Ìwọ Ha Rántí Bí?
Àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti ẹnu àìpẹ́ yìí ha ti ràn ọ́ lọ́wọ́ gidigidi bí? Nígbà náà, èé ṣe tí o kò ṣe fi àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí dán agbára ìrántí rẹ wò?
◻ Kí ni ìyàtọ̀ láàárín “ọjọ́ Olúwa” àti “ọjọ́ Jèhófà”? (Ìṣípayá 1:10; Jóẹ́lì 2:11)
“Ọjọ́ Olúwa” ní ìmúṣẹ àwọn ìran 16 tí a ṣàpèjúwe nínú Ìṣípayá orí 1 sí 22 àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdáhùn sí ìbéèrè àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀, nínú. Gẹ́gẹ́ bí òtéńté ọjọ́ Olúwa, ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà yóò dé, nígbà tí ó bá mú ìdájọ́ ṣẹ sórí ayé oníbàjẹ́ ti Sátánì. (Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:11)—12/15, ojú ìwé 11.
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn apá títayọlọ́lá ti Bíbélì Makarios?
Orúkọ náà, Jèhófà, fara hàn ju ìgbà 3,500 lọ nínú Bíbélì Makarios. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú ìwé ìsìn ilẹ̀ Rọ́ṣíà sọ pé: “Ìtumọ̀ [náà] rọ̀ pinpin mọ́ èyí tí ó ti wà ní èdè Hébérù, ọ̀rọ̀ inú ìtumọ̀ rẹ̀ kò lábùlà, ó sì bá kókó ọ̀rọ̀ mu.”—12/15, ojú ìwé 27.
◻ Kí ni “òtítọ́” tí Jésù sọ pé yóò dá wa sílẹ̀ lómìnira? (Jòhánù 8:32)
Nípa “òtítọ́,” Jésù ń sọ nípa ìsọfúnni tí Ọlọ́run mí sí—pàápàá ìsọfúnni tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọ́run—tí a pa mọ́ nínú Bíbélì.—1/1, ojú ìwé 3.
◻ Àwọn wo ni Jéhù àti Jèhónádábù òde òní?
Jéhù ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi, tí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ń ṣojú fún lórí ilẹ̀ ayé. (Gálátíà 6:16; Ìṣípayá 12:17) Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhónádábù ti jáde wá pàdé Jéhù, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” láti inú àwọn orílẹ̀-èdè ti jáde wá láti ran àwọn aṣojú Jésù lórí ilẹ̀ ayé lọ́wọ́. (Ìṣípayá 7:9, 10; 2 Àwọn Ọba 10:15)—1/1, ojú ìwé 13.
◻ Kí ni ‘bíbá Ọlọ́run rìn’ túmọ̀ sí? (Jẹ́nẹ́sísì 5:24; 6:9)
Èyí túmọ̀ sí pé àwọn tí ń ṣe bẹ́ẹ̀, bí Énọ́kù àti Nóà, hùwà lọ́nà kan tí ó fẹ̀rí hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ lílágbára nínú Ọlọ́run. Wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún wọn, wọ́n sì gbé ìgbésí ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀, láti inú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú aráyé.—1/15, ojú ìwé 13.
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ẹnì kan wéwèé ṣáájú fún ṣíṣeé ṣe rẹ̀ láti kú?
Ní ọ̀nà kan, ṣíṣe irú ètò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn kan fún ìdílé ẹni. Ó fi ìfẹ́ hàn. Ó fẹ̀rí hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ọkàn láti ‘pèsè fún àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé ẹni,’ àní nígbà tí a kò sí pẹ̀lú wọn mọ́ pàápàá. (1 Tímótì 5:8)—1/15, ojú ìwé 22.
◻ Kí ni “májẹ̀mú láéláé” ṣàṣeparí rẹ̀? (2 Kọ́ríńtì 3:14)
Ó ṣàpẹẹrẹ májẹ̀mú tuntun, pẹ̀lú àwọn ìrúbọ rẹ̀ tí a ń ṣe lemọ́lemọ́, ó fi hàn pé ènìyàn nílò ìràpadà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú lójú méjèèjì. Ó jẹ́ “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ . . . tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.” (Gálátíà 3:24)—2/1, ojú ìwé 14.
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni májẹ̀mú tuntun gbà jẹ́ àìnípẹ̀kun? (Hébérù 13:20)
Lákọ̀ọ́kọ́, láìdàbí májẹ̀mú Òfin, a kò lè fi òmíràn rọ́pò rẹ̀. Èkejì, ìyọrísí iṣẹ́ rẹ̀ wà pẹ́ títí. Ẹ̀kẹta, àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé yóò máa jàǹfààní nìṣó láti inú ìṣètò májẹ̀mú tuntun náà wọnú Ẹgbẹ̀rúndún.—2/1, ojú ìwé 22.
◻ Àwọn àǹfààní wo ni ó ń tinú mímoore wá?
Ọ̀yàyà tí ẹnì kan ń gbádùn, nítorí pé ó moore nínú ọkàn àyà rẹ̀, ń fi kún ayọ̀ àti àlàáfíà tó ní. (Fi wé Òwe 15:13, 15.) Nítorí pé ìmoore jẹ́ ànímọ́ rere, ó ń dáàbò bo ẹni lọ́wọ́ àwọn ìmọ̀lára búburú bí ìbínú, owú, àti ìkórìíra.—2/15, ojú ìwé 4.
◻ Inú àwọn májẹ̀mú wo ni a ti mú àwọn tí a fi ẹ̀mí bí wọ̀?
Májẹ̀mú tuntun, tí Jèhófà dá pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà Ísírẹ́lì tẹ̀mí, àti májẹ̀mú fún Ìjọba, tí Jésù dá pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí a fòróró yàn, tí wọ́n ń tọ ipasẹ̀ rẹ̀. (Lúùkù 22:20, 28-30)—2/15, ojú ìwé 16.
◻ Àwọn àjọyọ̀ ńlá mẹ́ta wo ni a pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ṣe?
Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú, tí ń wáyé kété lẹ́yìn Ìrékọjá Nísàn 14; Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀, tí ń ṣẹlẹ̀ ní àádọ́ta ọjọ́ lẹ́yìn Nísàn 16; àti Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé, tàbí Àjọyọ̀ Àtíbàbà, tí ń wáyé ní oṣù keje. (Diutarónómì 16:1-15)—3/1, ojú ìwé 8, 9.
◻ Èé ṣe tí ó fi jẹ́ àǹfààní láti lọ sí àwọn ìpéjọpọ̀ Kristẹni?
Jésù sọ pé: “Níbi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọpọ̀ sí ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàárín wọn.” (Mátíù 18:20; 28:20) Àti pé, ọ̀nà pàtàkì kan tí a ń gbà fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ wa ni nípasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ àti àwọn àpéjọ ńlá. (Mátíù 24:45)—3/1, ojú ìwé 14.
◻ Kí ni orírun orúkọ náà, Nímírọ́dù?
Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ní ojú ìwòye náà pé kì í ṣe Nímírọ́dù ni orúkọ àbísọ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kà á sí orúkọ tí a fún un lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti bá ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀ mu, lẹ́yìn tí ó hàn sójútáyé.—3/15, ojú ìwé 25.
◻ Báwo ni ìdílé ṣe ṣe pàtàkì tó fún àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn?
Ìdílé jẹ́ ohun kòṣeémánìí fún ẹ̀dá ènìyàn. Ìtàn fi hàn pé bí ètò ìdílé ṣe ń díbàjẹ́, ni okun ẹgbẹ́ àwùjọ àti ti orílẹ̀-èdè ń yìnrìn. Nítorí náà, ìdílé ní ipa tààràtà lórí ìdúró déédéé àwùjọ àti ire àwọn ọmọ àti ti ìran ọjọ́ iwájú.—4/1, ojú ìwé 6.
◻ Àwọn ẹ̀rí mẹ́ta pàtàkì wo ni ó wà pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
(1) Ó péye ní ti sáyẹ́ǹsì; (2) ó kún fún àwọn ìlànà tí kò mọ sí sáà kan, tí ó wúlò fún ìgbésí ayé òde òní; (3) ó kún fún àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtó tí ó ti nímùúṣẹ, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìtàn ti fi hàn.—4/1, ojú ìwé 15.