Gàmálíẹ́lì—Ó Kọ́ Sọ́ọ̀lù Ará Tásù Lẹ́kọ̀ọ́
ÀWỌN ènìyàn náà pa rọ́rọ́. Ní àkókò díẹ̀ ṣáájú, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ẹni tí a tún mọ̀ sí Sọ́ọ̀lù ará Tásù, àwọn ẹgbẹ́ ogun Róòmù ti gbà á sílẹ̀, ó sì dojú kọ àwọn ènìyàn náà nísinsìnyí láti orí àtẹ̀gùn tí ó wà nítòsí tẹ́ḿpìlì ní Jerúsálẹ́mù.
Ní fífọwọ́ rẹ̀ ṣàpèjúwe pé kí wọ́n dákẹ́, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù, ní sísọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará àti ẹ̀yin bàbá, ẹ gbọ́ ìgbèjà mi sí yín nísinsìnyí. . . . Júù ni mí, tí a bí ní Tásù ti Sìlíṣíà, ṣùgbọ́n tí a fún ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní ìlú ńlá yìí lẹ́bàá ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì, tí a fún ní ìtọ́ni ní ìbámu pẹ̀lú àìgbagbẹ̀rẹ́ Òfin àwọn baba ńlá ìgbàanì, tí mo jẹ́ onítara fún Ọlọ́run gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti jẹ́ lónìí yìí.”—Ìṣe 22:1-3.
Pẹ̀lú ìwàláàyè rẹ̀ tí ó wà nínú ewu, èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ ìgbèjà rẹ̀ nípa sísọ pé Gàmálíẹ́lì ni ó kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́? Ta ni Gàmálíẹ́lì, kí sì ni kíkọ́ tí ó kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ ní nínú? Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí ha nípa lóri Sọ́ọ̀lù àní lẹ́yìn tí ó di Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá bí?
Ta Ni Gàmálíẹ́lì?
Gàmálíẹ́lì jẹ́ Farisí tí a mọ̀ bí ẹní mowó. Ó jẹ́ ọmọ-ọmọ Hílẹ́lì Àgbà, ẹni tí ó dá ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ ńlá méjì ti àwùjọ àwọn olójú ìwòye kan náà láàárín ìsìn àwọn Júù ti Farisí sílẹ̀.a A ka ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Hílẹ́lì sí èyí tí ó túbọ̀ rọjú ju ti ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Ṣámáì, lọ. Lẹ́yìn ìparun tẹ́ḿpìli Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, a tẹ́wọ́ gba Beti Hílẹ́lì (Ilé Hílẹ́lì) dípò Beti Ṣámáì (Ilé Ṣámáì). Ilé Hílẹ́lì di ọ̀rọ̀ tí ó wọ́pọ̀ nínú ìsìn àwọn Júù, níwọ̀n bí àwọn ẹ̀ya ìsìn yòókù ti pòórá pẹ̀lú ìparun tẹ́ḿpìlì. Ìpinnu Beti Hílẹ́lì ni ó sábà jẹ́ ìdí ìpìlẹ̀ fún Òfin Júù nínú Mishnah, tí ó wá di ìpìlẹ̀ Talmud, ó sì ṣe kedere pé ipa ìdarí Gàmálíẹ́lì jẹ́ ìdí abájọ pàtàkì nínú ìjẹgàba rẹ̀.
A gbé Gàmálíẹ́lì gẹ̀gẹ̀ débi pé òun ni a kọ́kọ́ pè ní rábánì, orúkọ oyè tí ó ga ju ti rábì lọ. Ní tòótọ́, Gàmálíẹ́lì di ẹni tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí Mishnah fi sọ nípa rẹ̀ pé: “Nígbà ti Rábánì Gàmálíẹ́lì àgbà kú, ògo Tórà dópin, àìlábàwọ́n àti ìjẹ́mímọ́ [ní òwuuru, “ìyàsọ́tọ̀”] rẹ̀ sì parẹ́.”—Sotah 9:15.
Gàmálíẹ́lì Kọ́ Ọ Lẹ́kọ̀ọ́ —Lọ́nà Wo?
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwùjọ náà ní Jerúsálẹ́mù pé ‘a dá òun lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì,’ kí ni ó ní lọ́kàn? Kí ni ó ní nínú láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn olùkọ́ kan bíi Gàmálíẹ́lì?
Nípa irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Dov Zlotnick ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìsìn Àwọn Àlùfáà ti Júù ní America kọ̀wé pé: “Ìpépérépéré òfin àtẹnudẹ́nu, títí kan ìṣeégbáralé rẹ̀, fẹ́rẹ̀ẹ́ sinmi pátápátá lórí ipò ìbátan ọ̀gá sí ọmọ ẹ̀yìn: ìsapá tí ọ̀gá bá ṣe láti fi òfin náà kọ́ni àti ìfẹ́ ọkàn ọmọ ẹ̀yìn náà láti kọ́ ọ. . . . Nítorí náà, a rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti jókòó sẹ́bàá ẹsẹ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ . . . ‘kí wọ́n sì máa fi tìtaratìtara kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ náà.’”—Avot 1:4, Mishnah.
Nínú ìwé rẹ̀ A History of the Jewish People in the Time of Jesus Christ, Emil Schürer là wá lóye lórí àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àwọn olùkọ́ rábì ọ̀rúndún kìíní. Ó kọ̀wé pé: “Àwọn Rábì tí ó lókìkí jù sábà máa ń kó àwọn èwe tí ń fẹ́ ìtọ́ni jọ sọ́dọ̀ ara wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, fún ète mímú kí wọ́n dojúlùmọ̀ gidigidi pẹ̀lú onírúurú àti ọ̀pọ̀ yanturu ‘òfin àtẹnudẹ́nu.’ . . . Ìtọ́ni náà ní ìfidánrawò àkọ́sórí tí ń bá a nìṣó láìdábọ̀ nínú. . . . Olùkọ́ náà yóò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè òfin fún ìpinnu wọn, yóò sì jẹ́ kí wọ́n dáhùn wọn tàbí kí òun fúnra rẹ̀ dáhùn wọn. A gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láyè pẹ̀lú láti béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ olùkọ́ náà.”
Lójú ìwòye àwọn rábì, ohun tí ó ṣe pàtàkì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ju wíwulẹ̀ kẹ́sẹ járí ní kíláàsì lọ fíìfíì. A kìlọ̀ fún àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ irú àwọn olùkọ́ bẹ́ẹ̀ pé: “Ẹni yòówù tí ó bá gbàgbé ohun kan ṣoṣo nínú ohun tí ó ti kọ́—Ìwé Mímọ́ kà á sí pé ó ti jẹ̀bi ikú.” (Avot 3:8) Akẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá dà bíi “kàǹga tí a rẹ́ inú rẹ̀, tí kò jo ẹ̀kán omi kan dànù,” ni a fún ní ìyìn gíga jù lọ. (Avot 2:8) Irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yẹn ni Pọ́ọ̀lù, tí a mọ̀ pẹ̀lú orúkọ Hébérù rẹ̀ nígbà yẹn, Sọ́ọ̀lù ará Tásù, gbà láti ọ̀dọ̀ Gàmálíẹ́lì.
Ìtumọ̀ Ẹ̀kọ́ Gàmálíẹ́lì Ní Ti Gidi
Láti wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Farisí, Gàmálíẹ́lì gbé ìgbàgbọ́ nínú òfin àtẹnudẹ́nu lárugẹ. Ó tipa báyìí gbé ìtẹnumọ́ gíga karí àṣà àwọn rábì ju karí Ìwé Mímọ́ onímìísí. (Mátíù 15:3-9) Mishnah fa ọ̀rọ̀ Gàmálíẹ́lì yọ tí ó sọ pé: “Wá olùkọ́ kan [rábì kan] fún ara rẹ, kí o sì mú iyè mejì kúrò, nítorí pé ìwọ kò gbọdọ̀ san ìdámẹ́wàá ré kọjá àlà nípa ìméfòó.” (Avot 1:16) Èyí túmọ̀ sí pé nígbà tí àwọn Ìwé Mímọ́ Léde Hébérù kò bá sọ ohun tí a ní láti ṣe ní pàtó, ẹnì kan kò gbọdọ̀ lo ọgbọ́n ìrònú tirẹ̀ tàbí tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ láti ṣe ìpinnu. Kàkà bẹ́ẹ̀, òún ní láti wá rábì kan tí ó tóótun tí yóò ṣe ìpinnu fún un. Gẹ́gẹ́ bí Gàmálíẹ́lì ti sọ, kìkì ní ọ̀nà yìí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan fi lè yẹra fún dídẹ́ṣẹ̀.—Fi wé Róòmù 14:1-12.
Bí ó ti wù kí ó rí, a mọ Gàmálíẹ́lì ní gbogbogbòò fún ẹ̀mí ìrònú aráragba-nǹkan-sí àti àìlekoko nínú òfin ìdájọ́ ìsìn rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn obìnrin nígbà tí ó pàṣẹ pé òun yóò “fàyè gba aya kan láti tún ìgbéyàwó ṣe bí ẹlẹ́rìí kan bá lè jẹ́rìí [sí ikú ọkọ rẹ̀].” (Yevamot 16:7, Mishnah) Ní àfikún sí i, láti dáàbò bo ẹni tí a kọ̀ sílẹ̀, Gàmálíẹ́lì ṣe ìgbékalẹ̀ àwọn ìkálọ́wọ́kò mélòó kan nínú fífúnni ní lẹ́tà ìkọ̀sílẹ̀.
A tún rí ẹ̀mí ìrònú yìí nínú ìbálò Gàmálíẹ́lì pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ní àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Ìwé Ìṣe ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn aṣáájú Júù yòókù wọ́nà láti pa àwọn àpọ́sítélì Jésù tí wọ́n ti fàṣẹ ọba mú nítorí wíwàásù, “ọkùnrin kan báyìí dìde nínú Sànhẹ́dírìn, Farisí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì, olùkọ́ Òfin tí gbogbo ènìyàn kà sí, ó sì pa àṣẹ pé kí a fi àwọn ọkùnrin náà sí òde fún ìgbà díẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ kíyè sí ara yín ní ti ohun tí ẹ ń pètepèrò láti ṣe nípa àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. . . . Mo wí fún yín pé, Ẹ má ṣe tojú bọ ọ̀ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹ fi wọ́n sílẹ̀; . . . bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gàsíkíá.’” Wọ́n kọbi ara sí ìmọ̀ràn Gàmálíẹ́lì, wọ́n sì dá àwọn àpọ́sítélì sílẹ̀.—Ìṣe 5:34-40.
Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí fún Pọ́ọ̀lù?
A ti dá Pọ́ọ̀lù lẹ́kọ̀ọ́, a sì ti kọ́ ọ ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ rábì tí ó ga jù lọ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Kò sí iyè méjì pé dídá tí àpọ́sítélì náà dárúkọ Gàmálíẹ́lì mú kí àwùjọ náà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù pe àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn nípa Olùkọ́ kan tí ó sàn ju Gàmálíẹ́lì lọ fíìfíì—Jésù, Mèsáyà náà. Nísinsìnyí, Pọ́ọ̀lù ń bá àwùjọ náà sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kì í ṣe ti Gàmálíẹ́lì.—Ìṣe 22:4-21.
Dídá tí Gàmálíẹ́lì dá Pọ́ọ̀lù lẹ́kọ̀ọ́ ha nípa lórí ìkọ́ni rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni bí? Ó ṣeé ṣe kí àwọn ìtọ́ni ṣíṣe kókó nínú Ìwé Mímọ́ àti òfin àwọn Júù ti wúlò fún Pọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni olùkọ́. Síbẹ̀, lẹ́tà onímìísí àtọ̀runwá ti Pọ́ọ̀lù tí a rí nínú Bíbélì fi hàn kedere pé ó kọ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Farisí ti Gàmálíẹ́lì. Pọ́ọ̀lù darí àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti àwọn mìíràn sí Jésù Kristi, kì í ṣe sí àwọn rábì ìsìn àwọn Júù tàbí sí àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí ènìyàn dá sílẹ̀.—Róòmù 10:1-4.
Ká ní Pọ́ọ̀lù ti ń bá a nìṣó láti máa jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Gàmálíẹ́lì ni, òun ì bá ti gbádùn ipò iyì gíga. Àwọn mìíràn láti inú àwùjọ Gàmálíẹ́lì ṣèrànwọ́ láti pinnu ọjọ́ ọ̀la ìsìn àwọn Júù. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ Gàmálíẹ́lì, Síméónì, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù, kó ipa pàtàkì nínú ìṣọ̀tẹ̀ àwọn Júù lòdì sí Róòmù. Lẹ́yìn ìparun tẹ́ḿpìlì, ọmọ-ọmọ Gàmálíẹ́lì, Gàmálíẹ́lì Kejì, mú ọlá àṣẹ Sànhẹ́dírìn padà bọ̀ sípò, ní gbígbé e lọ sí Yavneh. Ọmọ-ọmọ Gàmálíẹ́lì Kejì, Júdà Há-Násì, ni olùṣàkójọ Mishnah, tí ó wá di ìpìlẹ̀ ìrònú àwọn Júù títí di ọjọ́ wa.
Gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ Gàmálíẹ́lì, Sọ́ọ̀lù ará Tásù ì bá ti yọrí ọlá nínú ìsìn àwọn Júù. Síbẹ̀, nípa irú iṣẹ́ ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ èrè fún mi, ìwọ̀nyí ni mo ti kà sí àdánù ní tìtorí Kristi. Họ́wù, ní ti èyíinì, ní tòótọ́ mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi. Ní tìtorí rẹ̀ èmí ti gba àdánù ohun gbogbo mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jère Kristi.”—Fílípì 3:7, 8.
Nípa kíkọ iṣẹ́ ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Farisí sílẹ̀, tí ó sì di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, Pọ́ọ̀lù ń ṣe ìfisílò ìmọ̀ràn olùkọ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí láti ṣọ́ra lòdì sí dídi ‘ẹni tí a rí tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gàsíkíá.’ Nípa dídá ṣíṣenúnibíni rẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù dúró, Pọ́ọ̀lù ṣíwọ́ bíbá Ọlọ́run jà. Kàkà bẹ́ẹ̀, nípa dídi ọmọlẹ́yìn Kristi, ó di ọ̀kan nínú “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.”—Kọ́ríńtì Kìíní 3:9.
Àwọn onítara Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa pòkìkí ìhìn iṣẹ́ ìsìn Kristẹni tòótọ́ ní ọjọ́ wa. Gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí ti ṣe ìyípadà pípabambarì nínú ìgbésí ayé wọn. Àwọn kan tilẹ̀ ti fi iṣẹ́ ìgbésí ayé tí ń mówó wá sílẹ̀ kí wọ́n baà lè nípìn-ín gíga jù nínú ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba náà, iṣẹ́ kan ní tòótọ́ láti “ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Ìṣe 5:39) Ẹ wo bí inú wọ́n ṣe dùn tó pé wọ́n ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù dípò ti olùkọ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀rí, Gàmálíẹ́lì!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn orísun kan sọ pé Gàmálíẹ́lì jẹ́ ọmọ Hílẹ́lì. Talmud kò ṣe ṣàkó lórí ọ̀ràn yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù ará Tásù pòkìkí ìhìn rere náà fún àwọn ènìyan orílẹ̀-èdè