ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 12
  • Àwọn Èèyàn Kọ́ Ilé Gogoro

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Èèyàn Kọ́ Ilé Gogoro
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọn Kò Ṣe Orúkọ Lílókìkí fún Ara Wọn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ilé Gogoro Bábélì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ṣé “Ilé Gogoro Bábélì” Ni Èdè Wa Ti Bẹ̀rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 12
Àwọn tó ń kọ́lé ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ síra wọn, wọn ò sì gbọ́ra wọn yé

ÌTÀN 12

Àwọn Èèyàn Kọ́ Ilé Gogoro

Ọ̀PỌ̀ ọdún ti kọjá. Àwọn ọmọ Nóà ti bí ọmọ rẹpẹtẹ. Àwọn ọmọ tiwọn náà sì tún bí ọ̀pọ̀ ọmọ sí i nígbà tí wọ́n dàgbà. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn èèyàn di púpọ̀ láyé.

Ọ̀kan nínú àwọn èèyàn wọ̀nyí ni ọmọ-ọmọ ọmọ Nóà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nímírọ́dù. Èèyàn búburú ni Nímírọ́dù, ó máa ń dọdẹ ẹranko àtèèyàn ó sì máa ń pa wọ́n. Nímírọ́dù tún sọ ara rẹ̀ di ọba lórí àwọn èèyàn tó kù. Inú Ọlọ́run kò dùn sí Nímírọ́dù.

Ilé gogoro Bábélì

Èdè kan ṣoṣo ni gbogbo èèyàn máa ń sọ nígbà náà. Nímírọ́dù fẹ́ kí gbogbo wọn wà lójú kan kó lè máa jọba lé wọn lórí. Nítorí náà, ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣe? Ó sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n dá ìlú ńlá kan sílẹ̀ kí wọ́n sì kọ́ ilé gogoro sínú rẹ̀. Bíríkì tí wọ́n máa fi kọ́ ilé náà lò ń wò tí wọ́n ń mọ nínú àwòrán yìí.

Inú Jèhófà Ọlọ́run ò dùn sí ilé tí wọ́n ń kọ́ yìí. Ńṣe ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn náà tú ká kí wọ́n sì máa gbé ibi gbogbo láyé. Ṣùgbọ́n ohun táwọn èèyàn náà sọ ni pé: ‘Ẹ wá! Ẹ jẹ́ ká dá ìlú ńlá kan sílẹ̀ ká sì mọ ilé gogoro kan tí orí rẹ̀ yóò kan ọ̀run. Àwa yóò sì di olókìkí!’ Ara wọn ni àwọn èèyàn náà fẹ́ fi èyí gbé ga kì í ṣe Ọlọ́run.

Nítorí náà, Ọlọ́run mú kí wọ́n ṣíwọ́ kíkọ́ ilé gogoro náà. Ǹjẹ́ o mọ bó ṣe ṣe é? Ó mú kí àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi èdè lójijì, dípò kí wọ́n máa sọ èdè kan ṣoṣo. Ni àwọn mọlé-mọlé ò bá gbọ́ èdè ara wọn mọ́. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi ń pe orúkọ ìlú náà ní Bábélì, tàbí Bábílónì, èyí tó túmọ̀ sí “Ìdàrúdàpọ̀.”

Àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi Bábélì sílẹ̀. Àwọn tí wọ́n bá rí i pé àwọn gbọ́ èdè ara àwọn á kóra jọ, wọ́n á sì lọ máa gbé apá ibòmíràn ní ayé.

Jẹ́nẹ́sísì 10:1, 8-10; 11:1-9.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́