ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 7/15 ojú ìwé 28-30
  • Àwọn Karaite àti Bí Wọ́n Ṣe Wá Òtítọ́ Kiri

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Karaite àti Bí Wọ́n Ṣe Wá Òtítọ́ Kiri
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Awuyewuye náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
  • Àwọn Karaite àti Àwọn Rabi Wọ̀yá-Ìjà
  • Báwo Ni Àwọn Rabi Ṣe Hùwàpadà?
  • Àjọ Àwọn Karaite Pàdánù Agbára Ìsúnniṣe
  • Òfin Àtẹnudẹ́nu—Èé Ṣe Tí A Fi Kọ Ọ́ Sílẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ibi Ìkówèésí Àkọ́kọ́ Nílẹ̀ Rọ́ṣíà Fi Hàn Kedere Pé Òótọ́ Lọ̀rọ̀ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Kí Ni Talmud?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Kí Ni Ìwé Àwọn Masorete?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 7/15 ojú ìwé 28-30

Àwọn Karaite àti Bí Wọ́n Ṣe Wá Òtítọ́ Kiri

“WÁ INÚ [Ìwé Mímọ́] dáradára má sì ṣe gbáralé èrò mi.” Aṣáájú Karaite kan ní ọ̀rúndún kẹjọ C.E. ni ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Àwọn wo ni àwọn Karaite? A ha lè rí ohunkóhun tí ó níyelórí kọ́ láti inú àpẹẹrẹ wọn bí? Láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ padà sínú ìtàn sí awuyewuye kan tí ó ti wà fún ìgbà pípẹ́ tí ó yọrí sí àjọ àwọn Karaite.

Báwo Ni Awuyewuye náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀?

Ní òpin àwọn ọ̀rúndún ṣáájú Sànmánì Tiwa, ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn titun kan jẹyọ láàárín àwọn onísìn Júù. Ó jẹ́ ìpìlẹ̀ èrò pé Ọlọrun fúnni ní Òfin méjì ní Òkè-Ńlá Sinai, a kọ ọ̀kan sílẹ̀ ọ̀kan sì jẹ́ àtẹnudẹ́nu.a Nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún kìn-ínní C.E., àtakò gbígbóná janjan bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn wọnnì tí wọ́n ti ẹ̀kọ́ titun yìí lẹ́yìn àti àwọn wọnnì tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn Farisi ni agbátẹrù rẹ̀, nígbà tí ó sì jẹ́ pé àwọn Sadusi àti Essene wà lára àwọn alátakò.

Ní àárín awuyewuye ti ń bá a lọ yìí, Jesu ti Nasareti fara hàn gẹ́gẹ́ bí Messia náà tí a ṣèlérí. (Danieli 9:24, 25; Matteu 2:1-6, 22, 23) Jesu kojú gbogbo àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ Júù náà tí ń forígbárí. Ní ríronú pẹ̀lú wọn, ó dẹ́bi fún sísọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun di asán nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. (Matteu 15:3-9) Jesu tún kọ́ni ní àwọn òtítọ́ tẹ̀mí lọ́nà kan tí ó jẹ́ pé Messia náà nìkan ṣoṣo ni ó lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Johannu 7:45, 46) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu tòótọ́ nìkan ni ó fúnni ní ẹ̀rí pé àwọn ní ìtìlẹyìn àtọ̀runwá. Wọn di àwọn tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristian.—Ìṣe 11:26.

Nígbà tí a pa tẹ́ḿpìlì Jerusalemu run ní 70 C.E., àwọn Farisi nìkan ni àwọn ẹ̀ya ìsìn tí ó làájá láìyingin. Nísinsìnyí láìsí ẹgbẹ́ àlùfáà, ìrúbọ, àti tẹ́ḿpìlì, àwọn Farisi onísìn Júù lè hùmọ̀ àwọn ohun àfirọ́pò fún gbogbo ìwọ̀nyí, ní fífàyègba àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti ìtumọ̀ láti borí Òfin tí a kọ sílẹ̀. Èyí ṣí ilẹ̀kùn sílẹ̀ fún kíkọ “àwọn ìwé mímọ́ ọlọ́wọ̀” titun. Mishnah ni ó kọ́kọ́ jẹyọ, pẹ̀lú àwọn àfikún tí ó ní sí òfin àtẹnudẹ́nu àti àwọn ìtumọ̀ wọn. Nígbà tí ó ṣe, àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn tí a kójọpọ̀ ni a fi kún un tí a sì pè é ní Talmud. Ní àkókò kan náà, àwọn Kristian apẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ sí fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú àwọn ẹ̀kọ́ Jesu. Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì mú ètò ìsìn tí ó lágbára jáde—ọlá-àṣẹ rabi ní apá kan àti ọlá-àṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì ní apá kejì.

Nítorí ìforígbárí tí ń bẹ láàárín àwọn Júù àti ilẹ̀ Romu abọ̀rìṣà àti lẹ́yìn náà pẹ̀lú ilẹ̀ Romu onísìn “Kristian”, ojúkò ìsìn Júù ni a gbé lọ sí Babiloni ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Níbẹ̀ ni a ti ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé Talmud ní ọ̀nà tí wọ́n gbà péye jùlọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn rabi jẹ́wọ́ pé Talmud ṣí ìfẹ́-inú Ọlọrun payá lọ́nà tí ó túbọ̀ péye, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù nímọ̀lára pé ọlá-àṣẹ àwọn rabi ń pọ̀ síi wọ́n sì ń yánhànhàn fún ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí Mose àti àwọn wòlíì fifún wọn.

Ní apá ìlàjì tí ó kẹ́yìn ọ̀rúndún kẹjọ C.E., àwọn Júù ní Babiloni tí wọ́n tako ọlá-àṣẹ àwọn rabi àti ìgbàgbọ́ wọn nínú òfin àtẹnudẹ́nu dáhùnpadà lọ́nà rere sí ọ̀mọ̀wé aṣáájú kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Anan ben David. Ó polongo ẹ̀tọ́ Júù kọ̀ọ̀kan láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu láìsí ìkálọ́wọ́kò gẹ́gẹ́ bí orísun kanṣoṣo fún ìsìn tòótọ́, láìka ìtumọ̀ àwọn rabi tàbí Talmud sí. Anan kọ́ni pé: “Wá inú Torah [òfin Ọlọrun tí a kọ sílẹ̀] dáradára má sì ṣe gbáralé èrò mi.” Nítorí ìtẹnumọ́ yìí tí a gbékarí Ìwé Mímọ́, àwọn ọmọlẹ́yìn Anan di àwọn tí a mọ̀ sí àwọn Qa·ra·ʼimʹ, orúkọ Heberu kan tí ó túmọ̀ sí “àwọn òǹkàwé.”

Àwọn Karaite àti Àwọn Rabi Wọ̀yá-Ìjà

Kí ni àpẹẹrẹ díẹ̀ lára ẹ̀kọ́ àwọn Karaite tí ó dá ìfòyà sílẹ̀ láàárín agbo àwọn rabi? Àwọn rabi ka jíjẹ ẹran àti wàrà papọ̀ léèwọ̀. Wọ́n gbé èyí kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlàyé òfin àtẹnudẹ́nu ti Eksodu 23:19, tí ó sọ pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.” Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn Karaite kọ́ni pé ẹsẹ̀ yìí wulẹ̀ túmọ̀ sí kìkì ohun tí ó sọ—kò jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n jiyàn pé ìkálọ́wọ́kò ti àwọn rabi jẹ́ ìhùmọ̀ ènìyàn.

Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe túmọ̀ Deuteronomi 6:8, 9, àwọn rabi gbà pé àwọn ọkùnrin Júù gbọ́dọ̀ so àpótí aláwọ mọ́ra bí wọ́n bá ń gbàdúrà, àti pé a gbọ́dọ̀ fi àkájọ ẹsẹ̀ Bibeli sí àtẹ́rígbà kọ̀ọ̀kan.b Àwọn Karaite ka àwọn ẹsẹ̀ wọ̀nyí sí èyí tí ó ní kìkì ìtumọ̀ ìṣàpẹẹrẹ àti alápèjúwe, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ irú ìlànà àwọn rabi bẹ́ẹ̀ sílẹ̀.

Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn àwọn Karaite kánilọ́wọ́kò ju àwọn rabi lọ. Fún àpẹẹrẹ, gbé ojú-ìwòye wọn lórí Eksodu 35:3 yẹ̀wò, tí ó kà pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dá iná ní ilé yín gbogbo ní ọjọ́ ìsinmi.” Àwọn Karaite ka fífi fìtílà tàbí iná sílẹ̀ láìpa á léèwọ̀ àní bí a bá tilẹ̀ ti tàn án ṣáájú Sábáàtì pàápàá.

Ní pàtàkì lẹ́yìn ikú Anan, àwọn aṣáájú Karaite kì í fohùnṣọ̀kan nígbà gbogbo lórí ìwọ̀n àti ìpìlẹ̀ àwọn ìkálọ́wọ́kò kan, ìhìn-isẹ́ wọn kì í sìí fìgbà gbogbo ṣe kedere. Kò sí ìṣọ̀kan láàárín àwọn Karaite nítorí pé wọn kò tẹ́wọ́gba aṣáájú kanṣoṣo èyíkéyìí ṣùgbọ́n wọ́n gbé ìtẹnumọ́ karí ìwé kíkà àti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ fúnra ẹni, ní ìtakora pẹ̀lú ọ̀nà ọlá-àṣẹ àwọn rabi. Bí ó ti wù kí ó rí, láìka èyí sí, àjọ àwọn Karaite ń gbèrú níti òkìkí àti ipa ìdarí rékọjá ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn Júù tí ń gbé Babiloni ó sì tànkálẹ̀ jákèjádò Middle East. A tilẹ̀ dá ojúkò pàtàkì kan ti àwọn Karaite sílẹ̀ ní Jerusalemu.

Ní ọ̀rúndún kẹsàn-án àti ìkẹwàá C.E., àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Karaite tayọlọ́lá nínú àtúnṣe ẹ̀kọ́ èdè Heberu wọ́n sì gbádùn sànmánì onídùnnú. Wọ́n ka àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu sí mímọ́, kì í ṣe àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àtẹnudẹ́nu. Àwọn Karaite kan di afarabalẹ̀ adàwékọ ti Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Níti tòótọ́, ìpèníjà àwọn Karaite ni ó sún àwọn Masorete láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ láàárín àwọn Júù, láti rí i dájú pé a ní ẹsẹ̀ Bibeli tí a tọ́júpamọ́ lọ́nà tí ó túbọ̀ pé pérépéré lónìí.

Láàárín sáà ìdàgbàsókè yíyára kánkán yìí, àwọn Karaite onísìn Júù lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a kò fibò láàárín àwọn Júù mìíràn. Èyí gbé ìfòyà tí ó hàn gbangba dìde síwájú àwọn rabi onísìn Júù.

Báwo Ni Àwọn Rabi Ṣe Hùwàpadà?

Ìgbéjàkò padà tí àwọn rabi ṣe jẹ́ ti sísọ òkò ọ̀rọ̀, pẹ̀lú ìṣeéyípadà ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ àti yíyí àwọn ẹ̀kọ́ wọn padà. Ní àwọn ọ̀rúndún tí ó tẹ̀lé ìgbéjàkò tí Anan ṣe, àwọn rabi onísìn Júù lo àwọn ọgbọ́n Karaite mélòókan. Àwọn rabi túbọ̀ di ọ̀jáfáfá síi nínú ṣíṣàyọlò Ìwé Mímọ́, ní lílo ọgbọ́n àti ọ̀nà ìgbàṣe ti àwọn Karaite nínú ìsọ̀rọ̀ wọn.

Aṣáájú tí a mọ̀ nínú ìjà òkò ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú àwọn Karaite ni Saʽadia ben Joseph, ẹni tí ó di olórí ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn Júù ní Babiloni ní apá ìlàjì àkọ́kọ́ ti ọ̀rúndún kẹwàá C.E. Ìwé Saʽadia tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, The Book of Beliefs and Opinions, ni a túmọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì láti ọwọ́ Samuel Rosenblatt, ẹni tí ó sọ nínú ìfáárà rẹ̀ pé: “Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé . . . òun ni aláṣẹ lórí Talmud nígbà ayé rẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ orísun àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù yìí ni [Saʽadia] lò, èyí tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ nítorí pé ó jẹ́ ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ láti fi ohun-ìjà àwọn Karaite gan-an ṣẹ́gun wọn, àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́gba Òfin Alákọsílẹ̀ nìkan ṣoṣo bí èyí tí ó jẹ́ òtítọ́.”

Ní títẹ̀lé ipasẹ̀ Saʽadia, àwọn rabi onísìn Júù jèrè agbára ìdarí púpọ̀ síi. Ó ṣàṣeparí èyí nípa lílo Òfin Alákọsílẹ̀ dé ìwọ̀n mímú ẹ̀rí lílágbára kúrò nínú àríyànjiyàn àwọn Karaite. Moses Maimonides ni ó ṣe àṣekágbá gbogbo rẹ̀, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Talmud ti ọ̀rúndún kejìlá tí a mọ̀-bí-ẹni-mowó. Nítorí ìwà rírí ara gba nǹkan sí tí ó ní fún àwọn Karaite tí ó ti bá gbé papọ̀ ní Egipti, àti ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tí ó lè yíniléròpadà rẹ̀, ó jèrè ìkansáárásí wọn ó sì sọ ipò àwọn aṣáájú wọn di ahẹrẹpẹ.

Àjọ Àwọn Karaite Pàdánù Agbára Ìsúnniṣe

Níwọ̀n bí kò ti sí ìṣọ̀kan àti ìgbésẹ̀ tí a wéwèé dáradára lòdì sí àtakò, àjọ àwọn Karaite pàdánù agbára ìsúnniṣe àti àwọn ọmọlẹ́yìn. Bí àkókò ti ń kọjá lọ, àwọn Karaite tún ojú-ìwòye àti ìlànà wọn ṣe. Leon Nemoy, òǹkọ̀wé kan lórí àjọ awọn Karaite, kọ̀wé pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fòfinde Talmud, púpọ̀ lára àwọn àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ Talmud ni a yọ́ mú wọ inú òfin àti àṣà àwọn Karaite.” Níti gidi, àwọn Karaite pàdánù ète wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ wọ́n sì tẹ́wọ́gba púpọ̀ lára ohun tí àwọn rabi onísìn Júù kọ́ni.

Nǹkan bí 25,000 àwọn Karaite ṣì wà ní Israeli. A lé rí àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún díẹ̀ síi ní àwọn àgbájọ ẹgbẹ́ àwùjọ mìíràn, ní pàtàkì ní Russia àti ní United States. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n yàtọ̀ sí àwọn Karaite àkọ́kọ́ nítorí níní tí wọ́n ní àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àtẹnudẹ́nu tiwọn.

Kí ni a lè rí kọ́ láti inú ìtàn àwọn Karaite? Pé àṣìṣe wíwúwo ni ó jẹ́ láti “sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ nitori òfin àtọwọ́dọ́wọ́.” (Matteu 15:6) Láti lè ja àjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn tí ń di ẹrù-ìnira kani lórí ń béèrè ìmọ̀ pípéye nínú Ìwé Mímọ́. (Johannu 8:31, 32; 2 Timoteu 3:16, 17) Bẹ́ẹ̀ni, àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti mọ ìfẹ́-inú Ọlọrun tí wọ́n sì fẹ́ ṣe é kì í gbáralé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi taápọn taápọn ṣàyẹ̀wò Bibeli wọ́n sì ń fi àwọn ìtọ́ni aṣeniláǹfààní ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mí sí sílò.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé lórí ohun tí a fẹnu lásán pè ní òfin àtẹnudẹ́nu, wo ojú-ìwé 8 sí 11 ìwé pẹlẹbẹ náà Will There Ever Be a World Without War?, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

b Àpótí aláwọ jẹ́ àpótí kékeré aláwọ onígun mẹ́rin tí ó ní àwọn ìwé pelebe tí ó ní àwọn ìpínrọ̀ Ìwé Mímọ́ nínú. Àwọn àpótí yìí ni a máa ń so mọ́ ọwọ́ òsì àti mọ orí nígbà àdúrà òwúrọ̀ ti àárín ọ̀sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Àkájọ ẹsẹ̀ Bibeli jẹ́ àkájọ awọ kékeré tí a kọ Deuteronomi 6:4-9 àti 11:13-21 sí, tí a fi sínú àpótí tí a kàn mọ́ àtẹ́rígbà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn Karaite

[Credit Line]

Láti inú ìwé náà The Jewish Encyclopedia, 1910

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́