Ìgbésí Ayé Tí N kò Kábàámọ̀ rí
GẸ́GẸ́ BÍ PAUL OBRIST ṢE SỌ Ọ́
Ní 1912, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà, Màmá kú nígbà tí ó fẹ́ bí ọmọ rẹ̀ karùn-ún. Ní nǹkan bí ọdún mèjí lẹ́yìn náà, ọ̀dọ́bìnrin kan tí ń ṣe ọmọ ọ̀dọ̀, Berta Weibel, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ fún ìdílé wa. Nígbà tí Bàbá fẹ́ ẹ ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, inú àwa ọmọ dùn pé a tún pa dà ní màmá kan.
A GBÉ ní Brugg, ìlú kékeré kan ní apá ibi tí a ti ń sọ èdè German ní ilẹ̀ Switzerland. Kristẹni ni Berta ní tòótọ́, mo sì fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìtẹ̀jáde Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà) ní 1908, ó sì ń ṣàjọpín ohun tí ó kọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
Ní 1915, kété lẹ́yìn tí Berta àti Bàbá fẹ́ra wọn, mo tẹ̀ lé e lọ síbi tí a ti fi àwòrán “Photo-Drama of Creation” (Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá) hàn. Àwòrán àti sinimá ti Ẹgbẹ́ Àwọn Onítara Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé yìí nípa lórí èrò inú àti ọkàn àyà mi. Ó wú àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú lórí. Gbọ̀ngàn tí ó wà ní Brugg kún fọ́fọ́ débi pé àwọn ọlọ́pàá ti àwọn ilẹ̀kùn, tí wọ́n sì dá àwọn mìíràn tí ń dé pa dà. Ọ̀pọ̀ sì gbìyànjú láti gba ojú fèrèsé kan tí a ṣí sílẹ̀ wọlé nípa lílo àkàbà, àwọn díẹ̀ sì ṣàṣeyọrí.
Àpẹẹrẹ Àtàtà Màmá
Ogun Àgbáyé Kìíní ń jà lọ́wọ́ ní Europe, àwọn ènìyàn sì ń bẹ̀rù nípa ọjọ́ ọ̀la. Nítorí náà, láti kàn síni láti ilé dé ilé pẹ̀lú ìhìn iṣẹ́ títuni nínú nípa Ìjọba Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Màmá ti ṣe, jẹ́ iṣẹ́ àyànfúnni wíwúni lórí. Nígbà míràn, ó máa ń jẹ́ kí n tẹ̀ lé òun lọ, mo sì máa ń gbádùn èyí gidigidi. Ní 1918, ó ṣeé ṣe fún Màmá láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Bàbá kò dá sí ìjọsìn Màmá títí tí ó fi ṣe ìrìbọmi, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò ó. Ní ọjọ́ kan, ó kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀, ó sì jù wọ́n sínú sítóòfù. Kìkì Bíbélì Màmá ni ó ṣeé ṣe fún un láti sáré yọ kúrò nínú iná. Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe tẹ̀ lé e jẹ́ ìyàlẹ́nu ńlá. Ó tọ Bàbá lọ, ó sì gbá a mọ́ra. Kò di kùnrùngbùn sí i rárá.
Pẹ̀lú ìyàlẹ́nu ńlá, Bàbá sinmẹ̀dọ̀. Ṣùgbọ́n, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń gbé àtakò dìde, a sì ní láti fara da ìbínú rẹ̀.
Iṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́ àti Ìtẹ̀síwájú Nípa Tẹ̀mí
Ní 1924, lẹ́yìn tí mo parí kíkọ́ṣẹ́ aṣerunlóge fún ọdún mẹ́ta, mo fi ilé sílẹ̀, mo sì rí iṣẹ́ sí apá ibi tí a ti ń sọ èdè Faransé ní ilẹ̀ Switzerland. Èyí fún mi láǹfààní láti túbọ̀ mọ èdè Faransé sí i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣíkúrònílé náà pa ìtẹ̀síwájú mi nípa tẹ̀mí lára lọ́nà kan ṣáá, n kò pàdánù ìfẹ́ tí mo ní fún òtítọ́ Bíbélì. Nítorí náà, nígbà tí mo pa dà sílé ní ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ìjọ Kristẹni ní Brugg.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo ṣí lọ sí Rheinfelden, ìlú kékeré kan tí ó tó nǹkan bíi 40 kìlómítà sílé. Mo ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ní ṣọ́ọ̀bù tí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ti ń ṣe irun lóge, mo sì ń bá ìtẹ̀síwájú mi nípa tẹ̀mí lọ nípa pípàdé pọ̀ pẹ̀lú àwùjọ kékeré ti Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó ń mú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ wa sópin, Arákùnrin Soder, alàgbà tí ń ṣàbójútó, béèrè pé: “Ta ni ń wéwèé láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ní ọjọ́ Sunday?” Mo yọ̀ǹda ara mi, ní ríronú pé n ó tẹ̀ lé ẹnì kan, tí a óò sì fi bí a ti ń ṣe iṣẹ́ náà hàn mí.
Nígbà tí Sunday kò, tí a sì dé ìpínlẹ̀ wa, Arákùnrin Soder sọ pé, “Ọ̀gbẹ́ni Obrist yóò ṣiṣẹ́ níbẹ̀ yẹn.” Bí ọkàn àyà mi tilẹ̀ ń lù kìkìkì ju ti ìgbàkígbà rí lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kàn sí àwọn ènìyàn nínú ilé wọn, mo sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 20:20) Láti ìgbà yẹn wá, n kò juwọ́ sílẹ̀ nínú títẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣàṣeparí ṣáájú kí òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí tó dé. (Mátíù 24:14) Ní March 4, 1934, nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún 28, mo fẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi.
Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, mo rí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣerunlóge ní Lugano, ìlú kan ni apá ibi tí a ti ń sọ èdè Ítálì ní Switzerland. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere níbẹ̀ láìjáfara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò gbọ́ èdè Ítálì tó bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ní Sunday tí mo kọ́kọ́ jáde fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, mo fi 20 ìwé kékeré tí mo ní lápò síta. Bí àkókò ti ń lọ, ó ṣeé ṣe fún mi láti kó àwọn olùfìfẹ́hàn díẹ̀ jọ, láti dá àwùjọ kan sílẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ṣe ìrìbọmi, a sì dá ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sílẹ̀ ní Lugano, ní February 1937.
Ní oṣù méjì lẹ́yìn náà, ní April 1937, mo gba lẹ́tà kan tí ó yí ìgbésí ayé mi pa dà pátápátá. Ìkésíni láti wá ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì ni, bí a ti ń pe ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè kan. Mo tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà kíákíá—ìpinnu kan tí n kò kábàámọ̀ rí. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ ohun tí ó di iṣẹ́ ìgbésí ayé ọlọ́gọ́ta ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nìyẹn.
Iṣẹ́ Ìsìn Bẹ́tẹ́lì ní Àkókò Oníwàhálà
Ìlú Bern, olú ìlú Switzerland ni Bẹ́tẹ́lì Swiss wà ní ìgbà náà. A máa ń tẹ àwọn ìwé ńlá, ìwé kékeré, àti àwọn ìwé ìròyìn jáde ní èdè 14, a sì máa ń fi ìwọ̀nyí ránṣẹ́ jákèjádò Europe. Ní ìgbà kan, mo máa ń fi kẹ̀kẹ́ ìkẹ́rù kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ti tẹ̀ lọ sí ibùdókọ̀ ojú irin, níwọ̀n bí ọkọ̀ akẹ́rù kì í ti í fìgbà gbogbo wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àwọn ìgbà yẹn. Iṣẹ́ àyànfúnni mi àkọ́kọ́ ní Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ní Ẹ̀ka Ìto Ọ̀rọ̀ Pọ̀, níbi tí a ti máa ń to àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ tí a óò tẹ̀ jáde jọ. Kò pẹ́ kò jìnnà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní yàrá ìgbàlejò, mo sì tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onígbàjámọ̀ fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì.
Ní September 1939, Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀, ìkọlù ìjọba Nazi sì tàn kálẹ̀ jákèjádò Europe. Switzerland jẹ̀ orílẹ̀-èdè tí kò dá sí tọ̀tún tòsì, tí ó wà ní agbedeméjì àwọn orílẹ̀-èdè tí ń jagun. Lákọ̀ọ́kọ́, a ń ṣe ìgbòkègbodò Kristẹni wa lọ, láìsí ìyọnu. Nígbà tí ó yá, ní July 5, 1940, ní aago méjì ọ̀sán, nígbà tí mo wà lórí àga mi ní yàrá ìgbàlejò, ọlọ̀tọ̀ ìlú kan wọlé, sójà kan tí ó gbé ìbọn dáni, tí ó sì fi idà kọ́rùn tẹ̀ lé e.
Ọlọ̀tọ̀ ìlú náà kígbe pé: “Ibo ni Zürcher wà?” Franz Zürcher ni alábòójútó ẹ̀ka iṣẹ́ ìwàásù wa ní Switzerland nígbà yẹn lọ́hùn-ún.
Mo béèrè pé: “Ta ni kí n sọ pé ó ń béèrè rẹ̀?” Lójú ẹsẹ̀, wọ́n gbá mi mú, wọ́n sì wọ́ mi lọ sókè, wọ́n pàṣẹ fún mi láti mú wọn lọ sí ọ́fíìsì Zürcher.
Wọ́n pàṣẹ fún gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì—nǹkan bí 40 ni wá nígbà yẹn—láti kóra jọ sí yàrá ìjẹun. Wọ́n gbé ẹ̀rọ arọ̀jò ọta mẹ́rin síwájú ìta láti dẹ́rù ba ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ sá lọ. Nínú ilé, àwọn sójà bí 50 bẹ̀rẹ̀ sí í túlé. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun tí wọ́n ń retí, wọn kò rí ẹ̀rí kankan pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ sí gbígbé àtakò sí ṣíṣiṣẹ́ ológun lárugẹ. Síbẹ̀, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ọ̀pọ̀ yaturu ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, wọ́n sì fi ọkọ̀ ogun akẹ́rù márùn-ún rù wọ́n lọ.
Nígbà tí a kọ̀ láti jẹ́ kí ìjọba ṣòfíntótó Ilé Ìṣọ́, wọ́n dá títẹ̀ ẹ́ ní Switzerland dúró. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn òṣìṣẹ́ díẹ̀ ni a nílò, a sì rọ àwọn mẹ́ńbà ìdílè náà tí wọ́n ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ láti fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀, kí wọ́n sì di aṣáájú ọ̀nà, bí a ti ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún.
Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà Nígbà Ogun
Ní July 1940, mo pa dà sí àgbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Ítálì ní Switzerland, nítòsí Lugano, níbi tí mo gbé kí n tó wá sí Bẹ́tẹ́lì. Ìpínlẹ̀ tí àwọn Kátólíìkì tí kò fi ẹ̀sìn wọn ṣeré kún inú rẹ̀ yí, tí ó tún wà lábẹ́ agbára Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀, di ìpínlẹ̀ tí a yàn fún mi gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ọjọ́ kan tí àwọn ọlọ́pàá kò dá mi dúró láti pàṣẹ fún mi pé kí n jáwọ́ nínú ìgbòkègbodò ìwàásù mi. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí mo ń bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ ní ẹnu ọ̀nà ọgbà kan, ọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ àmúròde gbá mi mú láti ẹ̀yìn, ó fà mi lọ sídìí ọkọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ìlú, ó sì wà mí lọ sí Lugano. Ó fà mí lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n fi ìbéèrè wá mi lẹ́nu wò, mo ṣàlàyé pé Jèhófà Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wa láti wàásù.
Ọlọ́pàá náà fi ìgbéraga dáhùn pé: “Níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé, àwa ni a ń pàṣẹ. Ọlọ́run lè máa pàṣẹ ní ọ̀run!”
Nígbà ogun, ó ṣe kókó ní pàtàkì pé kí a kọbi ara sí ìmọ̀ràn Jésù láti “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò síbẹ̀ kí a jẹ́ ọlọ́rùn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.” (Mátíù 10:16) Nítorí náà, mo fi èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mi pa mọ́ sínú àpò abẹ́nú ṣẹ́ẹ̀tì mi. Láti lè rí i dájú pé n kò pàdánù èyíkéyìí, mo wọ ṣòkòtò péńpé tí ó fún tinríntinrín ní itan.
Bí àkókò ti ń lọ, mo gba ìtọ́ni láti ṣí lọ sí àfonífojì Engadine, níbi tí àwọn ọlọ́pàá tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọdẹ mi kiri, tí mo sì ń sá fún wọn. Èyí jẹ́ àfonífojì ẹlẹ́wà kan ní ìlà oòrùn Àwọn Òkè Ńlá Swiss, tí yìnyín máa ń bò mọ́lẹ̀ nígbà òtútù, nítorí náà mó ránṣẹ́ pé kí wọ́n fi bàtà orí yìnyín ránṣẹ́ sí mi, kí ó baà lè ṣeé ṣe fún mi láti rìn káàkiri ìpínlẹ̀ mi.
Ó ṣe pàtàkí láti wọ ìbọ̀wọ́ tí ń mọ́wọ́ móoru nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò nígbà òtútù. Nítorí tí mo máa ń lò ó léraléra, tèmi bẹ̀rẹ̀ sí í gbó. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó ní ọjọ́ kan láti gba àpò ìwé tí n kò retí rárá nípasẹ̀ ìfìwérańṣẹ́, tí súwẹ́tà tí a fọwọ́ hun àti ìbọ̀wọ́ tí ń mọ́wọ́ móoru wà nínú rẹ̀! Kristẹni arábìnrin kan tí ó wà nínú ìjọ tí mo wà tẹ́lẹ̀ ní Bern ni ó hun ún fún mi. Àní títí di ìsinsìnyí, nígbà tí mo ba ronú nípa rẹ̀, ọkàn mi máa ń kún fún ọpẹ́.
Ọ̀pọ̀ Àǹfààní Gbígbádùnmọ́ni
Ní 1943, ipò nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í fara rọ ní Switzerland, a sì pè mí pa dà sí Bẹ́tẹ́lì. Nítorí àwọn ìṣòro kan tí ìjọ tí a ti ń sọ èdè Faransé ní Lausanne, tí ó jìn tó 100 kìlómítà ní, a yàn mí láti máa ṣèbẹ̀wò sí ìlú yẹn déédéé láti ran àwọn akéde lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye tí ó yẹ nípa ètò àjọ Ọlọ́run.
Lẹ́yìn náà, mo sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká fún gbogbo ìjọ tí ń sọ èdè Faransé ní Switzerland. Ní àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀, mo máa ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, ṣùgbọ́n mo máa ń lo ọjọ́ Friday, Saturday, àti Sunday láti bẹ̀ ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ní àfikún sí i, nígbà tí a dá ìjọ tí ń sọ èdè Faransé sílẹ̀ ní Bern ní 1960, mo di alábòójútó olùṣalága rẹ̀. Mo di ipò yí mú títí di ọdún 1970, nígbà tí Bẹ́tẹ́lì ṣí kúrò ní Bern lọ sí àyíká ẹlẹ́wà tí ó wà nísinsìnyí ní ìlú Thun.
Inú mi dùn láti rí àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí kékeré kan tí ń sọ èdè Ítálì ní Thun, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Bí àkókò ti ń lọ, a dá ìjọ kan sílẹ̀, mo sì ṣíṣẹ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, títí di ìgbà tí àwọn ọ̀dọ́ arákùnrin di ẹni tí ó tóótun láti gbé ẹrù iṣẹ́ náà.
Ohun kan tí mo kà sí àǹfààní gbígbádùnmọ́ni ní pàtàkí ni, lílọ sí àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ti àwọn ènìyàn Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, ní 1950, a ṣe Àpéjọ Ìbísí Ìjọba mánigbàgbe kan ní Yankee Stadium, New York. Ṣíṣèbẹ̀wò sí orílé-iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, wú mi lórí gidigidi. N kò sì jẹ́ gbàgbé àsọyé tí Arákùnrin Milton G. Henschel sọ ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e ní Àpéjọ Ìjọsìn Mímọ́ ní London, England, tí ó tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ Jésù náà, “Mo sọ fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá dákẹ́, àwọn òkúta yóò ké jáde.” (Lúùkù 19:40) Arákùnrin Henschel béèrè pé, “Ǹjẹ́ ẹ rò pé àwọn òkúta yóò ní láti ké jáde bí?” Mo ṣì lè gbọ́ igbe, “Rárá!” tí àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá ké.
Nígbà tí mo lọ sí Bẹ́tẹ́lì ní ọdún 1937, bàbá mi, tí ó gbọ́ pé owó táṣẹ́rẹ́ ni a ń gbà, béèrè tàníyàntàníyàn pé, “Ọmọ, báwo ni ìwọ yóò ṣe bójú tó ara rẹ ní ọjọ́ ogbó?” Mo dáhùn nípa ṣíṣàyọlò ọ̀rọ̀ Dáfídì onísáàmù náà pé: “Èmi kò tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú ọmọ rẹ̀ kí ó máa ṣagbe oúnjẹ.” (Orin Dáfídì 37:25) Dájúdájú, ọ̀rọ̀ yí ti ní ìmúṣẹ sí mi lára.
Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó pé ní èyí tí ó ju 80 ọdún lọ, Berta Weibel fẹ́ Bàbá mi, àti pé nípasẹ̀ àpẹẹrẹ àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀, mo di ẹni tí ó mọ Jèhófà àti àwọn ànímọ́ rẹ̀! Bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé mi yòó kù tilẹ̀ fi í ṣẹ̀sín, ó fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ ní 1983. Kò kábàámọ̀ rí láé pé òun sin Ọlọ́run òun, Jèhófà; bẹ́ẹ̀ sì ni èmi náà kò kábàámọ̀ rí láé pé mo jẹ́ àpọ́n, pé mo sì ya ìgbésí ayé mi pátá sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ṣíṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì