ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 12/15 ojú ìwé 2-3
  • Kérésìmesì—Ọdún Ayé Tàbí Ọdún Ìsìn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kérésìmesì—Ọdún Ayé Tàbí Ọdún Ìsìn?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Burú Nínú Ọdún Kérésì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Orísun Kérésìmesì Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Keresimesi—Eeṣe Ti Ó Fi Gbajúmọ̀ Tobẹẹ ni Japan?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Kérésìmesì—Èé Ṣe Táwọn Ará Ìlà Oòrùn Ayé Pàápàá Fi Ń Ṣe É?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 12/15 ojú ìwé 2-3

Kérésìmesì—Ọdún Ayé Tàbí Ọdún Ìsìn?

NÍ China, a ń pè é ní Bàbá Arúgbó Kérésìmesì. Ní United Kingdom, a mọ̀ ọ́n sí Bàbá Kérésìmesì. Orúkọ tí àwọn ará Rọ́ṣíà ń pè é ni Bàbá Àgbà Yìnyín, a sì ń pè é ní Santa Claus ní United States.

Ọ̀pọ̀ ka bàbá arúgbó abikùn ńlá, onírùngbọ̀n yẹ́úkẹ́ fífunfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ẹlẹ́rìn-ín ẹ̀yẹ yìí sí ẹni tí ó dúró fún Kérésìmesì gan-an. Ṣùgbọ́n ohun tí gbogbo ènìyàn ti mọ̀ ni pé ìtàn àròsọ lásán ni Bàbá Kérésìmésì jẹ́, ìtàn àtẹnudẹ́nu tí a gbé karí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀bù Myra (ní Turkey òde òní) ti ọ̀rúndún kẹrin.

Àṣà àti ìṣẹ̀dálẹ̀ ti fìgbà gbogbo nípa ńláǹlà lórí àwọn ayẹyẹ, èyí kò sì yọ Kérésìmesì sílẹ̀. Ìtàn àròsọ nípa Bàbá Kérésì wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan ṣoṣo nínú ìtàn ìṣẹ̀ǹbáyé tí a so mọ́ ọdún kan tí ó gbajúmọ̀. Bí ọ̀pọ̀ tilẹ̀ ń sọ pé a gbé àwọn àṣà Kérésìmesì karí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sínú Bíbélì, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àṣà wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà.

Àpẹẹrẹ kan ni ti igi Kérésìmesì. Ìwé gbédègbéyọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Lẹ́yìn tí wọ́n di ẹlẹ́sìn Kristẹni, igi bíbọ, tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ará Yúróòpù abọ̀rìṣà, ń bá a lọ nínú àṣà àwọn ará Scandinavia ti fífi ewéko tútù ṣe ilé àti abà lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà Ọdún Tuntun láti lé èṣù jìnnà àti láti gbé igi tí àwọn ẹyẹ yóò máa bà lé kalẹ̀ lákòókò Kérésìmesì.”

Ṣíṣe igi holly tàbí àwọn ewéko tútù míràn lọ́ṣọ̀ jẹ́ àṣà olókìkí mìíràn nígbà Kérésìmesì. Èyí pẹ̀lú pilẹ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn abọ̀rìṣà. Àwọn ará Róòmù ìgbàanì ń lo àwọn ẹ̀ka igi holly láti ṣe tẹ́ńpìlì wọn lọ́ṣọ̀ọ́ nígbà ayẹyẹ Saturnalia, ayẹyẹ ọlọ́jọ́ méje nígbà òtútù, tí a yà sọ́tọ̀ fún Saturn, ọlọ́run iṣẹ́ àgbẹ̀. Ayẹyẹ àwọn abọ̀rìṣà yí ni a mọ̀ dáradára mọ́ àríyá aláriwo àti ìwà pálapàla rẹ̀ tí kò ṣeé ṣàkóso.

Àṣà Kérésìmesì ti fífẹnukonu lábẹ́ ẹ̀ka igi àfòmọ́ (tí a yàwòrán rẹ̀ síhìn-ín) lè dà bí ọ̀ràn ìfẹ́ lójú àwọn kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń ránni létí Sànmánì Agbedeméjì. Àwọn Druid ti Britain ìgbàanì gbà gbọ́ pé igi àfòmọ́ ní agbára idán; nítorí náà, wọ́n ń lò ó fún ìdáàbòbò kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù, èèdì, àti oríṣi nǹkan ibi mìíràn. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ìgbàgbọ́ asán náà jẹ yọ pé fífẹnukonu lábẹ́ igi àfòmọ́ yóò yọrí sí ìgbéyàwó. Àṣà yí ṣì wọ́pọ̀ láàárín àwọn kan nígbà Kérésìmesì.

Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ Kérésìmesì òde òní tí ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà ti nípa lé lórí tàbí tí ó pilẹ̀ láti inú wọn ní tààràtà. Ṣùgbọ́n, o lè ṣe kàyéfì nípa bí gbogbo èyí ṣe bẹ̀rẹ̀. Báwo ni ọdún kan tí a sọ pé ó ń bọlá fún ìbí Kristi ṣe wá di èyí tí a yí pọ̀ mọ́ àwọn àṣà tí kì í ṣe ti àwọn Kristẹni? Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ọ̀ràn náà?

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ojú ìwé 3: Bàbá Kérésìmesì: Thomas Nast/Dover Publications, Inc., 1978; ẹ̀ka igi àfòmọ́ lójú ìwé 3 àti àwòrán lójú ìwé 4: Discovering Christmas Customs and Folklore láti ọwọ́ Margaret Baker, tí Shire Publications tẹ̀ jáde, ní 1994

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́