ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 6/15 ojú ìwé 14-19
  • “Akọ àti Abo ni Ó Dá Wọn”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Akọ àti Abo ni Ó Dá Wọn”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojúlówó Ànímọ́ Ọkùnrin àti Ojúlówó Ànímọ́ Obìnrin
  • Ìrísí Òde Ara
  • Àwọn Ọkùnrin àti Obìnrin Kristẹni—Ojúlówó Ọkùnrin àti Obìnrin
  • Ṣé Káwọn Obìnrin Máa Bo Ẹwà Wọn Mọ́ra Ni?
    Jí!—2005
  • Ipa Tí Obinrin Kó Ninu Iwe Mimọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin Tiẹ̀ Jẹ Ọlọ́run Lógún?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ọkùnrin àti Obìnrin Ipò Iyì Ni Ọlọ́run Fi Kálukú Wọn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 6/15 ojú ìwé 14-19

“Akọ àti Abo ni Ó Dá Wọn”

“Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; àti akọ àti abo ni ó dá wọn.”—JẸ́NẸ́SÍSÌ 1:27.

1. Báwo ni òtítọ́ ṣe jẹ́ ìbùkún fún àwọn Kristẹni lọ́kùnrin lóbìnrin?

Ẹ WO bí ó ti dára tó láti wà lára àwọn ènìyàn Jèhófà àti láti máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọdékùnrin àti àwọn ọmọdébìnrin, tí nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ṣíṣègbọràn sí i jẹ́ ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn! Òtítọ́ tún dá wa sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn ìwà àti ìṣe tí kò tẹ́ Jèhófà Ọlọ́run lọ́rùn, ó sì ń kọ́ wa láti máa gbé gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yẹ Kristẹni. (Jòhánù 8:32; Kólósè 3:8-10) Fún àpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn níbi gbogbo ní àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tàbí èròǹgbà nípa ọ̀nà tí ó yẹ kí àwọn ọkùnrin gbà fi ànímọ́ ọkùnrin hàn àti ọ̀nà tí ó yẹ kí àwọn obìnrin gbà fi ànímọ́ obìnrin hàn. A ha wulẹ̀ bí àwọn ọkùnrin láti máa ṣe bí akọ, tí a sì bí àwọn obìnrin láti máa ṣe bí abo bí? Àbí àwọn kókó abájọ mìíràn wà tí a ní láti gbé yẹ̀ wò?

2. (a) Kí ní yẹ kí ó pinnu ojú ìwòye wa nípa ànímọ́ ọkùnrin àti ànímọ́ obìnrin? (b) Kí ní ti ṣẹlẹ̀ sí ojú ìwòye àwọn ènìyàn nípa ọkùnrin àti obìnrin?

2 Fún àwọn Kristẹni, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ọlá àṣẹ tí a ń juwọ́ sílẹ̀ fún, láìka ojú ìwòye ara ẹni, ti àṣà ìbílẹ̀, tàbí ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí a lè ti ní sí. (Mátíù 15:1-9) Bíbélì kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa onírúurú nǹkan tí ó para pọ̀ jẹ́ ànímọ́ ọkùnrin àti ànímọ́ obìnrin. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi àyè sílẹ̀ fún fífi ànímọ́ ọkùnrin àti ti obìnrin hàn ní onírúurú ọ̀nà, irú èyí tí à ń rí nínú ọ̀kankòjọ̀kan àwùjọ. Kí wọ́n tó lè jẹ́ ohun tí Ọlọ́run dá wọn láti jẹ́, àwọn ọkùnrin gbọ́dọ̀ ní ànímọ́ ọkùnrin, kí àwọn obìnrin sì ní ànímọ́ obìnrin. Èé ṣe? Nítorí pé, ní àfikún sí dídá ọkùnrin àti obìnrin láti jẹ́ àṣekún ara wọn nípa ti ara, wọ́n tún ní láti fi ànímọ́ ọkùnrin àti ànímọ́ obìnrin ṣe àṣekún ara wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18, 23, 24; Mátíù 19:4, 5) Síbẹ̀, a ti lọ́ ojú ìwòye àwọn ènìyàn nípa ọkùnrin àti obìnrin po, a sì ti gbé e gbòdì. Ọ̀pọ̀ gbà pé níní ànímọ́ ọkùnrin jẹ́ ohun kan náà pẹ̀lú jíjẹgàba lọ́nà líle koko, rírorò, tàbí fífagbára ọkùnrin hàn. Nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, ó jẹ́ ohun tí ó ṣọ̀wọ́n, tí ó tilẹ̀ ń tini lójú, fún ọkùnrin láti sunkún, yálà ní gbangba tàbí ní ìkọ̀kọ̀. Síbẹ̀, láàárín ọ̀pọ̀ ènìyàn níwájú ibojì Lásárù, “Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í da omijé.” (Jòhánù 11:35) Ìyẹn kì í ṣe ohun tí kò bójú mu fún Jésù, tí ànímọ́ ọkùnrin rẹ̀ pé pérépéré. Lóde òní, ojú ìwòye ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti di èyí tí kò wà déédéé nípa ànímọ́ obìnrin, wọ́n kà á sí kìkì ẹwà ti ara àti jíjẹ́ àrímáleèlọ.

Ojúlówó Ànímọ́ Ọkùnrin àti Ojúlówó Ànímọ́ Obìnrin

3. Ìyàtọ̀ wo ni ó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin?

3 Kí ni ojúlówó ànímọ́ ọkùnrin kí sì ni ojúlówó ànímọ́ obìnrin? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin yàtọ̀ síra, kì í ṣe kìkì nínú ìrísí ara nìkan, ṣùgbọ́n nínú ìwà àti ìfẹ́ ọkàn wọn pàápàá. Àpapọ̀ apilẹ̀ àbùdá ló fa díẹ̀ lára àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí. . . . Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìyàtọ̀ tí kò ní í ṣe pẹ̀lú ìrísí ti ara dà bí èyí tí a gbé karí ọ̀nà ìhùwà ọkùnrin àti obìnrin, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan kọ́. A ń bí ènìyàn lákọ tàbí lábo, ṣùgbọ́n àwọn ni yóò kọ́ ànímọ́ ọkùnrin tàbí ànímọ́ obìnrin.” Ó lè jẹ́ pé àpapọ̀ apilẹ̀ àbùdá wa ni ó ń mú wa ṣe ọ̀pọ̀ ohun tí a ń ṣe, ṣùgbọ́n mímú ànímọ́ ọkùnrin tàbí ànímọ́ obìnrin yíyẹ dàgbà sinmi lórí kíkọ́ tí à ń kọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa ó sì tún sinmi lórí ohun tí a yàn láti lépa nínú ìgbésí ayé.

4. Kí ni Bíbélì ṣí payá nípa ipa ọkùnrin àti ti obìnrin?

4 Ìtàn Bíbélì fi hàn pé ipa Ádámù jẹ́ láti mú ipò iwájú gẹ́gẹ́ bí orí ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀. Ó tún ní láti mú ara rẹ̀ bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu láti kún orí ilẹ̀ ayé, kí ó ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ó sì máa jọba lórí gbogbo ẹ̀dá rírẹlẹ̀ ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ipa obìnrin nínú ìdílé tí a fún Éfà ni láti jẹ́ “olùrànlọ́wọ́,” kí ó jẹ́ “àṣekún” fún Ádámù, kí ó wà ní ìtẹríba fún ipò orí rẹ̀, kí ó fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú mímú ète Ọlọ́run tí ó fi lélẹ̀ fún wọn ṣẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 2:18, NW; Kọ́ríńtì Kíní 11:3.

5. Báwo ni a ṣe ba ipò ìbátan tí ó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin jẹ́?

5 Ṣùgbọ́n Ádámù kò bójú tó ẹrù iṣẹ́ rẹ̀, Éfà sì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ lo ànímọ́ obìnrin tí ó ní láti tan Ádámù sínú dídara pọ̀ mọ́ ọn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Nípa gbígba ara rẹ̀ láyè láti ṣe ohun tí ó mọ̀ pé kò tọ́, Ádámù kùnà láti fi ojúlówó ànímọ́ ọkùnrin hàn. Lọ́nà tí ó fi hàn pé ó dẹra sílẹ̀, ó yàn láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ tí a ti tàn jẹ, dípò kí ó ṣègbọràn sí ohun tí Bàbá àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀ sọ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Kò pẹ́ kò jìnnà, tọkọtaya àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í nírìírí ohun tí Ọlọ́run ti rí ṣáájú pé yóò jẹ́ àbájáde àìgbọràn. Ádámù, tí ó ti fi ọ̀rọ̀ ewì tí adùn rẹ̀ légbá kan ṣàpèjúwe aya rẹ̀ tẹ́lẹ̀, wá tọ́ka sí i jábẹ́tẹ́ gẹ́gẹ́ bí ‘obìnrin tí o fún mi.’ Àìpé rẹ̀ ba ànímọ́ ọkùnrin rẹ̀ jẹ́, ó sì mú kí ó ṣì í lò, tí ó yọrí sí ‘jíjọba lé aya rẹ̀ lórí.’ Éfà ní tirẹ̀ yóò máa ní “ìfàsí ọkàn” sí ọkọ rẹ̀, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ lọ́nà tí ó ré kọjá ààlà tàbí lọ́nà tí kò wà déédéé.—Jẹ́nẹ́sísì 3:12, 16, NW.

6, 7. (a) Ìgbégbòdì wo nípa ànímọ́ ọkùnrin ni ó jẹ yọ ṣáájú Ìkún Omi? (b) Kí ni a lè rí kọ́ láti inú ipò tí ó wáyé ṣáájú Ìkún Omi?

6 Àṣìlò ànímọ́ ọkùnrin àti ànímọ́ obìnrin di ohun tí ó búrẹ́kẹ́ gẹ́rẹ́ ṣáájú Ìkún Omi. Àwọn áńgẹ́lì tí ó fi ipò tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ ní ọ̀run sílẹ̀, gbé ara ènìyàn wọ̀, kí wọ́n baà lè gbádùn ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú àwọn obìnrin. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2) Àkọsílẹ̀ tọ́ka sí kìkì àwọn ọmọkùnrin tí ó ti inú àjọṣepọ̀ tí kò bá òfin ìṣẹ̀dá mu náà jáde. Ó sì jọ bí ẹni pé gbogbo àwọn ọmọ náà jẹ́ àdàmọ̀dì, tí wọn kò lè bímọ. Wọ́n di àwọn tí a mọ̀ sí akọni, Néfílímù, tàbí Abiniṣubú, níwọ̀n bí wọn yóò ti mú kí àwọn ẹlòmíràn ṣubú. (Jẹ́nẹ́sísì 6:4; àkíyèsí ẹsẹ ìwé, NW) Ó ṣe kedere pé wọ́n jẹ́ oníwà ipá, oníjàgídíjàgan, tí kì í fi ìgbatẹnirò oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ kankan hàn fún àwọn ẹlòmíràn.

7 Ó ṣe kedere pé, ẹwà ara, ìrísí ara, ìtóbi, tàbí okun nìkan kò ní kí a ní ànímọ́ ọkùnrin tàbí ànímọ́ obìnrin tí ó fani mọ́ra. Ó ṣeé ṣe kí àwọn áńgẹ́lì tí ó gbé ara ènìyàn wọ̀ náà lẹ́wà. Àwọn Néfílímù pẹ̀lú tóbi, wọ́n sì ki pọ́pọ́, ṣùgbọ́n a ti gbé èrò orí wọn gbòdì. Àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn náà àti àwọn ọmọ wọn fi ìwà pálapàla takọtabo àti ìwà ipá kún orí ilẹ̀ ayé. Nítorí èyí, Jèhófà mú ayé yẹn wá sí òpin. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5-7) Ṣùgbọ́n, Ìkún Omi náà kò mú agbára ìdarí ẹ̀mí èṣù kúrò, bẹ́ẹ̀ sì ni kò mú àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kúrò. Ànímọ́ ọkùnrin àti ànímọ́ obìnrin tí a fi hàn lọ́nà tí kò yẹ tún jẹ yọ lẹ́yìn Àkúnya náà, àwọn àpẹẹrẹ tí ó dára àti èyí tí kò dára sì wà nínú Bíbélì tí a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára wọn.

8. Àpẹẹrẹ àtàtà wo nípa ànímọ́ tí ó yẹ ọkùnrin ni Jósẹ́fù fi lélẹ̀?

8 Jósẹ́fù àti aya Pọ́tífárì fi ìyàtọ̀ lílágbára lélẹ̀ nípa ànímọ́ tí ó yẹ ọkùnrin àti ànímọ́ obìnrin lójú ìwòye ti ayé. Aya Pọ́tífárì, tí ó ní ìfẹ́ onígbòónára sí Jósẹ́fù arẹwà, gbìyànjú láti fa ojú rẹ̀ mọ́ra. Ní àkókò yẹn, kò tí ì sí òfin kankan tí a kọ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí ó ka àgbèrè tàbí panṣágà léèwọ̀. Síbẹ̀, Jósẹ́fù sá kúrò lọ́dọ̀ obìnrin oníwà pálapàla yẹn, ó sì fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọkùnrin ti Ọlọ́run, ọ̀kan tí ń fi ànímọ́ ọkùnrin tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà hàn.—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9, 12.

9, 10. (a) Báwo ni Ayaba Fáṣítì ṣe ṣi ànímọ́ obìnrin rẹ̀ lò? (b) Àpẹẹrẹ àtàtà wo nípa ànímọ́ obìnrin ni Ẹ́sítérì pèsè fún wa?

9 Ẹ́sítérì àti Ayaba Fáṣítì pèsè àpẹẹrẹ yíyàtọ̀ síra lọ́nà kíkàmàmà fún àwọn obìnrin. Fáṣítì lè ti ronú pé òun lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ tí Ọba Ahasuwérúsì yóò máa jọ́hẹn sí gbogbo ohun tí òun bá fẹ́. Ṣùgbọ́n, ẹwà ojú lásán ni ó ní. Kò ní ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ànímọ́ obìnrin, nítorí tí ó kùnà láti tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀, tí ó tún jẹ́ ọba. Ọba kọ̀ ọ́, ó sì yan obìnrin kan tí ó ní ojúlówó ànímọ́ obìnrin, tí ó bẹ̀rù Jèhófà ní tòótọ́, láti jẹ́ aya rẹ̀.—Ẹ́sítérì 1:10-12; 2:15-17.

10 Ẹ́sítérì jẹ́ àpẹẹrẹ àgbàyanu fún àwọn obìnrin Kristẹni. Ó “ní ẹwà, ó sì dára láti wò,” síbẹ̀ ó fi ọ̀ṣọ́ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” hàn. (Ẹ́sítérì 2:7; Pétérù Kíní 3:4) Kò ka ọ̀ṣọ́ ṣekárími sí ohun bàbàrà. Ẹ́sítérì fi ọgbọ́n àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn, ó tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀, Ahasuwérúsì, àní nígbà tí ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ̀ wà nínú ewu pàápàá. Ẹ́sítérì dákẹ́ jẹ́ẹ́ nígbà tí ó bọ́gbọ́n mu láti ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó sọ̀rọ̀ tìgboyàtìgboyà nígbà tí ó pọn dandan àti nígbà tí ó yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Ẹ́sítérì 2:10; 7:3-6) Ó tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Módékáì, mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tí ó dàgbà dénú. (Ẹ́sítérì 4:12-16) Ó fi ìfẹ́ àti ìdúróṣinṣin hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀.

Ìrísí Òde Ara

11. Kí ní yẹ kí a ní lọ́kàn ní ti ìrísí òde ara?

11 Kí ni àṣírí ànímọ́ tí ó yẹ kí obìnrin ní? Ìyá kan sọ pé: “Ojú dáradára ní ẹ̀tàn, ẹwà sì já sí asán: ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa, òun ni kí a fi ìyìn fún.” (Òwe 31:30) Nítorí náà, níní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run ṣe kókó, inú rere ìfẹ́, ìwà ẹ̀yẹ, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà, àti ahọ́n tútù ń ṣàlékún ànímọ́ obìnrin dáradára ju bí ẹwà ti ara ti ń ṣe lọ.—Òwe 31:26.

12, 13. (a) Lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́, irú ọ̀rọ̀ wo ní ń jáde lẹ́nu ọ̀pọ̀ ènìyàn? (b) Kí ni ìtumọ̀ Òwe 11:22?

12 Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin kì í fi ọgbọ́n ya ẹnu wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni inú rere ìfẹ́ kò sí lórí ahọ́n wọn. Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn máa ń kún fún èébú, ọ̀rọ̀ àgálámàṣà, ọ̀rọ̀ rírùn, àti ọ̀rọ̀ tí kò fi ìgbatẹnirò hàn. Àwọn ọkùnrin kan máa ń rò pé ọ̀rọ̀ rírùn jẹ́ àmì ànímọ́ ọkùnrin, àwọn obìnrin kan sì máa ń fi àìlọ́gbọ́n fara wé wọn. Síbẹ̀, bí obìnrin kan bá rẹwà, ṣùgbọ́n tí kò ní làákàyè, tí ó sì máa ń jiyàn, tí ó máa ń sọ̀rọ̀ àgálámàṣà, tàbí tí ó jẹ́ agbéraga, a ha lè sọ pé ó rẹwà ní tòótọ́ bí, pé ó ní ànímọ́ obìnrin ní tòótọ́? “Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni arẹwà obìnrin tí kò mòye.”—Òwe 11:22.

13 Ẹwà òun ọ̀rọ̀ àìmọ́, ọ̀rọ̀ àgálámàṣà, tàbí àìní làákàyè kò lè bá ànímọ́ obìnrin tí ẹnì kan lè fi hàn pé òun ní mu. Ní tòótọ́, irú ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu bẹ́ẹ̀ lè mú kí ẹnì kan tí ó rẹwà ní ti gidi dà bí òburẹ́wà. A lè tètè lóye pé, ìrísí ọkùnrin tàbí obìnrin kan kò lè mú ipa búburú tí ìbínú, ìlọgun, tàbí ọ̀rọ̀ èébú ẹnu rẹ̀ ń ní lórí ẹni kúrò tàbí kí ó sọ ọ́ di ohun tí ó dára. Gbogbo Kristẹni lè mú kí àwọn jẹ́ arẹwà lójú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn tí a gbé karí Bíbélì, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.—Éfésù 4:31.

14. Irú ọ̀ṣọ́ wo ni a gbóríyìn fún nínú Pétérù Kíní 3:3-5, kí sì ni èrò rẹ nípa rẹ̀?

14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ànímọ́ tẹ̀mí ni a gbé ojúlówó ànímọ́ obìnrin àti ànímọ́ ọkùnrin kà, ìyọsíni àti ìrísí wa, títí kan aṣọ tí a wọ̀ àti ọ̀nà tí a gbà wọ̀ ọ́, ń sọ ohun kan nípa wa. Kò sí iyè méjì pé àpọ́sítélì Pétérù ní àwọn àṣà aṣọ àti ìmúra pàtó kan ní ọ̀rúndún kìíní lọ́kàn, nígbà tí ó fún àwọn obìnrin Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì ṣe jẹ́ ti irun dídì lóde ara àti ti fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára tàbí ti wíwọ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó ní ìníyelórí ńláǹlà ní ojú Ọlọ́run. Nítorí, nígbà yẹn lọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obìnrin mímọ́ tí wọ́n ní ìrètí nínú Ọlọ́run máa ń ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, ní fífi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ tiwọn.”—Pétérù Kíní 3:3-5.

15. Kí ní yẹ kí àwọn obìnrin Kristẹni tiraka láti fi hàn nínú ìmúra wọn?

15 A rí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ lórí ìwọṣọ obìnrin nínú Tímótì Kíní 2:9, 10 pé: “Mo ní ìfẹ́ ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú . . . ní ọ̀nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí wọn jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ onífọkànsìn fún Ọlọ́run, èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.” Níbẹ̀, ó tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìwọṣọ tí ó wà létòletò, tí ń fi ìyè kooro èrò inú hàn.

16, 17. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń ṣi aṣọ lò lónìí? (b) Ìparí èrò wo ni ó yẹ kí a dé lójú ìwòye ìmọ̀ràn tí ó wà nínú Diutarónómì 22:5?

16 Fún ọkùnrin tàbí obìnrin, ọmọdékùnrin tàbí ọmọdébìnrin, láti hùwà tàbí múra ní ọ̀nà tí ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ takọtabo sókè kì yóò ṣàlékún ojúlówó ànímọ́ ọkùnrin tàbí ojúlówó ànímọ́ obìnrin, ó sì dájú pé kò ní fi ọlá fún Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú ayé máa ń ṣe àṣejù débi fífi ànímọ́ ìwà ọkùnrin tàbí ànímọ́ ìwà obìnrin ṣe fọ́rífọ́rí nínú ìwọṣọ àti nínú ìwà wọn. Àwọn mìíràn ń mú kí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin rúni lójú nítorí ète ìwà pálapàla. Ẹ wo bí ó ti yẹ kí àwa Kristẹni kún fún ọpẹ́ tó, pé Bíbélì ṣí èrò Ọlọ́run payá! Jèhófà sọ fún Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Obìnrin kò gbọ́dọ̀ mú ohun tí í ṣe ti ọkùnrin wọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò gbọ́dọ̀ mú aṣọ obìnrin wọ̀: nítorí pé gbogbo ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ìríra ni wọ́n sí OLÚWA.”—Diutarónómì 22:5.

17 Nípa èyí, ó dájú pé ìwọ yóò gbádùn ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1988 sọ ní ojú ìwé 17, pé: “Ọ̀ràn-àríyànriyàn naa kii ṣe yálà ọ̀nà-àṣà kan pàtó jẹ́ eyi tí a ṣe dé-góńgó-ìpẹ̀kun lọna àṣà-òde bikoṣe yálà ó bamuwẹku fun ẹnikan tí ó jẹwọsọ pe òun jẹ́ ojiṣẹ Ọlọrun. (Rome 12:2; 2 Corinth 6:3) Awọn aṣọ tí wọn ṣe ṣákálá-yẹpẹrẹ jù tabi tí wọn funni-pinpin lè bu ìhìn-iṣẹ́ wa kù. Awọn ọ̀nà-àṣà tí ńdìídì sọ ọkunrin di obinrin tàbí sọ obinrin di ọkunrin lọna tí ó hàn-gbangba-kedere niti pàtó jẹ́ ohun tí kò bá àṣẹ-ìtọ́ni mu. (Fiwe Deuteronomy 22:5.) Dajudaju-nitootọ, awọn àṣà agbègbè-àdúgbò lè yàtọ̀síra, ní ìbámu pẹ̀lú ojú-ọjọ́, àwọn ohun ti iṣẹ́-àjókòótì nbeere fun, àti bẹẹ bẹẹ lọ, kí ijọ Kristian má baa ṣe àwọn òfin-ìdíwọ̀n líle-gbagidi lati ní ẹgbẹ́-àwọn-ará kárí-ayé ninu.”

18. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni a lè gbé ní lílo ìmọ̀ràn inú Bíbélì nípa ìwọṣọ àti ìmúra?

18 Ẹ wo bí ìmọ̀ràn yí ṣe wà déédéé tí ó sì ṣe wẹ́kú tó! Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn Kristẹni kan, tọkùnrin tobìnrin, ń fi ìkùgbù tẹ̀ lé ohun yòó wù tí ayé bá gbé lárugẹ nínú àṣà ìwọṣọ àti ìmúra, láìronú nípa bí yóò ṣe fi Jèhófà àti ìjọ Kristẹni hàn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe àyẹ̀wò ara rẹ̀ fínnífínní láti rí i bí ìrònú ayé bá ti nípa lórí wa. A sì lè tọ arákùnrin tàbí arábìnrin onírìírí tí a bọ̀wọ̀ fún dáradára lọ, pé kí ó sọ ojú ìwòye rẹ̀ nípa ìyípadà èyíkéyìí tí a lè ṣe nínú àṣà ìwọṣọ wa, kí a sì ronú lórí àwọn àbá náà jinlẹ̀jinlẹ̀.

Àwọn Ọkùnrin àti Obìnrin Kristẹni—Ojúlówó Ọkùnrin àti Obìnrin

19. Agbára ìdarí burúkú wo ni ó yẹ kí a gbéjà kò?

19 Sátánì ni ọlọ́run ayé yìí, a sì lè rí agbára ìdarí rẹ̀ nínú ìdàrúdàpọ̀ tí ó ti dá sílẹ̀ nínú ọ̀ràn jíjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ìyẹn sì lọ ré kọjá ọ̀ràn aṣọ wíwọ̀. (Kọ́ríńtì Kejì 4:4) Ní àwọn ilẹ̀ kan, ọ̀pọ̀ obìnrin ń bá àwọn ọkùnrin díje lórí ipò jíjẹ́ olórí, láìka ìlànà Bíbélì sí. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àìmọye ọkùnrin ń kọ ẹrù iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí orí sílẹ̀, bí Ádámù ti ṣe. Àwọn kan tilẹ̀ wà tí wọ́n ń gbìyànjú láti yí ipa wọn nínú ìgbésí ayé pa dà nípa dídi ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin lò pọ̀ àti obìnrin tí ń bá obìnrin lò pọ̀. (Róòmù 1:26, 27) Bíbélì kò gbé ọ̀nà ìgbésí ayé àfirọ́pò èyíkéyìí kalẹ̀, tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. Àwọn tí ó bá sì jẹ́ wí pé kí wọ́n tó di Kristẹni, wọ́n ń ṣiyè méjì nípa ipa wọn gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tàbí obìnrin, tàbí tí wọ́n ń ṣiyè méjì nípa nínífẹ̀ẹ́ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí pẹ̀lú ọkùnrin àti obìnrin, lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run yóò jẹ́ fún ire wọn ayérayé, ọ̀pá ìdiwọ̀n kan tí ó dájú pé gbogbo àwọn tí ó bá dé ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn yóò mọrírì.

20. Ipa wo ni ó yẹ kí Gálátíà 5:22, 23 ní lórí ojú ìwòye wa nípa ànímọ́ ọkùnrin àti ànímọ́ obìnrin?

20 Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ó yẹ kí àwọn Kristẹni lọ́kùnrin lóbìnrin mú èso ẹ̀mí Ọlọ́run dàgbà—ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu—kí wọ́n sì máa fi í hàn. (Gálátíà 5:22, 23) Nínú arabaríbí ọgbọ́n rẹ̀, Ọlọ́run mú kí àwọn ọkùnrin lè ṣàlékún ànímọ́ ọkùnrin wọn, kí àwọn obìnrin sì ṣàlékún ànímọ́ obìnrin tiwọn pẹ̀lú, nípa mímú àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn dàgbà. Ó rọrùn láti bọ̀wọ̀ fún ọkùnrin tí ń fi èso tẹ̀mí hàn, ó sì rọrùn láti nífẹ̀ẹ́ obìnrin tí ń ṣe bẹ́ẹ̀.

21, 22. (a) Ọ̀nà ìgbésí ayé wo ni Jésù fi lélẹ̀? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi ànímọ́ ọkùnrin rẹ̀ hàn?

21 Jésù Kristi ni ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tí ì gbé ayé rí, ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ ló sì yẹ kí àwọn Kristẹni fara wé. (Pétérù Kíní 2:21-23) Gẹ́gẹ́ bíi Jésù, ó yẹ kí àwọn ọkùnrin àti obìnrin jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, kí wọ́n sì ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Jésù fi àgbàyanu ànímọ́ ìfẹ́, ìwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, àti àánú hàn. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, a retí pé kí a fara wé e, kí a sì fẹ̀rí hàn pé a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.—Jòhánù 13:35.

22 Jésù Kristi jẹ́ ojúlówó ọkùnrin, a sì lè rí àwọn ànímọ́ ọkùnrin tí ó ní ní kedere, bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Kò fẹ́yàwó rí, ṣùgbọ́n Bíbélì fi hàn pé ó gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí ó wà déédéé pẹ̀lú àwọn obìnrin. (Lúùkù 10:38, 39) Àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú ọkùnrin àti obìnrin mọ́, ó sì lọ́lá ní gbogbo ìgbà. Òun jẹ́ àpẹẹrẹ pípé pérépéré nínú fífi ànímọ́ ọkùnrin hàn. Kò gba ẹnikẹ́ni láyè—ì báà jẹ́ ọkùnrin, obìnrin, tàbí áńgẹ́lì aláìgbọràn—láti gba ànímọ́ ọkùnrin oníwà-bí-Ọlọ́run tí ó ní àti ìṣòtítọ́ sí Jèhófà lọ́wọ́ rẹ̀. Kò lọ́ tìkọ̀ láti gba ẹrù iṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ láìṣàròyé.—Mátíù 26:39.

23. Ní ti ipa tí ọkùnrin àti obìnrin ń kó, báwo ni a ṣe bù kún àwọn Kristẹni tòótọ́ lọ́na tí ó yàtọ̀ gédégbé?

23 Ẹ wo irú ìdùnnú tí ń mú wá láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn Jèhófà àti láti máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọdékùnrin àti àwọn ọmọdébìnrin, tí nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti ṣíṣègbọràn sí i jẹ́ ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn! Ṣíṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò há wa mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a dá wa sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ ayé yìí àti àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí ń sọ ẹwà, ète, àti ipa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ọkùnrin tàbí obìnrin ń kó dìbàjẹ́. A lè ní ojúlówó ayọ̀ tí ó máa ń wá láti inú ṣíṣe ipa tí Ọlọ́run yàn fún wa nínú ìgbésí ayé, yálà a jẹ́ akọ tàbí abo. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó sí Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá, fún gbogbo ìpèsè rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ nítorí wa, àti fún dídá tí ó dá wa ní akọ àti abo!

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Ipa yíyẹ wo fún ọkùnrin àti obìnrin ni Bíbélì ṣàpèjúwe?

◻ Báwo ni a ṣe gbé ànímọ́ ọkùnrin gbòdì ṣáájú Ìkún Omi, báwo ni a sì ti lọ́ ànímọ́ ọkùnrin àti ànímọ́ obìnrin pọ̀ ní ọjọ́ wa?

◻ Ìmọ̀ràn Bíbélì wo nípa ìrísí ni ìwọ yóò sapá láti fi sílò?

◻ Báwo ni àwọn Kristẹni lọ́kùnrin lóbìnrin ṣe lè fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọkùnrin àti obìnrin?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bí Ẹ́sítérì tilẹ̀ rẹwà, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú ìwà tútù rẹ̀ ni a sábà máa ń rántí jù lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Fún ìmúra rẹ ní àfiyèsí tí ó yẹ, bí o ti ń fún ẹwà inú lọ́hùn-ín ní ìjẹ́pàtàkì títóbi jù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́