Ẹ̀KỌ́ 7
Ilé Gogoro Bábélì
Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi omi pa àwọn èèyàn búburú run, àwọn ọmọ Nóà bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ, àwọn ọmọ wọn sì pọ̀ gan-an. Bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tàn káàkiri ayé. Ohun tí Jèhófà sì fẹ́ kí wọ́n ṣe nìyẹn.
Ṣùgbọ́n, àwọn kan wà lára àwọn èèyàn náà tí kò ṣègbọràn sí Jèhófà. Wọ́n sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká kọ́ ìlú ńlá kan síbí, ká sì máa gbé ibẹ̀. A máa kọ́ ilé gogoro kan, tó máa ga gan-an tí orí ẹ̀ sì máa kan ọ̀run. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á mọ̀ wá níbi gbogbo.’
Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́lé nìyẹn, àmọ́ inú Jèhófà ò dùn sóhun táwọn èèyàn yẹn ń ṣe, torí náà Jèhófà dá iṣẹ́ yẹn dúró. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn? Jèhófà mú kí wọ́n máa sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lójijì, nǹkan yí pa dà, wọn ò gbọ́ èdè ara wọn mọ́, bó ṣe di pé wọn ò lè kọ́ ilé náà mọ́ nìyẹn. Orúkọ ìlú tí wọ́n ń kọ́ nígbà yẹn la wá mọ̀ sí Bábélì, tó túmọ̀ sí “Ìdàrúdàpọ̀.” Àwọn èèyàn náà tú ká, wọ́n sì lọ ń gbé níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ káàkiri ayé. Àmọ́, ìwà burúkú tó ti mọ́ wọn lára náà ni wọ́n ń hù ní gbogbo ibi tí wọ́n lọ. Ṣé gbogbo èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn ló ń hùwà burúkú àbí àwọn kan wà tó ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà? Inú orí tó kàn la ti máa mọ̀.
“Gbogbo ẹni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”—Lúùkù 18:14