ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 10/1 ojú ìwé 21-25
  • Mo Dúpẹ́ Fún Àkókò Gígùn Tí Mo Lò Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Dúpẹ́ Fún Àkókò Gígùn Tí Mo Lò Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojú Ìwòye Ìsìn Nípa Lórí Mi
  • Ìdúró Mi fún Òtítọ́ Bíbélì
  • Iṣẹ́ Ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì
  • Mo Ní Ìgbọ́kànlé Nínú Ìrètí Ìjọba
  • Ìgbòkègbodò Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì
  • Ìgbòkègbodò Lákọ̀tun Lẹ́yìn Ogun
  • Ṣíṣe Ohun Tí Mo Lè Ṣe
  • Dídi Ìgbàgbọ́ Mú Títí Dé Òpin
  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìgbésí Ayé Alárinrin Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Gbogbo Èèyàn La Pè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 10/1 ojú ìwé 21-25

Mo Dúpẹ́ Fún Àkókò Gígùn Tí Mo Lò Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

GẸ́GẸ́ BÍ OTTILIE MYDLAND ṢE SỌ Ọ́

Ní apá ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn ọkọ̀ òkun máa ń tò lọ rẹrẹ ní èbúté Kopervik ní ìwọ̀ oòrùn Norway. Ní ayé ìgbà náà, àwọn ènìyàn àti ẹṣin máa ń fa ọkọ̀ káàkiri àwọn òpópónà. Fìtílà tí ń lo òróró ni àwọn ènìyàn máa ń tàn láti ríran, iná igi àti èédú ni a fi ń mú àwọn ilé onígi tí a fi ọ̀dà funfun kùn móoru. Ibẹ̀ ni a bí mi sí ní June 1898, èmi ni ọmọ kejì nínú àwa márùn-ún.

N Í 1905, Bàbá kò níṣẹ́ lọ́wọ́, nítorí náà, ó lọ sì United States. Ó darí dé ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà pẹ̀lú àpò ńlá tí ó kún fún àwọn ẹ̀bùn mèremère fún àwa ọmọ àti aṣọ ṣẹ́dà àti àwọn ohun mìíràn fún Màmá. Ṣùgbọ́n àwọn ìdìpọ̀ tí Charles Taze Russell ṣe, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Studies in the Scriptures, ni dúkìá rẹ̀ tí ó ṣeyebíye jù lọ.

Bàbá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ohun tí ó ti kọ́ nínú àwọn ìwé wọ̀nyí fún àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí. Ní àwọn ìpàdé ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò, ó lo Bíbélì láti fi hàn pé kò sí ọ̀run àpáàdì. (Oníwàásù 9:5, 10) Ní 1909, ọdún kejì tí Bàbá ti United States dé, Arákùnrin Russell ṣèbẹ̀wò sí Norway, ó sì sọ àsọyé ní Bergen àti Kristiania, tí a mọ̀ sí Oslo nísinsìnyí. Bàbá lọ sí Bergen láti lọ tẹ́tí sí i.

Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn fẹ̀sùn kan Bàbá pé ó ń gbé ẹ̀kọ́ èké lárugẹ. Àánú rẹ̀ ṣe mí, mo sì ràn án lọ́wọ́ láti pín àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú nípa Bíbélì fún àwọn aládùúgbò. Ní 1912, mo fún ọmọbìnrin àlùfáà kan ní ìwé àṣàrò kúkúrú lórí hẹ́ẹ̀lì. Ó bú èmi àti Bàbá. Ó yà mí lẹ́nu gidigidi pé ọmọ àlùfáà lè lo irú èdè rírùn bẹ́ẹ̀!

Àwọn Àkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míràn, orúkọ tí a ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà lọ́hùn-ún, máa ń bẹ̀ wá wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ní Kopervik, títí kan Theodor Simonsen, olùbánisọ̀rọ̀ dídáńgájíá kan. Mo máa ń ké sí àwọn ènìyàn wá sí àwọn àsọyé tí ó máa ń sọ ní ilé wa. Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, yóò ta zither, yóò sì kọrin, yóò sì kọrin àkọparí lẹ́yìn tí ó bá sọ àsọyé rẹ̀ tán. A ní ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ̀ fún un.

Anna Andersen, olùpín ìwé ìsìn kiri tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan, jẹ́ àlejò míràn tí ó máa ń ṣèbẹ̀wò sí ilé wa. Ó sábà máa ń fi kẹ̀kẹ́ ológeere rìnrìn àjò láti ìlú kan sí òmíràn jákèjádò Norway, ní fífi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì síta fún àwọn ènìyàn. Ó ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀gá nínú Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ìgbàlà, ó sì mọ àwọn ọ̀gá Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ìgbàlà díẹ̀ ní Kopervik. Wọ́n yọ̀ǹda fún un láti sọ àsọyé Bíbélì ní ilé tí wọ́n ti ń pàdé, mo sì ké sí àwọn ènìyàn láti wá tẹ́tí sí i.

Karl Gunberg jẹ́ olùpín ìwé ìsìn kiri mìíràn tí ó ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wa ní Kopervik. Ọkùnrin tí ó mẹ̀tọ́ mọ̀wà, ẹni jẹ́jẹ́, aláwàdà ènìyàn yí tún máa ń ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí olùtumọ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Oslo. A jọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà.

Ojú Ìwòye Ìsìn Nípa Lórí Mi

Nígbà náà lọ́hùn-ún, kì í ṣe pé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ní ìgbàgbọ́ lílágbára nípa Ọlọ́run àti Bíbélì nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún ní ìgbàgbọ́ lílágbára nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí ó ti jinlẹ̀ lọ́kàn wọn, irú bí ọ̀run àpáàdì àti Mẹ́talọ́kan. Nítorí náà, ó fa rúkèrúdò ńlá nígbà tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́ni pé àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ wọ̀nyí kò bá Bíbélì mu. Ẹ̀sùn burúkú tí àwọn aládùúgbò wa fi kan Bàbá pé ó jẹ́ aládàámọ̀ nípa lórí mi. Mo tilẹ̀ sọ fún un nígbà kan pé: “Ohun tí o fi ń kọ́ni kì í ṣe òtítọ́. Ẹ̀kọ́ àdámọ̀ ni!”

Ó rọ̀ mí pé: “Wá níhìn-ín Ottilie, kí o sì fojú ara rẹ rí ohun tí Bíbélì sọ.” Lẹ́yìn náà ó ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún mi. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ìgbọ́kànlé mi nínú rẹ̀ àti nínú ohun tí ó fi ń kọ́ni lágbára sí i. Ó rọ̀ mí láti ka àwọn ìwé Studies in the Scriptures, nítorí náà, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn 1914, mo máa ń jókòó sórí òkìtì tí ó dojú kọ ìlú náà láti kàwé.

Ní August 1914, àwọn ènìyàn ṣù jọ sí iwájú ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn àdúgbò láti kà nípa ìbẹ́sílẹ̀ Ogun Àgbáyé Kìíní. Bàbá sún mọ́bẹ̀, ó sì rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ó kígbe pé: “Ọlọ́run ṣeun o!” Ó lóye pé ogun tí ó bẹ́ sílẹ̀ náà jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí ó ti ń wàásù rẹ̀. (Mátíù 24:7) Nígbà náà lọ́hùn-ún, ọ̀pọ̀ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà gbọ́ pé àwọn yóò lọ sí ọ̀run láìpẹ́. Nígbà tí èyí kò wáyé, ìjákulẹ̀ bá àwọn kan.

Ìdúró Mi fún Òtítọ́ Bíbélì

Ní 1915, ní ọmọ ọdún 17, mo parí ẹ̀kọ́ mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì kan. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Ilé Ìṣọ́ déédéé. Ṣùgbọ́n ní ọdún 1918 ni a tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpàdé déédéé ní Kopervik. Ní ìbẹ̀rẹ̀, àwa márùn-ún péré ni a máa ń pésẹ̀. A máa ń ka àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society, irú bíi Studies in the Scriptures, a sì máa ń jíròrò àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà nípasẹ̀ ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Màmá máa ń sọ̀rọ̀ dáradára nípa Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn, òun kò di ọ̀kan lára wa.

Ní ọ́fíìsì tí mo ti ń ṣiṣẹ́, bẹ̀rẹ̀ láti 1918, mo di ojúlùmọ̀ Anton Saltnes, tí ó ṣeé ṣe fún mi láti ràn lọ́wọ́ láti di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo di akéde tí ń ṣe déédéé ní àkókò yí, mo sì ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ kan ní Bergen ní ọdún 1921.

Ní May 1925, a ṣe àpéjọ kan fún gbogbo ilẹ̀ Scandinavia ní Örebro, Sweden. Iye tí ó lé ní 500 ni ó wà níjokòó, títí kan Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society. Nǹkan bí 30 nínú wa wọ ọkọ̀ ojú irin tí a ti ṣètò fún wa láti Oslo.

A ṣèfilọ̀ nínú àpéjọ yìí pé a óò gbé Ọ́fíìsì Àríwá Europe kan kalẹ̀ sí Copenhagen, Denmark, láti bójú tó iṣẹ́ ìwàásù jákèjádò àwọn ilẹ̀ Scandinavia àti àwọn orílẹ̀-èdè Baltic. A yan William Dey, tí ó wá láti Scotland, láti bójú tó iṣẹ́ ìwàásù náà. A fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi, kò sì pẹ́ tí a fi bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Ọkùnrin Mẹ́ta ará Scotland. Ní ìbẹ̀rẹ̀, Arákùnrin Dey kò gbọ́ èdè ilẹ̀ Scandinavia èyíkéyìí, nítorí náà, yóò jókòó sí ọwọ́ ẹ̀yìn ní àwọn ìpàdé àti àpéjọ, yóò sì máa tọ́jú àwọn ọmọdé, kí àwọn òbí wọn baà lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí a ń sọ lórí pèpéle.

Ilé Ìṣọ́ March 1, 1925 (Gẹ̀ẹ́sì), jíròrò Ìṣípayá orí 12, ó sì ṣàlàyé pé orí yìí ní í ṣe pẹ̀lú ìbí Ìjọba Ọlọ́run, àti pé ìbí yìí ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run ní ọdún 1914. Ó ṣòro fún mi gidigidi láti lóye, nítorí náà mo ka àpilẹ̀kọ náà ní àkàtúnkà. Inú mi dùn gidigidi nígbà tí mo wá lóye rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

Nígbà tí a ṣe ìyípadà nínú òye tí a ní nípa kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì kan, àwọn kan kọsẹ̀, tí wọ́n sì fi àwọn ènìyàn Ọlọ́run sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà tí irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ bá ṣòro fún mi láti lóye, mo máa ń ka àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà ní àkàtúnkà láti lè lóye ọ̀nà tí a gbà ronú. Bí n kò bá lóye àlàyé tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe náà síbẹ̀síbẹ̀, mo máa ń dúró dé àlàyé síwájú sí i. Irú sùúrù bẹ́ẹ̀ ti mérè wá lọ́pọ̀ ìgbà.

Iṣẹ́ Ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, mo ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú ìwé ìṣirò owó, akọ̀wé, àti olùṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ìnáwó ìjọba ìbílẹ̀. Ní 1928, ẹni tí ń mójú tó àkọsílẹ̀ ìṣirò owó Society bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn, ó sì ní láti fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀. Níwọ̀n bí mo ti nírìírí nínú irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, a ké sí mi láti wá ṣe iṣẹ́ náà. Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsín Bẹ́tẹ́lì ní June 1928. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, Arákùnrin Dey máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wa, ó sì máa ń ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ìṣirò owó mi. Ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa tún mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù ní Oslo, níbi tí ó jẹ́ pé ìjọ kan ṣoṣo ni a ní níbẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún.

Díẹ̀ lára wa ran ìránṣẹ́ ìkówèéránṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, Arákùnrin Sakshammer, lọ́wọ́ láti di The Golden Age (tí a mọ̀ sí Jí! nísinsìnyí), àti láti kó wọn ránṣẹ́. Arákùnrin Simonsen àti Gunberg wà lára àwọn tí ó ràn wá lọ́wọ́. A gbádùn ara wa, a sì sábà máa ń kọrin bí a ti ń ṣiṣẹ́ lọ.

Mo Ní Ìgbọ́kànlé Nínú Ìrètí Ìjọba

Ní ọdún 1935, a wá lóye pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà kì í ṣe ẹgbẹ́ onípò kejì tí ń lọ sí ọ̀run. A kẹ́kọ̀ọ́ pé, kàkà bẹ́ẹ̀, ó dúró fún ẹgbẹ́ tí ó la ìpọ́njú ńlá já, tí ó sì ní àǹfààní gbígbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 7:9-14) Pẹ̀lú òye tuntun yìí, àwọn kan tí wọ́n ti nípìn-ín nínú jíjẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí wá mọ̀ pé ìrètí àwọn jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ṣíwọ́ jíjẹ ẹ́.

Bí n kò tilẹ̀ ṣiyè méjì rí nípa ìrètí ọ̀run tí mo ní, mo máa ń ronú lọ́pọ̀ ìgbà pé, ‘Èé ṣe tí Ọlọ́run fi nílò mi?’ Mo nímọ̀lára pé n kò yẹ fún àǹfààní ńlá bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí obìnrin jáńjálá, tí ó sì ń tijú, ó máa ń ṣòro fún mi láti ro ara mi gẹ́gẹ́ bí ọba, tí ń ṣàkóso pọ̀ pẹ̀lú Kristi nínú ọ̀run. (Tímótì Kejì 2:11, 12; Ìṣípayá 5:10) Ṣùgbọ́n, mo sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé “kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn alágbára” ni a pè, ṣùgbọ́n “Ọlọ́run . . . yan àwọn ohun aláìlera ayé, kí ó baà lè kó ìtìjú bá àwọn ohun tí ó lágbára.”—Kọ́ríńtì Kíní 1:26, 27.

Ìgbòkègbodò Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì

Ní April 9, 1940, àwọn ọmọ ogun Germany gbógun wọ Norway, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi gba orílẹ̀-èdè náà. Nítorí ogun náà, ọ̀pọ̀ dáhùn pa dà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba. Láti October 1940 sí June 1941, a fi ìwé ńlá àti ìwé pẹlẹbẹ tí ó lé ní 272,000 síta. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, ní ìpíndọ́gba, ọ̀kọ̀ọ̀kan Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó lé ní 470 nígbà náà lọ́hùn-ún ní Norway fi ìwé ńlá àti ìwé pẹlẹbẹ tí ó lé ní 570 síta, láàárín oṣù mẹ́sàn-án yẹn!

Ní July 8, 1941, Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ gbogbo alábòójútó olùṣalága, wọ́n sì sọ fún wọn pé, bí wọn kò bá fi òpin sí iṣẹ́ ìwàásù náà, a óò rán wọn lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Àwọn ọ̀gá ọlọ́pàá Germany márùn-ún wá sí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú ilé Watch Tower Society. Wọ́n mú ìdílé Bẹ́tẹ́lì lọ láti fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò, ṣùgbọ́n wọn kò fi èyíkéyìí nínú wa sẹ́wọ̀n. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ní July 21, 1941, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ilé Society tí ó wà ní Inkognitogaten 28 B, wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Mo pa dà sí Kopervik, mo sì wá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ṣe láti gbọ́ bùkátà mi.

Ní àkókò yẹn, Bàbá ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Ní ọjọ́ kan, àwọn Nazi wá, wọ́n sì tú ilé Bàbá. Wọ́n kó gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, títí kan àwọn Bíbélì rẹ̀ àti Bíbélì atọ́ka rẹ̀. Ìwọ̀nba oúnjẹ táṣẹ́rẹ́ nípa tẹ̀mí ni a ń rí gbà ní àkókò yí. Láti lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí, a ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé ògbólógbòó léraléra, irú bí ìwé Government, a sì ń bá a lọ láti wàásù.

Ó bani nínú jẹ́ pé, ní ọ̀pọ̀ ibi, àwọn arákùnrin kò fìmọ̀ ṣọ̀kan. Èrò àwọn kan ni pé kí a máa wàásù ní gbangba, kí a sì máa lọ láti ilé dé ilé, nígbà tí àwọn mìíràn ronú pé kí a túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ lábẹ́lẹ̀, ní kíkàn sí àwọn ènìyàn ní àwọn ọ̀nà míràn. Nípa báyìí, àwọn arákùnrin tí wọ́n mú ipò iwájú, tí wọ́n ti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáradára pẹ̀lú ara wọn tẹ́lẹ̀, tí a sì nífẹ̀ẹ́ gidigidi, ń bá ara wọn yandì. Ìpinyà tí ó wà láàárín wọn kó ìrora ọkàn bá mi ju ipò èyíkéyìí mìíràn nínú ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí lọ.

Ìgbòkègbodò Lákọ̀tun Lẹ́yìn Ogun

Lẹ́yìn ogun, ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1945, Arákùnrin Dey ṣèbẹ̀wò sí Norway, ó sì ṣèpàdé ní Oslo, Skien, àti Bergen. Ó jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún àwọn ará láti fọwọ́ wọ́nú, ó sì sọ pé kí gbogbo àwọn tí ó bá ń fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ dìde dúró. Gbogbo àwùjọ ni ó dìde dúró! Aáwọ̀ náà yanjú pátápátá ní December 1945, lẹ́yìn ìbẹ̀wò Nathan H. Knorr, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà.

Ṣáájú àkókò yẹn, ní July 17, 1945, mo gba wáyà kan láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ẹ̀ka, Arákùnrin Enok Öman, tí ó sọ pé: ‘Ìgbà wo ni o lè pa dà sí Bẹ́tẹ́lì?’ Àwọn kan sọ pé kí n dúró sílé, kí n tọ́jú bàbá mi, tí ó ti lé ní 70 ọdún nígbà náà. Ṣùgbọ́n, Bàbá fún mi níṣìírí láti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ní 1946, Marvin F. Anderson, arákùnrin kan láti United States, di alábòójútó ẹ̀ka wa, a sì tún ètò iṣẹ́ ìwàásù ṣe.

Nígbà ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, mo máa ń lọ sí Kopervik láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìdílé mi. Ẹ̀gbọ́n mi àti àwọn àbúrò mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kò di Ẹlẹ́rìí, ṣùgbọ́n wọ́n fẹ́ràn èmi àti Bàbá. Ẹ̀gbọ́n mi di ọ̀gá èbúté àti ọ̀gá ọkọ̀ òkun, àbúrò mi ọkùnrin sì di olùkọ́. Bí n kò tilẹ̀ rí jájẹ nípa ti ara, Bàbá máa ń sọ fún wọn pé: “Ottilie lọ́rọ̀ jù yín lọ.” Òtítọ́ sì ni! Ohun tí wọ́n ti kó jọ kò lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọrọ̀ tẹ̀mí tí mo ń gbádùn! Bàbá kú ní ẹni ọdún 78 ní 1951. Màmá ti kú ní ọdún 1928.

Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú ìgbésí ayé mi ni lílọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ti àwọn ènìyàn Jèhófà ní New York City ní ọdún 1953. Ní ọdún yẹn, pápá àgbáyé kọjá góńgó 500,000 akéde, àwọn ènìyàn tí ó sì wá sí àpéjọpọ̀ náà lé ní 165,000! Ṣáájú àpéjọpọ̀ ọdún 1953 náà, mo ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ kan ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn, orílé-iṣẹ́ ètò àjọ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé.

Ṣíṣe Ohun Tí Mo Lè Ṣe

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ẹbọ́ ojú kò jẹ́ kí n ríran dáradára mọ́. Mo ṣì lè ka àwọn ìwé gàdàgbàgàdàgbà díẹ̀díẹ̀ pẹ̀lú awò ojú lílágbára àti awò ìmú-nǹkan-tóbi sí i. Àwọn Kristẹni arábìnrin sì máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì máa ń kàwé sí mi létí ní ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀, mo sì dúpẹ́ gidigidi fún èyí.

Ìwọ̀nba ni mo lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn Kristẹni arábìnrin máa ń mú mi jáde nínú kẹ̀kẹ́ arọ mi lọ sí ibi tí mo ti lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù díẹ̀. Mo sì máa ń fi ìwé ìròyìn àti ìwé pẹlẹbẹ ránṣẹ́ déédéé sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ní Kopervik, irú bí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí mo lọ ní nǹkan bí 100 ọdún sẹ́yìn. Inú mi dùn pé mo ṣì lè jẹ́ akéde tí ó ń ṣe déédéé.

Mo dúpẹ́ pé yàrá ìjẹun àti Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní àjà kan náà tí yàrá mi wà ní Bẹ́tẹ́lì, tí a kọ́ sí Ytre Enebakk, lẹ́yìn Oslo, láti ọdún 1983. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe fún mi láti wá sí ìjọsìn òwúrọ̀, láti wá jẹun, àti láti wá sí àwọn ìpàdé wa pẹ̀lú ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀. Inú mi sì dùn pé mo ṣì lè lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ àti àwọn àpéjọ. Mo máa ń gbádùn ṣíṣalábàápàdé àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ti mọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tuntun, àti àwọn ọmọ dáradára.

Dídi Ìgbàgbọ́ Mú Títí Dé Òpin

Ìbùkún ńlá ni láti jẹ́ ẹni tí àwọn ènìyàn aláápọn, tí wọ́n dùn ún bá gbé, tí wọ́n sì jẹ́ ẹni tẹ̀mí rọ̀gbà yí ká ní Bẹ́tẹ́lì níhìn-ín. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì, ìdílé náà látòkè délẹ̀ jẹ́ àwọn tí wọ́n nírètí àtilọ sí ọ̀run. (Fílípì 3:14) Nísinsìnyí, gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní Bẹ́tẹ́lì fojú sọ́nà fún gbígbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, àyàfi èmi nìkan.

Òtítọ́ ni pé, a ti retí pé kí Jèhófà gbé ìgbésẹ̀ ṣáájú ìsinsìnyí. Síbẹ̀, ọkàn mi yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ sí rírí i tí àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń pọ̀ sí i. Ẹ wo irú ìbísí ńlá tí mo ti fojú rí! Nígbà tí mo lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́, nǹkan bí 5,000 akéde ni ó wà káàkiri àgbáyé. Nísinsìnyí, a lé ní 5,400,000! Ní tòótọ́, mo ti rí i tí “ẹni kékeré kan . . . di ẹgbẹ̀rún, àti kékeré kan di alágbára orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 60:22) A ní láti máa retí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí wòlíì Hábákúkù ti kọ̀wé pé: “Bí ó tilẹ̀ pẹ́, dúró dè é, nítorí ní dídé, yóò dé, kì yóò sì pẹ́.”—Hábákúkù 2:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́