Ìwọ Ha Rántí Bí?
Àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ha ti wúlò fún ọ ní ti gidi bí? Nígbà náà, èé ṣe tí o kò fi fi àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí dán agbára ìrántí rẹ wò?
◻ Báwo ni Amágẹ́dọ́nì yóò ṣe rí? (Ìṣípayá 16:14, 16)
Kì yóò dà bí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ti átọ́míìkì tàbí ìjàǹbá tí aráyé ṣokùnfà. Rárá o, èyí jẹ́ ogun Ọlọ́run tí yóò fòpin sí gbogbo ogun tí ẹ̀dá ènìyàn ń jà, tí yóò fòpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé irú ogun bẹ́ẹ̀ lárugẹ, tí yóò sì mú àlàáfíà tòótọ́ wá fún àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà. Kì yóò pẹ́. (Hábákúkù 2:3)—4/15, ojú ìwé 17.
◻ Irú ayẹyẹ ìgbéyàwó wo ní ń bọlá fún Jèhófà?
Ayẹyẹ ìgbéyàwó tí àwọn ohun tẹ̀mí ti jọba lórí àwọn ọ̀nà ayé yóò bọlá fún Jèhófà ní tòótọ́. Àwọn Kristẹni yóò gbádùn ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí wọ́n bá yẹra fún àwọn àṣà ayé dídíbàjẹ́, àwọn ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, àti àṣerégèé; bí wọn kò bá jẹ́ kí ó forí gbárí pẹ̀lú àwọn ìgbòkègbodò déédéé ti ìṣàkóso Ọlọ́run; àti bí wọ́n bá fi ẹ̀mí ìwọ̀ntúnwọ̀nsì hàn dípò ẹ̀mí ṣekárími.—4/15, ojú ìwé 26.
◻ Kí ni a fi ń dá ọkùnrin oníwàtítọ́ mọ̀ yàtọ̀?
Kì í ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ ọkùnrin oníwàtítọ́ kan nìkan ṣoṣo ni ó lè gbẹ́kẹ̀ lé e, ṣùgbọ́n, ní pàtàkì jù, Ọlọ́run pẹ̀lú lè gbẹ́kẹ̀ lé e. A ń rí ìmọ́gaara ọkàn àyà irú ẹni bẹ́ẹ̀ nínú ìwà rẹ̀. Kò sí àrékérekè kankan lọ́wọ́ rẹ̀. Kì í ṣe békebèke tàbí ìbàjẹ́. (Kọ́ríńtì Kejì 4:2)—5/1, ojú ìwé 6.
◻ Kí ni fífi tí Mósè àti Èlíjà fara hàn nínú ìran ìyípadà ológo náà dúró fún?
Nínú àyíká ọ̀rọ̀ ìyípadà ológo náà, Mósè àti Èlíjà dúró fún àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù lọ́nà bíbá a mu wẹ́kú. Pé àwọn, àti Jésù, “fara hàn pẹ̀lú ògo” ṣàpẹẹrẹ pé a óò ṣe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ “lógo pa pọ̀” pẹ̀lú Jésù nínú ètò Ìjọba ọ̀run. (Lúùkù 9:30, 31; Róòmù 8:17; Tẹsalóníkà Kejì 1:10)—5/15, ojú ìwé 12, 14.
◻ Kí ni ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ Ọlọ́run? (Kọ́ríńtì Kíní 2:7)
Ọ̀dọ̀ Jésù Kristi ni ‘àṣírí ọlọ́wọ́’ Ọlọ́run darí àfiyèsí sí. (Éfésù 1:9, 10) Ṣùgbọ́n, kì í ṣe kìkì dídá Jésù mọ̀ yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà tí a ṣèlérí náà. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣàkóso ti ọ̀run, Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ Mèsáyà náà, ó tún kan ipa tí a yàn fún Jésù láti kó nínú ète Ọlọ́run.—6/1, ojú ìwé 13.
◻ Ojú wo ni ó yẹ kí Kristẹni kan fi wo ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn?
Dípò tí òun yóò fi máa wo irú àdánwò bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń pààlà sí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà, ó yẹ kí ó wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan láti mú kí òun túbọ̀ gbára lé e. Ó yẹ kí ó tún rántí pé kì í ṣe kìkì bí ìgbòkègbodò Kristẹni kan ṣe tó nìkan ni a fi ń díwọ̀n ìníyelórí rẹ̀, ṣùgbọ́n nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti bí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó pẹ̀lú. (Máàkù 12:41-44)—6/1, ojú ìwé 26.
◻ Báwo ni lílò tí Jèhófà lo àwọn ẹ̀dá ènìyàn dípò àwọn áńgẹ́lì láti kọ Bíbélì ṣe fi ọgbọ́n ńlá rẹ̀ hàn?
Bí kò bá ní ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn nínú, ì bá ṣòro fún wa láti lóye ìhìn iṣẹ́ inú Bíbélì. Bákan náà, gẹ́gẹ́ bí ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní, Bíbélì tani jí, ó kún fún onírúurú ọ̀rọ̀, ó sì fani mọ́ra.—6/15, ojú ìwé 8.
◻ Kí ni àṣírí ayọ̀ ìdílé?
Àṣírí náà ń bẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, àti nínú lílo àwọn ìlànà rẹ̀, irú bí ìkóra-ẹni-níjàánu, mímọ ipò orí, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídánmọ́rán, àti ìfẹ́.—6/15, ojú ìwé 23, 24.
◻ Báwo ni àwọn ìmúláradá tí Jésù ṣe ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ pé àwọn ní agbára ìwòsàn ń ṣe lónìí?
Àwọn èrò kò fi ìmọ̀lára lílágbára hàn, Jésù kò sì mẹ́mìí wọn gbóná láti mú wọn jí gìrì. Ní àfikún sí i, Jésù kò kùnà láé láti mú àwọn aláìsàn lára dá ní ṣíṣàwáwí pé owó tí wọ́n ń dá kò pọ̀ tó tàbí pé wọn kò ní ìgbàgbọ́.—7/1, ojú ìwé 5.
◻ Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní àyè kan nínú ète rẹ̀ àtọ̀runwá ní ti orúkọ rẹ̀ àti Ìjọba rẹ̀?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà ti fi òtítọ́ síkàáwọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀. Ìkejì, ó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Àti ìkẹta, a ní ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé àti ìṣètò gbígbádùn mọ́ni ti ètò àjọ Jèhófà fún ìjọsìn.—7/1, ojú ìwé 19, 20.
◻ Kí ni ìwà funfun?
Ìwà funfun jẹ́ ìwà gíga lọ́lá, ìwà rere, ìgbésẹ̀ àti ìrònú títọ́. Kì í ṣe ànímọ́ tí kì í ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ó jẹ́ èyí tí ń ṣiṣẹ́, tí ń ṣiṣẹ́ rere. Ìwà funfun ní nínú ju yíyẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ lọ; ó túmọ̀ sí lílépa ohun rere. (Tímótì Kíní 6:11)—7/15, ojú ìwé 14.
◻ Kí ni ogún tí ó níye lórí jù lọ tí àwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn?
Ogún tí ó níye lórí jù lọ ni àpẹẹrẹ àwọn fúnra wọn ní ti fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn. Lọ́nà títayọ lọ́lá, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ rí àwọn òbí wọn tí ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí Ọlọ́run nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe, kí wọ́n sì gbọ́ wọn tí wọ́n ń sọ ọ́ jáde.—7/15, ojú ìwé 21.
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun pàtàkì tí dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí ó gbéṣẹ́ ní nínú?
Ẹ gbọ́dọ̀ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé. Ẹ gbọ́dọ̀ ‘ra àkókò pa dà’ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. (Éfésù 5:15-17) Jẹ́ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ta àwọn ọmọ jí nípa jíjẹ́ kí Bíbélì tani jí. Kí àwọn ọmọdé lè gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ kópa.—8/1, ojú ìwé 26, 28.