Fífi Ìdúróṣinṣin Gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tí A Mí Sí Lárugẹ
“Àwa ti kọ àwọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tini lójú sílẹ̀ ní àkọ̀tán, a kò rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣe àbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—KỌ́RÍŃTÌ KEJÌ 4:2.
1. (a) Kí ni ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ tí a là sílẹ̀ nínú Mátíù 24:14 àti 28:19, 20 ti béèrè fún? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe wà lárọ̀ọ́wọ́tó tó ní èdè àwọn ènìyàn nígbà tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀?
NÍNÚ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pípabanbarì nípa àkókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba àti ti òpin ètò ìgbékalẹ̀ ògbólógbòó ti àwọn nǹkan, Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A óò sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Ó tún fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé: “Ẹ . . . máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ń béèrè fún iṣẹ́ púpọ̀ ní ti títúmọ̀ àti títẹ Bíbélì jáde, ní kíkọ́ àwọn ènìyàn ní ohun tí ó túmọ̀ sí, àti ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti lò ó nínú ìgbésí ayé wọn. Ẹ wo àǹfààní ńláǹlà tí ó jẹ́ láti nípìn-ín nínú irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀! Nígbà tí yóò fi di ọdún 1914, a ti tẹ Bíbélì jáde lódindi tàbí lápá kan ní 570 èdè. Ṣùgbọ́n, láti ìgbà náà wá, ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èdè àdúgbò ni a ti fi kún un, ọ̀pọ̀ èdè sì ní ju ẹyọ ìtumọ̀ kan lọ.a
2. Onírúurú ète wo ni ó ti nípa lórí iṣẹ́ àwọn olùtumọ̀ Bíbélì àti àwọn tí ó ṣe é jáde?
2 Ìpèníjà ni ó jẹ́ fún olùtumọ̀ èyíkéyìí láti mú kí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ kan ní èdè kan di èyí tí ó ṣeé lóye fún àwọn tí ń ka èdè kejì, tí wọ́n sì gbọ́ ọ. Àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan ti fi òye jíjinlẹ̀ gidigidi ṣe iṣẹ́ wọn, ní mímọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ń tú. Ìpèníjà ẹ̀kọ́ ìwé tí iṣẹ́ yìí ní nínú nìkan ni ó fa àwọn mìíràn mọ́ra. Wọ́n ti lè ka ohun tí ó wà nínú Bíbélì sí kìkì àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó ṣeyebíye. Fún àwọn kan, ìsìn ni iṣẹ́ ajé wọn, títẹ̀wé kan tí a kọ orúkọ wọn sí gẹ́gẹ́ bí olùtumọ̀ tàbí òǹtẹ̀wé jáde jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà jẹun. Ó hàn gbangba pé ète wọn ń nípa lórí ọwọ́ tí wọ́n fi ń mú iṣẹ́ wọn.
3. Ojú wo ni Ìgbìmọ̀ Atúmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun fi wo iṣẹ́ rẹ̀?
3 Gbólóhùn yí tí Ìgbìmọ̀ Atúmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun lò gba àfiyèsí: “Títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ túmọ̀ sí títú èrò àti àwọn àsọjáde Jèhófà Ọlọ́run . . . sí èdè míràn . . . Ìyẹn jẹ́ èrò tí ń múni ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀. Àwọn olùtumọ̀ ìwé yìí, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Olú Ọ̀run tí í ṣe Òǹṣèwé Ìwé Mímọ́, nímọ̀lára àkànṣe ẹrù iṣẹ́ sí I láti túmọ̀ àwọn èrò àti àwọn ìpolongo rẹ̀ lọ́nà pípéye bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Wọ́n tún nímọ̀lára ẹrù iṣẹ́ sí àwọn òǹkàwé tí ń ṣèwádìí tí wọ́n gbára lé ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ tí a mí sí tí í ṣe ti Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ fún ìgbàlà wọn ayérayé. Pẹ̀lú níní ẹrù iṣẹ́ tí ń múni ronú jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́kàn ni ó fi jẹ́ pé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìgbìmọ̀ àwọn ènìyàn olùfọkànsìn yìí fi mú Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures jáde.” Góńgó ìgbìmọ̀ náà ní láti ní ìtumọ̀ Bíbélì kan tí yóò ṣe kedere, tí yóò ṣeé lóye, tí yóò sì rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ èdè Hébérù àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ débi tí yóò fi pèsè ìpìlẹ̀ fún dídàgbà sí i nínú ìmọ̀ pípéye.
Ohun Tí Ó Ti Ṣẹlẹ̀ sí Orúkọ Ọlọ́run?
4. Báwo ni orúkọ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó nínú Bíbélì?
4 Ọ̀kan lára olórí ète Bíbélì ni láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run tòótọ́. (Ẹ́kísódù 20:2-7; 34:1-7; Aísáyà 52:6) Jésù Kristi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé kí orúkọ Bàbá rẹ̀ “di sísọ di mímọ́,” kí a bọ̀wọ̀ fún un, tàbí kí a fọwọ́ mímọ́ mú un. (Mátíù 6:9) Ọlọ́run mú kí orúkọ rẹ̀ gan-an wà nínú Bíbélì ní èyí tí ó ju ìgbà 7,000 lọ. Ó fẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ orúkọ yẹn àti ànímọ́ Ẹni tí ń jẹ́ orúkọ náà.—Málákì 1:11.
5. Ọ̀nà wo ni onírúurú olùtumọ̀ gbà gbé orúkọ àtọ̀runwá náà kalẹ̀?
5 Ọ̀pọ̀ àwọn olùtumọ̀ Bíbélì ti fi ọ̀wọ̀ àtọkànwá hàn fún orúkọ àtọ̀runwá náà, wọ́n sì ti lò ó léraléra nínú iṣẹ́ wọn. Àwọn olùtumọ̀ kan yan lílo Yahweh láàyò. Àwọn mìíràn ti yan ẹ̀yà orúkọ àtọ̀runwá tí a mú bá èdè wọn mu, níwọ̀n bí ó bá ti ṣe kedere pé ó bá ohun tí ó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù mu, bóyá èyí tí lílò ó fún ìgbà pípẹ́ ti mú kí a mọ̀ bí ẹní mowó. Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures lo Jèhófà nígbà 7,210 nínú ẹsẹ rẹ̀.
6. (a) Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, kí ni àwọn olùtumọ̀ ti ṣe sí àwọn ìtọ́kasí orúkọ àtọ̀runwá náà? (b) Báwo ni àṣà yí ṣe tàn kálẹ̀ tó?
6 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, bí àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kò tilẹ̀ yọ orúkọ àwọn ọlọ́run kèfèrí bíi Báálì àti Mólékì kúrò, ó túbọ̀ ń ṣẹlẹ̀ léraléra pé wọ́n ń yọ orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ náà gan-an kúrò nínú àwọn ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó mí sí. (Ẹ́kísódù 3:15; Jeremáyà 32:35) Nínú irú àyọkà bíi Mátíù 6:9 àti Jòhánù 17:6, 26, ìtumọ̀ kan tí a pín kiri lọ́nà gbígbòòrò ní èdè Albanian wulẹ̀ tú gbólóhùn èdè Gíríìkì náà fún “orúkọ ìwọ” (ìyẹn ni, orúkọ Ọlọ́run) sí “ìwọ,” bí ẹni pé àwọn ẹsẹ wọnnì kò tọ́ka sí orúkọ kankan. Nínú Orin Dáfídì 83:18, Bíbélì The New English Bible àti Today’s English Version yọ orúkọ Ọlọ́run gan-an àti ìtọ́kasí èyíkéyìí tí ó fi hàn pé Ọlọ́run ní orúkọ kan kúrò pátápátá. Bí orúkọ àtọ̀runwá náà tilẹ̀ fara hàn nínú ìtumọ̀ àtijọ́ ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ní èdè tí ó pọ̀ jù lọ, àwọn ìtumọ̀ tuntun sábà máa ń yọ ọ́ kúrò pátápátá tàbí kí wọ́n fi í sínú àlàyé etí ìwé. Bí ọ̀ràn ti rí nìyẹn ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, àti ní ọ̀pọ̀ èdè ní Europe, Áfíríkà, Gúúsù America, Íńdíà, àti àwọn erékùṣù Pásífíìkì.
7. (a) Itú wo ni àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan ní èdè Áfíríkà ti fi orúkọ àtọ̀runwá náà pa? (b) Kí ni èrò rẹ nípa ìyẹn?
7 Àwọn olùtumọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè Áfíríkà kan kò dá a mọ ní kékeré. Kàkà tí wọn yóò wulẹ̀ fi orúkọ oyè inú Ìwé Mímọ́ kan bí Ọlọ́run tàbí Olúwa rọ́pò orúkọ àtọ̀runwá náà, wọ́n ń fi àwọn orúkọ tí wọ́n wá láti inú àwọn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ rọ́pò rẹ̀. Nínú Bíbélì The New Testament and Psalms in Zulu (ìtẹ̀jáde ti 1986), a fi orúkọ ara ẹni kan (uMvelinqangi) tí àwọn Súlú gbà pé ó ń tọ́ka sí ‘baba ńlá kan tí a ń jọ́sìn nípasẹ̀ àwọn baba ńlá tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn’ rọ́pò orúkọ oyè náà, Ọlọ́run (uNkulunkulu). Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Bible Translator, ti October 1992, sọ pé nígbà tí iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lórí Bíbélì Lédè Chichewa tí a óò máa pè ní Buku Loyera, àwọn olùtumọ̀ ń lo Chauta gẹ́gẹ́ bí orúkọ gan-an ti yóò rọ́pò Jèhófà. Àpilẹ̀kọ náà ṣàlàyé pé, Chauta ni “Ọlọ́run tí wọ́n ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́, tí wọ́n sì ń jọ́sìn.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí tún ń jọ́sìn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó jẹ́ ẹ̀mí àwọn òkú. Òtítọ́ ha ni pé bí àwọn ènìyàn bá ń gbàdúrà sí “Ẹni Gíga Jù Lọ” kan, nígbà náà, orúkọ èyíkéyìí tí wọ́n bá ń lò fún “Ẹni Gíga Jù Lọ” náà yóò ṣe rẹ́gí dáradára pẹ̀lú orúkọ náà gan-an, Jèhófà, láìka ohunkóhun tí ìjọsìn wọn lè ní nínú sí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá! (Aísáyà 42:8; Kọ́ríńtì Kíní 10:20) Fífi ohun kan tí ń mú kí àwọn ènìyàn rò pé ìgbàgbọ́ àbáláyé wọn tọ̀nà ní tòótọ́ rọ́pò orúkọ Ọlọ́run gan-an, kì í jẹ́ kí àwọn ènìyàn sún mọ́ Ọlọ́run tòótọ́ náà pẹ́kípẹ́kí.
8. Èé ṣe tí a kò tí ì dabarú ète Ọlọ́run láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀?
8 Gbogbo èyí kò tí ì yí ète Jèhófà pa dà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò dabarú ète rẹ̀ láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀. Bíbélì tí ó ní orúkọ àtọ̀runwá náà nínú ṣì pọ̀ lọ jàra ní àwọn èdè Europe, Áfíríkà, àwọn ilẹ̀ America, Ìlà Oòrùn Ayé, àti àwọn erékùṣù òkun. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó lé ní 5,400,000 sì wà ní orílẹ̀ èdè àti ìpínlẹ̀ 233, tí wọ́n ń para pọ̀ ya wákàtí tí ó lé ní bílíọ̀nù kan lọ́dún sọ́tọ̀ láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ náà àti ète rẹ̀. Wọ́n ń tẹ Bíbélì—ọkàn tí ó lo orúkọ Ọlọ́run—jáde, wọ́n sì ń pín in kiri ní èdè tí nǹkan bí 3,600,000,000 olùgbé ayé ń sọ, títí kan Gẹ̀ẹ́sì, èdè Chinese, Russian, Spanish, Potogí, Faransé, àti Dutch. Wọ́n tún ń tẹ àwọn àrànṣe fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde ní àwọn èdè tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé ayé gbọ́. Láìpẹ́, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò gbégbèésẹ̀ lọ́nà kan tí yóò mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nímùúṣẹ délẹ̀délẹ̀, pé “wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé [òun] ni Jèhófà.”—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:23, NW.
Ìgbà Tí Èrò Ara Ẹni Nípa Lórí Ìtumọ̀
9. Báwo ni Bíbélì ṣe fi ẹrù iṣẹ́ bàǹtà banta tí ó já lé àwọn tí ń túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run léjìká hàn?
9 Ẹrù iṣẹ́ bàǹtà banta ni ó já lé àwọn tí ń túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn tí ń fi kọ́ni léjìká. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Àwa ti kọ àwọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tini lójú sílẹ̀ ní àkọ̀tán, a kò rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣe àbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ fífi òtítọ́ hàn kedere a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà olúkúlùkù ẹ̀rí ọkàn ẹ̀dá ènìyàn níwájú Ọlọ́run.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:2) Láti ṣe àbùlà túmọ̀ sí láti ṣàdàlù nǹkan nípa dída ohun tí ó yàtọ̀ sí i tàbí tí kì í ṣe ojúlówó pọ̀ mọ́ ọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò dà bí àwọn aláìṣòótọ́ olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì ní ọjọ́ Jeremáyà, tí Jèhófà bá wí nítorí pé wọ́n wàásù èrò ara wọn dípò ohun tí Ọlọ́run sọ. (Jeremáyà 23:16, 22) Ṣùgbọ́n kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ ní àkókò òde òní?
10. (a) Báwo ni àwọn ète tí ó yàtọ̀ sí ìdúróṣinsin sí Ọlọ́run ṣe nípa lórí àwọn olùtumọ̀ kan ní òde òní? (b) Ipò ta ni wọ́n gbà lọ́nà tí kò tọ́?
10 Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ìgbìmọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àti àwọn pásítọ̀ lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ìjọba Nazi ní Germany láti mú “Májẹ̀mú Tuntun” tí a tún ṣe, tí ó yọ gbogbo ìtọ́kasí bíbáradé tí a ṣe nípa àwọn Júù àti gbogbo ohun tí ó fi hàn pé ìran àwọn Júù ni Jésù Kristi ti wá sọ nù pátápátá, jáde. Láìpẹ́ yìí, àwọn olùtumọ̀ tí wọ́n mú Bíbélì The New Testament and Psalms: An Inclusive Version jáde tún gba ọ̀nà míràn yọ, ní sísakun láti yọ gbogbo ohun tí ó fi hàn pé àwọn Júù jẹ̀bi ikú Kristi sọ nù pátápátá. Àwọn olùtumọ̀ náà tún rò pé inú àwọn obìnrin òǹkàwé yóò dùn sí i bí a bá pe Ọlọ́run ní, Bàbá Òun Ìyá dípò Bàbá, tí a sì pe Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run dípò Ọmọkùnrin Ọlọ́run. (Mátíù 11:27) Bí wọ́n ti ń ṣe èyí, wọ́n yọ ìlànà ìtẹríba aya fún ọkọ àti ìgbọràn ọmọ sí òbí kúrò. (Kólósè 3:18, 20) Ó ṣe kedere pé àwọn tí wọ́n mú àwọn ìtumọ̀ wọnnì jáde kò ṣe irú ìpinnu tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe, láti má ṣe “ṣàbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Wọ́n ń gbàgbé ojúṣe olùtumọ̀, ní gbígba ipò òǹṣèwé, ní mímú àwọn ìwé tí ó lo orúkọ rere Bíbélì láti gbé èrò tiwọn lárugẹ jáde.
11. Báwo ni ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe forí gbárí pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ nípa ọkàn àti ikú?
11 Ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù fi ń kọ́ni ní gbogbogbòò pé ọkàn ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ ẹ̀mí, pé ó ń fi ẹran ara sílẹ̀ lẹ́yìn ikú, pé ó sì jẹ́ àìleèkú. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ọlọ́jọ́ pípẹ́ ní ọ̀pọ̀ jù lọ èdè sọ gbangba pé ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ ọkàn, pé ẹranko jẹ́ ọkàn, àti pé ọkàn ń kú. (Jẹ́nẹ́sísì 12:5; 36:6; Númérì 31:28; Jákọ́bù 5:20) Ìyẹn ti fi àwùjọ àlùfáà sínú ìdààmú.
12. Lọ́nà wo ni àwọn ìtumọ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ kan gbà fi àwọn òtítọ́ pàtàkì inú Bíbélì pa mọ́?
12 Wàyí o, àwọn ìtumọ̀ kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde fi àwọn òtítọ́ wọ̀nyí pa mọ́. Lọ́nà wo? Nínú àwọn ẹsẹ kan, wọ́n wulẹ̀ yẹra fún títúmọ̀ ọ̀rọ̀ orúkọ èdè Hébérù náà, neʹphesh (ọkàn), ní tààràtà. Nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:7, wọ́n lè sọ pé ọkùnrin àkọ́kọ́ “bẹ̀rẹ̀ sí í wà láàyè” (dípò “di alààyè ọkàn”). Tàbí kí wọ́n pe “ọkàn” ní “ẹ̀dá” nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ ẹranko. (Jẹ́nẹ́sísì 1:21) Nínú àwọn ẹsẹ bí Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4, 20, “ẹni” tàbí “ẹni náà” ni wọ́n sọ pé yóò kú, (dípò “ọkàn”). Ó ṣeé ṣe kí olùtumọ̀ wí àwíjàre fún lílo irú ìtumọ̀ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, báwo ni wọ́n ṣe ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ń fi gbogbo ọkàn wá òtítọ́ tó, àwọn tí ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ti nípa lórí ìrònú wọn?b
13. Lọ́nà wo ni àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan gbà fi ète Ọlọ́run nípa ilẹ̀ ayé pa mọ́?
13 Nínú ìsapá láti ti ìgbàgbọ́ wọn lẹ́yìn pé gbogbo ènìyàn rere ni yóò lọ sí ọ̀run, àwọn olùtumọ̀—tàbí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tí wọ́n yẹ iṣẹ́ wọn wò—tún lè sakun láti fi ohun tí Bíbélì sọ nípa ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé pa mọ́. Ní Orin Dáfídì 37:11, àwọn ìtumọ̀ mélòó kan kà pé, àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò jogún “ilẹ̀ náà.” “Ilẹ̀” jẹ́ ìtumọ̀ tí a lè lò fún ọ̀rọ̀ náà, (ʼeʹrets), tí a lò nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ṣùgbọ́n, Bíbélì Today’s English Version (tí ó ti jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ìtumọ̀ sí ọ̀pọ̀ èdè míràn) kò dá a mọ ní kékeré. Bí ìtumọ̀ yí tilẹ̀ tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, ge, sí “ilẹ̀ ayé” nígbà 17 nínú Ìhìn Rere Mátíù, nínú Mátíù 5:5 ó fi gbólóhùn náà, “ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí,” rọ́pò “ilẹ̀ ayé.” Àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì sábà máa ń rò pé ọ̀run ni èyí ń tọ́ka sí. A kò fún wọn ní ìsọfúnni aláìṣàbòsí pé Jésù Kristi, nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, sọ pé àwọn ọlọ́kàn tútù, oníwà tútù, tàbí àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóò “jogún ilẹ̀ ayé.”
14. Ète onímọtara-ẹni-nìkan wo ni ó hàn gbangba nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan?
14 Ó hàn gbangba pé a ṣe àwọn ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ kan kí àwọn oníwàásù baà lè rí owó oṣù tí ó jọjú gbà. Òtítọ́ ni pé Bíbélì sọ pé: “Aṣiṣẹ́ yẹ fún owó ọ̀yà rẹ̀.” (Tímótì Kíní 5:18) Ṣùgbọ́n nínú Tímótì Kíní 5:17, níbi tí a ti sọ pé àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣàbójútó lọ́nà rere “yẹ fún ọlá onílọ̀ọ́po méjì,” kìkì ọlá tí àwọn kan lára wọn rí bí èyí tí ó yẹ láti mẹ́nu kàn ni ti èyí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú owó. (Fi wé Pétérù Kíní 5:2.) Nípa báyìí, Bíbélì The New English Bible sọ pé “ó yẹ kí a ka” àwọn alàgbà wọ̀nyí “sí ẹni tí ó yẹ fun owó oṣù ìlọ́po méjì,” Bíbélì Contemporary English Version sì sọ pé wọ́n “yẹ fún ìlọ́po méjì iye tí wọ́n ń gbà.”
Fífi Ìdúróṣinṣin Gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lárugẹ
15. Báwo ni a ṣe lè pinnu ìtumọ̀ Bíbélì tí ó yẹ kí a ṣàyọlò?
15 Kí ni gbogbo èyí túmọ̀ sí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń ka Bíbélì àti fún àwọn tí ń lo Bíbélì láti fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́? Ní ọ̀pọ̀ èdè tí a ń sọ níbi gbogbo, ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ń bẹ tí a ti lè yan èyí tí a fẹ́. Lo ìfòyemọ̀ nínú ṣíṣàṣàyàn Bíbélì tí ìwọ yóò lò. (Òwe 19:8) Bí ìtumọ̀ kan bá ṣàbòsí nípa ẹni tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ jẹ́—ní yíyọ orúkọ rẹ̀ kúrò nínú Ọ̀rọ̀ tí ó mí sí láìka ohun yòó wù tí ó lè fà á sí—àwọn olùtumọ̀ náà kò ha ti lè tọwọ́ bọ àwọn apá mìíràn nínú ẹsẹ Bíbélì náà bí? Bí o bá ń ṣiyè méjì nípa bí ìtumọ̀ kan ti lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó, sakun láti fi í wé àwọn ìtumọ̀ tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀. Bí o bá jẹ́ olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yan àwọn ìtumọ̀ tí wọ́n rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ohun tí ó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ lédè Hébérù àti Gíríìkì láàyò.
16. Báwo ni gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe lè fi ìdúróṣinṣin wa hàn nínú ọ̀nà tí a gbà ń lo Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí?
16 Ó yẹ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa dídàníyàn gidigidi nípa ohun tí ó wà nínú rẹ̀, bí ó bá sì ṣeé ṣe, kí a lo àkókò díẹ̀ lójoojúmọ́ láti ka Bíbélì. (Orin Dáfídì 1:1-3) A ń ṣe èyí nípa lílo ohun tí ó sọ nínú ìgbésí ayé wa, ní kíkọ́ láti lo àwọn ìlànà àti àpẹẹrẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ṣíṣe ìpinnu tí ó yè kooro. (Róòmù 12:2; Hébérù 5:14) A ń fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin alágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa fífi ìtara wàásù rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, a tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìṣọ́ra lo Bíbélì, ní ṣíṣàìlọ́ ọ lọ́rùn tàbí fífẹ ohun tí ó sọ lójú láti bá èrò tiwa mu. (Tímótì Kejì 2:15) Ohun tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ yóò ṣẹ láìtàsé. Òun jẹ́ adúróṣinṣin ní ti mímú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ǹjẹ́ kí a lè jẹ́ adúróṣinṣin ní gbígbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lárugẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní 1997, Ìparapọ̀ Àwọn Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì gbé àkọsílẹ̀ 2,167 èdè àti èdè àdúgbò tí a ti tẹ Bíbélì jáde lódindi, tàbí lápá kan. Iye yìí ní ọ̀pọ̀ èdè àdúgbò ti àwọn èdè kan nínú.
b Ìjíròrò yí dá lórí àwọn èdè tí wọ́n lágbára láti mú kí ọ̀ràn náà ṣe kedere, ṣùgbọ́n tí àwọn olùtumọ̀ yàn láti má ṣe bẹ́ẹ̀. Ní àwọn èdè kan, bí ọ̀rọ̀ èdè ti pọ̀ tó ń ní ipa púpọ̀ lórí ohun tí àwọn olùtumọ̀ lè ṣe. Nítorí náà, àwọn aláìlábòsí olùkọ́ ìsìn yóò ṣàlàyé pé bí olùtumọ̀ tilẹ̀ lo onírúurú ọ̀rọ̀ tàbí tí ó lo ọ̀rọ̀ kan tí ó ní ìtumọ̀ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ọ̀rọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, neʹphesh, ni a lò fún ẹ̀dá ènìyàn àti ẹranko, ó sì dúró fún ohun kan tí ń mí, tí ń jẹun, tí ó sì lè kú.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Àwọn ète wo ni ó ti nípa lórí iṣẹ́ àwọn olùtumọ̀ Bíbélì ní òde òní?
◻ Èé ṣe tí àṣà ìtumọ̀ òde òní kò fi dabarú ète Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ̀?
◻ Báwo ni àwọn ìtumọ̀ kan ṣe fi òtítọ́ Bíbélì nípa ọkàn, ikú, àti ilẹ̀ ayé pa mọ́?
◻ Àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà fi hàn pé a ń fi ìdúróṣinṣin gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lárugẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìtumọ̀ Bíbélì wo ni ó yẹ kí o lò?