ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 12/1 ojú ìwé 3-4
  • Kí ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ọ̀dọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ọ̀dọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Wọ́n Ti Yàtọ̀ Tó?
  • Ta Ni Ó Ni Ẹ̀bi?
  • Bí Ìgbà Èwe Rẹ Ṣe Lè Dùn Bí Oyin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Báwo Ni Ìsìn Ṣe Ń Jẹ Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́kàn Tó?
    Jí!—1998
  • Nígbà Tí Ìrètí àti Ìfẹ́ Bá Pòórá
    Jí!—1998
  • Wàhálà Tó Ń Báwọn Ọ̀dọ́ Òde Ìwòyí Fínra
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 12/1 ojú ìwé 3-4

Kí ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ọ̀dọ́?

ÌRÒYÌN rere tàbí ìròyìn búburú—èwo ni o kọ́kọ́ fẹ́ gbọ́? Nígbà tí a béèrè ìbéèrè yí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ yàn láti kọ́kọ́ gbọ́ ìròyìn búburú ná, ní ríretí pé ìròyìn rere ni yóò wà ní ọkàn wọn fún ìgbà pípẹ́.

Nígbà tí a ṣàyẹ̀wò ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọ̀dọ́, a kọ́kọ́ gbé ipò tí a ń rí lónìí yẹ̀ wò. Ní gbogbogbòò, àwọn àgbàlagbà máa ń ṣàròyé pé àwọn ọ̀dọ́ òde òní kò dàbí àwọn ọ̀dọ́ àtijọ́. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ kórìíra sísọ pé wọn kò kún ojú ìwọ̀n ọ̀pá ìdiwọ̀n àwọn ọdún tí ó ti kọjá sẹ́yìn. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ń kíyè sí ìran ènìyàn kínníkínní fohùn ṣọ̀kan pé àwọn èwe òde òní yàtọ̀ sí àwọn ti àtijọ́.

Báwo Ni Wọ́n Ti Yàtọ̀ Tó?

Bí àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò tilẹ̀ gbà gbọ́ pé ó yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ mọ̀wàáhù, kí wọ́n ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ti gidi yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé tí a mẹ́nu kàn wọ̀nyí. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé agbéròyìnjáde The Independent ti London, àwọn ọ̀dọ́ “ń mú ‘ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ tuntun’ dàgbà lòdì sí ayé kan tí wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ti já àwọn kulẹ̀ gan-an.” “Ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ tuntun” yìí jẹ yọ nínú àwárí tí a ṣe, tí ó fi hàn pé ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀dọ́ òde òní kò fẹ́ ka ara wọn sí “onílàákàyè àti ẹni tí ó ṣeé gbára lé.” Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fẹ́ ka ara wọn sí “ọmọọ̀ta àti ẹni tí kò ṣeé fọkàn tán.”

Fún àpẹẹrẹ, ní Britain, ìwà ọ̀daràn tí a ṣàkọsílẹ̀—tí èyí tí ó pọ̀ jù lọ jẹ́ láti ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́—lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́wàá láàárín 1950 sí 1993. Ìjoògùnyó àti ìmukúmu pẹ̀lú lọ sókè lọ́nà kan náà. Bákan náà, ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London, sọ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà ni ó ti rí “ìlọsókè kíkàmàmà nínú ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ tí ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà láàárín àwọn èwe ń mú wá láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí David J. Smith, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ òfin nípa ìwà ọ̀daràn, sọ, àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì wọ̀nyí “kò ní í ṣe pẹ̀lú òṣì tàbí ọrọ̀ rárá.” Ìwádìí fi hàn pé ìyàtọ̀ ńlá ń fara hàn kedere nísinsìnyí láàárín àwọn ọ̀dọ́ àti àgbàlagbà.

Àwọn ọmọdé àti àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ìgbà ọ̀dọ́langba ń dojú kọ másùnmáwo tí ń pọ̀ sí i lónìí. Àwọn ọ̀ràn ìṣekúpara-ẹni, tí a gbìdánwò tàbí tí a ṣe yọrí, ń ṣẹlẹ̀ káàkiri. Ìwé agbéròyìnjáde Herald ti Glasgow Scotland ròyìn pé, iye àwọn ọmọ tí kò tó ọmọ ọdún 12, tí ń gbìdánwò láti ṣekú pa ara wọn ti lọ́po lọ́nà méjì láàárín ohun tí kò tí ì pé ọdún mẹ́wàá. Àwọn ọmọ tí ó dàgbà jù wọ́n lọ ń jẹ́ kí àìnírètí sún wọn lọ sí ṣíṣe ohun kan náà. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Àwọn ìgbìdánwò láti para ẹni wọ̀nyí ni àbájáde lílékenkà tí ìṣòro ọpọlọ tí ń peléke sí i láàárín àwọn ọ̀dọ́ ń yọrí sí, ó sì ṣeé ṣe kí apá ìrànwọ́ tí a ń nà sí wọn máà ká a.”

Ta Ni Ó Ni Ẹ̀bi?

Ó rọrùn fún àwọn àgbàlagbà láti dá àwọn èwe lẹ́bi fún níní ojú ìwòye “oníyapa.” Síbẹ̀, ní ti tòótọ́, kì í ha ń ṣe àwọn àgbàlagbà ni ó ni ẹ̀bi tí ó pọ̀ jù fún ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí láàárín àwọn ọ̀dọ́ bí? A sábà máa ń mẹ́nu kan ìbúmọ́ni, àìbìkítà àwọn òbí, àìsí àwọn ẹni àwòkọ́ṣe tí àwọn èwe lè fọkàn tán, nígbà tí a bá ń ṣàlàyé ìdí tí àwọn èwe fi ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Alàgbà Michael Rutter, olóòtú Àjọ Ìwádìí Ìṣègùn Lórí Àìsàn Ọpọlọ Àwọn Ọmọdé ti Ilẹ̀ Britain, sọ pé: “Ìsoríkọ́ láàárín àwọn ará ìlú ní gbogbogbòò kò kọjá bí ó ṣe wà ní 30 ọdún sẹ́yìn.” Ó fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n, ó túbọ̀ ń peléke sí i láàárín àwọn ọ̀dọ́langba àti àgbàlagbà ọ̀dọ́. . . . Kò sí àní-àní pé ìforíṣánpọ́n ìdílé wà lára àwọn ohun tí ń fà á; kì í ṣe ìkọ̀sílẹ̀ lásán, bí kò ṣe àìnírẹ̀ẹ́pọ̀ àti ìforígbárí láàárín àwọn àgbàlagbà.”

Olùṣèwádìí kan sọ pé àwọn ọ̀dọ́ “ń kọ àwọn àṣà àtijọ́ sílẹ̀.” Èé ṣe? “Nítorí àwọn àṣà àtijọ́ náà kò wúlò fún wọn.” Fún àpẹẹrẹ, wo ojú ìwòye tí ó ń yí pa dà ní ti ànímọ́ ọkùnrin àti obìnrin. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin ń gba ìwà ọkùnrin ti fífínràn àti híhùwà ipá lò, nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin túbọ̀ ń fẹ́ sọ ara wọn di obìnrin. Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ tó sí àṣà àtijọ́!

Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí a fi ń rí irú àwọn ìyípadà tegbòtigaga bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí? Ìròyìn rere wo ni ó sì wà nípa àwọn ọ̀dọ́ lónìí? Báwo ni wọ́n ṣe lè ní ọjọ́ ọ̀la tí ó fọkàn ẹni balẹ̀? Àpilẹ̀kọ wa tí ó tẹ̀ lé e gbé ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́