọn ènìyàn inú Bíbélì, àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n, èròǹgbà ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí—ni a ń pè ní Hágádà, láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà “láti sọ.” Hálákà àti Hágádà máa ń wọnú ara wọn nígbà àríyànjiyàn àwọn rábì.
Nínú ìwé rẹ̀ The World of the Talmud, Morris Adler ṣàlàyé pé: “Ọlọ́gbọ́n olùkọ́ yóò fòpin sí ìjiyàn olófìn-ín-dé tí kò tán bọ̀rọ̀, tí ó sì ṣòro láti lóye nípa yíyí kókó ọ̀rọ̀ padà sí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ nira, tí ó sì ń gbéni ró. . . . Nípa báyìí, a máa ń rí ìtàn àtẹnudẹ́nu àti ìtàn nípa ìṣẹ̀lẹ̀, sáyẹ́ǹsì òde òní àti ìtàn ìṣẹ̀ǹbáyé, àlàyé àti ìtàn nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ Bíbélì, àwíyé àti ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí a kó pa pọ̀ sínú ohun tí ó lè dà bí dída lúúrú pọ̀ mọ́ ṣàpà, lójú ẹni tí kò mọ ọ̀nà tí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga náà gbà ń ṣiṣẹ́.” Lójú ìwòye àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga wọnnì, gbogbo irú ìpawọ́dà bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún ète kan, ó sì tan mọ́ kókó tí wọ́n ń jíròrò lé lórí. Hálákà àti Hágádà jẹ́ ohun èlò fún gbígbé ìṣètò tuntun tí ń lọ lọ́wọ́ kalẹ̀ nínú àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga àwọn rábì.
Ṣíṣe Àkójọ Talmud Méjì
Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a ṣí lájorí ibùdó àwọn rábì tí ó wà ní Palẹ́sìnì lọ sí Tìbéríà. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga pàtàkì-pàtàkì mìíràn wà ní Sepphoris, Kesaréà, àti Lídà. Ṣùgbọ́n ipò ìṣúnná owó tí ń burú sí i, ipò ìṣèlú tí kò fi gbogbo ìgbà dúró sójú kan, àti níkẹyìn pákáǹleke àti inúnibíni láti ọwọ́ ẹ̀sìn Kristẹni apẹ̀yìndà, ṣokùnfa ṣíṣílọ ní tìtì-rẹrẹ sí lájorí àwùjọ mìíràn tí àwọn Júù ń gbé ní Ìlà Oòrùn—Babilóníà.
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ́ láti Babilóníà lọ sí Palẹ́sìnì láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ àwọn rábì ńlá ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga. Ọ̀kan lára irúfẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ni Abba ben Ibo, tí a tún ń pè ní Abba Arika—Abba ẹni gíga—ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe a kàn ń pè é ní Rab. Ó padà dé sí Babilóníà ní nǹkan bí ọdún 219 Sànmánì Tiwa lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ Judah ha-Nasi, èyí sì jẹ́ àkókò mánigbàgbé fún ìjẹ́pàtàkì nípa tẹ̀mí ti àwùjọ àwọn Júù tí ó wà ní Babilóníà. Rab dá ilé ẹ̀kọ́ gíga kan sílẹ̀ ní Sura, àgbègbè kan tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù wà, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní ìwọ̀nba àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ díẹ̀. Òkìkí rẹ̀ fa 1,200 àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ́ra, àwọn tí ń wá déédéé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀, pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún púpọ̀ sí i tí ń wá ní oṣù Ádárì àti Élúlì ti àwọn Júù. Samuel, tí í ṣe gbajúmọ̀ alájọgbáyé Rab, dá ilé ẹ̀kọ́ gíga kan sílẹ̀ ní Nehardea. A dá àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga mìíràn tí ó ṣe pàtàkì sílẹ̀ ní Pumbeditha àti Mehoza.
Wàyí o, kò pọndandan láti rìnrìn àjò lọ sí Palẹ́sínì, nítorí pé èèyàn lè kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ àwọn àgbà ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní Babilóníà. Gbígbé Mishnah kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó yàtọ̀ ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìdádúró gedegbe àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tí ó wà ní Babilóníà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú àṣà àti ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ wá gbèrú ní Palẹ́sínì àti Babilóníà, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ àti pàṣípààrọ̀ àwọn olùkọ́ nígbà gbogbo dáàbò bo ìṣọ̀kan àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga náà.
Ní apá ìparí ọ̀rúndún kẹrin àti ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkarùn-ún ti Sànmánì Tiwa, ipò nǹkan wá le gan-an fún àwọn Júù tí ń bẹ ní Palẹ́sínì. Ọ̀pọ̀ ìkálọ́wọ́kò àti inúnibíni lábẹ́ ọlá àṣẹ tí ń dìde bọ̀ ti Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà yọrí sí ìkọlù ìkẹyìn ti fífòpin sí Sànhẹ́dírìn àti ipò Nasi (baba ńlá) nígbà tí ó máa fi di nǹkan bí ọdún 425 Sànmánì Tiwa. Nítorí náà, láti lè rí i dájú pé a dáàbò bo àwọn lájorí kókó inú àwọn àríyànjiyàn wọnnì tí ó wáyé ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga, àwọn Ámóráímù ti Palẹ́sínì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkópọ̀ wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí sínú ìwé kan ṣoṣo. Ìwé yìí, tí wọ́n sáré kó jọ ní apá ìparí ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, ni a wá mọ̀ sí Talmud ti Palẹ́sínì.b
Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Palẹ́sínì ń dín kù, ṣe ni agbára àwọn Ámóráímù ti Babilóníà ń pọ̀ sí i. Abaye àti Raba mú ipele àríyànjiyàn tẹ̀ síwájú di ìjiyàn dídíjú tí ó kún fún ọ̀rínkinniwín, èyí tí ó wá di àwòṣe lẹ́yìn ìgbà náà nígbà tí a bá ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ tí ó jẹ mọ́ Talmud. Lẹ́yìn èyí, Ashi, ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ gíga tí ó wà ní Sura (371 sí 427 Sànmánì Tiwa), bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkójọ àwọn kókó inú àríyànjiyàn, ó sì ń ṣe àtúnṣe wọn. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Steinsaltz wí, ó ṣe bẹ́ẹ̀ “nítorí ìbẹ̀rù pé, níwọ̀n bí gbogbo ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti wá di rúdurùdu, ewu ń bẹ pé, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àkójọpọ̀ òfin àtẹnudẹ́nu náà lè di ohun ìgbàgbé.”
Àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ rẹpẹtẹ yìí pọ̀ ju ohun tí ẹnì kan tàbí ohun tí ìran kan pàápàá lè ṣe létòlétò. Sáà àwọn Ámóráímù dópin ní Babilóníà ní ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Tiwa, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ṣíṣe àtúnṣe ìkẹyìn sí Talmud ti Babilóníà ń bá a nìṣó wọnú ọ̀rúndún kẹfà Sànmánì Tiwa nípasẹ̀ ẹgbẹ́ kan tí a mọ̀ sí àwọn Sábóráímù, ọ̀rọ̀ èdè Árámáíkì tí ó túmọ̀ sí “àwọn alálàyé,” tàbí “àwọn amètemèrò.” Àwọn olùṣàtúnṣe ìgbẹ̀yìn wọ̀nyí kó ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìsọfúnni yìí jọ pọ̀ di odindi, wọ́n dárà sí Talmud ti Babilóníà tí ó mú kí ó ta yọ gbogbo ìwé àwọn Júù tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀.
Kí Ni Talmud Ṣe Ní Àṣeparí?
Àwọn rábì tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Talmud pinnu láti fi hàn pé Mishnah wá láti orísun kan náà tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti wá. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí wọ́n fẹ́ fi èyí hàn? Jacob Neusner ṣàlàyé pé: “Àríyànjiyàn tí wọ́n sọ pé ó wà nílẹ̀ ni ibi tí Mishnah dúró sí nínú ọ̀ràn náà. Ṣùgbọ́n ibi tí wàhálà wà gan-an ni ọlá àṣẹ amòye náà tìkára rẹ̀.” Láti rí i pé àṣẹ náà múlẹ̀, gbogbo ìlà Mishnah, nígbà mìíràn gbogbo ọ̀rọ̀ Mishnah, ni a yẹ̀ wò, ni a pè níjà, ni a ṣàlàyé, ni a sì mú bára mu lọ́nà kan pàtó. Neusner ṣàkíyèsí pé lọ́nà yìí, àwọn rábì “darí Mishnah gba ibòmíràn.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ṣe é ní ìwé tí ó dá dúró gedegbe, Mishnah ni wọ́n ti wá fi àlàyé fọ́ sí wẹ́wẹ́ báyìí. Nígbà tí wọ́n ń ṣe èyí, wọ́n yí i padà, wọ́n tún un ṣẹ̀dá.
Ìwé tuntun yìí—Talmud—ṣiṣẹ́ fún ète àwọn rábì. Àwọn ni wọ́n gbé òfin ìfọ́síwẹ́wẹ́ kalẹ̀, nítorí náà ó kọ́ àwọn ènìyàn láti máa ronú bí àwọn rábì. Àwọn rábì gbà gbọ́ pé ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ àti ìgbàṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ tiwọn ṣàgbéyọ èrò inú Ọlọ́run. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Talmud fúnra rẹ̀ wá di góńgó, ọ̀nà ìjọsìn—lílo èrò inú lọ́nà tí wọ́n sọ pé ó fara jọ ti Ọlọ́run. Ní àwọn ìran tí ń bọ̀, ọ̀nà kan náà yìí ni a óò máa gbà fọ́ Talmud sí wẹ́wẹ́. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Òpìtàn náà, Cecil Roth, kọ̀wé pé: “Talmud . . . fún [àwọn Júù] ní àmì ìdánimọ̀ tí ó mú kí wọ́n yàtọ̀ gedegbe sí àwọn ẹlòmíràn, àti agbára aláìlẹ́gbẹ́ tí wọ́n ní láti dènà ìyípadà àti láti wà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan. Ìfèròwérò inú rẹ̀ fi kún agbára ìfinúmòye wọn, ó sì fún wọn ní . . . agbára ìmọnúúrò tí ó mú hánhán. . . . Talmud fún Júù tí a ń ṣe inúnibíni sí ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú ní ayé mìíràn tí ó lè sá sí . . . Ó fún un ní ilẹ̀ ìbílẹ̀, tí ó lè máa gbé káàkiri nígbà tí ó pàdánù ilẹ̀ tirẹ̀.”
Nípa fífi ìrònú àwọn rábì kọ́ àwọn ẹlòmíràn, dájúdájú Talmud ní agbára. Ṣùgbọ́n ìbéèrè fún gbogbo ènìyàn—àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù—ni pé, Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni Talmud ń ṣàgbéyọ èrò inú Ọlọ́run?—1 Kọ́ríńtì 2:11-16.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni púpọ̀ sí i nípa bí Mishnah ṣe bẹ̀rẹ̀ àti ohun tí ó wà nínú rẹ̀, wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Mishnah àti Òfin Tí Ọlọ́run fún Mósè” nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 1997.
b Talmud ti Palẹ́sínì ni àwọn ènìyàn mọ̀ sí Talmud ti Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n, àṣìlò ọ̀rọ̀ ni èyí jẹ́, nítorí pé ní sáà àwọn Ámóráímù, a kò gba àwọn Júù láyè láti wọ Jerúsálẹ́mù.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]
Talmud Méjèèjì—Kí Ni Ìyàtọ̀ Wọn?
Ọ̀rọ̀ Hébérù náà “Talmud” túmọ̀ sí “ìkẹ́kọ̀ọ́” tàbí “ẹ̀kọ́.” Àwọn Ámóráímù ti Palẹ́sínì àti Babilóníà múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́, tàbí láti ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ Mishnah. Talmud méjèèjì (ti Palẹ́sínì àti ti Babilóníà) ṣe èyí, ṣùgbọ́n kí ni ìyàtọ̀ wọn? Jacob Neusner kọ̀wé pé: “Talmud àkọ́kọ́ ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ẹ̀rí, ìkejì ń ṣèwádìí ìpìlẹ̀ ẹ̀rí; ti àkọ́kọ́ fi ara rẹ̀ mọ sí ààlà àgbègbè tí a ń gbé yẹ̀ wò, ìkejì lọ ré kọjá ààlà náà gidigidi.”
Kì í ṣe kìkì pé àtúnṣe tí ó jinlẹ̀, tí ó sì kúnná, tí a ṣe sí Talmud ti Babilóníà mú kí ó tóbi sí i nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún mú kí ó jinlẹ̀ sí i, kí ó sì wọni lọ́kàn sí i ní ti ìrònú àti ìfọ́síwẹ́wẹ́. Nígbà tí a bá mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ náà “Talmud,” Talmud ti Babilóníà ni a sábà máa ń ní lọ́kàn. Èyí ni Talmud tí a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ jù lọ tí a sì ti ṣàlàyé lé lórí jù lọ jálẹ̀jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún. Nínú èrò Neusner, Talmud ti Palẹ́sínì “jẹ́ iṣẹ́ tí ó pegedé,” Talmud ti Babilóníà sì “jẹ́ iṣẹ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n.”