Ojú Wo Ni O Fi Ń Wo Ẹ̀ṣẹ̀?
“O KÒ ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan, o kò sì sí ní ipò òṣì kankan; agbára gíga jù lọ ń bẹ nínú rẹ.” Vivekananda, gbajúgbajà ọlọ́gbọ́n èrò orí, tí ó tún jẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù, ni ó sọ gbólóhùn yí jáde nígbà tí ó ń ṣàlàyé àyọkà kan láti inú ìwé mímọ́ ẹ̀sìn Híńdù, Bhagavad Gita. Ní títọ́ka sí ọgbọ́n èrò orí Vedanta, ó wí pé: “Àṣìṣe tí ó tóbi jù lọ ni láti sọ pé o jẹ́ aláìlera, pé o jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.”a
Ṣùgbọ́n, ṣé lóòótọ́ ni pé ènìyàn kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan? Bí ohunkóhun bá tilẹ̀ wà rárá, kí ni ẹnì kan jogún nígbà tí a bí i? Elérò orí tí ó tún jẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù náà, Nikhilananda, sọ pé, kìkì “àwọn àbùdá tí a lè fojú rí nìkan ni a lè jogún.” “Àwọn ìgbésẹ̀ ẹni nígbà àkọ́wáyé” ni ó ń pinnu àwọn ànímọ́ yòó kù. Gẹ́gẹ́ bí Vivekananda ti sọ, “ìwọ ni olùṣẹ̀dá kádàrá ara rẹ.” Ẹ̀sìn Híńdù kò fi ohunkóhun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá kọ́ni.
Èròǹgbà ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá kò sí nínú ìgbàgbọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Zoroaster, àwọn ẹlẹ́sìn Ṣintó, àwọn ọmọlẹ́yìn Confucius, àti àwọn ẹlẹ́sìn Búdà pẹ̀lú. Kódà nínú àwọn ẹ̀sìn tí ó pilẹ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù àti ti Kristẹni, tí wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ wọn, ojú ìwòye àwọn ènìyàn nípa ẹ̀ṣẹ̀ ń yí pa dà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lónìí ni kò ka ara wọn sí ẹlẹ́ṣẹ̀.
Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Cornelius Plantinga kékeré, sọ pé: “Òye òde òní kò fúnni níṣìírí láti báni wí fún híhu ìwà ibi; ní pàtàkì, kò fúnni níṣìírí láti bá ara ẹni wí.” Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù pín nínú ẹ̀bi fífojú kékeré wo ẹ̀ṣẹ̀. Àlùfáà kan ní Yunifásítì Duke sọ pé: “Má wulẹ̀ lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì bí o bá fẹ́ gbọ́ ohunkóhun nípa ẹ̀ṣẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí Plantinga sì ti sọ, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.
Òtítọ́ ni pé, àjálù tí ń dé bá ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà lónìí pọ̀ rẹpẹtẹ. Ìwà ipá, ìwà ọ̀daràn, ogun, gbọ́nmisi-omi-ò-to ti ẹ̀yà ìran, ìjoògùnyó, àbòsí, ìninilára, àti híhu ìwà ipá sí àwọn ọmọdé wọ́pọ̀. Ní tòótọ́, a ti sọ pé ọ̀rúndún ogún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rúndún tí ó kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ jù lọ nínú gbogbo ọ̀rúndún tí aráyé tí ì rí rí. Fi ìrora àti ìyà tí ń jẹ yọ láti inú àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú kún èyí. Ta ni kì í yán hànhàn láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro ńláǹlà tí ó wà nínú ayé lónìí?
Nígbà náà, kí ni ojú ìwòye rẹ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀? Ẹ̀ṣẹ̀ ha jẹ́ àjogúnbá bí? A óò ha bọ́ lọ́wọ́ ìrora àti ìyà láé bí? Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A gbé ọgbọ́n èrò orí Vedanta ka àkọsílẹ̀ Upanishad, tí ó wà ní apá ìparí ìwé mímọ́ ẹ̀sìn Híńdù, Vedas.