Wọn Kò Ṣe Orúkọ Lílókìkí fún Ara Wọn
BÍBÉLÌ kò dárúkọ àwọn tí ó kọ́ ilé gogoro Bábélì tí ó lókìkí burúkú. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Wọ́n sọ wàyí pé: ‘Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú ńlá kan dó fún ara wa kí a sì tún kọ́ ilé gogoro tí téńté rẹ̀ dé ọ̀run, ẹ sì jẹ́ kí a ṣe orúkọ lílókìkí fún ara wa, kí a má bàa tú ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.’”—Jẹ́nẹ́sísì 11:4.
Ta ni “wọ́n”? Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní nǹkan bí 200 ọdún lẹ́yìn Ìkún Omi. Nígbà yẹn, Nóà, tí ó ti tó ẹni 800 ọdún, ń gbé láàárín ẹgbẹẹgbẹ̀rún àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Èdè kan náà ni gbogbo wọn ń sọ, wọ́n sì ń gbé pa pọ̀ ní àgbègbè kan náà tí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀ dó lẹ́yìn Ìkún Omi. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Ní àkókò kan, apá kan nínú ọ̀pọ̀ olùgbé yìí ṣí lọ sí ìhà ìlà oòrùn, wọ́n sì “ṣàwárí pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì kan ní ilẹ̀ Ṣínárì.”—Jẹ́nẹ́sísì 11:2.
Ìjákulẹ̀ Pátápátá
Àfonífojì yìí ni àwùjọ náà ti pinnu láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Tóò, Jèhófà Ọlọ́run ti sọ ète rẹ̀ di mímọ̀ nígbà tí ó pàṣẹ fún tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ láti “máa so èso, kí [wọ́n] sì di púpọ̀, kí [wọ́n] sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ó tún èyí sọ fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn Ìkún Omi. Ọlọ́run fún wọn nítọ̀ọ́ni pé: “Ní tiyín, ẹ máa so èso kí ẹ sì di púpọ̀, ẹ máa gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ ayé kí ẹ sì di púpọ̀ nínú rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:7) Ní títako àṣẹ Jèhófà, àwọn ènìyàn náà tẹ ìlú ńlá kan dó kí wọ́n má “bàa tú ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé gogoro láti lè ṣe “orúkọ lílókìkí” fún ara wọn. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn náà bẹ́yìn yọ, wọn kò parí kíkọ́ ilé gogoro náà. Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé Jèhófà da èdè wọn rú, kí wọ́n má bàa gbọ́ ara wọn yé mọ́. Àkọsílẹ̀ onímìísí náà sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ Jèhófà tú wọn ká kúrò níbẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n sì dẹ́kun títẹ ìlú ńlá náà dó.”—Jẹ́nẹ́sísì 11:7, 8.
Òtítọ́ náà pé orúkọ àwọn kọ́lékọ́lé náà kò di ‘èyí tí ó lókìkí,’ tàbí èyí tí a mọ̀ níbi gbogbo mú kí ìforíṣánpọ́n ìdáwọ́lé yìí ṣe kedere. Ní tòótọ́, a kò mọ orúkọ wọn, wọ́n sì ti parẹ́ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Ṣùgbọ́n Nímírọ́dù, àtọmọdọ́mọ Nóà ńkọ́? Kì í ha í ṣe òun ni òléwájú nínú ìṣọ̀tẹ̀ yìí sí Ọlọ́run? A kò ha mọ orúkọ rẹ̀ níbi gbogbo bí?
Nímírọ́dù—Ọlọ̀tẹ̀ Aláfojúdi
Kò sí iyèméjì pé Nímírọ́dù ní olórí wọn. Jẹ́nẹ́sísì orí 10 pè é ní “ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 10:9) Ìwé Mímọ́ tún sọ pé “ó bẹ̀rẹ̀ dídi alágbára ńlá ní ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 10:8) Jagunjagun ni Nímírọ́dù, ẹ̀dá oníjàgídíjàgan sì ni. Òun ni alákòóso ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ lẹ́yìn Ìkún Omi, ó yan ara rẹ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí ọba. Nímírọ́dù tún jẹ́ kọ́lékọ́lé. Bíbélì sọ pé ó tẹ ìlú ńlá mẹ́jọ dó, títí kan Bábélì.—Jẹ́nẹ́sísì 10:10-12.
Nítorí náà, kò sí iyèméjì pé Nímírọ́dù—aṣòdì sí Ọlọ́run, ọba Bábélì, àti ẹni tí ó tẹ àwọn ìlú ńlá dó—lọ́wọ́ nínú kíkọ́ ilé gogoro Bábélì. Òun kò ha ṣe orúkọ lílókìkí fún ara rẹ̀ bí? Nípa orúkọ náà, Nímírọ́dù, Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú àṣà àwọn Ará Ìlà-Oòrùn, E. F. C. Rosenmüller, kọ̀wé pé: “Láti inú [ma·radhʹ], tí ó túmọ̀ sí ‘ó ṣọ̀tẹ̀,’ ‘ó mọ̀ọ́mọ̀ yapa,’ ní èdè Hébérù, ni Nímírọ́dù ti gba orúkọ rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, Rosenmüller ṣàlàyé pé “ó jẹ́ àṣà àwọn Ará Ìlà-Oòrùn láti máa pe àwọn ọ̀tọ̀kọ̀lú wọn ní orúkọ tí a sọ wọ́n lẹ́yìn ikú wọn, èyí tí ó máa ń fa ìbáramu yíyanilẹ́nu nígbà mìíràn láàárín orúkọ wọn àti ohun tí wọ́n ṣe.”
Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ní ojú ìwòye náà pé kì í ṣe Nímírọ́dù ni orúkọ àbísọ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kà á sí orúkọ tí a fún un lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti bá ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀ mu, lẹ́yìn tí ó hàn sójútáyé. Fún àpẹẹrẹ, C. F. Keil sọ pé: “Orúkọ náà fúnra rẹ̀, Nímírọ́dù, tí ó wá láti inú ọ̀rọ̀ náà, [ma·radhʹ], ‘a óò ṣọ̀tẹ̀,’ ń tọ́ka sí àwọn ìwà ipá kan láti ṣòdì sí Ọlọ́run. Ó bá ìwà rẹ̀ mu tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé kìkì àwọn alájọgbáyé rẹ̀ nìkan ni ó lè fún un ní orúkọ náà, tí ó sì tipa báyìí di orúkọ rẹ̀.” Nínú àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé kan, Keil ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé òpìtàn Jacob Perizonius kọ pé: “Mo gbà gbọ́ pé, láti lè ru ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ sókè nínú àwọn yòókù, ọkùnrin yìí [Nímírọ́dù], gẹ́gẹ́ bí ọdẹ ẹhànnà tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀gbà yí ká, máa ń fìgbà gbogbo sọ ọ̀rọ̀ náà jáde pé ‘nímírọ́dù, nímírọ́dù,’ ìyẹn ni pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a ṣọ̀tẹ̀! Ẹ jẹ́ kí a ṣọ̀tẹ̀!’ Nítorí náà, nígbà tí ó yá, àwọn ẹlòmíràn, àní Mósè pàápàá, sọ ọ̀rọ̀ yẹn di orúkọ rẹ̀ gan-an.”
Ó ṣe kedere pé, Nímírọ́dù kò ṣe orúkọ lílókìkí fún ara rẹ̀. Ó hàn gbangba pé a kò mọ orúkọ àbísọ rẹ̀ gan-an. Ó ti parẹ́ nínú ìtàn, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣe parẹ́. Kò tilẹ̀ fi ọmọ kankan sílẹ̀ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ̀. Kàkà tí yóò fi gba ògo àti òkìkí, ó pòfo pátápátá. Orúkọ náà, Nímírọ́dù, yóò máa fi í hàn títí ayérayé gẹ́gẹ́ bí ọlọ̀tẹ̀ aláfojúdi tí ó fi ìwà òmùgọ̀ pe Jèhófà Ọlọ́run níjà.